“Àlẹ̀mọ́ A: Fún Àwọn Òbí—Mímúrasílẹ̀ fún Àwọn Ọmọ Yín Fún Ìgbé-ayé ní Ipa-Ọnà Májẹ̀mú ti Ọlọ́run,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Àlẹ̀mọ́ A,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Àlẹ̀mọ́ A
Fún Àwọn Òbí—Mímúrasílẹ̀ fún Àwọn Ọmọ Yín Fún Ìgbé-ayé ní Ipa-Ọnà Májẹ̀mú ti Ọlọ́run
Nítorí Ó nifẹ yín, ó gbẹ́kẹ̀lé yín, ó sì mọ agbára-ìlèṣe yín, Baba Ọ̀run ti fún yín ní àyè láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti wọlé àti láti lọsíwájú ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú Rẹ̀, ipa-ọ̀nà sí ìyè ayérayé (wo Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 68:25–28). Èyí pẹ̀lú ríran wọn lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ àti láti pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́, bí irú májẹ̀mú ìrìbọmi àti àwọn májẹ̀mú tí a ṣe nínú tẹ́mpìlì. Nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí, àwọn ọmọ yín yíò lè fi ayọ̀ so ara wọn pọ̀ mọ́ Olùgbàlà, Jésù Krístì.
Àwọn ọ̀nà púpọ̀ lo wa lati pèsè àwọn ọmọ yín sílẹ̀ fún ìrìn-àjò yí ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú, àti pé Baba Ọ̀run yíò ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àwárí ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn. Bí ẹ ṣe nwá ìmísí, ẹ ni lọ́kan pé kíì ṣe gbogbo ìkọ́ni ni o nṣẹlẹ̀ ní àkokò àwọn ẹ̀kọ́ tí a ṣètò. Ní tòótọ́, ara ohun kan tí ó jẹ kí ìkọ́ni ní ilé lágbára ni ànfàní láti kọ́ nípasẹ̀ àpẹrẹ àti nípasẹ̀ àwọn àkokò ìkọ́ni kékèké, ti o rọrun—irú èyítí ó wáyé ní àdánidá ní ṣíṣàn ìgbé-ayé ojojúmọ́. Gẹ́gẹ́bí títẹ̀lé ipa-ọ̀nà májẹ̀mú ti jẹ́ àìyẹsẹ̀, ètò ìgbésí-ayé, bẹ́ẹ̀náà ni kíkọ́ nípa ipa-ọ̀nà májẹ̀mú náà. (Wo “Ilé àti Ẹbí,” Ìkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà [2022], 30–31.)
Ní ìsàlẹ̀ ni díẹ̀ nínú àwọn èrò tí ó lè já sí ìmísí síwájú si. Ẹ lè wá àwọn ìmọ̀ràn àfikún fún kikọ àwọn ọmọdé-ọjọ́-orí Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ nìnú “Àlẹ̀mọ́ B: Mímúrasílẹ̀ fún Àwọn Ọmọ Yín Fún Ìgbé-ayé ní Ipa-Ọnà Májẹ̀mú ti Ọlọ́run.”
Ìrìbọmi àti Ìfẹsẹ̀múlẹ̀
Néfì kọ́ni pé “ẹnu ọ̀nà tí o yẹ kí [á] fi wọ̀” ipa-ọ̀nà májẹ̀mú náà “ni ìrònúpìwàdà àti ṣíṣe ìrìbọmi nípasẹ̀ omi” (2 Néfì 31:17). Ìtiraka yín láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ fún ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ lè mú kí ẹsẹ̀ wọn dúró gbọingbọin sí ipa-ọ̀nà náà. Àwọn ìtiraka wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìkọ́ni nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti ìrònúpìwàdà. Wọ́n tún pẹ̀lú kíkọ́ni nípa bí a ṣe ntún májẹ̀mú ìrìbọmi wa ṣe nípa jíjẹ oúnjẹ Oúnjẹ Olúwa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
Néfì kọ́ni pé “ẹnu ọ̀nà tí o yẹ kí [á] fi wọ” ipa-ọ̀nà májẹ̀mú náà “ni ìrònúpìwàdà àti ṣíṣe ìrìbọmi nípasẹ̀ omi” (2 Néfì 31:17).
Ní ìhín ni díẹ̀ nínú àwọn ohun-èlò tí ó lè ṣèrànwọ́ fún yín: 2 Néfì 31; àkànṣe ọ̀ràn ti Ọ̀rẹ́ ìwé ìròhìn nípa ìrìbọmi; Àwọn Àkọlé àti ìbéèrè, “ìrìbọmi,” ibi Ìkàwé Ìhìnrere.
-
Nígbàkugbà tí ẹ bá ní ìrírí tí ó fún ìgbàgbọ́ yín lókun nínú Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì, ẹ ṣe àbápín rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ yín. Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní òye pé ìgbàgbọ́ jẹ́ nkan tí ó lè dàgbà síi kí ó sì ní agbára si ní gbogbo ìgbé-ayé. Kíni díẹ̀ lára àwọn ohun tí ọmọ yín lè ṣe láti mú ìgbàgbọ́ tó ní agbára nínú Krístì gbèrú kí wọ́n tó ṣe ìrìbọmi?
-
Nígbàtí ọmọ yín ba ṣe yiyan ti ko tọ, ẹ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ayọ̀ nípa ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà. Ati nígbàtí ẹ bá ṣe yíyàn tí kò tọ́, ẹ ṣe àbápín ayọ̀ tí ó wá nígbàtí ẹ ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín lójojúmọ́. Ẹ jẹri pé nítorí Jésù Krístì jìyà àti pé Ó kú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, a lè ronúpìwàdà lójojúmọ́, gbà ìdáríjì, kí a sì gba agbára láti yípadà. Nígbàtí ọmọ yín bá nwá ìdáríjì yín, ẹ dáríjì lọfẹ àti ayọ̀.
-
Ẹ sọ fún ọmọ yín nípa ìrìbọmi yín. Ẹ ṣe àfihàn àwọn àwòrán kí ẹ sì ṣe àbápín àwọn ìrántí. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀lára yín, bí pípa májẹ̀mú ìrìbọmi yín mọ́ ti ṣe ràn yín lọ́wọ́ láti mọ Jésù Krístì dáadáa, àti bí àwọn májẹ̀mú yín ṣe túnbọ̀ nbùkún ìgbésí ayé yín. Ẹ gba ọmọ yín nìyánjù láti bèèrè àwọn ìbéèrè.
-
Nígbàtí ìrìbọmi kan bá wà nínú ẹ̀bí yín tàbí wọ́ọ̀dù, ẹ mú ọmọ yín lọ láti ríi. Ẹ sọ̀rọ̀ papọ̀ nípa ohun tí ẹ̀yin àti ọmọ yín rí tí ẹ sì ní ìmọ̀lára rẹ̀. Bó bá ṣeé ṣe, ẹ bá ẹni tó nṣe ìrìbọmi sọ̀rọ̀, kí ẹ sì bèèrè àwọn ìbéèrè bíi: “Báwo lẹ ṣe ṣe ìpinnu yí? Báwo ni ẹ ṣe múra?”
-
Nígbàkugbà tí ẹ bá ṣe àkíyèsí tí ọmọ yín nṣe ohun kan tí wọ́n ṣe ìlérí láti ṣe, ẹ fún un ní ìyìn tòótọ́. Ẹ tọ́ka sí i pé pípa àwọn ìpinnu mọ́ nràn wá lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ láti pa àwọn májẹ̀mú tí a bá dá nígbàtí a bá ṣe ìrìbọmi mọ́. Kíni a ṣe ìlérí fún Ọlọ́run nígbàtí a ṣe ìrìbọmi? Kíni Ó ṣèlérí fún wa? (Wo Mòsíàh 18:8–10, 13.)
-
Ẹ sọ̀rọ̀ nípa bí ìfẹsẹ̀múlẹ̀ àti dídi ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti ìwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn ṣe bùkún yín. Fún àpẹrẹ, báwo ni ẹ ṣe súnmọ́ Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì bí ẹ ṣe nsin àwọn ẹlòmíràn àti bí àwọn ẹlòmíràn ṣe nsìn yín? Ẹ ran ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú àwọn ọ̀nà láti sìn àti láti fún àwọn ẹlòmíràn lókun gẹ́gẹ́bí ọmọ Ìjọ. Ẹ tún ṣe ìrànwọ́ fún wọn láti ní ìrírí kí wọ́n sì dá ayọ̀ tí ó nwá láti iṣẹ́-ìsìn mọ̀.
-
Nígbàtí ẹ̀yin àti ọmọ yín bá ní ìrírí mímọ́ papọ̀ (bíiti ní ìjọ, nígbàtí ẹ bá nka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́, tàbí nígbàtí ẹ bá nsìn ẹnìkan), ẹ sọ àwọn ìmọ̀lára ti ẹ̀mí tàbí àwọn ìtẹ̀mọ́ra tí ẹ ní. Ẹ pe ọmọ yín láti ṣe àbápín ìmọ̀lára tí wọ́n ní. Ẹ ṣe àkíyèsí oríṣiríṣi ọ̀nà tí Ẹ̀mí lè gbà bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, pèlú àwọn ọ̀nà tí Ó ngbà bá yín sọ̀rọ̀ fúnra yín. Ẹ ran ọmọ yín lọ́wọ́ láti dá àti láti ṣe àbápín pẹ̀lú yín àwọn àkókò nígbàtí wọ́n lè nní ìrírí ipa ti Ẹ̀mí Mímọ́.
-
Ẹ wo díẹ̀ lára àwọn fídíò tó wà nínú ibi Ìkàwé Ìhìnrere papọ̀ tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Gbọ́ Tirẹ̀!” Ẹ sọ̀rọ̀ papọ̀ nípa àwọn ọ̀nà oríṣiríṣi ti àwọn ìránṣẹ́ Olúwa fi ngbọ́ ohùn Rẹ̀. Ẹ pe ọmọ yín láti ya àwòrán tàbí ṣe fídíò kan nípa bí wọ́n ṣe gbọ́ ohùn Olùgbàlà.
-
Ẹ mú kí oúnjẹ Olúwa jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ mímọ́ àti ayọ̀ nínú ẹbí yín. Ẹ ṣe àbápín pẹ̀lú ọmọ yín bí ẹ ṣe nkọjúsí Jésù Krístì ní àkókò oúnjẹ Olúwa. Ẹ ran ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe ètò láti fihàn pé oúnjẹ Olúwa jẹ́ mímọ́ fún wọn. Fún àpẹrẹ, gbígbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àdúrà oúnjẹ Olúwa lè rán wa létí májẹ̀mú ìrìbọmi wa.
-
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtẹ̀jáde Fríẹ́ndì ìwé ìròhìn pẹ̀lú àwọn nkan, ìtàn, àti ìṣe láti ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ fún ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ọmọ yín yan díẹ̀ nínú rẹ̀ láti kà àti gbàdún pẹ̀lú yín. (Bákannáà wo àkójọpọ̀ “Mímúrasílẹ̀ fún Ìrìbọmi”nínú ìpín àwọn ọmọdé nínú Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.)
Agbára, Àṣẹ, àti Àwọn kọ́kọ́rọ́ Oyè-àlùfáà
Oyè-àlùfáà ni agbára àti àṣẹ nípasẹ̀ èyí tí Ọlọ́run fi nbùkún àwọn ọmọ Rẹ̀. Oyè-àlùfáà Ọlọ́run wà lórí ilẹ̀ ayé ní òní nínú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn. “Gbogbo àwọn ọmọ Ìjọ tí wọ́n pa májẹ̀mú wọn mọ́—àwọn obìnrin, àwọn ọkùnrin, àti àwọn ọmọ—ni a bùkún fún pẹ̀lú agbára oyè-àlùfáà Ọlọ́run nínú ilé wọn láti fún arawọn àti àwọn ẹbí wọn lókun” (Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 3.6, Ibi Ìkàwé Ìhìnrere). Agbára yí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọ ìjọ ní ṣíṣe iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga Ọlọ́run ní ìgbé-ayé araẹni àti àwọn ẹbí (wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 2.2).
Nígbàtí àwọn ọkùnrin àti obìnrin bá sìn nínú àwọn ìpè Ìjọ, wọ́n nṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ oyè-àlùfáà, lábẹ́ ìdarí àwọn tí wọ́n di kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà mú. Gbogbo àwọn ọmọ Baba Ọ̀run—Àwọn ọmọkùnrin Rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin Rẹ̀—yíò di alábùkún bí wọ́n ṣe nwá láti ní òye oyè-àlùfáà Rẹ̀ dáadáa.
A ngba àwọn ìlànà nípa àṣẹ́ oyè-àlùfáà. “Àwọn ọmọ Ìjọ ọkùnrin yíyẹ ngba àṣẹ oyè-àlùfáà nípasẹ̀ ìfúnni ní oyè-àlùfáà àti yíyàn sí àwọn ipò oyè-àlùfáà” (Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 3.4). Àwọn tí wọ́n di oyè-àlùfáà mú lè gba àṣẹ láti ọwọ́ ẹnìkan tí ó di kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà mú láti ṣe àwọn ìlànà oyè-àlùfáà.
Láti kọ́ ẹ̀kọ́ sí i nípa oyè àlùfáà, wo Russell M. Nelson, “Àwọn Ìṣúra ti Ẹ̀mí,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2019, 76–79; Russell M. Nelson, “Ìdíyelé Agbára Oyè-àlùfáà,” Làìhónà, Oṣù karun 2016, 66–69; “Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Oyè-àlùfáà,” ìpín 3 ní Ìwé-ìléwọ́ Gbogboò.
-
Ẹ jẹ́ kí àwọn ìlànà oyè-àlùfáà di ara kan ìgbésí ayé ẹbí yín déédé. Fún àpẹrẹ, ẹ ran ọmọ yín lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ nípa ti ẹ̀mí fún oúnjẹ Olúwa ní ọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ẹ gba ọmọ yín níyànjú láti wá àwọn ìbùkún oyè-àlùfáà nígbàtí wọ́n bá nṣe àìsàn tàbí nílò ìtùnú tàbí ìtọ́sọ́nà. Ẹ jẹ́ kí ó jẹ́ àṣà láti tọ́kasí àwọn ọ̀nà tí Olúwa fi nbùkún ẹbí yín nípasẹ̀ agbára Rẹ̀.
-
Bí ẹ ṣe nka àwọn ìwé mímọ́ papọ̀, ẹ wá ọ̀nà fún àwọn ànfàní láti jíròrò bí Ọlọ́run ṣe nbùkún àwọn ènìyàn nípasẹ̀ agbára Rẹ̀. E ṣe àbápín àwọn ìmọ̀lára yín nípa bí Olúwa ti nbùkún yín nípasẹ̀ oyè-àlùfáà Rẹ̀. Fún àwọn àpẹrẹ ti àwọn ìbùkún tí a gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ oyè-àlùfáà, wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogboò, 3.2, 3.5.
-
Ẹ kọ́ ọmọ yín pé lẹ́hìn ìrìbọmi, wọ́n lè gba agbára Ọlọ́run nípa pípa májẹ̀mú ìrìbọmi mọ́. Ẹ ṣe àtúnyẹ̀wò ọ̀rọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson papọ̀ “Àwọn Iṣura Ti Ẹ̀mí” (Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2019, 76–79). Ẹ sọ fún ọmọ yín bí àwọn ìlànà oyè-àlùfáà ṣe nmú agbára Ọlọ́run wá sínú ìgbé-ayé yín. Fún àtòkọ díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà tí a fi ndi alábùkún nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run, wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogboò, 3.5.
-
Ẹ jíròrò lórí ìbéèrè náà “Kí ni ìránṣẹ́ Olúwa jọ?” Ẹ ka Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 121:36–42papọ̀, kí ẹ sì wá àwọn ìdáhùn. Nígbàkugbà tí ẹ bá ṣàkíyèsí pé ọmọ yín (tàbí ẹlòmíràn) lílo ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tàbí àwọn ìkàsí nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, tọ́ka sí i.
-
Nìgbátì ẹ̀yin tàbí ọmọ yín bá nlo àwọn kọ̀kọ̀rọ̀ láti ṣí ilẹ̀kùn tàbí bẹ̀rẹ̀ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan, ẹ fi àkókò díẹ̀ sílẹ̀ làti fi àwọn kọ̀kọ̀rọ̀ náà wé àwọn kọ́kọ́rọ́ tí àwọn olórí oyè-àlùfáà dímù. (Fún ìtumọ̀ àwọn kọ̀kọ̀rọ̀ oyè-àlùfáà, wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogboò, 3.4.1). Kíni àwọn kọ̀kọ̀rọ̀ oyè-àlùfáà “ṣí” tàbí “bẹ̀rẹ̀” fún wa? Bákannáà wo Gary E. Stevenson, “Níbo ni Àwọn Kọ̀kọ̀rọ̀ àti Àṣẹ Oyè-Àlùfáà Wa?,” Làìhónà, Oṣù karun 2016, 29–32; “Níbo ni Àwọn Kọ̀kọ̀rọ̀ Wà?” (fídíò), Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.
2:51Where Are the Keys?
Jíjẹ Rírìbọmi àti Ìfẹsẹ̀múlẹ fún Àwọn Babanlá
Àwọn tẹ́mpìlì jẹ́ ara pàtàkì kan ti ètò Baba Ọ̀run fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Nínú ilé Olúwa, a ndá májẹ̀mú mímọ́ pẹ̀lú Baba Ọ̀run bí a ṣe nkópa nínú àwọn ìlànà mímọ́, gbogbo èyí tí ó tọ́ka sí Jésù Krístì. Baba Ọ̀run ti pèsè ọ̀nà kan fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ láti dá májẹ̀mú kí wọ́n sì kópa nínú àwọn ìlànà, pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọn kò gbà wọ́n ní ayé yí. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tí ọmọ yín bá pé ọdùn méjìlá, wọ́n ti dàgbà tó láti ṣe ìrìbọmi kí wọ́n sì ṣe ìfẹsẹ̀múlẹ̀ nínú tẹ́mpìlì fún àwọn babanlá tó ti kú (bákanáà wo 1 Kọ́ríńtì 15:29).
-
Ẹ lọ sí ilé Olúwa ní gbogbo ìgbà bí àwọn ipò yín bá ṣe gbà láàyè. Ẹ sọ fún ọmọ yín nípa ìdí tí ẹ fi nlọ àti bí tẹ́mpìlì ṣe nṣe ìrànwọ́ fún yín láti ní ìmọ̀lára sísúnmọ̀ Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì.
-
Ẹ ṣe àtúnyẹ̀wọ̀ kí ẹ sì jíròrò àwọn ìbéèrè ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì papọ̀. A lè wá wọn lórí ojú-ìwé 36–37 ti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́: Ìtọ́nisọ́nà kan fún Ṣíṣe àwọn Àṣàyàn. Ẹ sọ fún ọmọ yín nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ìkaniyẹ tẹ́mpìlì kan. Ẹ ṣe àbápín ìdí tí níní ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì ṣe jẹ́ pàtàkì fún yín.
-
Ẹ ka Málákì 4:6papọ̀. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa bí ọkàn yín ṣe lè yípadà sí àwọn babanlá yín. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ díẹ̀ si nípa àwọn babanlá nípa ṣíṣe ìwákiri ìwé-ìtàn ẹbí yín papọ̀ lórí FamilySearch.org. Ẹ wá àwọn babanlá tí ó nílò láti ṣe ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀. Olùfọ̀rànlọ̀ wọ́ọ̀dù kan fún tẹ́mpìlì àti ìwé-ìtàn ẹbí lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín.
-
Ẹ ṣe àtúnyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ohun èlò inú àkójọpọ̀ tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Tẹ́mpìlì” ní abala àwọn ọmọdé Ibi Ìkàwé Ìhìnrere. (Bákanáà wo “Mímúra Ọmọ Yín Sílẹ̀ fún Àwọn Ìrìbọmi àti Ìfẹsẹ̀múlẹ̀mú Tẹ́mpìlì” lórí ChurchofJesusChrist.org.)
Gbígba Ìbùkún Babanlá kan
Ìbùkún babanlá lè jẹ́ orísun ìtọ́sọ́nà, ìtùnú, àti ìmísí. Ó pẹ̀lú ìmọ̀ràn araẹni fún wa láti ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run ó sì nràn wá lọ́wọ́ láti ní òye ìdánimọ̀ àti èrèdí ayérayé wa. Ẹ ran ọmọ yín lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ láti gba ìbùkún babanlá nípa kíkọ́ wọn ní pàtàkì àti ìwà-ẹ̀dá mímọ́ ti àwọn ì̀bùkún ti babanlá.
Láti kẹọ́ ẹ̀kọ́ sí i, wo Àwọn Àkòrí àti Ìbéèrè, “Ìbùkún Babanlá,” Ibi-Ìkàwé Ìhìnrere.
-
Ẹ ṣe àbàpín ìrírí gbígba ìbùkún babanlá yín pẹ̀lú ọmọ yín. Ẹ lè ṣe àbápín àwọn nkan bí ẹ ṣe múrasílẹ̀ láti gbà á, bí ó ṣe ràn yín lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run, àti bí Ó ṣe ntẹ̀síwájú láti tọ́ọ yín sọ́nà nípasẹ̀ ìbùkún yìí. Ẹ tún lè pe ọmọ yín láti bá àwọn ọmọ ẹbí míràn tí wọ́n ti gba àwọn ì̀bùkún babanlá wọn sọ̀rọ̀.
-
Ẹ ṣe àtúnyẹ̀wò ọ̀rọ̀ Randall K. Bennett papọ̀ “Ìbùkún Babanlá Rẹ—Ìtọ́sọ́nà onimisi láti ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run” àti ọ̀rọ̀ Alàgbà Kazuhiko Yamashita “Ìgbà tí ẹ lè Gba Ìbùkún Babanlá Rẹ” (Làìhọ́nà, Oṣù karun 2023, 42–43, 88–90). Ẹ ṣe àbápín pẹ̀lú ara yín nípa ohun tí ẹ kọ́ látinú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa ìdí tí Baba Ọ̀run ṣe fẹ́ kí á gba ì̀bùkún baba nlá. Láti kọ́ nípa ìlànà gbígba ìbùkún babanlá, wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogboò, 18.17.
-
Bí ẹ bá ní àwọn babanlá tí ó gba àwọn ì̀bùkún baba nlá, ó lè jẹ́ ìmísí láti ka díẹ̀ nínú wọn pẹ̀lú ọmọ yín. Láti bèèrè àwọn ìbùkún ti àwọn babanlá tí ó ti kú, wọlé sí ChurchofJesusChrist.org, tẹ Àwọn irinṣẹ́ ní igun apá ọ̀tún òkè ti ìbòjú, kí ẹ sì yan Ìbùkún Babanlá.
-
Lẹ́hìn tí ọmọ yín ti gba ì̀bùkún babanlá, ẹ pe àwọn ọmọ ẹbí èyíkèyí tí ó wà láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìmọ̀lára wọn kí ẹ sì ṣe àbápín wọn pẹ̀lú ọmọ yín.
Gbígba Ẹ̀bùn Tẹ́mpìlì náà
Ọlọ́run fẹ́ láti fún, tàbí bùkún, gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ pẹ̀lú “agbára láti òkè wá” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 95:8). A nlọ sí tẹ́mpìlì láti gba ẹ̀bùn tiwa lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n a`wọn májẹ̀mú tí a ndá pẹ̀lú Ọlọ́run àti agbára ti ẹ̀mí tí Ó nfún wa gẹ́gẹ́bí ara ẹ̀bùn tẹ́mpìlì náà lè bùkún wa lójojúmọ́ ti ìgbésí ayé wa.
-
Ẹ ṣe àfihàn àwòrán tẹ́mpìlì ní ilé yín. Ẹ sọ fún ọmọ yín nípa àwọn ìmọ̀lára tí ẹ ní ìrírí rẹ̀ nínú ilé Olúwa. Ẹ sọ nígbàgbogbo nípa ìfẹ́ yín fún Olúwa àti ilé Rẹ̀ àti àwọn májẹ̀mú tí ẹ ti ṣe níbẹ̀. Ẹ wá àwọn ayé láti lọ sí tẹ́mpìlì pẹ̀lú ọmọ yín láti ṣe àwọn ìrìbọmi àti àwọn ìfẹsẹ̀múlẹ̀ fún àwọn babanlá wọn.
-
Yẹ temples.ChurchofJesusChrist.org wò papọ̀. Ẹ ka àwọn nkan bíi “Nípa Ẹ̀bùn Tẹ́mpìlì” àti “Mímúrasílẹ̀ fún Ilé Olúwa.” Ẹ jẹ́ ki ọmọ yín bèèrè àwọn ìbèèrè èyíkèyí tí wọ́n ní nípa tẹ́mpìlì. Fún ìtọ́ni nípa ohun tí ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa ìta tẹ́mpìlì, wo ọ̀rọ̀ Alàgbà David A. Bednar “Múrasílẹ̀ láti Gba Gbogbo Nkan tí a Nílò” (Làìhónà, Oṣù karun 2019, 101–4; wo ní pátàkì apákan ti àkolé “Kíkọ́ Ẹ̀kọ́ àti Mímúrasílẹ̀ Tẹ́mpìlì Ààrin-gbungbun-ilé àti Àtìlẹ́hìn-Ìjọ”).
-
Bí ẹyin àti ọmọ yín ṣe nṣe àbápín nínú tàbí jẹri àwọn ìlànà míràn (gẹ́gẹ́bí tàbí ìbùkún ìmúláradá), ẹ wá àkókò kan láti jíròrò lórí àmì tí ó wà nínú ìlànà náà. Kíni àwọn àmì náà rọ́pò? Báwo ni wọ́n ṣe jẹri nípa Jésù Krístì? Èyí lè ran ọmọ yín lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ láti ronú lórí ìtumọ̀ àmì ti àwọn ìlànà tẹ́mpìlì, tí ó tún jẹri nípa Jésù Krístì.
-
Ẹ ràn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe àkíyèsí bí wọ́n ṣe npa májẹ̀mú ìrìbọmi tí a ṣe àpèjúwe nínú Mòsíàh 18:10, 13 mọ́ (bákanáà wo ẹsẹ 8–9, tí ó ṣe àpèjúwe àwọn èso májẹ̀mú náà). Ẹ tún ran ọmọ yín lọ́wọ́ láti kíyèsí bí Olúwa ṣe nbùkún wọn. Ẹ gbé ìgbẹ́kẹ̀lé ọmọ yín sí agbára wọn láti pa àwọn májẹ̀mú mọ́ ga.
-
Ẹ sọ ní gbangba àti nígbàgbogbo nípa bí àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì yín ṣe jẹ́ ìtọ́sọ́nà àwọn yíyàn yín tí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti dàgbà súnmọ́ Jésù Krístì. Ẹ lè wo Ìwé-ìléwọ Gbogboò, 27.2, láti ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn májẹ̀mú tí a ṣe nínú tẹ́mpìlì. Bí ẹ bá ti gba ẹ̀bùn náà, ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín nípa bí ẹ̀wù tẹ́mpìlì ṣe nràn yín lọ́wọ́ láti rántí àwọn májẹ̀mú yín pẹ̀lú Jésù Krístì (wo “Aṣọ Tẹmpili Mímọ́” [fídíò], Ibi Ìkàwé Ìhìnrere; Anette J. Dennis, “Gbé Olúwa Jésù Krístì Wọ̀.,” Làìhónà, Oṣù karun 2024, 10–13).
4:12Sacred Temple Clothing
Sísin Míṣọ̀n
Alàgbà David A. Bednar kọ́ni pé: “Ohun kan ṣoṣo tó ṣe pàtàkì jù lọ tí ẹ lè ṣe láti múrasílẹ̀ fún ìpè láti sìn ni láti di ìránṣẹ́ ìhìnrere tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ kí ẹ tó lọ sí míṣọ̀n. … Ọ̀ràn náà kìí ṣe lílọ sí míṣọ̀n; ṣùgbọ́n, ọ̀ràn náà ni dída ìránṣẹ́ ìhìnrere àti sísìn ní gbogbo ìgbé-ayé wa pẹ̀lú gbogbo ọkàn, agbára, inú, àti okun wa. … Ẹ̀ nmúrasílẹ̀ fún iṣẹ́ ìhìnrere ní gbogbo ọjọ́ ayé yín” (“Dída Ìránṣẹ́ Ìhìnrere kan,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2005, 45–46). Àwọn ìrírí ọmọ yínní dída ìránṣẹ́ ìhìnrere yíò bùkún wọn títí ayérayé, kìí ṣe fún àkókò tí wọ́n lè sìn ní míṣọ̀n nìkan.
Láti kọ́ ẹ̀kọ́ díẹ̀ si, wo Russell M. Nelson, “Wíwàásù Ìhìnrere Àláfíà,” Làìhónà, Oṣù karun 2022, 6–7; Gary E. Stevenson, “Ìfẹ́, Pín, Pè,” Làìhónà,Oṣù karun 2022, 84–87; “Ṣíṣe Àtúnṣe sí Ìgbé-ayé Ọ̀jíṣẹ́,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.
-
Ẹ lè ṣe àbápín ìhìnrere ní àwọn ọ̀nà déédé àti àdánidá. Nígbàgbogbo ẹ máa fojúsọ́nà sí àwọn ànfàní láti ṣe àbápín àwọn ìmọ̀lára yín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nípa Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà àti àwọn ìbùkún tí ẹ gbà látinú ìhìnrere Olùgbàlà tí a ti múpadàbọ̀sípò àti gẹ́gẹ́bí ọmọ Ìjọ Rẹ̀. E pè àwọn míràn láti darapọ̀ mọ́ ẹbí yín nínú àwọn ìṣe Ìjọ àti ẹbí.
-
Ẹ wa àwọn ànfàní fún ẹbí yín láti bárasọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere. Ẹ pè wọ́n láti kọ́ àwọn ọ̀rẹ́ yín, tàbí gbà láti jẹ́ kí wọn kọ́ àwọn ènìyàn ní ilé yín. Ẹ béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere nípa àwọn ìrírí tí wọ́n ní àti bí iṣẹ́ ìsìn ìhìnrere ṣe nràn wọ́n lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jésù Kristi. Ẹ tún bèèrè ohun tí wọ́n ṣe (tàbí fẹ́ kí wọ́n ti ṣe) làti múra láti da ìránṣẹ́ ìhìnrere.
-
Bí ẹ bá sin míṣọ̀n kan, ẹ sọ̀rọ́ ní gbangba àti nígbàgbogbo nípa àwọn ìrírí yín. Tàbí kí ẹ pe àwọn ọ̀rẹ́ tàbí àwọn ọmọ ẹbí tí ó sin míṣọ̀n láti sọ̀rọ̀ nípa tiwọn. Ẹ tún lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà tí ẹ ti ṣe àbápín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn míràn ní gbogbo ìgbé-ayé yín. Ẹ ran ọmọ yín lọwọ lati ronu awọn ọna ti wọn fi lè pín ìhìnrere naa.
-
Ẹ fún ọmọ yín ní ànfàní láti kọ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ẹbí nípa ìhìnrere. Ọmọ yín tun le ṣe adaṣe pinpin àwọn ìgbàgbọ́ wọn pẹ̀lú àwọn míràn. Fun apẹrẹ, ẹ le jíròrò àwọn ìbèèrè bíi “Báwo ni a ṣe lè ṣe àfihàn Ìwe ti Mọ́mọ́nì fún ẹnikan ti kò tíì gbọ́ ọ rí?” tabi “Báwo ni a ṣe lè ṣe àpèjúwe ìwulò fún Olùgbàlà fún ẹnìkan ti kìí ṣe Krìstẹ̀ẹ́nì?” Wo Ahmad S. Corbitt, “Ṣé Ẹ Mọ Ìdí Tí Èmi Bí Krìstẹ́ẹ̀nì Ṣe Gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì?,” Làìhónà, Oṣù Karun 2023, 119–21.)
-
Ẹ ran ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní ìtùnú láti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀. Kíni díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà dídára láti bẹ̀rẹ̀ ìbárasọ̀rọ̀? Ẹ gba ọmọ yín níyànjú láti kọ́ bí wọ́n ṣe lè fetísí ohun ti àwọn míràn nsọ, kí wọ́n ní òye ohun tí ó wà nínú ọkàn wọn, kí wọ́n sì pín àwọn òtítọ́ ìhìnrere tí ó lè bùkún ìgbé-ayé wọn.
-
Ẹ wá àwọn ànfàní fún ọmọ yín lati kọ́ ẹ̀kọ́ nípa àwọn àṣà ati àwọn ìgbàgbọ́ míràn. Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dámọ̀ àti láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ rere àti òtítọ́ nínú àwọn ìgbàgbọ́ ẹlòmíràn.
Gbígba Ìlànà Èdidì
Nínú tẹ́mpìlì, ọkọ àti aya lè ṣe ìgbeyàwó fún ayérayé. Èyí nṣẹlẹ̀ nínú ìlànà kan tí wọ́n npè ní “èdidì tẹ́mpìlì.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlànà yìí lè jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún síwájú fún ọmọbìnrin tàbí ọmọkùnrin yín, àwọn ohun kékeré, tí ó rọrùn, tí ó wà láìyẹsẹ̀ tí ẹ̀ nṣe papọ̀ ní àwọn ọdún wọnnì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ fún ìbùkún àgbàyanu yìí.
-
Ẹ kà papọ̀ “Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àgbáyé” (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere). Kíni ìkéde yìí kọ́ni nípa ìdùnnú nínú ìgbé-ayé ẹbí àti nípa àṣeyege ìgbéyàwó? Pẹ̀lú ọmọ yín, ẹ yan ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí a tòkọ nínú ìkéde náà láti ṣe àṣàrò. Ẹ lè wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ náà mu nínú ìtọ́sọ́nà sí Ìwé mímọ́. Ẹ tún lè gbé àwọn ìlépa kalẹ̀ láti fi ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ náà sí ìlò ní kíkún nínú ẹbí yín. Bí ẹ ti nṣiṣẹ́ lé àwọn ìlépa yín, ẹ jíròrò papọ̀ nípa ipa tí gbígbé ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ náà nní lórí ìgbé-ayé ẹbí.
-
Pẹ̀lú ọmọ yín, ẹ ka ọ̀rọ̀ Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf “Ní Ìyìn Àwọn Tí Ó Gbàlà” (Làìhónà, Oṣù karun 2016, 77–80). Nígbàtí ẹ bá dé ìpín tí ó ní àkolé “Àwùjọ Àwọn Ìsọnù Kan,” ẹ lè wá àwọn nkan nínú ilé yín tí ó jẹ́ nkan ìsọnù àti àwọn ohun míràn tí kìí ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ sọ́rọ́ nípa bí ẹ ṣe ntọ́jú àwọn nkan ní oríṣiríṣi nígbàtí ẹ bá fẹ́ kí wọ́n pẹ́ ní gígùn. Kí ni èyí dá àbá nípa bí ó ṣe yẹ kí a máa ṣe sí ìbáṣepọ̀ ìgbéyàwó àti ẹbí? Kíni ohun míràn tí a kọ́ látinú ọ̀rọ̀ Ààrẹ Uchtdorf nípa bí Olùgbàlà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé àwọn ìgbeyàwó àti àwọn ẹbí alágbára ga?
-
Ẹ sọ fún ọmọ yín nípa àwọn ohun tí ẹ̀yin àti lọ́kọláyà yín nkọ́ nípa ìgbéyàwó ayérayé tí ó ní ààrin-gbùngbùn-Krístì àti àwọn ọ̀nà tí ẹ fi ngbìyànjú lati mú gbèrú. Bí ẹ̀yin àti ọkọ tàbí aya yín bá ti fi èdidì di nínú tẹ́mpìlì, ẹ fi han ọmọ yín nípa àpẹrẹ bí ẹ ṣe ntiraka láti pa àwọn májẹ̀mú yín pẹ̀lú Olúwa mọ́. Ẹ sọ fún ọmọ yín bí ẹ ṣe ntiraka láti mú kí Baba Ọrun àti Olùgbàlà jẹ́ oókan ti ìbáṣepọ̀ yín àti bí Wọ́n ṣe nràn yín lọ́wọ́ (bákanáà wo Ulisses Soares, “Ní Àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Olúwa,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2022, 42–45).
-
Nígbàtí ẹbí bá nílò láti ṣe àwọn ìpinnu, ẹ ṣe àwọn ìgbìmọ̀ ẹbí àti àwọn ìbárasọ̀rọ̀. Ẹ ri dájú pé gbogbo àwọn ọmọ ẹbí ni a gbọ́ ìmọ̀ràn wọn ti a sì mú wọn níyì. Ẹ lo àwọn ìbárasọ̀rọ̀ wọ̀nyí bí ànfàní láti ṣe àpẹrẹ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ lílera àti inúrere nínú àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí, pàápàá nígbà tí kìí ṣe gbogbo ènìyàn ni wọ́n rí àwọn nkan ní ọ̀nà kannáà. (Wo M. Russell Ballard, “Àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹbí,” Làìhónà, Oṣù karun 2016, 63–65.)
-
Nígbà tí èdèàìyédè tàbí asọ̀ bá wà nínú ẹbí, ẹ fi sùúrù àti ìyọ́nú hàn. Ẹ ran ọmọ yín lọ́wọ́ láti rí bí fífi ọ̀nà ìwà bí Krístì yànjú asọ̀ ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ fún ìgbéyàwó aláyọ̀. Ẹ ka Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 121:41–42papọ̀, kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ inú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí ṣe lè wúlò fún ìgbéyàwó.