“Oṣù Kínní 12–18. ‘Ní Àtètèkọ́ṣe Ọlọ́run Dá Ọ̀run Òun Ayé’: Gẹ́nẹ́sísì 1–2; Mósè 2–3; Ábráhámù 4–5,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kínní 12–18. ‘Ní Àtètèkọ́ṣe Ọlọ́run Dá Ọ̀run Òun Ayé’,” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026
Oṣù Kínní 12–18: “Ní Àtètèkọ́ṣe Ọlọ́run Dá Ọ̀run Òun Ayé”
Gẹ́nẹ́sísì 1–2; Mósè 2–3; Ábráhámù 4–5
Nítorí ayé ní àyíká wa rẹwà ó sì lọ́lá gidi, ó le láti ro ilẹ̀ ayé nígbàtí ó wà “láìní ohunkan, tí ó sì ṣófo” àti “gbayawu àti dahoro” (Gẹ́nẹ́sísí 1:2; Ábráhámù 4:2). Ohun kan tí ìtàn Ìṣẹ̀dá kọ́ wa ni pé Ọlọ́run lè, ní àkokò díẹ̀, ṣe ohunkan títóbi jáde nínú ohunkan tí a kò ṣètò. Èyí ṣèrànwọ́ láti rántí ìgbàtí ìgbé ayé bà dàbí rúdurùdu. Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì ni Aṣẹ̀dá, àti pé iṣẹ́ àtinúdá Wọn pẹ̀lú wa kò tíì parí. Wọ́n lè mú ìmọ́lẹ̀ tàn ní àkokò ṣíṣókùnkùn nínú ayé wa. Wọ́n lè kún àwọn àlàfo wa pẹ̀lú ìyè. Wọ́n lè yí wa padà sínú ẹni àtọ̀runwá tí ó yẹ kí a jẹ́. Èyí ni ohun tí ó túmọ̀sí láti jẹ́ dídá nínú àwòrán Ọlọ́run, ní ìjọra Rẹ̀ (wo Gẹ́nẹ́sísì 1:26). A ní agbára ìlèṣe láti dàbí Tirẹ̀: gbígbéga, ológo, tọ̀run.
Fún àkópọ̀ ìwé ti Gẹ́nẹ́sísì, wo “Gẹ́nẹ́sísì” nínú Ìtumọ̀ Bíbélì.
Àwọn èrò fún Kíkọ́ni ní Ilé àti Ìjọ
Gẹ́nẹ́sísì 1:1–25; Mósè 2:1–25; Ábráhámù 4:1–25
“Nípa Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ni mo dá àwọn ohun wọ̀nyí.”
Bíótilẹ̀jẹ́pé a kò mọ ohun gbogbo níp bí a ti dá ayé, ó wuni láti kíyèsí ohun tí Ọlọ́run ti yàn láti fihàn nípa Ìṣẹ̀dá. Kínni Ọlọ́run kọ́ yín nípa rẹ nínú Gẹ́nẹ́sísì 1:1–25; Mósè 2:1–25; àti Ábráhámù 4:1–25? Kínni ìdí tí Ó fi fẹ́ kí ẹ mọ àwọn ohun wọ̀nyí? Bí ẹ ti njíròrò àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí, bákannáà ẹ lè yẹ ohun tí wọ́n kọ́ yín wò nínú Baba Ọ̀run, Jésù Krístì, ayé, àti ara yín.
Láti ṣìkẹ́ àṣàrò yín, ẹ yẹ kíka àwọn ẹsẹ wọ̀nyí nígbàtí ẹ jáde ní àárín àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run tàbí nígbàtí ẹ̀ nfetísílẹ̀ sí orin kan bíiti “Gbogbo Ẹ̀dá Ọlọ́run Wa àti Ọba” (Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 62). Ẹ lè wá àwọn àwòrán ti àwọn ìṣẹ̀dá Rẹ̀ tí ó nràn yín lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ọ̀wọ̀ fún Aṣẹ̀dá. Ẹ yẹ pípín àwọn àwòrán wọ̀nyí wò, lẹgbẹ pẹ̀lú ẹ̀rí yín, pẹ̀lú àwọn ẹlòmírán.
Bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:5.
Ọgbà Édẹ́nì, láti ọwọ́ Grant Romney Clawson
Gẹ́nẹ́sísì 1:26–27; Mósè 2:26–27; Ábráhámù 4:26–27
A dá mi ní àwòrán Ọlọ́run.
