“Àlẹ̀mọ́ B: Fún Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀—Mi´múrasílẹ̀ fún Àwọn Ọmọ Yín Fún Ìgbé-ayé ní Ipa-Ọnà Májẹ̀mú ti Ọlọ́run,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Àfikún B,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Àfikún B
Fún Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀—Mímúrasílẹ̀ fún Àwọn Ọmọ Yín Fún Ìgbé Ayé ní Ipa-Ọnà Májẹ̀mú ti Ọlọ́run
Ní àwọn oṣù tí ó ní Ọjọ Ìsinmi marun, a gba àwọn olùkọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ níyànjú láti rọ́po ìṣètò náà Wá, Tẹ̀lé Mi tí a là sílẹ̀ nì ọjọ́ Ìsinmi karun pẹ̀lú ọ̀kan tàbí díẹ̀ síi nípa àwọn ìṣe ikẹkọ wọ̀nyí.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ àti Ìlànà Ìhinrere Jésù Krístì.
Ẹ̀kọ́ Krístì kọ́ wa bí a ṣe lè padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Nígbàtí Jésù Krístì farahan àwọn ènìyàn ní Àmẹ́ríkà, Ó kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ Rẹ̀. Ó sọ pé a lè wọ ìjọba Ọlọ́run bí a bá ní ìgbàgbọ́, tí a ronúpìwàdà, tí a ṣe ìrìbọmi, tí a gba Ẹ̀mí Mímọ́, tí a sì faradà dé òpin (wo 3 Néfì 11:31–40; bákanáà wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:29). Àwọn ìṣe ṣíṣe ìsàlẹ̀ lè ràn yín lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ pé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àti àwọn ìlànà wọ̀nyí yíò ràn wá lọ́wọ́ láti sún mọ́ Olùgbàlà ní gbogbo ìgbésí ayé wa.
Láti kẹkọ díẹ̀ síi nípa ẹ̀kọ́ Krístì, wo 2 Néfì 31.
Àwọn Ìṣe Ṣíṣe tí ó Ṣeéṣe.
-
Fún àwọn ọmọdé ní àwọn àwòràn tí ó dúró fún ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, ìrònúpìwàdà, ìrìbọmi, àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ (wo Ìwé Ọnà Ìhìnrere, nọ́mbà 1, 111, 103, àti 105). Ẹ kà tàbí kà sórí pẹ̀lú àwọn ọmọdé náà ìkẹ́rin nkan ìgbàgbọ́, kí ẹ sì bèèrè lọ́wọ́ wọn láti gbé àwọn àwòràn wọn sóké nígbàtí ẹ bá mẹ́nuba ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tàbí ìlànà náà. Ẹ ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti ní òye bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àti àwọn ìlànà wọ̀nyí ṣe nràn wá lọ́wọ́ láti dàbi Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì síi.
-
Báwo ni ẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti ní òye pé ìgbàgbọ́, ìrònúpìwàdà, ìrìbọmi, àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ kì í ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà kan ṣoṣo ṣùgbọ́n ó nní ipa lórí ìdàgbàsókè ti ẹ̀mí wa ní gbogbo ìgbésí ayé wa? Ẹ lè fi àwòràn irúgbìn àti igi nlá kan hàn wọ́n (tàbí ya nkan wọ̀nyí lórí pákó). Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn nkan tó máa jẹ́ kí irúgbìn náà dàgbà di igi nlá, irú bí omi, ilẹ̀, àti ìmọ́lẹ̀-oòrùn. Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí i pé àwọn nkan wọ̀nyí dà bí àwọn ohun tí a nṣe láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbésí ayé wa—gbígbé ìgbàgbọ́ wa lé Jésù Krístì, níní ìrònúpìwàdà lójojúmọ́, gbígbé májẹ̀mú ìrìbọmi, ṣíṣe àbápín oúnjẹ olúwa, àti gbígba Ẹ̀mí Mímọ́.
-
Ẹ ṣe àbápín ọ̀rọ̀ ìtàn nípa aparun náà láti ọwọ́ Alàgbà Dale G. Renlund pẹ̀lú àwọn ọmọdé “Báwo ni Ìrònúpìwàdà Ṣe Lè Rànmílọ́wọ́ Láti Ní Ìdùnnú?” (Ọ̀rẹ́, Oṣù kéjìlá 2017, 12–13, tàbí Làìhónà, Oṣù kejìlá 2017, 70–71; bákanáà wo fídíò náà “Ìrònúpìwàdà: Yíyàn Aláyọ̀ Kan” [Ibi Ìkàwé Ìhìnrere]). Ní oríṣiríṣi ọ̀nà nígbà ìtàn náà, pe àwọn ọmọdé láti ronú nípa bí nkan ṣe ti rí lára Alàgbà Renlund. Kínìdí tí a fi nní ayọ̀ tí a bá ronúpìwàdà? Ẹ ṣe àbápín ayọ̀ àti ìfẹ́ tí ẹ ní ìmọ̀lára rẹ̀ nígbàtí ẹ bèèrè lọ́wọ́ Baba Ọ̀run láti dáríjì yín pẹ̀lú àwọn ọmọdé.
4:36Repentance: A Joyful Choice
Ìrìbọmi
Jésù Kristi fi àpẹrẹ lélẹ̀ fún mi nígbàtí Ó ṣèrìbọmi.
Bíótilẹ̀jẹ́pé Jésù kò ní ẹ̀ṣẹ̀, Ó ṣe ìrìbọmi láti fi àpẹrẹ pípé kan lélẹ̀ nípa ìgbọràn sí Baba Ọ̀run (wo 2 Néfì 31:6–10).
Láti kẹkọ díẹ̀ si nípa ìrìbọmi, wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:37; Àwọn Àkọlé Àti Ìbéèrè, “Ìrìbọmi,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.
Àwọn Ìṣe Ṣíṣe tí ó Ṣeéṣe.
-
Ẹ ṣe àfihàn àwòrán ìrìbọmi Olùgbàlà àti ìrìbọmi ẹlòmíràn (tàbí wo Ìwé Iṣẹ́ ọnà Ìhìnrere, nọ́mbà 35 àti bóyá nọ́mbà 103 tàbi nọ́mbà 104). Ẹ ní kí àwọn ọmọdé láti ṣe àbápín ohun tí ó yàtọ́ àti ohun tí ó jẹ́ ọ̀kannáà ní àárín àwọn àwòrán méjì. Ẹ ka Máttéù 3:13–17 papọ̀ tàbí “Ọrí 10: Jésù Ṣe Ìrìbọmi” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Titun, 26–29. Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé tọ́ka sí àwọn nkan tí ó wà nínú àwọn àwòrán tí wọ́n gbọ́ nínú àwọn ìtàn wọ̀nyí. Ẹ sọ fún àwọn ọmọdé nípa ìfẹ́ yín fún Olùgbàlà àti ìfẹ́ yín láti tẹ̀lé E.
1:52Chapter 10: Jesus Is Baptized
-
Ẹ fẹ́tísílẹ̀ tàbí kọ orin kan nípa ìrìbọmi, irú bíi ““Nígbàtí A Ṣe ìrìbọmi Jésù Krístì” (Ìwé Orin Awọn ọmọdé, 102). Kíni a kọ́ nípa ìrìbọmi nínú orin náà? Ẹ ka 2 Néfì 31:9–10, kí ẹ sì pe àwọn ọmọ láti gbọ́ èrèdí tí Jésù Krístì fi ṣe ṣe ìrìbọmi. Ẹ pè wọ́n láti ya àwòrán ar wọn ní ọjọ́ ìrìbọmi wọn.
Mo lè yàn láti bá Ọlọ́run dá májẹ̀mú kí nsì ṣe ìrìbọmi.
Mímúrasílẹ̀ fún ìrìbọmi túmọ̀ sí púpọ̀ ju mímúra sílẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ kan. Ó túmọ̀ sí mímúrasílẹ̀ láti dá májẹ̀mú àti lẹ́hìnnáà pípa májẹ̀mú náà mọ́ fún gbogbo ọjọ́ ayé. Ẹ ronú nípa bí ẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti ní òye májẹ̀mú tí wọn yíò bá Baba Ọ̀run dá nígbàtí wọ́n bá ṣe ìrìbọmi, tí ó pẹ́lú àwọn ìlérí tí Ó ṣe fún wọn àti àwọn ìlérí tí wọ́n ṣe fún Un.
Àwọn Ìṣe Ṣíṣe tí ó Ṣeéṣe.
-
Ẹ ṣe àlàyé pé májẹ̀mú jẹ́ ìlérí ní àárín ènìyàn àti Baba Ọ̀run. Bí a ti nlàkàkà láti pa àwọn ìlérí wa mọ́, Ọlọ́run ṣe ìlérí láti bùkún wa. Ẹ kọ̀ àwọn ìlérí mi sí Ọlọ́run sí orí pákó àti àwọn ìlérí mi sí Ọlọ́run. Ẹ kà Mósíàh 18:10, 13 papọ̀ àti Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:37, kí ẹ sì ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ṣe àtòkọ àwọn ìlérí tí wọ́n rí lábẹ́ àwọn àkọlé tí ó yẹ (bákanáà wo Dallin H. Oaks, “Májẹ̀mú Ìrìbọmi Rẹ,” Fríẹ́ndì, Oṣù kejì 2021, 2–3). Ẹ ṣe àbápín bí Baba Ọ̀run ti bùkún fún yín bí ẹ ṣe nlàkàkà láti pa májẹ̀mú ìrìbọmi yín mọ́.
-
Ẹ ṣe àfihàn àwọn àwòrán ohun tí Jésù Krístì ṣe fún àwọn ọmọdé ní àkokò iṣẹ́-ìránṣẹ́ Rẹ̀ (fún àwọn àpẹrẹ díẹ̀, wo Ìwé Ọnà Ìhìnrere, nọ́mbà 33–49). Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ sọ ohun tí Jésù ńṣe nínú àwòrán kọ̀ọ̀kan. Ka Mòsíàh 18:8–10, 13, kí ẹ sì pe àwọn ọmọdé láti fetísílẹ̀ fún àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè fi pa májẹ̀mú ìrìbọmi mọ́ (bákanáà wo “Májẹ̀mú Ìrìbọmi Mi,” Làìhónà, Oṣù kẹ́jọ 2023, 10–11). Báwo ni májẹ̀mú ìrìbọmi ṣíṣe ṣe lè nípa lórí ìṣe wa lójojúmọ́? Pe àwọn ọmọdé láti ya àwòrán ara wọn ní ríran ẹnìkan lọ́wọ́ ní ọ̀nà tí Jésù ṣe.
Ìfẹsẹ̀múlẹ̀
Nígbàtí mo ṣe ìrìbọmi tí a sì fẹsẹ̀mimúlẹ̀, mo di ọmọ ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.
Jíjẹ́ ọmọ Ìjọ ti Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn nmú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbùkún wa, pẹ̀lú àwọn ààyè fún àwọn ọmọdé láti jẹ́ alabaṣe aláápọn nínú iṣẹ́ Ọlọ́run.
Àwọn Ìṣe Ṣíṣe tí ó Ṣeéṣe.
-
Ẹ pe ẹnìkan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìrìbọmi tí ó sì fẹsẹ̀múlẹ̀ láti wá sí kíláàsì kí ó ṣe àbápín ohun tí ó túmọ̀sí láti ṣe fẹsẹ̀múlẹ̀. Ẹ sọ fún ẹnì yí làti sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó túmọ̀ sí fún un láti di ọmọ Ìjọ Jésù Krístì tí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ọ̀nà láti pa májẹ̀mú ìrìbọmi mọ́ gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọ Ìjọ. Ẹ ṣe àbápín bí ṣíṣe àwọn nkan wọ̀nyí ti ṣèrànlọ́wọ́ fún yín láti ní ìmọ̀lára ayọ̀ ti jíjẹ́ ọmọ Ìjọ Krístì.
-
Ẹ ṣe àfihàn àwòrán kan nípa àwọn ènìyàn létí Omi Mọ́mọ́nì (wo Ìwé Ọnà Ìhìnrere, nọ́mbà 76), kí ẹ sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọdé láti ṣe àpèjúwe ohun tí wọ́n rí nínú àwòràn náà. Ẹ sọ ìtàn Álmà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n ṣe ìrìbọmi níbẹ̀ (wo Mòsíàh 18:1–17; “Álmà ní ibi Omi Mọ́mọ́nì,” nínú Ìwé Ìtàn Mọ́mọ́nì). Ẹ ṣe àtúnyẹ̀wò Mòsíàh 18:8–9 kí ẹ sì pe àwọn ọmọdé láti ṣe àwọn ìṣe láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn láti rántí àwọn ohun tí àwọn ènìyàn fẹ́ láti ṣe gẹ́gẹ́bí ọmọ Ìjọ Krístì. Ẹ ṣe àbápín ìrírí kan nígbàtí ẹ ti jẹri àwọn ọmọ ìjọ tó nṣiṣẹ́ ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí.
2:41Alma at the Waters of Mormon
Nígbàtí mo ṣe fẹsẹ̀múlẹ̀, mo gba ẹ̀bún Ẹ̀mí Mímọ́.
Nígbàtí a bá ṣe ìrìbọmi tí a sì ṣe fẹsẹ̀múlẹ̀, Baba Ọ̀run ṣe ìlérí pé a “le ní Ẹ̀mí rẹ̀ nígbà gbogbo láti wà pẹ̀lú [wa]” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú). Ẹ̀bùn àgbàyanu láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a npè ní ẹ̀bùn Ẹmí Mímọ́.
Láti kẹkọ sí i nípa ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí Mímọ́, wo, “Àwọn Ìṣítí ti Ẹ̀mí,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2023, 42–45; Àwọn Àkọlé àti Ìbéèrè, “Ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí Mímọ́.,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.
Àwọn Ìṣe ṣíṣe tí ó Ṣeéṣe.
-
Ẹ ka Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 33:15, kí ẹ sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọdé láti fetísí ẹ̀bùn pàtàkì tí Baba Ọ̀run fún wa nígbàtí a bá ti ṣe rìbọmi tí a sì ṣe fẹsẹ̀ wa múlẹ̀. Láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹkọ sí i nípa bí ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́, ẹ ṣe àtúnyẹ̀wò papọ̀ Jòhánnù 14:26; Gàlátíà 5:22–23; 2 Néfì 32:5; 3 Néfì 27:20. Ẹ tún lè ṣe àtúnyẹ̀wò nkan náà “Ẹ̀bùn Pàtàkì Kan” (Làìhónà, Oṣù kẹ́jọ 2023, 18–19).
-
Ṣaájú kíláàsì, ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn òbí ọ̀kan tàbí díẹ̀ si ti àwọn ọmọdé láti ṣe àbápín bí a ti bùkún wọn nítorí wọ́n ní ẹ̀bùn ti Ẹmi Mimọ. Báwo ni Ó ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́? Báwo ni wọ́n ṣe gbọ́ ohùn Rẹ̀?
-
Ẹ kọ orin kan papọ̀ nípa Ẹ̀mí Mímọ́, gẹ́gẹ́bí “Ẹmí Mímọ́” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 105). Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ní òye ohun tí orin náà kọ́ wa nípa bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́.
Ẹ̀mí mímọ́ lè bá mi sọ̀rọ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà.
Àwọn ọmọ tí wọ́n lè dá ohùn Ẹ̀mí mọ̀ yíò múrasílẹ̀ láti gba ìfihàn ti araẹni láti tọ́ wọn sọ́nà ní gbogbo ìgbésí ayé wọn. Ẹ ran wọ́n lọ́wọ́ láti ní òye pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà tí Ẹmí Mímọ́ lè bá wa sọ̀rọ̀ ló wà.
Àwọn Ìṣe Ṣíṣe tí ó Ṣeéṣe.
-
Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ronú nípa onírurú ọ̀nà tí a lè gbà bá ọ̀rẹ́ wọn kan tí ó wà ní ọ̀nà jíjìn sọ̀rọ̀, bíi kíkọ lẹ́tà, fífi í-meèlì ránṣẹ́, tàbí sísọ̀rọ̀ lórí fóònù. Ẹ kọ́ wọn pé Baba Ọ̀run lè bá wa sọ̀rọ̀ ní àwọn ọ̀nà oríṣiríṣi nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Lo ọ̀rọ̀ Alàgbà President Dallin H. Oaks “Báwo ni Baba Ọ̀run Ṣe Nbáwa Sọ̀rọ̀?” láti ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti ní òye àwọn ọ̀nà oríṣiríṣi tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi lè sọ̀rọ̀ sí inú àti ọkàn wa (Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹ́ta 2020, 2–3, tàbí Làìhónà, Oṣù kẹ́ta 2020, F2–F3).
-
Ẹ ṣe àbápín ìrírí kan nígbàtí Ẹ̀mí Mímọ́ bá yín sọ̀rọ̀, yálà nípasẹ̀ àwọn èrò yín tàbí nípa ìmọ́lára inú ọkàn yín (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 6:22–23; 8:2–3; bákanáà wo Henry B. Eyring, “Ṣí Ọkàn Rẹ sí Ẹ̀mí Mímọ́,” Làìhónà, Oṣù kẹjọ 2019, F2–F3). Ẹ jẹri fún àwọn ọmọdé pé Ẹ̀mí Mímọ́ lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn ní ọ̀nàkannáà.
-
Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti mọ àwọn àkokò tí wọ́n ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí—fún àpẹrẹ, nígbàtí wọ́n bá nkọ orin kan nípa Olùgbàlà tàbí nígbàtí wọ́n nṣe inúrere fún àwọn ẹlòmíràn. Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ìmọ̀lára ẹ̀mí tí Ẹ̀mí Mímọ́ mú wá, ní pàtàkì àwọn ìṣílétí Rẹ̀ láti ṣe ìṣe. Kínìdí tí ẹ rò pé Ẹ̀mí Mímọ́ fi nfún wa ní àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí? Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ohun tí a nílò láti ṣe láti gbọ́ tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá nbá wa sọ̀rọ̀. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ẹ ṣe láti gbọ́ Ẹ̀mí ní kedere díẹ̀ síi.
Oúnjẹ Olúwa Náà
Nígbàtí mo bá jẹ́ oúnjẹ Olúwa, mo nrántí ìrúbọ Olùgbàlà mo sì ndá májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀.
Nígbàtí a bá nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, a ndá májẹ̀mú láti rántí Olùgbàlà nígbàgbogbo, gbé orúkọ Rẹ̀ sórí wa, kí a sì pa àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ mọ.
Láti kẹkọ síi, wo Máttéù 26:26–30; 3 Néfì 18:1–12; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20:77, 79.
Àwọn Ìṣe Ṣíṣe tí ó Ṣeéṣe.
-
Ẹ pe àwọn ọmọdé láti kun “Jésù Ṣe Àfihàn Oúnjẹ Olúwa sí Àwọn Ará Néfì” nínú Ìtàn Ìwé mímọ́ Kíkún: Ìwé Mọ́mọ́nì (2019), 26. Ẹ sọ fún wọn láti tọ́ka sí ohun tí àwọn ènìyàn nrònú nípa nínú àworan náà. Ẹ kà àwọn ìpín ti 3 Néfì 18:1–12 sí w`ọn ọmọdé tàbí “Jésù Pín Oúnjẹ Olúwa,” nínú Àwọn Ìwé Ìtàn Mọ́mọ́nì. Kíni a lè ṣe láti rántí Jésù Krístì ní àkokò oúnjẹ Olúwa?
-
Ẹ sọ fún àwọn ọmọdé láti sọ díẹ̀ nínú àwọn ohun tí ó yẹ kí wọ́n rántí nígbàgbogbo láti ṣe fún yín, bíi díde bàtà wọn tàbí fífọ ọwọ́ wọn ṣaájú kí wọ́n tó jẹun. Kínìdí tí ó fi ṣe pàtàkì láti rántí àwọn nkan wọ̀nyí? Ẹ ka Mórónì 4:3 sí àwọn ọmọdé, kí ẹ sì pè wọ́n láti fetísí ohun tí a ṣèlérí láti rántí nígbàgbogbo nígbàtí a bá ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa. Kínìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká rántí Jésù Kristi? Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ní òye bí búrẹ́dì àti omi oúnjẹ Olúwa ṣe nràn wá lọ́wọ́ láti rántí ohun tí Jésù ti ṣe fún wa (wo Mórónì 4:3; 5:2).
-
Ẹ kọ sí pákó “Mo ṣèlérí láti …” Ẹ ka àwọn àdúrà oúnjẹ Olúwa sí àwọn ọmọdé (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20:77, 79). Nígbàtí wọ́n bá gbọ́ ìlérí tí a ṣe fún Ọlọ́run, ẹ dáwọ́dúró kí ẹ sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti parí gbolohùn ọ̀rọ̀ tí ó wà lójú pákó pẹ̀lú ìlérí tí wọ́n gbọ́.
-
Kíni ó túmọ̀ sí láti gbé orúkọ Jésù Kristi lé ara wa? Láti ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè yí, ẹ ṣe àbápín àpẹrẹ ohun kan tí a fi orúkọ wa lé. Kínìdí tí a fi fi àwọn orúkọ wa sí àwọn nkan wọ̀nyí? Kínìdí tí Jésù Krístì yíò fẹ́ láti gbé orúkọ Rẹ̀ lé ara wa? Ẹ gbèrò ṣíṣe àbápín àlàyé yí láti ọ̀dọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson: “Gbígbé orúkọ Olùgbàlà lé ara wa pẹ̀lú kìkéde àti jijẹri fún àwọn ẹlòmíràn—nípasẹ̀ ìṣe wa àti àwọn ọ̀rọ̀ wa—pé Jésù ni Krístì náà” (“Orúkọ Títọ́ ti Ìjọ,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2018, 88).
Agbára, Àṣẹ, àti àwọn kọ́kọ́rọ́ Oyèàlùfáà
Ọlọ́run nbùkún àwọn ọmọ Rẹ̀ nípasẹ̀ agbára oyèàlùfáà.
Gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run—lákọ àti lábo, ọ̀dọ́ àti àgbà—gba agbára Ọlọ́run bí wọ́n ṣe npa àwọn májẹ̀mú tí wọ́n ti dá pẹ̀lú Rẹ̀ mọ́. A dá àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí nígbàtí a bá gba àwọn ìlànà oyèàlùfáà gẹ́gẹ́bí ìrìbọmi (wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 3.5, 3.6, Ibi Ìkàwé Ìhìnrere). Láti kẹkọ díẹ̀ si, wo Russell M. Nelson, “Àwọn Ìṣúra ti ẹ̀mí,” Làíhónà, Oṣù kọkànlá 2019, 76–79; “Àwọn Ìlànà Oyèàlùfáà,” orí 3 nínú Ìwé-ìléwọ́ Gbogboò.
Àwọn Ìṣe Ṣíṣe tí ó Ṣeéṣe.
-
Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ṣe àkíyèsí àwọn ìbùkún tí wọ́n gbà nítorì oyèàlùfáà. Láti fún wọn ní àwọn èrò, ẹ lè fi fídíò náà “Àwọn Ìbùkún Oyèàlùfáà” (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere) hàn. Ẹ gbèrò ṣíṣe àtòkọ àwọn ìbùkún wọ̀nyí lójú pákó. Kínìdì tí àwọn ìbùkún wọ̀nyí fi ṣe pàtàkì sí wa? Ẹ jẹri pé àwọn ìbùkún wọ̀nyí nwá sọ́dọ̀ wa nítorí Jésù Krístì àti agbára oyèàlùfáà Rẹ̀.
3:5Blessings of the Priesthood
-
Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti wá àwọn àwòrán tí ó ṣe àpèjúwe bí Ọlọ́run ṣe nlo agbára Rẹ̀ láti bùkún wa. Fún àpẹrẹ, wọ́n lè rí àwòrán ayé tí Ó dá fún wa, àwọn àpẹrẹ ìmúláradá àwọn aláìsàn, àti àwọn ìlànà mímọ́ tí Ó ti pèsè fún wa (wo Ìwé Ọnà Ìhìnrere, nos. 3, 46, 104, 105, 107, 120). Ẹ ṣe àbápín èrèdí tí ẹ fi dúpẹ́ fún oyèàlùfáà àti àwọn ìbùkún tí ó mú wá. Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ìrírí nígbàtí agbára oyèàlùfáà Ọlọ́run bùkún wọn.
-
Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà pàtàkì tí a fi ngbà àwọn ìbùkún agbára Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé wa ni nípasẹ̀ àwọn ìlànà oyèàlùfáà (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:20). Láti ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ yìí, ẹ lè ṣe àtòkọ àwọn ìwé mímọ́ wọ̀nyí sínú pákó: 3 Néfì 11:21–26, 33 (ìrìbọmi); Mórónì 2 (ìfẹsẹ̀múlẹ̀); Mórónì 4–5 (oúnjẹ Olúwa). Àwọn ọmọdé náà lè yan ọ̀kan nínú àwọn àyọkà wọ̀nyí kí wọ́n sì dá ìlànà tí ó ṣe àpèjúwe mọ̀. Pe àwọn ọmọdé láti ṣàbápín bí a ti bùkún wọn fúnra wọn nípa gbígba àwọn ìlànà oyèàlùfáà.
-
Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ní òye pé wọ́n yíò gba agbára láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí wọ́n ṣe nṣe ìrìbọmi tí wọ́n sì npa májẹ̀mú ìrìbọmi wọn mọ́. Ẹ sọ fún àwọn ọmọdé bí agbára yí ṣe lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn.
Iṣẹ́ Ọlọ́run ni à ndarí nípasẹ̀ àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà tí a sì nṣe àṣeparí rẹ̀ nípasẹ̀ àṣẹ oyèàlùfáà.
Nígbàkúgbà tí a bá ya ènìyàn sọ́tọ̀ fún ìpè tàbí yàn láti ṣe ìrànlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Ọlọ́run, lóbìnrin tàbí lọ́kùnrin lè lo àṣẹ oyèàlùfáà tí a yàn. Ní àfikún, àwọn ọmọ ìjọ ọkùnrin tí ó yẹ lè ní oyèàlùfáà tí a fi fún wọn kí a sì yàn wọ́n sí ipò oyèàlùfáà. Lílo gbogbo àṣẹ oyèàlùfáà nínú Ìjọ jẹ́ dídarí nípasẹ̀ àwọn olùdarí tí wọ́n di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà mú, gẹ̀gẹ̀bì ààrẹ èèkàn, bíṣọ́pù, àti àwọn ààrẹ iyejú. Àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà jẹ́ àṣẹ láti darí lílo oyèàlùfáà ní ṣíṣe iṣẹ́ Olúwa.
Àwọn Ìṣe Ṣíṣe tí ó Ṣeéṣe.
-
Ẹ ka Márkù 3:14–15, pẹ̀lú àwọn ọmọdé kí ẹ sì fi àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ṣe àpèjúwe níbẹ̀ hàn wọ́n (bíi Ìwé Ọnà Ìhìnrere, nọ́mbà 38). Ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọdé tí wọ́n bá ti rí ẹnìkan tí a yà sọ́tọ̀ fún ìpè tàbí yàn sí ipò oyèàlùfáà rí (tàbí sọ fún wọn nípa àwọn ìrírí tí ẹ ti ní). Báwo ni èyí ṣe jọra pẹ̀lú ohun tí Olùgbàlà ṣe pẹ̀lú àwọn Àpọ́sítélì Rẹ̀? Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ṣe àtòkọ àwọn ìpè tàbí àwọn ipò oyèàlùfáà tí a lè fi fún àwọn ọmọ Ìjọ, bíi olùkọ́ tàbí olórí nínú ètò ìkójọ kan sójú pákó. Ẹ tẹ̀lé ìpè kọ̀ọ̀kan tàbí ipò, ẹ lè kọ ohun tí ẹnìkan tí ó ní ìpè tàbí ipò ní àṣẹ láti ṣe. Ẹ sọ fún àwọn ọmọdé bí ẹni tí a yà sọ́tọ̀ nípasẹ̀ ẹnìkan pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà ti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti sìn.
-
Ẹ pe àwọn ọmọdé láti ronú nkan tí ẹ nílò kọ́kọ́rọ́ fún, bíi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tàbí ilẹ̀kùn. Kíni yíò ṣẹlẹ̀ tí ẹ kò bá ní kọ́kọ́rọ́ náà? Ẹ ka Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 65:2, papọ̀ kí ẹ sì ṣe àbápín ẹ̀rí yín nípa pàtàkì níní àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà. Ẹ tún lè wo fídíò náà “Níbo Ni Àwọn kọ́kọ́rọ́ náà Wà?” (Ibi Ikàwé Ìhìnrere) kí ẹ sì wá ohun tí Alàgbà Gary E. Stevenson kọ́ nípa àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà.
2:51Where Are the Keys?
Tẹ́mpìlì àti Ètò Ìdùnnú
Tẹ́mpìlì jẹ́ ilé Olúwa.
Àwọn tẹ́mpìlì jẹ́ ara kan ti ètò Baba Ọ̀run fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Nínú àwọn tẹ́mpìlì, a ndá májẹ̀mú mímọ́ pẹ̀lú Rẹ̀, a nfún wa ní agbára oyèàlùfáà láti òkè, gba ìfihàn, ṣe àwọn ìlànà fún àwọn babanlá wa tó ti kú, a sì nfi èdidì di àwọn ẹbí wa fún ayérayé. Gbogbo èyí ṣeé ṣe nítorí Jésù Krístì àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀
Báwo ni ẹ ṣe lè ran àwọn ọmọdé tí ẹ̀ nkọ́ lọ́wọ́ láti mọ jíjẹ́-mímọ́ ti ilé Olúwa kí wọ́n sì múra ara wọn sílẹ̀ láti yẹ láti kópa nínú àwọn ìlànà tẹ́mpìlì? Ẹ gbèrò ṣíṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ohun èlò wọ̀nyí: Russell M. Nelson, “Tẹ́mpìlì Náà àti Ìpìlẹ̀ Ẹ̀mí Rẹ,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2021, 93–96; “Ìdí tí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn Tí Wọ́n Kọ́ Tẹ́mpìlì,” temples.ChurchofJesusChrist.org.
Àwọn tẹ́mpìlì jẹ́ ara kan ti ètò Baba Ọ̀run fún àwọn ọmọ Rẹ̀.
Àwọn Ìṣe Ṣíṣe tí ó Ṣeéṣe.
-
Ẹ ṣe àfihàn ọ̀kan tàbí díẹ̀ si lára àwọn àwòrán tẹ́mpìlì. Ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọdé ohun tí ó jẹ́ kí tẹ́mpìlì jẹ́ ààyè pàtàkì kan. Tọ́ka sí i pé lára tẹ́mpìlì kọ̀ọ̀kan ni àkọlé yi wà: “Mímọ́ sí Olúwa—Ilé Olúwa.” Ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọdé ohun ti wọn ro pe “Iwa-mimọ si Oluwa” lè túmọ̀ sí. Kínìdí tí a fi npe tẹ́mpìlì ní ilé Olúwa? Kíni èyí kọ́ wa nípa tẹ́mpìlì? Bí èyíkèyí nínú àwọn ọmọdé náà bá ti lọ sí tẹ́mpìlì, wọ́n tún lè ṣe àbápín bí wọ́n ṣe ní ìmọ̀lára nígbàtí wọ́n wà níbẹ̀. Bí ẹ bá ti lọ sí tẹ́mpìlì, ṣàbápín ìmọ̀lára tí ẹ ní níwájú Olúwa níbẹ̀, kí o sì sọ ìdí tí tẹ́mpìlì fi jẹ́ ibi mímọ́ fún yín.
-
Ẹ ka Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 97:15–17papọ̀. Ẹ ní kí àwọn ọmọdé wa ohun tí Olúwa nretí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n wọ ilé mímọ́ Rẹ̀. Kínìdí tí a nílò láti yẹ láti wọ ilé Rẹ̀? Gẹ́gẹ́bí ara kan ìbáraẹnisọ̀rọ̀ yi, ẹ sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọdé nípa àwọn ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì, pẹ̀lú bí ẹ ṣe lè gbà ọ̀kan. Ẹ lè pe ọmọ ẹgbẹ́ Bíṣọ̀prìk láti ṣe àbápín pẹ̀lú wọn ohun tí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì jẹ àti àwọn ìbéèrè tí a nbèèrè nínú ọkan.
Nínú tẹ́mpìlì, a nbá Ọlọ́run dá májẹ̀mú.
Áárẹ̀ Russell M. Nelson kọ́ni, “Jésù Krístì pè wá láti gba ipa ọ̀nà májẹ̀mú padà sílé sí ọ̀dọ̀ Àwọn Òbí wa Ọ̀run kí a sì wà pẹ̀lú àwọn tí a fẹ́ràn” (“Wá, Tẹ̀lé Mi,” Làìhónà, Oṣù karun 2019, 91). Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ní òye pé ipa ọ̀nà májẹ̀mú pẹ̀lú ìrìbọmi, ìfẹsẹ̀múlẹ̀, àti ẹ̀bùn tẹ́mpìlì àti èdidì.
Àwọn Ìṣe Ṣíṣe tí ó Ṣeéṣe.
-
Ẹ ní kí àwọn ọmọdé láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn májẹ̀mú tí a dá pẹ̀lú Ọlọ́run nígbàtí a bá nṣe ìrìbọmi àti nígbàtí a bá nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa (wo Mòsíàh 18:10, 13; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20:77, 79). Ẹ ṣe àfihàn àwòrán tẹ́mpìlì, kí ẹ sì ṣe àlàyé pé Baba Ọ̀run ní àwọn ìbùkún díẹ̀ si tí Ó fẹ́ láti fún wa nínú tẹ́mpìlì.
-
Ẹ ya ẹnu-ọ̀nà tí ó lọ sí ipa ọ̀nà kan. Ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọdé èrèdí tí wọ́n fi rò pé ó ṣe ìrànlọ́wọ́ láti ní ọ̀nà láti rìn lórí rẹ̀. Ẹ ka 2 Néfì 31:17–20, papọ̀ níbi tí Néfì ti fi májẹ̀mú ìrìbọmi wé ẹnu-ọ̀nà kan tí ó sì pè wá láti tẹ̀síwájú ní ipa ọ̀nà lẹ́hìn ìrìbọmi. Àwọn májẹ̀mú púpọ̀ wà láti ṣe lẹ́hìn ìrìbọmi, títí kan àwọn májẹ̀mú tí a nṣe nínú tẹ́mpìlì. Ẹ ṣe àlàyé pé Ààrẹ Nelson ti pe ipa ọ̀nà yí ní “ipa ọ̀nà májẹ̀mú.”
Nínú tẹ́mpìlì, a lè ṣe ìrìbọmi kí a sì ṣe ìfẹsẹ̀múlẹ fún àwọn baba nlá tí wọ́n ti kú.
Ìhìnrere Jésù Krístì jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run láti padà láti gbé pẹ̀lú Rẹ̀, pàápàá tí wọ́n bá kú láì mọ ìhìnrere náà. Nínú tẹ́mpìlì, a lè ṣe ìrìbọmi kí a sì ṣe ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ní ipò wọn.
Àwọn Ìṣe Ṣíṣe tí ó Ṣeéṣe.
-
Ẹ sọ̀rọ̀ nípa àkókò kan tí ẹnìkan ṣe ohun kan fún yín tí ẹ kò lè ṣe fúnra yín. Ẹ pe àwọn ọmọdé láti ṣe àbápín ìrírí tí wọ́n ní tí ó jọra. Ẹ ṣe àlàyé pé nígbàtí a bá lọ sí tẹ́mpìlì, a lè gba àwọn ìlànà mímọ́ bíi ìrìbọmi fún àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ti kú. Báwo ni a ṣe ndàbí Jésù nígbàtí a bá nṣe iṣẹ́ fún áwọn òkú? Kíni Ó ṣe fún wa tí a kò lè ṣe fún ara wa?
-
Ẹ pe ọ̀dọ́ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n ti ṣe ìrìbọmi fún àwọn babanlá wọn láti sọ ìrírí wọn. Ẹ bèèrè lọ́wọ́ wọn bí ó ti rí nínú tẹ́mpìlì. Ẹ gba wọ́n níyànjú láti sọ bí wọ́n ṣe ní ìmọ̀lára ṣíṣe iṣẹ́ yí fún àwọn babanlá wọn.
-
Ẹ ya igi kan sójú pákó, pẹ̀lú àwọn gbòngbò àti àwọn ẹ̀ka. Ẹ sọ fún àwọn ọmọdé láti ronú bí ẹbí ṣe dàbí igi. Ẹ sààmì sí àwọn gbòngbò Àwọn Àtẹ̀lé, ẹ sààmì sí àwọn ẹ̀ka Àwọn Ìran, kí ẹ sì sààmì sí ẹ̀hìn igi náà Ẹ̀nyin. Ẹ ka gbólóhùn yí papọ̀ látinú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 128:18: “Nítorí àwa láìsí wọn [àwọn babanlá wa] a kò lè ṣe wá ní pípé; bẹ́ẹ̀ni láìsí àwa a kò lè ṣe wọ́n ní pípé. Ẹ béèrè àwọn ìbéèrè bíi: “Kínìdí tí a fi nílò àwọn babanlá wa? Kínìdí tí àwọn babanlá wa fi nílò wa? Báwo ni àwọn òbí wa, àwọn òbí wa àgbà àti àwọn babanlá wa ṣe ràn wá lọ́wọ́?” Ẹ pe àwọn ọmọdé láti wa ìyókù Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 128:18 fún gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan tí ó ṣe àpèjúwe bí a ṣe lè ṣe ìrànlọ́wọ fún àwọn babanlá wa.
-
Ẹ gbèrò ṣíṣe iṣẹ́ pẹ̀lú àwọn òbí ọmọ kọ̀ọ̀kan láti wá orúkọ babanlá kan tí ó nílò àwọn ìlànà nínú tẹ́mpìlì (wo FamilySearch.org).