Come, Follow Me
Oṣù Kínní 5–11. “Èyí Ni Iṣẹ́ Mi àti Ògo Mi”: Mósè 1; Ábráhámù 3


Oṣù Kínní 5–11. ‘Èyí Ni Iṣẹ́ Mi àti Ògo Mi’: Mósè 1; Ábráhámù 3,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

Oṣù Kínní 5–11. ‘Èyí Ni Iṣẹ́ Mi àti Ògo Mi’,” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026

àwọn ìràwọ̀ àti nébúlà ní àláfo òde

Oṣù Kínní 5–11: “Èyí Ni Iṣẹ́ Mi àti Ògo Mi”

Mósè 1; Ábráhámù 3

Bíbélì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ “ní àtètèkọ́ṣe Ọlọ́run dá ọ̀run òun ayé” (Gẹ́nẹ́sísì 1:1). Ṣùgbọ̀n kínni ó wà níbẹ̀ ṣíwájú “àtètèkọ́ṣe” yí? Àti pé kínni ìdí tí Ọlọ́run fi dá gbogbo èyí? Nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, Olúwa ti tàn ìmọ́lẹ̀ sí àwọn ìbèèrè wọ̀nyí.

Fún àpẹrẹ, Ó fún wa ní àkọsílẹ̀ ìran kan nínú èyí tí Ábráhámù rí wíwà wa bí àwọn ẹ̀mí “ṣíwájú kí ayé tó wà” (wo Ábráhámù 3:22–28). Bákannáà Olúwa fún wa ní ìmísí ti ìyírọ̀padà tàbí àtúnkọ àwọn orí mẹfa àkọ́kọ́ ti Gẹ́nẹ́sísì, tí a pè ní ìwé ti Mósè—èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú “ní àtètèkọ́ṣe.” Dípò bẹ́ẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrírí kan tí Mósè ní tí ó pèsè àwọn àkóónú kan fún ìtàn ìṣẹ̀dá. Lápapọ̀, àwọn ìwé mímọ́ ọjọ́-ìkẹhìn wọ́nyí ni ibi rere láti bẹ̀rẹ̀ àṣàrò wa nípa Májẹ̀mú Láéláé nítorí wọ́n yanjú ìpilẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìbèèrè kan tí ó lè tún ìwé kíkà wa ṣe: Tani Ọlọ́run i ṣe? Tani àwa jẹ́? Kínni iṣẹ́ Ọlọ́run, kí sì ni ààyè wa nínú rẹ̀? Àwọn orí tí ó bẹ̀rẹ̀ Gẹ́nẹ́sísì ni a lè rí bí èsì Olúwa sí ìbèèrè Mósè: “Ṣe àánú fún ìránṣẹ́ rẹ, Áà Ọlọ́run, kí o sì sọ fún mi nípa ilẹ̀ ayé yìí, àti àwọn olùgbé inú rẹ̀, àti bákannáà àwọn ọ̀run” (Mósè 1:36).

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti ní Ìjọ

Mósè 1

àmì sẹ́mínárì
Bíi ọmọ Ọlọ́run, mo ní àyànmọ́ àtọ̀runwá.

“Bí Olúwa bá nbá yín sọ̀rọ̀ tààrà,” Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé, “ohun àkọ́kọ́ tí Òun yíò ri dájú pé ẹ ní òye rẹ̀ ni ìdánimọ̀ òtítọ́ yín” (“Àwọn Àṣàyàn Ayérayé” [ìsìn àkànṣe káríayé fún àwọn ọ̀dọ́ àgbà, Oṣù Karun 2022], Ibi-ìkàwé Ìhìnrere). Ó tẹ̀lé pé Sátánì yíò gbìyànjú láti dà yín láàmú lórí kókó ọ̀rọ̀ kannáà. Ẹ wá àwòṣe yí nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí Mósè nínú Mósè 1:4, 6 àti nínú àwọn ọ̀rọ̀ Sátánì nínú Mósè 1:12. Kínni ẹ kọ́ láti inú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí nípa àwọn ìyàtọ̀ láàrin Ọlọ́run àti Sátánì?

Ààrẹ Nelson kọ́ni bàkannàa pé, “Ọ̀nà tí ẹ fi nronú nípa ẹni tí ẹ jẹ́ lódodo nkan ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo ìpinnu tí ẹ ó ṣe rí láé” (“Àwọn Àṣàyàn Ayérayé”). Ẹ gbèrò ṣíṣe títòsílẹ̀ kan nípa àwọn àṣàyàn tí ẹ nṣe nítorípé ìdánimọ̀ yín bí ọmọ Ọlọ́run nwá ṣíwájú àwọn àmì míràn.

Àwọn àfikún ẹsẹ tàbí gbólóhùn ọ̀rọ̀ wo nínú Mósè 1 ni ó nràn yín lọ́wọ́ láti ní òye iyì àtọ̀runwá yín? Ẹ lè ka púpọ̀ ọ̀rọ̀ Ààrẹ Nelson síi ninú ìpín ti “Àwọn Aṣàyàn Ayérayé” tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Àkọ́kọ́: Ẹ mọ òtítọ́ nípa ẹni tí ẹ jẹ́.” Kínni ẹ ní ìmọ̀lára ìmísí láti ṣe láti fi ìdánimọ̀ yín bí ọmọ Ọlọ́run ṣe olùdánimọ̀ yín pàtàkì jùlọ?

Bákannáà wo “Èmi Jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run,” Àwọn Orin Ìsìn (1985), nọ́mbà 301; “Ìdánimọ̀ Òtítọ́ Wa” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere; Tàwọn Àkọlé àti Ìbèèrè, “Àwọn Ọmọ Ọlọ́run,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

3:39

Our True Identity

ìyá, baba, àti ọmọ-ọwọ́ nrẹrin

Mósè 1:12–26

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa, mo lè Sátánì.

Mósè 1 ṣe fihàn kedere, àwọn ìrírí alágbára ti ẹ̀mí kò túmọ̀sí pé a kò ní gba àdánwò mọ́ láéláé. Lódodo, ọ̀kan lára ète Sátánì ni láti dán wa wò láti ṣiyèméjì àwọn ìrírí wọ̀nyí. Bí ẹ ti nka èsì Mósè sí Sátánì nínú àwọn ẹsẹ 12–26, kínni ẹ kọ́ tí ó lè ràn yín lọ́wọ́ láti dúró ní òtítọ́ sí ẹ̀rí tí ẹ ti gbà? Kínni ó jẹ́ tí ó ṣèrànwọ́ fún Mósè nígbẹ̀hìn láti borí Sátánì?

Ẹ̀kọ́ míràn láti inú ìrírí Mósè ni pé Sátánì ndán wa wò pèlú àwọn ayédèrú ti òtítọ́ àti agbára Ọlọ́run. Ẹ ronú nípa àwọn ẹ̀dà èké ti àwọn ohun, bí irú ohun ọ̀gbìn àtọwọ́dọ́wọ́ tàbí ọmọlangidi. Báwo ni ẹ ṣe lè sọ bóyá wọ́n jẹ́ ayédèrú? Lẹ́hìnnáà ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn ayédèrú tí Sátánì nlò ní òní láti dán yín wò? Kínni ẹ kọ́ láti inú Mósè 1:13–18 nípa bí a ṣe lè dá a mọ̀ kí a sì kọ àwọn ayédèrú rẹ̀? Báwo ni Olúwa ṣe nràn yín lọ́wọ́? (wo Mósè 1:24–26).

