Come, Follow Me
Oṣù Kejìlá 14–20. “Èmi Ti Fẹ́ Yín, Ní Olúwa Wí”: Málákì


“Oṣù Kejìlá 14–20. ‘Èmi Ti Fẹ́ Yín, Ní Olúwa Wí’: Málákì,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Kejìlá 14–20. ‘Èmi Ti Fẹ́ Yín, Ní Olúwa Wí,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026

àwòrán Jésù níwájú ìràwọ̀ ọ̀run kan

Oṣù Kejìlá 14–20: “Èmi Ti Fẹ́ Yín, Ní Olúwa Wí”

Málákì

“Èmi ti fẹ́ yín,” ni Olúwa sọ fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì Málákì. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísráẹ́lì tí wọ́n ti jìyà ìpọ́njú àti ìgbèkùn ní ìrandíran, béèrè pé, “Níbo ni ìwọ ti fẹ́ wa?” (Málákì 1:2). Lẹ́hìn tí gbogbo Ísráẹ́lì ti kọjá, ó lè ti yà wọ́n lẹ́nu bóyá ìwé-ìtàn wọn jẹ́ ìtàn kan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ̀. Ní àwọn ọ̀nà kan, ó rọrùn láti rí i bí ìtàn àìlera àti ìṣọ̀tẹ̀ ènìyàn. Síbẹ̀ nínú gbogbo rẹ̀, Ọlọ́run kò ṣíwọ́ nínawọ́ jáde nínú ìfẹ́. Nígbàtí àwọn ọmọ Jákọ́bù hùwà ìkà sí Jósẹ́fù arákùnrin wọn, Olúwa ṣì gbà wọ́n lọ́wọ́ ìyàn (wo Gẹ́nẹ́sísì 45:4–8). Nígbàtí Ísráẹ́lì kùn nínú aginjù, ó fi mánà bọ́ wọn (wo Ẹksódù 16:1–4). Pàápàá nígbàtí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì yíjú sí àwọn ọlọ́run míràn tí wọ́n sì fọ́nká, Ọlọ́run ṣe i`lérí pé tí wọ́n bá ronúpìwàdà, òun yíò kó wọn jọ, yíò sì rà wọ́n padà “pẹ̀lú àánú nlá” (wo Ìsàíàh 54:7). Lóòtọ́, Májẹ̀mú Láéláé jẹ́ ìtàn ti sùúrù Ọlọ́run, ìfẹ́ pípẹ́. Àti pé ìtàn yí ntẹ̀síwájú ní òní. Jésù Krístì, “òòrùn Òdodo,” gẹ́gẹ́bí Málákì ṣe pè É, ti dé “pẹ̀lú ìwòsàn ní ìyẹ́ apá rẹ̀” (Málákì 4:2). Òun ni ẹ̀rí tó ga jù lọ tó fi ìfẹ́ Ọlọ́run fún Ísráẹ́lì àtijọ́ àti fún gbogbo wa hàn.

Fún àlàyé ṣókí nípa ìwé Dáníẹ́lì, wo “Málákì” nínú Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ

Málákì 1–4

“Padá sọ́dọ̀ mi, èmi yíò sì padà sọ́dọ̀ rẹ.”

Ní ọjọ́ Málákì, àwọn Ìsráẹ́lì ti tún tẹ́mpìlì kọ́ ní Jerúsálẹ́mù, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí àwọn ènìyàn wọ́n tún nílò láti tún ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe. Bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò Málákì, ẹ wá àwọn ìbéèrè tí Olúwa béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì tàbí tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Rẹ̀. Ẹ yẹ bíbéèrè àwọn ìbèèrè jíjọra lọ́wọ́ ara yín wò (àwọn àpẹrẹ kan wà nísàlẹ̀) láti ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àgbéyẹ̀wò ìbáṣepọ̀ yín pẹ̀lú Olúwa kí ẹ sì sún mọ́ Ọ.

  • Báwo ní mo ṣe nní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run fún mi? (wo Málákì 1:2).

  • Njẹ́ àwọn ọrẹ ẹbọ mi buọlá fún Un? (wo Málákì 1:6–11)

  • Àwọn ọ̀nà wo ni a nílò láti “padà” sọ́dọ̀ Olúwa? (wo Málákì 3:7).

  • Njẹ́ mo nja Ọlọ́run lólè lọ́nàkọnà? (wo Málákì 3:8–11).

  • Báwo ni ìhùwàsí mi nígbà ìṣòro ṣe nfi ìmọ̀lára mi sí Olúwa hàn? (wo Málákì 3:13–15; bákannáà wo 2:17).

Málákì 1:6–14

Olúwa béèrè fún “ẹbọ mímọ́.”

Bí o ṣe ń ka àwọn ọrẹ tí Málákì 1, kí lẹ ṣàkíyèsí nípa àwọn ẹbọ tí àwọn àlùfáà nrú? Kí ni àwọn ìrúbọ wọ̀nyí fi hàn nípa ìmọ̀lára àwọn àlùfáà sí Olúwa? (wo Málákì 1:13). Gbèrò ṣíṣe àtòkọ àwọn ọrẹ, tàbí àwọn ẹbọ, tí ẹ ṣe sí Olúwa. Fún ohun kọ̀ọ̀kan tí ó wà nínú àtòkọ náà, ẹ jíròrò ohun tí ó lè sọ ọ́ di “ẹbọ àìmọ́” tàbí ọrẹ ẹbọ “mímọ́” (Málákì 1:7, 11).

Málákì 3:8–12

àmì sẹ́mínárì
Olúwa ṣí fèrèsé ọ̀run bí mo ti nfi ìgbàgbọ́ mi hàn nípa sísan idamewa.

Ẹ ròó bí ẹ bá ti ní ọ̀rẹ́ kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ri pé ẹ nsan idamẹwa. “Kínìdí tí ẹ fi ṣe bẹ́ẹ̀?” ọ̀rẹ́ yín béèrè. Ẹ ronú nípa èyí bí ẹ ṣe nka Málákì 3:8–12. Kíni ẹ rí níbẹ̀ tó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè ọ̀rẹ́ yín? Kíni ohun míràn tí ẹ fẹ́ kí ọ̀rẹ́ yín ní òye nípa idamẹwa? Fún ìrànlọ́wọ́ púpọ̀ síi, ẹ lè wa ọ̀rọ̀ Alàgbà Neil L. Andersen “Idamẹwa: Ṣíṣí Fèrèsé ti Ọ̀run” (Làìhọ́nà, Oṣù kọkànlá 2023, 32–35), wíwá àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè bí wọ̀nyí:

  • Kínìdí tí Olúwa fi fẹ́ ká san idamẹwa?

  • Kíni ó lè mú kí ẹnìkan má san idamẹwa, báwo ni a sì ṣe lè borí àwọn ìṣòro náà?

  • Báwo ni sísan idamẹwa ṣe nfún ìgbàgbọ́ wa lókun nínú Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì?

Ẹ tún lé ṣe àbápín pẹ̀lú ọ̀rẹ́ yín bí Olúwa ti nbùkún fún yín nígbàtí ẹ bá san idamẹwa. Ẹ lè wá àwọn èrò ní ìpín tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ “Ẹ̀kọ́ Nọ́mbà 1—Pàtàkì Ṣùgbọ́n Ìbùkún Abẹ́lé” nínú ọ̀rọ̀ Alàgbà David A. Bednar “Fèrèsé” (Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2013, 17–18). Irú ènìyàn wo ni a ndà nípa sísan idamẹwa?

Kíni ẹ rò pé gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “ṣi àwọn fèrèsé ọ̀run fún yi” (ẹsẹ 10) lè túmọ̀ sí?” Bóyá ẹ lè wo ojú fèrèsé kan kí ẹ ronú nípa àwọn èrèdí àwọn fèrèsé. Kínìdí ti “àwọn fèrèsè ọ̀run” fi jẹ́ ọ̀nà tí ó dára láti ṣe àpèjúwe bí Olúwa ṣe nbùkún wa nígbàtí a bá san idamẹwa?

Jésù Krístì nfarahan Joseph Smith nínú Tẹ́mpìlì Kirtland

Ìran nínú Tẹ́mpìlì Kirtland, láti ọwọ́ Gary Smith

Málákì 4:5–6

“Èmi yíò rán wòlíì Èlíjàh sí ọ.”

Nígbàtí Mórónì ṣe àyọsọ Málákì 4:5–6 sí Joseph Smith, ó ṣe bẹ́ẹ̀ “pẹ̀lú ìyàtọ̀ díẹ̀ sí ọ̀nà tí ó ń gbà kàá” nínú Bíbélì (wo Ìtàn Àkọọ́lẹ̀—Joseph Smith 1:36–39). Kíni ìyàtọ̀ tí Mórónì fi ṣe àfikún sí òye yín nípa àsọtẹ́lẹ̀ yí? Ní pàtàkì, ẹ jíròrò àwọn ìbéèrè bi wọ̀nyí:

  • Àwọn wo ni “àwọn baba”? (see Deuterónómì 29:13). Àwọn ìlérí wo ni wọ́n ṣe fún wọn? (wo Ábráhámù 2:9–11). Báwo ni ẹ ṣe nṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú àwọn ìlérí wọ̀nyí ṣẹ?

  • Àwọn ìrírí wo ló ti ràn yín lọ́wọ́ láti yí ọkàn yín padà sọ́dọ̀ àwọn babanlá yín? Kínìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì sí ètò Baba Ọ̀run?

Láti kọ́ ẹ̀kọ́ síi nípa dídé Èlíjà àti bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ndí mímúṣẹ ní òní, wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 110:13–16 àti D. Todd Christofferson, “Agbára Èdidì” (Liahona, Oṣù kọkànlá 2023, 19–22). Kílódé tí ẹ fi ndúpẹ́ pé Èlíjàh ti dé?

Bákannáà wo Gerrit W. Gong, “Ọ̀kọ̀ọ̀kan Wa Ní Ìtàn,” Làìhónà, Oṣù karun 2022, 43–46; “Yí Ọkàn Rẹ Padà,” Àwọn orin, nọ́mbà 291; “Agbára Èdidì” (fídíò), ChurchofJesusChrist.org.

3:38

The Sealing Power

Fún púpọ̀ sí i, wo àwọn àtẹ̀jáde àwọn ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Làìhónà àti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ .

ìpín àmì àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Málákì 1:2

Olúwa fẹ́ràn mi.

  • Báwo ni ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín yíò ṣe dáhùn ìbéèrè tó wà nínú Málákì 1:2—“Níbo ni [Olúwa] ti fẹ́ràn wa?” ṢẸ ṣe àbápín pẹ̀lú ara yín ìdí míràn tí ẹ mọ̀ pé Ó fi fẹràn yín. Bóyá àwọn ọmọ yín lè ya àwọn àwòrán tí ó nrán wọn létí ìfẹ́ Rẹ̀.

Ẹ fún àwọn ọmọdé níṣe ṣe nínú àwọn ìsọ̀rọ̀ ìhìnrere. Bí ẹ ba nkọ àwọn ọmọ kékeré, ẹ lè nílò láti ronú àwọn ọ̀nà dídá láti mú wọn lọ́wọ́ nínú àwọn sísọ̀rọ̀ ìhìnrere. Fún àpẹrẹ, àwọn ọmọ yín lè kọjá ní àyíká bọ́ọ̀lù kan; nígbàtí wọ́n bá di bọ́ọ̀lù mú, wọ́n lè sọ ìdí kan tí wọ́n fi mọ̀ pé Jésù fẹ́ràn wọn.

òbí àti ọmọdekunrin kan ti ó nwo ojú fèrèsé

Málákì 3:8–12

Olúwa nbùkún mi bí mo ti nsàn idamẹwa

  • Báwo ni ẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa idamẹwa? Ẹ lè ní kí wọn ka àwọn nkan kékeré mẹ́wàá, gẹ́gẹ́bí àwọn owó ẹyọ lórí ojú-ewé ìṣẹ ṣíṣe ọ̀sẹ̀ yí. Lẹ́hìnnáà, wọ́n lè ya ọ̀kan lára àwọn ohun èlò náà sọ́tọ̀ kúrò lára ohun tó kù—èyí ni iye tí a nfún Olúwa gẹ́gẹ́bí idamẹwa. Gẹ́gẹ́bí i Málákì 3:8–12, kínìdí tí Olúwa fi fẹ́ kí á san idamẹwa? (Bákannáà wo “Wòlíì Málákì” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 171–72; “Ohun Àkọ́kọ́ Ṣaájú!” [Fídíò], Ibi Ìkàwé Ìhìnrere).

    0:58

    Malachi the Prophet

    1:18

    First Things First!

  • Bí ẹ ṣe nka Málákì 3:10 papọ̀, ẹ lè pe àwọn ọmọ yín láti dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ fèrèsé nígbàtí ẹ bá nka gbólóhùn náà “àwọn fèrèsé ọ̀run.” Tàbí ẹ lè da omi sínú ife kan títí tí yíò fi kún àkúnwọ́sílẹ̀ láti ṣe àkàwé gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “kì yíò sí àyè tó láti gbà á.” Ẹ sọ fún àwọn ọmọdé nípa àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run nfún yín bí ẹ ṣe nsan idamẹwa. Àwọn ọmọ yín lè ya àwọn àwòrán tí ó nṣe àfihàn àwọn ìbùkún wọ̀nyí kí ẹ sì gbé wọn kọ́ sí orí tàbí súnmọ́ fèrèsé nílé yín.

Málákì 4:5–6

Èlíjàh wá láti yí ọkàn wa padà sí àwọn ẹbí wa.

  • Nínú Málákì 4:5–6, àwọn ọmọ yín lè wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nípa àsọtẹ́lẹ̀ Málákì: Tani Olúwa ṣèlérí láti rán? Nígbà wo ni Ó sọ pé yíò wa? Kíni Olúwa sọ pé ẹni yìí yíò ṣe? Kínìdí tí ẹni yi yíò nílò láti wa? Níbo ní àsọtẹ́lẹ̀ yí ti di mímúṣẹ? (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 110:13–16).

  • Láti ṣe àwárí bí ìlérí tí ó wà nínú Málákì 4:5 ṣe di mímúṣẹ, ẹ tún lè ṣe àtúnyẹ̀wò “Joseph àti Oliver Gba Àwọn Kọ́kọ́rọ́ Oyèàlùfáà” nínú Àwọn Ìtàn Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, 26–30. Orin kan bíi “Ọkàn àwọn Ọmọdé” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 92) lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti mọ ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì pé Èlíjàh wá. Ẹ tún lè ṣe àbẹ̀wò sí FamilySearch.org/discovery, áàpù FamilySearch Tree, tàbí Ẹbí Mi ìwé kékeré fún ìṣe ṣíṣe tí ó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín láti yí ọkàn wọn sí àwọn babanlá yín.

Fún púpọ̀ sí i, wo ìtẹ̀jáde ìwé ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .

obìnrin kan nju aṣọ ìnuwọ́ funfun kan sókè

Hòsánnà Mourning, láti ọwọ́ Rose Datoc Dall. Obìnrin kan tí a npè ní Mourning dúró ní ayé ẹ̀mí, àwọn babanlá rẹ̀ yiká. Ó nṣe ayẹyẹ ìdándè wọn kúrò nínú ìgbèkùn ti ẹ̀mí.

Ojú-ewé ìṣe ṣíṣe alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Olúwa nbùkún mi bí mo ṣe nsan idamẹwa