Bí ẹ ti nka Gẹ́nẹ́sísì 1:26–27; Mósè 2:26–27; àti Ábráhámù 4:26–27, ẹ jíròrò ohun tí ó túmọ̀sí láti jẹ́ dídá ní àwòrán Ọlọ́run “àwòrán” tàbí “ìjọra,” ọkùnrin àti obìnrin. Kínni ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì fún yín láti mọ àwọn òtítọ́ nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí? Fún àpẹrẹ, báwo ni àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ṣe npa ọ`nà tí ẹ fi rí arayín, àwọn ẹlòmíràn, àti Ọlọ́run lára? Báwo ni wọ́n ṣe lè ràn yín lọ́wọ́ nígbàtí ẹ bá ní ìmọ̀lára àìdára nípa ara yín?
Láti ràn yín lọ́wọ́ nípa àwọn ìbèèrè wọ̀nyí, ẹ gbìyànjú píparí ẹ̀là ọ̀rọ̀ kan bíiti ọ̀kan yí: “Nítorí mo mọ̀ pé a dá mi nínú àwòrán Ọlọ́run, mo yàn láti …” Ṣe àtúnwò “Ara yín jẹ́ mímọ́” nínú Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́: Atọ́nà kan fún Ṣíṣe àwọn Àṣàyàn (àwọn ojú-ewé 22–29) lè ṣèrànwọ́. Ẹ yẹ yíyan ohunkan tí ẹ yíò ṣe láti fihan Ọlọ́run pé ẹ mọ̀ pé ara yín jẹ́ mímọ́.
Nínú fídíò “Ìṣẹ̀dá Ọlọ́run Títóbijùlọ” (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere), Ààrẹ Russell M. Nelson jẹ́ ẹ̀rí ti ìyanu ara ènìyàn. Bí ẹ ti nwo fídíò yí, ẹ bí arayín léèrè, “Báwo ni Baba Ọ̀run ṣe fẹ́ kí nní ìmọ̀lára nípa ara mi?” Báwo ni èyí fi yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹ lè gbọ́ láti ẹnu àwọn ẹlòmíràn?
God's Greatest Creation
Àwọn ènìyàn kan lè wípé jíjẹ́ dídá nínú àwòrán Ọlọ́run túmọ̀sí pé gbogbo àwọn èrò, ìmọ̀lára, àti ìfẹ́ wa tí a fọwọ́sí nípasẹ̀ Rẹ̀ tí a kò sì nílò láti (tàbí máṣe) gbèrú. Kínni ẹ ò sọ sí èyí? Kínni ìjìnlẹ̀ òyetí ẹ jèrè látinú Mòsíàh 3:19 àti Étérì 12:27?
Bákannáà wo Russell M. Nelson, “Ara Yín: Ẹ̀bùn Títóbi,” Làìhónà, Oṣù Kẹjọ. 2019, 50–55.
Gẹ́nẹ́sísì 1:27–28; 2:18–25; Mósè 3:18, 21–24; Ábráhámù 5:14–18
Ìgbeyàwó ní àárín ọkùnrin àti obìnrin kan ni a yàn láti ọwọ́ Ọlọ́run.
“Ádámù àti Éfà ni a dà papọ̀ nínú ìgbeyàwó fún àkokò àti fún gbogbo àìlópin nípa agbára ti oyè àlùfáà ayérayé [náà]” (Russell M. Nelson, “Àwọn Ẹ̀kọ́ láti ọ̀dọ̀ Éfà,” Ẹ́nsáìnì, Oṣù Kọkànlá. 1987, 87). Ẹ jíròrò èyí bí ẹ ti nka Gẹ́nẹ́sísì 1:27–28; 2:18–25; Mósè 3:18, 21–25; àti Ábráhámù 5:14–19. Báwo ni ẹ ṣe lè tọ́jú ìgbeyàwó yín pẹ̀lú ọ̀wọ̀ tí Ọlọ́run ti fún yín?
Bákannáà wo 1Kọ́ríntì 11:11; “Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àgbáyé,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Gẹ́nẹ́sísì 1:28; Mósè 2:28; Ábráhámù 4:28
Mo ní ojúṣe fún títọ́jú àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run.
Kínni Gẹ́nẹ́sísì 1:28; Mósè 2:28; àti Ábráhámù 4:28 dá àbá nípa ojúṣe wa níwájú àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run? Kínni Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 59:16–21 àti 104:13–18 fikún òye yín?
Bákannáà Gérald Caussé, “Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ti Ayé Wa,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2022, 57–59; Àwọn Àkọlé àti Ìbèèrè, “Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ àti Ìpamọ́ Àyíká,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Gẹ́nẹ́sísì 2:2–3; Mósè 3:2–3; Ábráhámù 5:2–3
Ọlọ́run nbùkún ó sì nya Ọjọ́ Ìsinmi sí mímọ́.
Ọlọ́run ya Ọjọ́ Ìsinmi sí mímọ́, Ó sì ní kí a pa á mọ́ ní mímọ́. Bi ẹ ti nka Gẹ́nẹ́sísì 2:2–3; Mósè 3:2–3; àti Ábráhámù 5:2–3, ẹ ronú nípa ohun tí ó nmú Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ “alábùkún” sí yín.
Bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 59:9–13; “Ọjọ́ Ìsinmi Jẹ́ Dídùn” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Highlight: The Sabbath Is a Delight
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé
Gẹ́nẹ́sísì 1:1–25; Mósè 2:1–25; Ábráhámù 4:1–25
Jésù dá ayé.
-
Báwo ni ẹ ó ṣe mú kíkọ́ nípa Ìṣẹ̀dá jẹ́ ìgbádùn fún àwọn ọmọ yín? Ẹ lè mú wọ́n lọ lórí ìwákiri òde fún irú àwọn ohun tí a ṣe ní àkokò Ìṣẹ̀dá kọ̀ọ̀kan. Bákannáà àwọn ọmọ yín lè wo àwọn àwòrán ti ohun tí Jésù dá (wo “Ìṣẹ̀dá ti Ilẹ̀ Ayé” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 8–12). Lẹ́hìnnáà ẹ̀yin àti ọmọ yín lè sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ ó ti ní ìmọ̀lára nípa Jésù Krístì lẹ́hìn kíkà nípa Ìṣẹ̀dá.
-
Ẹ yẹ kíkọ orin kan papọ̀ nípa ayé rírẹ̀wà wa, bí irú “Baba Ọ̀run Fẹ́ràn Mi” (Iwé-orin àwọn Ọmọdé, 228–29). Bóyá àwọn ọmọ yín lè fi àwọn ohun míràn kún orin náà tí Ọlọ́run dá tí ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀.
Ẹ ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti fi àtinúdá wọn hàn. “Nígbàtí ẹ bá pe àwọn ọmọ láti yà, kọ́, kùn, tàbí kọ ohunkan tí ó bá ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere mu, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní òye ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ dáradára síi kí ẹ sì fún wọn ní ìrántí” (Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà, 32).
Gẹ́nẹ́sísì 1:26–27; Mósè 2:26–27; Ábráhámù 4:26–27
A dá mi ní àwòrán Ọlọ́run.
-
Àwọn ọmọ yín lè gbèrú ọgbọ́n ọlá àti ọ̀wọ̀ fún ara ti arawọn àti ti àwọn ẹlòmíràn bí wọ́n ṣe nkọ́ pé gbogbo wa ní a dá ní àwòrán Ọlọ́run. Láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní òye ohun tí èyí túmọ̀sí, ẹ lè jẹ́ kí àwọn ọmọ yín wo àwòrán wọn nínú jígí tàbí àwòrán nígbàtí ẹ̀ nka Mósè 2:26–27 sí wọn. Bákannáà ẹ lè fi bí ọmọ-ọwọ́ ẹranko ṣe máa nwà ní “ìjọrọ” ti àwọn òbí wọn hàn wọ́n (wo àwòrán náà nínú ìlànà yí, fún àpẹrẹ). Èyí lè darí sí ìbárasọ̀rọ̀ nípa ìdí pàtàkì tí ó fi jẹ́ pàtàkì sí yín láti mọ̀ pé a dá yín ní àwòrán Baba Ọ̀run.
-
Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè gbádùn yíya ara ènìyàn àti gígé àwọn àwòrán náà sí àwọn ìrújú. Bí àwọn ọmọ yín ṣe nmú àwọn ìrújú wọn papọ̀, wọ́n lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi lè fihàn Baba Ọ̀run pé wọ́n ṣọpẹ́ fún ara wọn.
Gẹ́nẹ́sísì 2:2–3; Mósè 3:2–3; Ábráhámù 5:2–3
Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ mímọ́.
-
Bí ẹ ti nka Mósè 3:2–3, ẹ ní kí àwọn ọmọ yín fétísílẹ̀ sí ohun tí Ọlọ́run ṣe ní ọjọ́ kéje. Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti wá tàbí ya àwọn àwòrán ohun tí wọ́n lè ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi láti mu jẹ́ ọjọ́ mímọ́ àti àwọn ọjọ́ yíyàtọ̀ sí òmíràn. Ẹ pín ìdí tí ó fi jẹ́ pàtàkì láti pa Ọjọ́ Ìsinmi mọ́ ní mímọ́ pẹ̀lú ara yín.
-
Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe eré ṣíṣe àlàyé fún ọ̀rẹ́ kan ìdí tí wọ́n fi yàn láti ṣe àwọn nkan ní Ọjọ́ Ìsinmi tí ó bú-ọlá fún Baba Ọ̀run àti Jésù. Ẹ dá àbá pé kí wọ́n lo Gẹ́nẹ́sísì 2:2–3 nínú ṣíṣe àlàyé wọn. Báwo ni pípa Ọjọ́ Ìsinmi mọ́ ṣe nfi ìfẹ́ wa hàn fún Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì?
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .