Come, Follow Me
Oṣù Kejìlá 21–27. “Àwa Ti Dúró dè E, Òun ó sì Gbà Wá Là”: Kérésìmesì


“Oṣù Kejìlá 21–27. ‘Àwa Ti Dúró dè E, Òun ó sì Gbà Wá Là’: Ìsàíàh 50–57,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Kejìlá 21–27. ‘Àwa Ti Dúró dè E, Òun ó sì Gbà Wá Là,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026

ọmọ Jésù nsùn

Nítorí a Bí Ọmọ kan Fún Wa, nípasẹ̀ Simon Dewey

Oṣù Kejìlá 21–27: “Àwa Ti Dúró dè E, Òun ó sì Gbà Wá Là”

Kérésìmesì

Májẹ̀mú Láéláé ngbé ẹ̀mí ìfojúsọ́nà ìtara kan. Ní ọ̀na náà, ó dàbí àkokò Keresimesi díẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ádámù àti Éfà, àwọn baba nlá Májẹ̀mú Láéláé, àwọn wòlíì, àwọn akéwì, àti àwọn ènìyàn nretí àwọn ọjọ́ tí ó dárajùlọ, tí ó kún fún ìrètí fún ìmúdọ̀tun àti ìdándè Mèssáìh. Àwọn ọmọ Ísráẹ́lì sì máa nnílò ìrètí náà lemọ́lemọ́—yálà wọ́n wà ní ìgbèkùn Egypt tàbí Bábílónì tàbí ti ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìṣọ̀tẹ̀ tiwọn fà fúnra wọn. Nínú gbogbo rẹ̀, àwọn wòlíì rán wọn létí pé Mèssíàh kan, Olùdáǹdè, yíò wá “láti kéde òmìnira fún àwọn òndè” (Ìsàíàh 61:1).

Ìrètí náà ni a bẹ̀rẹ̀ sí ndámọ̀ nígbàtí wọ́n bí Jésù Krístì ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. A bi Olùdándè alágbára ti Ísráẹ́lì nínú ibùjẹ ẹran (wo Lúkù 2:7). Ṣùgbọ́n kì í ṣe Olùdándè àwọn ọmọ Ísráẹ́lì àtijọ́ nìkan ni. Ó wá láti gbà yín—láti ru ìbànújẹ́ yín,láti ru ìbànújẹ́ yín, láti palára fún àwọn àìṣedéédéé yín, kí ẹ̀yin lè rí ìwòsàn pẹ̀lú ìnà Rẹ̀ (wo Ìsàíàh 53:4–5). Èyí ni ìdí tí Kérésìmesì fi kún fún ìfojúsọ́nà ayọ̀ pàápàá ní òní. Mèssíàh náà dé ní nkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́hìn, Ó sì ntẹ̀síwájú láti wá sínú ìgbésí-ayé wa nígbàkugbà tí a bá wá A.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ

àmì sẹ́mínárì
Mo yọ̀ nínú Olùràpadà mi.

A mọ Kérésìmesì gẹ́gẹ́bí àkókò aláyọ̀ nítorí ayọ̀ tí Jésù Krístì mú wá sí ayé. Ní ọ̀pọ̀ sẹ́ntúrì ṣáájú kí a tó bí Olùgbàlà, àwọn wòlíì Májẹ̀mú Láéláé tún ní ìmọ̀lára ayọ̀ bí wọ́n ṣe nsọ̀rọ̀ nípa Mèssìàh tó nbọ̀. Ẹ ka díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí, kí ẹ sì ronú nípa ìdí tí wọ́n fi ṣe iyebíye fún àwọn ènìyàn tí wọ́n nfojúsọ́nà fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà: Orin Dáfídì 35:9; Ìsàíàh 25:8–9; 44:21–24; 51:11; Sẹfaníàh 3:14–20; Mósè 5:5–11. Kínìdì tí àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe jẹ́ iyebíye fún yín? Àwọn èrèdí wo ni àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ wọ̀nyí fún yín láti láyọ̀?

Bákannáà wo Dallin H. Oaks, “Ìhìn Rere ti Ayọ̀ Nlá” (Ìfọkànsìn Kérésìmesì Ààrẹ Kìnní, Oṣu kejila 4, 2022), Ibi Ìkàwé Ìhìnrere; “Ayọ̀ sí Ayé,” Àwọn orin, nọ́mbà 201.

ìràwọ̀ dídán ní alẹ́ ọ̀run

Àwọn àmì lè ṣèrànwọ́ fún mi láti rántí Jésù Krístì.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àṣà tí ó ṣíṣẹ́ pẹ̀lú Kérésìmesì lè ní àwọn ìtumọ̀ àmì tí ó tọ́ka sí Krístì. Bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò Májẹ̀mú Láéláé ní ọdún yi, ẹ lè ti ṣe àkíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àmì ti Olùgbàlà. Díẹ̀ ni a ṣe àtòkọ sí ìsàlẹ̀. Ẹ yẹ ṣíṣe àṣàrò wọ̀nyí kí ẹ sì ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n kọ́ yín nípa Rẹ̀.

  • Ìràwọ̀ (Númérì 24:17; Máttéù 2:2; Ìfihàn 22:16).

  • Olùṣọ́-àgùntàn (Orin Dáfídì 23; Lúkù 15:4–7; Jòhánnù 10:11)

  • Ọ̀dọ̀-àgùntàn (Gẹ́nẹ́sísì 22:8; Ẹ́ksódù 12:5; 1 Pétérù 1:18–20).

  • Omi (Ẹ́ksódù 17:1–6; Jeremíàh 2:13; Èsékíẹ̀lì 47:1–12; Jòhánnù 4:7–14).

  • Àpáta (1 Sámúẹ́lì 2:2; 2 Sámúẹ́lì 22:2–3; Orin Dáfídì 118:22–23; Ìsàíàh 28:16; Éfésù 2:20).

  • Ẹ̀ka (Ìsàíàh 11:1–2; Jeremíàh 23:5; 33:15).

  • Ìmọ́lẹ̀ (Orin Dáfídì 27:1; Ìsàíàh 9:2; 60:19; Míkà 7:8; Jòhánnù 8:12).

Àwọn àmì, àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀, àti àwọn àkọsílẹ̀ wo ni ẹ ti rí nínú àwọn ìwé-mímọ́ tí ó jẹri Jésù Krístì?

Bákannáà wo 2 Néfì 11:4; Mòsíàh 3:14–15; Mósè 6:63; “Àwọn Irú tàbí Àmì Krístì” àti “Jésù Krístì,” méjèèjì nínú Ìtọ́sọ́nà sí Ìwé Mímọ́ (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere).

“Orúkọ rẹ̀ ni a ó máa pè ní Ìyanu.”

Jésù Krístì ni a tọ́ka sí nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orúkọ àti àwọn àkọ́lé oríṣiríṣi. Ẹ wá àwọn àkọ́lé nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí: Orin Dáfídì 23:1; 83:18; Ìsàíàh 7:14; 9:6; 12:2; 63:16; Ámọ́sì 4:13; Sẹkaríàh 14:16; Mósè 7:53. Àwọn àkọ́lé míràn wo ni ẹ lè ronú nípa rẹ̀? Ẹ lè gbádùn títòkọ àwọn àkọ́lé Jésù Krístì tí ẹ rí nínú àwọn orin Kérésìmesì pàápàá. Báwo ni àkọ́lé kọ̀ọ̀kan ṣe ní ipa lórí ọ̀nà tí ẹ fi nronú nípa Rẹ̀?

Ẹ yẹ yíyan orúkọ oyè tàbí ipa ti Olùgbàlà tí yíò ràn yín lọ́wọ́ wò láti rántí Rẹ̀ ní gbogbo ọdún tó nbọ̀.

Bákannáà wo Quentin L. Cook, “Àláfíà ara ẹni ní àwọn Àkókò Ìpèníjà,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2021, 89–92; “Tẹ́tí! Ìkéde Ángẹ́lì Kọrin,” Àwọn orin ìsìn, nọ́mbà 209.

Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde àwọn ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Làìhónà àti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ .

ìpín àmì àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Májẹ̀mú Láéláé nkọ́ mi nípa Jésù.

  • Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè ní díẹ̀ nínú àwọn ọ̀ṣọ́ Kérésìmesì tí ẹ lè lò láti bẹ̀rẹ̀ ìbárasọ̀rọ̀ nípa Jésù Krístì. Bóyá ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa bí ìràwọ̀ Kérésìmesì, àwọn ìmọ́lẹ̀, tàbí ẹ̀bùn kan ṣe rán wa létí Olùgbàlà. Lẹ́hìnnáà ẹ lè wo ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí fún ohun kan tó lè ṣe àpẹrẹ Jésù Krístì: Gẹ́nẹ́sísì 22:8; Númérì 24:17; Orin Dáfídì 23:1; 27:1. Bóyá àwọn ọmọ yín lè gbé àwòrán kan tàbí ohun ọ̀ṣọ́ kan tí ó lọ pẹ̀lú ẹsẹ kọ̀ọ̀kan bí wọ́n ṣe nkà á. Báwo ni Jésù ṣe dàbí ọ̀dọ́ àgùntàn, ìràwọ̀, olùṣọ́-àgùntàn, tàbí ìmọ́lẹ̀? Ẹ yẹ kíkọrin Kérésìmesì ka papọ̀ wò, bíi “Àwọn Ìràwọ̀ Ndán” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 37).

  • Àwọn ọmọ yín tún lè wo àwòrán tó wà ní òpin ìlànà yìí bí ẹ ṣe nka Ìsàíàh 9:6 sí wọn. Ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín láti tọ́ka sí Jésù ọmọ-ọwọ́ nígbàtí wọ́n bá gbọ́ gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “a bí ọmọ kan.” Ẹ ṣe àbápín ẹ̀rí yín pé àwọn wòlíì nínú Májẹ̀mú Láéláé mọ̀ pé a ó bí Jésù.

  • Bí ẹ ṣe nmúra sílẹ̀ láti ṣe àṣàrò ìgbé-ayé Jésù Krístì nínú Májẹ̀mú Titun ní ọdún tó nbọ̀, ẹ yẹ ṣíṣe àtúnyẹ̀wò pẹ̀lú àwọn ọmọ yín ohun tí wọ́n ti kọ́ nípa Rẹ̀ ní ọdún yìí nínú Májẹ̀mú Láéláé. Ẹ lè ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ìlànà inú ohun-èlò yi àti àwọn àkọsílẹ̀ àṣàrò araẹni èyíkéyìí láti ṣe ìrànwọ́ fún yín láti rántí ohun tí ẹ ti kọ́. Àwọn ọmọdé kékeré lè ní ànfàní wíwò inú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé tàbí àwọn àwòrán nínú Wá, Tẹ̀lé Mi. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tàbí ìtàn wo ló ta yọ? Kíni a ti kọ́ nípa Olùgbàlà?

Àwọn àṣà Kérésìmesì lè tọ́ka sí Jésù Krístì.

  • Àwọn ẹbí Ìsráẹ́lì ní àwọn àṣà, gẹ́gẹ́bí àjọ ìrékọjá àti àwọn àjọ̀dún míràn, tí a túmọ̀ láti tọ́ka ọkàn àti inú wọn sí Olúwa (wo Ẹ́ksódù 12). Àwọn àṣà wo ni ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín ní ní àkókò Kérésìmesì tí ó ṣe ìrànwọ́ fún kíkọjúsí Jésù Krístì yín? Àwọn àṣà wo ni ẹ mọ̀ nípa ìwé-ìtàn ẹbí yín? Ẹ lè yẹ sísọ àwọn àṣà kan wò tí ẹ fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ yín. Díẹ̀ nínú àwọn èrò lè pẹ̀lú sísin ẹnìkan nínú aláìní, yíyan ohun kan tí ẹ̀yin yíò fúnni bí “ẹ̀bùn” sí Olùgbàlà, pípe ọ̀rẹ́ kan láti wo ìfọkànsìn Kérésìmesì ti Àjọ Ààrẹ Ìkínní pẹ̀lú yín (broadcasts.ChurchofJesusChrist.org), kíkọ orin Kérésìmesì tiyín, tàbí wíwá ọ̀nà alátúndá láti ṣe àbápín ọ̀rọ̀ ìbí Krístì.

