Come, Follow Me
Àlẹ̀mọ́ D: Fún Àwọn Iyejù Oyèàlùfáà Árọ́nì àti Kíláàsì àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin—Àgbéṣe Ìpàdé


“Àlẹ̀mọ́ D: Fún Àwọn Iyejù Oyèàlùfáà Árọ́nì àti Kíláàsì àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin—Àgbéṣe Ìpàdé,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Àlẹ̀mọ́ D,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026

Àlẹ̀mọ́ D

Fún Àwọn Iyejù Oyèàlùfáà Árọ́nì, àti Kíláàsì àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin—Àgbéṣe Ìpàdé

Àkokò ìpàdé:

Dídarí (ọmọ ẹgbẹ́ kílásì tàbí àjọ ààrẹ):

Bíbẹ̀rẹ̀

Orin (àṣàyàn):

Àdúrà:

Ẹ Tún Àkòrí Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin tàbí Iyejú Oyèalùfáà Áárónì sọ.

Ẹ dámọ̀ràn papọ̀

Ẹnití o ndarí ìpàdé náà, kíláàsì tàbí iyejú nlo ìṣẹ́jú marun sí mẹwa láti dámọ̀ràn papọ̀ nípa àwọn ojuṣe wọn nínú iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga Ọlọ́run. Èyí jẹ́ ànfàní fún kíláàsì tàbí Ààrẹ iyejú láti tẹ̀ lé àwọn ohun kan tí a jíròrò nínú àwọn ìpàdé Ààrẹ tàbí àwọn ìpàdé ìgbìmọ̀ àwọn ọ̀dọ́.

Ẹnití ó ndarí lè tún lo ọ̀kan tàbí díẹ̀ si nínú àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

Gbígbé ìhìnrere

  • Àwọn ìrírí àìpẹ́ wo ni ó ti fún àwọn ẹ̀rí wa nípa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ lokun?

  • Kíni à nṣe láti sún mọ́ Olùgbàlà? Báwo ni ẹ ṣe ngbìyànjú láti dàbí Rẹ̀ síi?

  • Báwo ni a ṣe nní ìmọ̀lára ìdarí Olúwa nínú ayé wa sí?

Títọ́jú àwọn ènìyàn nínú àìní

  • Tani a ti ní ìmọ̀lára ìtọ́sọ́nà láti rànlọ́wọ́ tàbí sìn? Àwọn iṣẹ́ yíyànfúnni wo lati rí gbà láti ran ẹnìkan tí ó wà nínú àìní lọ́wọ́?

  • Àwọn ìpèníjà wo ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ti kíláàsì wa tàbí iyejú ndojú kọ? Báwo ni a ṣe lè nṣe àtìlẹhìn fún ara wa nínú àwọn ohun tí a nlà kọjá?

  • Njẹ́ ẹnìkan ṣẹ̀ṣẹ̀ kó wá sí wọ́ọ̀dù wa láìpẹ́ yí tàbí darapọ̀ mọ́ Ìjọ? Báwo ni a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìkíni káàbọ̀?

Pípe gbogbo-ènìyàn láti gba ìhìnrere

  • Kíni a lè ṣe láti ran àwọn míràn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run?

  • Àwọn ṣíṣé wo ni ó nbọ̀ tí a lè pe àwọn ọ̀rẹ́ wa láti wá?

  • Àwọn ètò láti ṣe àbápín ìhìnrere wo ni a ti jíròrò ní àwọn ìpàdé ìgbìmọ̀ àwọn ọ̀dọ́? Báwo ni kíláàsì tàbí iyejú wa ṣe lè kópa?

Dída àwọn ẹbí pọ̀ fún Ayérayé

  • Kíni díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà ní àsopọ̀ dídára jùlọ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹbi, pẹ̀lú àwọn òbí-àgbà àti àwọn ìbátan?

  • Kíni a nṣe láti rí orúkọ àwọn babanlá wa tí wọ́n nílò àwọn ìlànà tẹ́mpìlì? Kíni a lè ṣe láti ran àwọn míràn lọ́wọ́ láti rí orúkọ àwọn babanlá wọn?

  • Báwo ni a ṣe lè kópa nínú iṣẹ́ tẹ́mpìlì—ní ẹnìkọ̀ọ̀kan àti gẹ́gẹ́bí kíláàsì tàbí iyejú?

Ẹ Kẹkọ Papọ̀

Olùdarí àgbà tàbí ọmọ ẹgbẹ́ ti iyejú tàbí kíláàsì ndarí ìtọ́sọ́nà nípa Wá, Tẹ̀lé Mi kíkà. Wọ́n lo àwọn èrò ṣíṣe àṣàrò nínú Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ. Èrò ṣíṣe àṣàrò pẹ̀lú àmì sẹ́mínárì àmì yí ní ìbámu pẹ̀lú sẹ́mínárì àti ní pàtàkì sí àwọn ọ̀dọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, èyíkéyìí àwọn èrò ṣíṣe àṣàrò ní a lè lo. Ìpín ìpàdé yìí máa ngba nkan bí 35 si 40 iṣẹ́jú.

Ìparí

Ẹnití o ndarí ìpàdé:

  • Njẹ́ ẹ̀rí nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí a kọ́.

  • Ẹ jíròrò bí kíláàsì tàbí iyejú yíò ṣe ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n kọ́—gẹ́gẹ́bí ẹgbẹ́ kan tàbí ẹnikọ̀ọ̀kan.

Àdúrà: