Come, Follow Me
Àlẹ̀mọ́ C: Fún Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀—Àwọn Ìtọ́nisọ́nà fún Àkókò Kíkọrin àti Ìgbékalẹ̀ Ìpàdé Oúnjẹ Olúwa Àwọn Ọmọdé


“Àlẹ̀mọ́ C: Fún Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀—Àwọn Ìtọ́nisọ́nà fún Àkókò Kíkọrin àti Ìgbékalẹ̀ Ìpàdé Oúnjẹ Olúwa Àwọn Ọmọdé,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Àlẹ̀mọ́ C,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026

àwọn ọmọdé nkọrin

Àlẹ̀mọ́ C

Àlẹ̀mọ́ C: Fún Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀—Àwọn Ìtọ́nisọ́nà fún Àkókò Kíkọrin àti Ìgbékalẹ̀ Ìpàdé Oúnjẹ Olùwa Àwọn Ọmọdé

Orin mímọ́ jẹ́ ohun èlò alágbára láti ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ètò ìdùnnú ti Baba Ọ̀run àti àwọn òtítọ́ ìpìlẹ̀ ti ìhìnrere Jésù Krístì. Bí àwọn ọmọdé ṣe nkọrin nípa àwọn ìlànà ìhìnrere, Ẹ̀mí Mímọ́ yíò jẹ́rìí sí òtítọ́ wọn. Àwọn ọ̀rọ̀ àti orin yíò dúró nínú àwọn ọkàn àti ẹ̀mí àwọn ọmọdé ní gbogbo ìgbésí-ayé wọn.

Ẹ wá ìrànlọ́wọ́ ti Ẹ̀mí bí ẹ ṣe nmúra láti kọ́ ìhìnrere nípasẹ̀ orin. Ẹ ṣe àbápín ẹ̀rí yín nípa àwọn òtítọ́ tí ẹ kọrin nípa rẹ̀. Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ri bí orin ṣe ní ìbámu sí ohun tí wọ́n nkọ́ àti ní ìrírí níle àti ní àwọn kílásì Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀.

Àwọn Ìtọ́nisọ́nà fún Ìgbékalẹ̀ Ìpàdé Oúnjẹ Olúwa

Pẹ̀lú ìdarí ti Bíṣọ́pù, ìgbékalẹ̀ ìpàdé oúnjẹ Olúwa ti àwọn ọmọdé ní déédé nwáyé lákokò ìdá kẹ́rin ọdun. Gẹ́gẹ́bí Àjọ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti olùdárí orin, ẹ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú olùdámọ̀ràn nínú bíṣọ́príkì tí ó nṣe àbojútó Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ láti ṣètò ìgbékalẹ̀ náà.

Ìgbékalẹ̀ yẹ kí ó fi àyè gba àwọn ọmọdé láti ṣe àfihàn ohun tí àwọn àti ẹbí wọn ti kọ́ láti Májẹ̀mú Láéláé nílé àti ní Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, pẹ̀lú àwọn orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n ti kọ́ ní àkokò ọdún. Bí ẹ ṣe nṣètò ìgbékalẹ̀ náà, ẹ ronú àwọn ọ̀nà tí ẹ lè fi ṣè ìrànlọ́wọ́ fún ìjọ láti kọjúsí Olùgbàlà àti àwọn ìkọ́ni Rẹ̀.

Àwọn ẹ̀ka tí ó ní nọ́mbà kékeré àwọn ọmọdé lè ronú àwọn ọ̀nà tí àwọn ọmọ ẹbí lè gbà láti kópa pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Ọmọ ẹgbẹ́ bíṣọ́príkì kan lè parí ìpàdé náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ṣókí.

Bí ẹ ṣe nmúra ìgbékalẹ̀ náà, ẹ rántí àwọn ìtọ́nisọ́nà wọ̀nyí:

  • Àwọn ìgbáradì kò yẹ kí ó gba àkokò tí kò yẹ kúrò nínú lọ́wọ́ àwọn kílásì alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tàbí àwọn ẹbí.

  • Àwọn ìwò, àwọn aṣọ, àti àwọn ìgbékalẹ̀ àwùjọ kò tọ́ fún ìpàdé oúnjẹ Olúwa.

Wo Ìwé Ìléwọ́ Gbogbogboò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 12.2.1.2, Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.

àwọn ọmọdé nkọrin

Ìtọ́sọ́nà fún Àkokò Kíkọrin

Ìṣẹ́jú Marun (Ààrẹ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀): Àdúrà ṣíṣí, ìwé mímọ́ tàbí nkan ìgbàgbọ́, àti ọ̀rọ̀ kan

Ìṣẹ́jú Ogún (olùdarí orin): Àkókò kíkọrin

Àjọ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti olùdarí orin yan àwọn orin fún oṣù kọ̀ọ̀kan láti ṣe ìmúdájú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí àwọn ọmọdé nkọ́ ní àwọn kílásì wọn àti nílé. Àtòkọ àwọn orin tí ó ṣe ìmúdájú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí wà nínú ìtọ́sọnà yí.