Nínú ilé, ikẹkọ àti gbígbé kò ṣeé yàsọ́tọ̀. “Ìhìnrere náà gba jíjẹ́ pàtàkì ẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní ilé. Ní ibẹ̀ ni àwọn ènìyàn pẹ̀lú ẹnití ẹ ti nkọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere náà ti jẹ́ àwọn ènìyàn tí ẹ̀yin yíò máa gbé nínú rẹ̀—lójojúmọ́. Ní òtìtọọ́, púpọ̀ jùlọ àkókò, gbígbé ìhìnrere jẹ́ bí a ṣe nkọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere náà. Nítorínáà bí ẹ ṣe nkọ́ ẹ̀kọ́ tí ẹ sì nkọ́ni ní ìhìnrere ní ilé, ẹ wa àwọn ọ̀nà láti so ohun tí ẹ nkọ́ pọ̀ pẹ̀lú ohun tí ẹ nṣe. Nínú ilé yín, jẹ́ kí ìhìnrere jẹ́ ohun kan tí ẹ nlàkàkà láti gbé, kìí ṣe ohun kan tí ẹ nsọ̀rọ̀ nípa” (Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà31).

ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣẹ̀dá kan

Àpèjúwe ti Ìṣẹ̀da, láti ọwọ́ Ethan Brown

Baba Ọ̀run fún mi ní ẹ̀bùn Ọmọ Rẹ̀ láti jẹ́ Olùgbàlà mi.

  • Báwo ni ẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ọ̀wọ̀ àti ayọ̀ ìbí Kristi? Ẹ lè wo fídíò “Krístì Ọmọ náà” (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere) tàbí ka papọ̀ Máttéù 1:18–25; 2:1–12; Lúkù 1:26–38; 2:1–20. Ọmọ kọ̀ọ̀kan lè yan ènìyàn kan láti inú fídíò tàbí àkọsílẹ̀ ìwé mímọ́ kí ẹ sì ṣe àbápín bí ẹni náà ṣe ní ìmọ̀lára nípa Olùgbàlà. Lẹ́hìnáà ẹ lè ṣe àbápín ìmọ̀lára tí ẹ ni nípa Rẹ̀ pẹ̀lú ara yín.

    17:57

    The Christ Child

  • Bóyá ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀bùn tí ẹ ti fún tàbí tí ẹ ti gbà fún àwọn ọdún tí ó ti mú ayọ̀ wá. Nígbànáà ẹ lè ka Ìsàíàh 25:9 papọ̀ kí ẹ sì sọ ìdí tí ẹ fi nyọ̀ pé Baba Ọ̀run rán Olùgbàlà kan sí wa. Láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ni òye ipa tí Jésù Krìstì nkó gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà wa dáadáa, pè wọ́n láti ka Ìsàíàh 25:8–9; 53:3–5; àti Hóséà 13:14. Kíni àwọn ìwé mímọ́ wọ̀nyí kọ́ wa nípa bí Olúwa ṣe ngbà wá?

  • Ẹ tún lè kọ orin kérésìmesì kan papọ̀, bíi “Jìnnà ní Bùjẹ Ẹran” (Orin Àwọn Ọmọdé, 42–43) tàbí “Ah Ìlú ti Bẹ́tlẹ́hẹ́mù” (Àwọn orin, nọ́mbà 208). Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti wá àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ nínú orin tí ó ṣe ìrànwọ́ fún wọn láti mọ̀ pé Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì fẹ́ràn wọn.

Fún púpọ̀ sí i, wo ìtẹ̀jáde ìwé ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .

ìṣẹ̀lẹ̀ Ìṣẹ̀dá kan

Ìṣẹ̀dá Náà, láti ọwọ́ Sharlotte Andrus

Ojú-ìwé ṣíṣe ìṣe alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Májẹ̀mú Láéláé nkọ́ mi nípa Jésù