29 Oṣù Kejìlá sí 4 Oṣù Kínní. Májẹ̀mú Kínní ti Jésù Krístì: Ọ̀rọ̀-ìṣaájú sí Májẹ̀mú Láéláé,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Ọ̀rọ̀-ìṣaájú sí Májẹ̀mú Láéláé,” Wá Tẹ̀lé Mi: 2026
29 Oṣù Kejìlá sí 4 Oṣù Kínní: Májẹ̀mú Kínní ti Jésù Krístì
Ọ̀rọ̀-ìṣaájú sí Májẹ̀mú Láéláé
Nígbàtí ẹ gbèrò ṣíṣé àṣàrò Májẹ̀mú Láéláé ní ọdún yí, irú ìmọ̀lára wo ni ẹ ní? Ìtara? Àìní-ìdánilójú? Bẹ̀rù? Gbogbo àwọn ẹ̀dùn ọkàn wọ̀nyí ni ó yéni. Májẹ̀mú Láéláé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àkópọ̀ ìwé kíkọ̀ pípẹ́jùlọ ní ayé, èyí sì lè mú kí ó jẹ́ méjèèjì wíwúnilórí àti dídẹ́rùbani. Àwọn ìwé kíkọ́ wọ̀nyí nwá láti inú àṣà àtijọ́ tí ó lè dàbí ti òkèrè àti nígbàmíràn àjèjì tàbí àní àìtunilára. Àti síbẹ̀ nínú àwọn ìwé kíkọ wọ̀nyí a rí àwọn ènìyàn tí wọ́n nní àwọn ìrírí tí ó dàbí ẹnipé a dámọ̀. A dá àwọn àkórí ìhìnrere mọ̀. tí ó jẹ́ ẹ̀rí nípa jíjẹ́ àtọ̀runwá Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ Bẹ́ẹ̀ni, àwọn ènìyàn bíi Ábráhámù, Sárà, Hánnà, àti Dáníẹ́lì gbé àwọn ìgbé ayé tí, ní àwọn ọ̀nà kan, ó yàtọ̀ gidi sí tiwa. Ṣùgbọ́n bákannáà wọ́n ní ìrírí ayọ̀ ẹbí àti àìṣọ̀kan ẹbí, àwọn àkókò ìgbàgbọ́ àti àkókò àìní-ìdánilójú, àti àwọn àṣeyege àti àwọn ìjákulẹ̀—bí gbogbo wa ti nṣe. Pàtàkì jùlọ, wọ́n lo ìgbàgbọ́, ronúpìwàdà, dá májẹ̀mú, ní àwọn ìrírí ti ẹ̀mí, wọn kò sì jáwọ́ lórí ìlérí Olùgbàlà. Bí a ti nkọ́ bí Ọlọ́run ṣe nṣe nínú ayé wọn, bákannáà a rí I nínú tiwa, a sì wí pẹ̀lú onísáàmù pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi. Nítorínáà ìránṣẹ́ rẹ fẹ ẹ” (Orin Dáfídì 119:105, 140).
Àwọn èrò orí fún Kíkọ́ni ní Ilé àti nínú Ìjọ
Májẹ̀mú Láéláé jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì.
Ọ̀nà kan láti rí ìṣìkẹ́ tí ẹ̀mí dídará nínú Májẹ̀mú Láéláé ni láti wákiri fún Búrẹ́dì Ìyè, Jésù Krístì (wo Jòhánnù 6:48). Fún àpẹrẹ, báwo ni ẹ ṣe rí Olùgbàlà nínú ìwọ̀nyí?
-
Mánnà (Ẹ́ksódù 16:4, 11–15; Jòhánnù 6:35)
-
Ọ̀dọ́-àgùtàn ìrúbọ (Ẹ́ksódù 12:3–5; Jòhánnù 1:29)
-
Ejò idẹ (Númérì 21:4–10; Jòhánnù 3:14)
-
Jónà (Jónà 1:4–17; Máttéù 12:38–41)
Kínni àwọn àpẹrẹ wọ̀nyí kọ́ni nípa Rẹ̀? Kínni àwọn ìtọ́kasí míràn sí Jésù Krístì nínú Májẹ̀mú Láéláé tí ẹ ní ìdámọ̀ pẹ̀lú?
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ “Jésù Krístì Ni Ìṣúra náà,” Alàgbà Dale G. Renlund gbà wá níyànjú láti “rántí kí a sì fojúsun Jésù Krístì” (Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2023, 98). Ẹ gbèrò kíka ọ̀rọ̀ rẹ̀, ní wíwá àwọn ohun tí ẹ lè ṣe láti rí Jésù Krístì kìí ṣe nínú Májẹ̀mú Láéláé nìkan ṣùgbọ́n bákannáà nínú ayé yín.
Bákannáà wo “Àwọn Ẹ̀yà tàbí Àpẹrẹ Krístì” nínú atọ́nà sí àwọn Ìwé Mímọ́, “Jésù Krístì,” Ibi-ìkawé Ìhìnrere; “Wá Olúwa ní Kùtùkùtù,” Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 108.
Ẹ wá àwọn àpẹrẹ tí ó jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì. Olúwa kọ́ Ádámù pé, “Ohun gbogbo ní àfijọ tiwọn, àti pé ohun gbogbo ni a dá tí a sì ṣe láti jẹ́ ẹ̀rí nípa mi” (Mósè 6:63). Bóyá ẹ nṣe àṣàrò tàbí kọ́ni, fífojúsùn sí Jésù Krístì lè ràn yín lọ́wọ́ láti rí ìtumọ̀ nínú àwọn ìwé mímọ́ kí ẹ sì mú ìfẹ́ fún àti ìgbàgbọ́ yín nínú Rẹ̀ pọ̀ síi. (Wo Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà,7.)
Jésù Krístì ni Jèhófàh nínú Májẹ̀mú Láéláé.
Ààrẹ Dallin H. Oaks kọ́ni pé: “Baba fi Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Kanṣoṣo, Jésù Krístì hàn, bí Olùgbàlà àti Olùràpadà wa ó sì fún wa ní àṣẹ láti ‘gbọ́ Tirẹ̀.’ Láti inú ìdarí yí a parí pé àwọn àkọsílẹ̀ ti ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ tí a sọ nípasẹ̀ ‘Ọlọ́run’ tàbí ‘Olúwa’ nígbàgbogbo fẹ́rẹ̀ jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ ti Jèhófàh, Olúwa wa tó jínde, Jésù Krístì” (“Àwọn Ìkọ́ni Jésù Krístì,” Láìhónà, Ọṣù Karun 2023, 102).
Àwọn Ìkọ́ni ti Jésù Krístì
Nígbàtí àwọn olùdarí Júù pe Jésù níjà nípa ìdánimọ̀ Rẹ̀, Ó kede pé, “Kí Ábráhámù tó wà, Èmi wà.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí mú kí àwọn ènìyàn tí wọ́n gbọ́ Jésù wárìrì, wọ́n sì ṣetán láti sọ Ọ́ ní òkúta (wo Jòhánnù 8:58–59). Ẹ gbèrò kíka Ẹ́ksódù 3:13–15; 6:3–5 láti rí ìdí tí àwọn Jùù kan fi bínú gidi sí ohun tí Jésù wí.
Kínni ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì sí yín láti mọ̀ pé Jésù Krístì ni Jèhófàh?
Olúwa mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ “àwọn ohun kedere ati iyebíye” padàbọ̀sípò nípasẹ̀ Joseph Smith.
Nínú ìran kan, Olúwa fi jíjáde wá Bíbélì han Néfì, ní ṣíṣe àlàyé pé “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun kedere ati iyebíye” ni a ó mú kúrò nínú rẹ̀. Ẹ gbèrò kíka 1 Néfì 13:21–29, 38–42, ní wíwá bí Olúwa ti ṣètò láti “mú àwọn ohun kedere ati iyebíye di mímọ̀.” Ní ìbámu sí 2 Néfì 3:12, báwo ni Bíbélì àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì ṣe nṣiṣẹ̀ papọ̀?
Bí ẹ ti nṣe àṣàrò Májẹ̀mú Láéláé ní ọdún yí, bákannáà ẹ ó ṣe àṣàrò “àwọn ìwé míràn” tí Néfì ti rítẹ́lẹ̀. Ìwọ̀nyí pẹ̀lú:
-
Ìwé ti Mósè, apákan ti ìyírọ̀padà Joseph Smith ti Bíbélì. Ó mú àwọn òtítọ́ àti àkọsílẹ̀ padàbọ̀sípò tí a kò rí nínú àtẹ̀kọ ti Gẹ́nẹ́sísì 1–6.
-
Ìwé ti Ábráhámù, èyí tí a fihàn sí Joseph Smith bí ó ti nyẹ pápírì Égíptì àtijọ́ wò (wo àwọn Àkọlé àti Ìbèèrè, “Ìwé ti Ábráhámù,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere).
-
Onírúurú àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ láti inú Ìyírọ̀padà Joseph Smith, àwọn èyí tí ó farahàn ninú àkọsílẹ̀ ránpẹ́ ìsàlẹ̀, àfikún ti Bíbélì, àti Atọ́nà sí àwọn Ìwé Mímọ́.
Ní ìhín ni àwọn àpẹrẹ kan nípa àwọn àkọsílẹ̀ Májẹ̀mú Láéláé tí a múpadàbọ̀sípò nípasẹ̀ Jósẹ́fù Smith: Ìlú Énọ́kù ti Síónì (Mósè 7:18–19), ìran Ábráhámù nípa ìgbìmọ̀ ní ọ̀run (Ábráhámù 3:22–28), àti iṣẹ́́ ìrànṣẹ́ Mẹlkisédékì (Ìyírọ̀padà Jósẹ́fù Smith, Gẹ́nẹ́sísì 14:25–40). Kínni ìdí tí àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ “kedere ati iyebíye” sí yín?
Ádámù àti Éfà Nrú Ẹbọ, láti ọwọ́ Keith Larson (àlàyé kíníkíní)
Májẹ̀mú Láéláé nràn mí lọ́wọ́ láti ní òye májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú Ọlọ́run.
Májẹ̀mú Láéláé jẹ́ ìtàn nípa Ọlọ́run tí ó nlépa láti mú wa jẹ́ “ìṣúra ọ̀tọ̀” Rẹ̀ nípa májẹ̀mú (Ẹ́ksódù 19:5). Fún èrèdí náà, ọ́nà rere kan láti múrasílẹ̀ láti ka Májẹ̀mú Láéláé ni láti kọ́ nípa àwọn májẹ̀mú—ní pàtó májẹ̀mú àìlópin tí Ọlọ́run fi fún àwọn wòlíì àtijọ́ bíi Ábráhámù, Ísáákì, Jákọ́bù, àti àwọn àtẹ̀lé wọn. Àti pé ọ̀nà títóbi láti kọ́ nípa àwọn májẹ̀mú ni láti ṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson “Májẹ̀mú Àìlópin” (Làìhónà, Oṣù Kẹwàá 2022, 4–11).
Bí ẹ ti nkàá, ẹ bèèrè lọ́wọ́ arayín pé: Kínni ìdí tí àwọn májẹ̀mú fi jẹ́ pàtàkì sí mi? Irú “ìfẹ́ àti àánú pàtàkì wo” ni mo ngbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí mo ti npa àwọn májẹ̀mú mi pẹ̀lú Rẹ̀ mọ́? Bí ẹ ti nka Májẹ̀mú Láéláé ní ọdún yí, ẹ maá wá àwọn ohun tí Ọlọ́run nfẹ́ láti kọ́ ọ yín nípa ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú yín pẹ̀lú Rẹ̀.
Bákannáà wo Jeremíàh 31:31–34.
Fún púpọ̀ síi, ẹ wo àwọn àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé ìrohìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́.