Bí ẹ ṣe nkọ́ àwọn ọmọdé ní àwọn orin, ẹ pè wọ́n láti ṣe àbápín ohun tí wọ́n ti kọ́ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìtàn àti ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí àwọn orin náà kọ́ni. Ẹ pe àwọn ọmọdé láti ṣe àbápín èrò àti ìmọ̀lára wọn nípa òtítọ́ tí a rí nínú àwọn orin náà.

Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé jẹ́ kókó ohun èlò fún orin nínú Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Àwọn orin látinú ìwé orin àti àwọn orin látinú Fríẹ́ndì tún tọ́. Ẹ tún lè lo àwọn orin látinú Àwọn Orin—Fún Ilé àti Ìjọ. Lílo èyíkéyìí orin míràn nínú Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ ìfọwọ́sí nípasẹ̀ Bíṣọ́pù (wo Ìwé Ìléwọ́ Gbogbogboò, 12.3.4).

Orin fún Àkokò Kíkọrin

Oṣù Ìkínní

  • Baba Mi Ọ̀run Nifẹ Mi,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 228–29

  • Èmi Ó Tẹ̀lẹ́ Ètò Ọlọ́run,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 164–65

Oṣù Èkejì

  • Tẹ̀lé Wòlíì náà,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 110–11

  • Àdúrà Ọmọdé,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 12–13

Oṣù Ẹ̀kẹ́ta

  • Inúrere Bẹ̀rẹ̀ Pẹ̀lú Mi,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 145

  • Mo Nílò Yín Nígbàgbogbo,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 98

Oṣù Kẹ́rin

  • Gẹ́tsémánè,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere

  • Pa Àwọn Òfin Mọ́,” Ìwé Orin Ọmọdé, 146

Oṣù Ẹ̀karún

  • “Àwọn Ibi Mímọ́,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere

  • Bí Mo Ṣe Nwádìí Ìwé mímọ́,” Àwọn orin, nọ́mbà

Oṣù Ẹ̀kẹfà

  • Èmi Yíò Jẹ́ Akọni,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 162.

  • Ẹ Fẹ́ràn Arayin,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 136

Oṣù Èkeje

  • Wádíì, Jíròrò, sì Gbàdúrà,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 109

  • Mo Gbàdúrà nínú Ìgbàgbọ́,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 14

Oṣù Ìkẹjọ

  • Gbóyà láti ṣe ohun Tótọ́,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 158

  • Mo Nímọ̀lára Ìfẹ́ Olùgbàlà Mi,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 74–75

Oṣù Ẹ̀kẹsán

  • Kọ́ Mi láti Rìn nínú Ìmọ́lẹ̀,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 177

  • Ìfẹ́ Ni À Nsọ Nihin,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 190–91

Oṣù kẹ́wàá

  • Tètè Wá Olúwa,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 108.

  • Mo Gbé ni Ọ̀run,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 4

Oṣù Ìkọkànlá

  • Ẹbí Lè Wà Papọ̀ Títíláé,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọd, 188

  • Yan Títọ́,” Àwọn orin, nọ́mbà 239

Oṣù Èkejìlá

  • A Ó Mú Òtítọ́ Rẹ̀ Wáyé,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 172–73

  • Ọkàn Ọmọdé,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 92–93.

Lílo Orin láti Kọ́ Ẹ̀kọ́

Àkókò kíkọrin ni èrò-inú láti ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn òtítọ́ ìhìnrere. Àwọn èrò wọ̀nyí lè fún yín ní ìmísí bí ẹ ṣe nṣètò àwọn ọ̀nà láti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere tí a rí nínú àwọn orin àti àwọn orin alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀.

Ka Ìwé Mímọ́ tó ní ìbámu. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orin tí ó wà nínú Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé àti ìwé Orin ìsìn, àwọn ìtọ́kasí sí àwọn ìwé mímọ́ tí ó ní ìbámu ni a kójọ. Ẹ ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti ka díẹ̀ lára àwọn àyọkà wọ̀nyí, kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ṣe bá orin náà mu. Ẹ tún lè to àwọn ìtọ́kasí ìwé mímọ́ díẹ̀ sórí pátákó náà kí ẹ sì pe àwọn ọmọdé láti tọ́kasí ọ̀kọ̀ọ̀kan sí orin tàbí ẹsẹ kan nínú orin kan.

Dí àlàfo. Kọ ẹsẹ kan orin náà sójú pákó pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tí ó sọnù. Lẹ́hìnnáà sọ fún àwọn ọmọdé láti kọ orin náà, ní fíf etísí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó dí àwọn àlàfo. Bí wọ́n ṣe ndí ọ̀kọ̀ọ̀kan àlàfo, sọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere tí ẹ kọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọnù.

àwọn ọmọdé nkọrin

Jẹ́ Ẹ̀rí Jẹri ṣókí sí àwọn ọmọdé nípa àwọn òtítọ́ ìhìnrere tí a rí nínú orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ náà. Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ní òye pé kíkọ orin jẹ́ ọ̀nà kan tí wọ́n lè jẹri kí wọ́n sì ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí.

Dúró gẹ́gẹ́bí ẹlẹ́rìí kan. Ẹ pè àwọn ọmọdé láti dúró ní ọ`kọ̀ọ̀kan kí wọ́n sì ṣe àbápín ohun tí wọ́n kọ́ nínú orin tí wọ́n nkọ tàbí ìmọ̀lára nípa òtítọ́ tí wọ́n nkọ́ nínú orin náà. Ẹ bèèrè báwo ni wọ́n ṣe ní ìmọ̀lára bí wọ́n ṣe nkọ orin náà, kí ẹ sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ìdánimọ̀ ipa ti Ẹ̀mí Mímọ́.

Ẹ lo àwọn àwòrán. Ẹ sọ fún àwọn ọmọdé láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti wá tàbí dá àwọn àwòrán tí ó lọ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tàbí àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ nínú orin náà sílẹ̀. Ẹ pè wọ́n láti ṣe àbápín bí àwọn àwòrán náà ṣe bá orin náà mu àti ohun tí orin náà kọ́ni. Fún àpẹrẹ, bí ẹ bá nkọ orin náà “Nígbàtí Ó Bá Wá Lẹ́ẹ̀kansi” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 82–83), ẹ lè fi àwọn àwòrán sí gbogbo yàrá tí ó nṣe àfihàn àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì látinú orin náà (bíi àwọn ángẹ́lì, yìnyín, àti ìràwọ̀). Ẹ sọ fún àwọn ọmọdé láti kó àwọn àwòrán jọ kí ẹ sì gbé wọn sókè ní ọ̀nà tí ó tọ́ bí ẹ ṣe nkọrin náà papọ̀.

Ẹ ṣe àbápín kókó ẹ̀kọ́ kan. Ẹ lè lo ohun kan láti ṣe ìmísí fún sísọ̀rọ̀ nípa orin kan. Fún àpẹrẹ, nígbàtí o bá nkọ orin náà “Baba Mi Ọ̀run Nifẹ Mi” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 228–29), ẹ lè fi àwòrán nkan bíi ẹyẹ, òjò, tàbí òdòdó han àwọn ọmọdé. Èyí lè darí sí sísọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe lè rí àwọn àmì ìfẹ́ Baba Ọ̀run ní gbogbo àyíká wa.

Ẹ pè ṣíṣe àbápín àwọn ìrírí ti araẹni. Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti so àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ inú orin pẹ̀lú àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí pọ̀. Fún àpẹrẹ, ṣaájú kíkọrin “Mo Fẹ́ láti Rí Tẹ́mpìlì” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 95), ẹ lè bèèrè lọ́wọ́ àwọn Ọmọdé láti gbé ọwọ́ wọn sókè tí wọ́n bá ti rí tẹ́mpìlì kan. Ẹ pè wọn, bí wọ́n ṣe nkọrin, láti ronú nípa bí wọ́n ṣe nní ìmọ̀lára nígbàtí wọ́n bá rí tẹ́mpìlì kan.

Ẹ bèèrè Àwọn ìbéèrè Àwọn ìbéère púpọ̀ ló wà tí ẹ lè bèèrè bí ẹ ṣe nkọ àwọn orin. Fún àpẹrẹ, ẹ lè bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọdé ohun tí wọ́n kọ́ látinú ẹsẹ kọ̀ọ̀kan nínú orin náà. Ẹ tún lè sọ fún wọn láti ronú nípa àwọn ìbéèrè tí orin náà dáhùn. Èyí lè yọrí sí sísọ̀rọ̀ nípa àwọn òtítọ́ tí a fi kọ́ni nínú orin náà.

Ẹ lo àwọn ìṣe ọwọ́ tí ó rọrùn. Ẹ pe àwọn ọmọdé láti ronú àwọn ìṣe ọwọ́ tí ó rọrùn láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn láti rántí àwọn ọ̀rọ̀ àti àwọn àtẹ̀kọ orin kan. Bí àpẹrẹ, nígbàtí ẹ bá nkọrin “Wá, Jíròrò, Sì Gbàdúrà” (Ìwé Àwọn Ọmọdé, 109), ẹ lè pe àwọn ọmọdé láti tọ́ka sí ojú wọn bí wọ́n ṣe nkọrin nípa wíwá Ìwé Mímọ́, kí wọ́n tọ́ka sí orí wọn bí wọ́n ṣe nkọrin nípa jíjíròrò, kí wọ́n sì di apá wọn bí wọ́n ṣe nkọrin nípa gbígbàdúrà.