Bákannáà wo Máttéù 4:1–11; Gary E. Stevenson, “Máṣe Tàn Mí Jẹ,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2019, 93–96; “Èmi Jẹ́ Ọmọkùnrin Ọlọ́run” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

6:31

I Am a Son of God

Kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní ilé ni a lè ṣètò ṣùgbọ́n bákannáà ní ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan. “Kíkọ́ àwọn ànfàní nínú ẹbí lemọ́lemọ́ nṣẹlẹ̀ ní ọ̀nà àìlèṣe-àlàyé, àwọn àkokò ojojúmọ́—nígbàtí à njẹ́ oúnjẹ, ṣíṣe iṣẹ́ ilé, ṣíṣé eré, [tàbí] rírin ìrìnàjò” (Ìkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà, 31). Fún àpẹrẹ, ní àfikún sí kíkà nípa bí Mósè ṣe kọ Sátánì nínú Mósè 1, ẹ lè lo àkokò díẹ̀ ní ìgbà oúnjẹ alẹ́ ní sísọ̀rọ̀ bí ẹbí nípa bí ẹ yíò ti kọ ipa ọ̀tá.

Mósè 1:27–39; Ábráhámù 3

Iṣẹ́ àti ògo Ọlọ́run ni láti ràn mí lọ́wọ́ láti jèrè ìyè ayérayé.

Lẹ́hìn rírí ìràn kan nípa àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run, Mósè wí fún Olúwa: “Wí fún mi … ìdí tí àwọn ohun wọ̀nyí fi jẹ́ bẹ́ẹ̀” (Mósè 1:30). Kínni o wọ̀ yín lọ́kàn nípa èsì Olúwa nínú Mósè 1:31–39? Kínni ìyàtọ́ ní àárín àìkú àti ìyè ayérayé? (Wo àwọn Àkọlé àti Ìbèèrè, “Ìyè Ayérayé,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere). Báwo ni Jésù Krístì ṣe nṣèrànwọ́ láti mú méjèèjì kọjá? Ábráhámù bákannáà ní ìran kan, tí a kọsílẹ̀ nínú Ábráhámù 3. Kínni ẹ rí nínú àwọn ẹsẹ 24–26 tí ó lè ran Mósè lọ́wọ́ láti dáhùn ìbèèrè Mósè?

Ábráhámù 3:24–25

Mo gbé bí ẹ̀mí ṣíwájú kí a tó bí mi sórí ilẹ̀ ayé.

A mọ díẹ̀ péré nípa ìgbé ayé ṣaájú ayé ikú wa. Ṣùgbọ́n púpọ̀ lára ohun tí a mọ̀ nwá láti inú ìran Ábráhámù nínú Ábráhámù 3:22–28. Bí ẹ ti nka àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, ẹ ṣe ìtòsílẹ̀ àwọn òtítọ́ tí ẹ rí—pẹ̀lú àwọn òtítọ́ nípa ara yín àti nípa Jésù Krístì. Kínni ìdí tí àwọn òtítọ́ wọ̀nyí fi níyelórí fún yín? Kínni ìyàtọ̀ tí wọ́n ṣe ní ìgbésí ayé yín?

Bákannáà wo Àwọn Àkọlé àti Àwọn Ìbèèrè, “Ìgbé Ayé Ṣaájú Ayé Ikú,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé ìróhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .

ìpín àmì àwọn ọmọdé 01

Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé

Mósè 1:1–4, 6, 12

Èmi Jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run.

  • Lẹ́hìn tí ẹ bá ka ọ̀rọ̀ Ọlọ́run papọ̀ nínú Mósè 1:4, ẹ yẹ jíjẹ́ kí àwọn ọmọ yín wo ìrísí wọn nínú jígí kí wọ́n sì fúnra wọn ní ọ`rọ̀ kannáà: “Èmi Jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run.” Lẹ́hìnnáà wọ́n lè fi irú ọ̀rọ̀ kannáà fún ara wọn: “Ẹ Jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.” Àní ẹ lè rí àwọn àwòrán onírúurú ti àwọn ènìyàn kí ẹ sì pe àwọn ọmọ yín láti nawọ́ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan kí wọ́n sì wípé, “Èyí jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.” Ẹ pín ìdí tí inú yín fi dùn láti mọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọ Ọlọ́run pẹ̀lú ara yín. Báwo ni ìmọ̀ yí ṣe lè yí ọ̀nà tí ẹ fi nṣe sí arayín àti àwọn ẹlòmíràn padà?

  • Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè ṣe àfiwé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí Mósè nínú Mósè 1:4 pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Sátánì nínú ẹsẹ 12. Báwo ni ẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti mọ ìyàtọ̀ ní àárín àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti Sátánì sí wọn?

Jèhófàh nfarahàn sí Mósè

Mósè Rí Jèhófàh, láti ọwọ́ Joseph Brickey (àlàyé kíníkíní)

Moses 1:6, 39

Baba Ọ̀run ní iṣẹ́ kan fún mi láti ṣe.

  • Bí ẹ ti nka Mósè 1:6 pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, ẹ lè sọ̀rọ̀ sí wọn nípa “iṣẹ́” tí Ọlọ́run ní fún Mósè. Ẹ yẹ lílo Ìwé Ọnà Ìhìnrere, àwọn nọ́mbà. 13–16, tàbí Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, àwọn ojú-ewé 64–84, láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti rí ohun tí Mósè ṣeyọrí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Baba Ọ̀run. Kínni iṣẹ́ tí Olúwa ní fún wa? (wo, fún àpẹrẹ, Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 11:20).

Mósè 1:12–26

Mo lè kọ àwọn àdánwò ti Sátánì.

  • Bí ẹ ti nṣe àṣàrò Mósè 1:12–26 pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àwárí ohun tí Mósè ṣe láti kọ Sátánì (wo àwọn ẹsẹ 13, 15, 18, 20–22, 26). Ó lè jẹ́ ìgbádùn fún wọn láti ṣe eré àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe láti kọ àdánwò (bí irú gbígbàdúrà, rírìn kúrò, tàbí bíbééré fún ìrànlọ́wọ́).

Ábráhámù 3:22–28

Mo gbé bí ẹ̀mí ṣíwájú kí a tó bí mi sórí ilẹ̀ ayé.

  • Mímọ̀ nípa ìgbésí ayé ṣaájú ayé ikú lè mísí àwọn ọmọ yín láti ṣe àwọn àṣàyàn tí ó dálé àwọn òtítọ́ ayérayé Láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ nípa rẹ̀, ẹ lè fún wọn ní àwọn kókó ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn ọ̀rọ̀ láti wá nínú Ábráhámù 3:22–28, bíiti “ṣíwájú kí ayé tó wà,” “àwọn ẹ̀mí,” “ṣe ayé,” àti “dán wò.” Kínni àwọn ẹsẹ wọ̀nyí kọ́ wa nípa ìdí tí Baba Ọ̀run fi rán wa wá sí ìlẹ̀ ayé?

  • Orin kan bíiti “Èmi Yíò Tẹ̀lé Ètò Ọlọ́run” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 164–65) lè tún ohun tí Ábráhámù 3 kọ́ sọ. Bóyá ẹ lè pe àwọn ọmọ yín láti ya àwọn àwòrán láti lọ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ náà.

  • Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú àwọn ipò nínú èyítí wọ́n ti ní láti yàn bóyá tàbí kí wọ́n máṣe ṣe ohun tí Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe (wo Ábráhámù 3:25; bákannáà wo Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́: Atọ́nà kan fún Ṣíṣe àwọn Àṣàyàn). Ẹ jẹ́ kí wọ́n gbáradì fún àwọn èsì tó ṣeéṣe sí àwọn ipò wọ̀nyí. Báwo ni Olùgbàlà ṣe nràn wá lọ́wọ́ nígbàtí a bá ṣe àṣàyàn àṣìṣe?

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .

Mósè ju Sátánì síta

Mósè Bori Sátánì, láti ọwọ́ Joseph Brickey

Ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Èmi jẹ́ ọmọ Ọlọ́run