Àwọn èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Mo lè kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Jésù Krístì nínú Májẹ̀mú Láéláé.
-
Àwọn ọ̀rọ̀ àti àṣà ti Májẹ̀mú Láéláé lè ṣòro fún àwọn ọmọdé láti ní òye, ṣùgbọ́n ẹ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí Jésù Krístì nínú àwọn àpẹrẹ àti ìtàn. Bóyá ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè wo àwòrán ìsàlẹ̀, Wòlíì Ísáíàh sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìbí Krístì. Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín nawọ́ àwọn àlàyé kíníkíní tí wọ́n rí jáde. Ẹ pe àkíyèsí wọn, ní pàtàkì, sí ọmọ-ọwọ́ Jésù. Nígbànáà ẹ lè kà ohun tí Ísáíàh kọ nípa ìbí Olùgbàlà pẹ̀lú wọn nínú Ísáíàh 7:14; 9:6. Ẹ pín pẹ̀lú àwọn ọmọ yín irú ìmọ̀lára tí ẹ ní nípa wíwá Olùgbàlà nínú Májẹ̀mú Láéláé ní ọdún yí.
Ísáíàh Kọ̀wé nípa Ìbí Krístì (Wòlíì Ísáíàh sọ Àsọtẹ́lẹ̀ ti Ìbí Krístì), láti ọwọ́ Harry Anderson
-
Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín bákannáà lè ka Orin Dáfídì 23 tàbí Ísáíàh 53:3–9 kí ẹ sì wá àwọn ọ̀rọ̀ tí ó nrán yín létí nípa Jésù Krístì. Kínni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kọ́ wa nípa ìgbé ayé àti Ètùtù Rẹ̀?
Baba Ọ̀run nfẹ́ láti dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú mi.
-
Àwọn májẹ̀mú ni kókó àkórí nínú Májẹ̀mú Láéláé. Láti fi àkórí yí hàn sí àwọn ọmọ yín, ẹ lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn nípa àwọn ìlérí tí wọ́n ṣe tí wọ́n sì npamọ́ pẹ̀lú ẹbí tàbí àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdí tí pípa àwọn ìlérí wọ̀nyí mọ́ fi ṣe pàtàkì. Lẹ́hìnnáà ẹ lè wo àwòrán kan nípa ìrìbọmi kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa ìlérí náà, tàbí májẹ̀mú, tí a dá pẹ̀lú Ọlọ́run nígbàtí a ṣe ìrìbọmi (wo Mòsíàh 18:10, 13). Bákannáà ẹ lè fi àwòrán kan hàn nípa tẹ́mpìlì kí ẹ sì pín ìmọ̀lára yín nípa àwọn májẹ̀mú tí a dá níbẹ̀.
-
Ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe ti ọ̀sẹ̀ yí lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní ìwúrí láti dá àti lá pa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Baba Ọ̀run. Ẹ lè kọ orin kan nípa dìdà àwọn májẹ̀mú, bíi “Nígbàtí Mo Bá Ṣe Ìrìbọmi” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 103).
Jésù Krístì ni Jèhófàh nínú Májẹ̀mú Láéláé.
-
Njẹ́ àwọn ọmọ yín mọ ẹnikẹ́ni tí ó lọ nípa àwọn orúkọ tó yàtọ̀ nínú àwọn àgbékalẹ̀ tó yàtọ̀? Bóyà òbí tàbí olùkọ́ kan tí à npè yàtọ̀ ní ibi iṣẹ́, ní ilé, àti nínú ìjọ. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn orúkọ wọnnì; lẹ́hìnnáà kí ẹ ka Ẹ́ksódù 6:3 papọ̀ kí ẹ sì pe àwọn ọmọ yín láti wá orúkọ Jésù Krístì tí a mọ̀ọ́ sí ṣaájú kí a tó bí I (bákannáà ẹ wo Ìyírọ̀padà Joseph Smith nínú àkọsílẹ̀ ránpẹ́ ìsàlẹ̀c).
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .