Come, Follow Me
Oṣù kọkànlá 30–Kejìlá 6. “Ó ní Inúdídùn Sí Àánú”: Míkà; Náhúmù; Hábákkúkù; Sefaníàh


“Oṣù kọkànlá 30–Kejìlá 6. ‘Ó ní Inúdídùn Sí Àánú’: Míkà; Náhúmù; Hábákkúkù; Sefaníàh,” Wá, Tẹ̀lẹ́ Mi—Fún Ié àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù kọkànlá 30–Kejìlá 6. ‘Ó ní Inúdídùn Sí Àánú,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026

ọkùnrin kan tí ó ní àwọn apa nínà jáde, nwo ìràwọ̀ òfúrufú

Ní Àtètèkọ́ṣe Ní Ọ̀rọ̀ Wa, láti ọwọ́ Eva Timothy

Oṣù kọkànlá 30–Kejìlá 6: “Ó ní Inúdídùn Sí Àánú”

Míkà; Náhúmù; Hábákkúkù; Sẹfaníàh

Kíka Májẹ̀mú Láéláé léraléra túmọ̀ sí kíka àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun. Olúwa npe àwọn wòlíì lemọ́lemọ́ láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn búburú nípa àwọn ìdájọ́ Rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ Míkà, Náhúmù, Hábákkúkù, àti Sẹfaníàh jẹ́ àwọn àpẹrẹ rere. Ní kúlẹ̀kúlẹ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àwọn wòlíì wọ̀nyí sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìṣubú àwọn ìlú nlá tí ó dà bí wọ́n ní okun tí wọ́n sì jẹ́ alágbára nígbà náà: Nínéfè, Bábílónì, àti Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n èyí jẹ́ ẹgbẹgbẹ̀ẹ̀rún ọdún sẹ́hìn. Kínìdí tí ó fi jẹ́ iyebíye láti ka àwọn àkọsílẹ̀ ní òní?

Àni bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ìlú agbéraga, oníwàbúburú ni a ti parun, ìgbéraga ìwà búburú ṣì tẹ̀ síwájú. A lè rí ipa rẹ̀ pàápá nínú ọkànti arawa. Àwọn wòlíì Májẹ̀mú Láéláé ṣe àfihàn bí a ṣe le yípadà kúrò nínú àwọn ibi wọ̀nyí. Bóyá èyí ni èrèdí kan tí a ṣì fi nka àwọn ọ̀rọ̀ wọn ní òní. Wọ́n kìí ṣe wòlíì ti aparun níkan—wọ́n jẹ́ wòlíì ìdándè. Àwọn àpèjúwe ìparun jẹ́ ìbínú nípasẹ̀ àwọn ìfipè láti wá sọ́dọ̀ Krístì àti láti gba ìdáríjì Rẹ̀. Gẹ́gẹ́bí Míkà ṣe sọ ọ́, inú Olúwa kò dùn láti dá wa lẹ́bi, ṣùgbọ́n “ó ní inú dídùn sí àánú” (Míkà 7:18). Èyí ni ọ̀nà Olúwa nígbà àtijọ́, àti pé ó jẹ́ ọ̀nà Rẹ̀ ní òní. “Ọ̀nà Rẹ̀ jẹ́ àìnípẹ̀kun” (Hábákkúkù 3:6).

Fún àlàyé ṣókí nípa àwọn ìwé wọ̀nyí, wo “Míkà,” “Náhúmù,” “Hábákkúkù,” and “Sẹfaníàh” nínú Ìwé ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ

Míkà 6:1–8

“Kíní Olúwa nfẹ́ kí ẹ ṣe?”

Míkà pè wá láti ro ohun tí ó lè dàbí láti “wá síwájú Olúwa, kí a sì tẹríba … níwájú Ọlọ́run Ọ̀gá” (Míkà 6:6). Kíni àwọn ẹsẹ 6–8 dá àbá fún yín nípa ohun tí ó ṣe pàtàkì fún Olúwa bí Ó ṣe ngbé ìgbé-ayé wa yẹ̀wò?

Bákannáà wo Dale G. Renlund, “Ṣe ní òdodo, Nifẹẹ Àánú, kí o sì Rìn ní Ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2020, 109–12.

òkúta odi tí odi

“Olúwa dára, odi agbára ní ọjọ ìpọ́njú” (Náhúmù 1:7).

Náhúmù 1

Olúwa jẹ́ méjèèjì alágbára àti aláàánú.

Iṣẹ́ yíyànfúnni Náhúmù ni láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìparun Nínéfè—olú ìlú ilẹ̀ ọba Ásíríà oníwà ipá, èyí tí ó fọ́n Ísráẹ́lì ká tó sì fì ìyà jẹ Júdàh. Náhúmù bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣe àpèjúwe ìbínú Ọlọ́run àti agbára tí kò láfiwé, ṣùgbọ́n Ó tún sọ̀rọ̀ nípa àánú àti inúrere Ọlọ́run. Ẹ wá àwọn ẹsẹ nínú orí 1 tí ó ṣèrànwọ́ fún yín láti ní òye ọ̀kọ́ọ̀kan nínú àwọn ìhùwàsí wọ̀nyí—àti àwọn ìhùwàsí Ọlọ́run míràn tí ẹ ṣàkíyèsí. Kínìdí tí ẹ rò pé ó ṣe pàtàkì láti mọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn nkan wọ̀nyí nípa Olúwa?

Hábákkúkù

àmì sẹ́mínárì
Mo lè gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Olúwa àti àkókò Rẹ̀.

Àwọn wòlíì pàápàá máa nní àwọn ìbéèrè nígbà míràn nípa àwọn ọ̀nà Olúwa. Hábákúkù, ẹni tí ó gbé ayé ní àkókò ìwà búburú tí ó gbilẹ̀ ní Júdà, bẹ̀rẹ̀ àkọsílẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìbéèrè sí Olúwa (wo Hábákúkù 1:1–4). Báwo ni ẹ ṣe lè ṣe àkópọ̀ àwọn àníyàn Hábákúkù? Irú àwọn ìbéèrè wo ni àwọn ènìyàn nbéèrè nípa Ọlọ́run ní òní? Njẹ́ ẹ ti ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ rí? Ẹ tún lè fi àwọn ìbéèrè yín wé àwọn míràn nínú àwọn ìwé mímọ́, irú bíi àwọn tí a rí nínú Máàkù 4:37–38 àti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 121:1–6.

Olúwa dáhùn sí àwọn ìbéèrè Hábákúkù nípa sísọ pé Òun yíò rán àwọn ará Kaldea (àwọn ará Bábílónì) láti jẹ Júdà níyà (wo Hábákúkù 1:5–11). Ṣùgbọ́n Hábákúkù ṣì wà nínú ìpọ́njú, nítorí ó dàbí ẹni pé kò tọ́ fún Olúwa láti dúró “nígbàtí ènìyàn búburú [Bábílónì] bá njẹ ọkùnrin tí ó jẹ́ olódodo jù [Júdà] run” (wo ẹsẹ 12–17). Kíni ẹ rí nínú Hábákúkù Hábákúkù 2:1–4 tí ó mísí yín láti gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa nígbà tí ẹ bá ní àwọn ìbéèrè àìdáhùn? (Bákannáà wo Máàkù 4:39–40; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 121:7–8; “Ọlọ́run Yíò Gbé Wa Sókè” [fídíò], Ibi Ìkàwé Ìhìnrere).

4:59

God Will Lift Us Up

Orí 3 jẹ́ àdúrà ìyìn àti ìgbàgbọ́ Hábákúkù. Báwo ni ohun orin Hábákúkù ní orí 3 ṣe yàtọ̀ sí orí 1? Ní ìhín ni èrò láti ràn yín lọ́wọ́ láti jíròrò àwọn ẹsẹ 17–19: Ẹ ṣe àtòkọ ti àwọn ìbùkún ti ara àti ti ẹ̀mí tí Ọlọ́run ti fún un yín. Lẹ́hìnnáà ẹ ròó pé ẹ pàdánù àwọn ìbùkún ti ara. Báwo ni èyí ṣe lè mú kí ẹ ní ìmọ̀lára àwọn ìbùkún míràn? Kínìdí tí ó fi lè nira láti “yọ̀ nínú Olúwa” (ẹsẹ 18) ní àkokò ìnira bíi àwọn tí a ṣe àpèjúwe nínú ẹsẹ 17? Ẹ jíròrò nípa bí ẹ ṣe lè ní ìgbàgbọ́ títóbi nínú Ọlọ́run, pàápàá nígbàtí ìgbésí ayé bá dà bí èyí tí kò ṣe déédé.

Bákannáà wo Gerrit W. Gong, “Ohun Gbogbo fún Dídára Wa,” Làìhónà, Oṣù karun 2024, 41–44; “Darí, Ìmọ́lẹ̀ Àánú,” Àwọn orin, nọ́mbà 97; Àwọn Àkọlé Àti Ìbéèrè, “Wíwá àwọn Ìbéèrè sí Ìdáhùn,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.

Ẹ ṣe sùúrù. Nígbà míràn a fẹ́ àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn òye ti ẹ̀mí gba àkokò àti pé a kò lè mu pẹ̀lú agbára. Gẹ́gẹ́bí Olúwa ti sọ fún Hábákúkù pé, “Dúró fún un; nítorí yíò dé dájúdájú” (Hábákúkù 2:3).

Sefaníàh

“Ẹ wá Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ayé.”

Bí ẹ ṣe nka àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Sẹfaníàh, ẹ ṣe àkíyèsí àwọn ìwà àti ìṣesí tí ó yọrí sí ìparun—ní pàtàkì wo Sẹfaníàh 1:4–6, 12; 2:8, 10, 15; 3:1–4. Lẹ́hìnnáà, wá ìwà àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run yíò dáàbò bò—wo Sẹfaníàh 2:1–3; 3:12–13, 18–19. Irú ọ̀rọ̀ wo ni ẹ ní ìmọ̀lára pé Olúwa ní fún yín nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí?

Sefaníàh 3:14–20

Olúwa yìó yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní Síónì.

Lẹ́hìn kíka Sẹfaníàh 3:14–20, ẹ wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà tí ẹ lè gbà parí gbólóhùn ọ̀rọ̀ yìí: “Ẹ yọ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn” nítorí … Kínìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí ẹ mọ̀ nípa àwọn èrèdí wọ̀nyí láti máa yọ̀? Ẹ lè fi àwọn ẹsẹ wọ̀nyí wé àwọn ìrírí tí a ṣe àpèjúwe ní 3 Néfì 17 kí ẹ sì jíròrò lórí bí Jésù Krístì fi nní ìmọ̀lára nípa àwọn ènìyàn Rẹ̀—pẹ̀lú yín.

Fún púpọ̀ sí i, wo àwọn àtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Làìhónà àti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ .

ìpín àmì àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Míkà 5:2

A bí Jésù Krístì ní Bẹ́tlẹ́hẹ́mù

  • Àwọn ọmọ yín lè má mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ Míkà ló ran àwọn Ọlọ́gbọ́n lọ́wọ́ láti rí Jésù ọmọ ọwọ́ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Lílo Míkà 5:2 and Máttéù 2:1–6, bóyá àwọn ọmọ yín lè tún ìrírí wọn ṣe. Lẹ́hìnnáà, ẹ lè sọ nípa ìdí tí ìbí Jésù fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn wòlíì fi mọ̀ nípa rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí I.

Àwọn Ọkùnrin Ọlọ́gbọ́n mẹ́ta nwo ìràwọ̀ titun

A Bí Ọmọ Mímọ́, láti ọwọ́ Dana Wood

Náhúmù 1:7

“Olúwa dára, odi agbára ní ọjọ́ ìṣòrò.”

  • Lẹ́hìn kíka Náhúmù 1:7, àwọn ọmọ yín lè kọ́ tàbí ya wọ́n “odi agbára” tàbí odi (àwòrán kan nínú ìlà yí wà). Kíni àwọn èrèdí díẹ̀ tí àwọn ènìyàn fi lè nílò odi? Kíni ó nmú kí ọjọ́ wa di “ọjọ́ ìṣòro”? Báwo ni Jésù Krístì ṣe dà bí odi agbára fún wa?

Hábákúkù 2:3

Ọlọ́run yíò máa mú àwon ìlérí Rẹ̀ ṣẹ.

  • Láti ṣe àfihàn Hábákúkù 2:3, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn nkan tó dára ṣùgbọ́n lẹ́hìn tí a bá dúró nìkan—bí èso tó yẹ kó hù tàbí ìyẹ̀fun tó yẹ kí wọ́n yan. Kíni ó máa ṣẹlẹ̀ tí a bá gbìyànjú láti jẹ èso tàbí ìyẹ̀fun náà kí ó tó ṣetán? Lẹ́hìnnáà ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa wòlíì Hábákúkù, ẹni tó fẹ́ mọ ìgbà tí Olúwa máa fi òpin sí ìwà ibi tó wà nínú ayé. Ẹ ka ìdáhùn Olúwa nínú Hábákúkù 2:3. Ẹ lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe ìlérí. Pẹ̀lú àpẹrẹ kọ̀ọ̀kan, ẹ lè sọ papọ̀, “Dúró dè é; nítorí pé dájúdájú yíò dé.”

Hábákúkù 2:14

Mo lè ṣèrànwọ́ láti fi ìmọ̀ Jésù Krístì kún ilẹ̀ ayé.

  • Láti ṣe ìjúwe Hábákúkù 2:14, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè fi àwòrán tàbí ọ̀rọ̀ tó dúró fún àwọn ohun tí Jésù ṣe tàbí àwọn ohun tí Jésù kọ́ni kún inú ìkòkò kan tàbí àpótí míràn. Báwo ni a ṣe lè ṣèrànwọ́ láti fi ìmọ̀ Olúwa kún ayé?

  • Ẹ tún lè fi máàpù àgbáyé han àwọn ọmọ yín (wo Ìtàn Àkọọ́lẹ̀ Ìjọ, nọ́mbà 7, “Máàpù Àgbáyé”). Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ibi tí wọ́n ngbé àti ibi tí àwọn ìránṣẹ́ ìhínrere tí wọ́n mọ̀ ti sìn. Ẹ lè kọ orin kan papọ̀ nípa ṣe àbápín ìhìnrere, gẹ́gẹ́bí “A ó Mú Òtítọ́ Rẹ̀ Wá fún Ayé,”” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 172–73). Kíni a lè sọ fún àwọn míràn nípa Jésù Krístì?

Sefaníàh 3:14–20

Jésù Krístì yọ̀ pẹ̀lú àwọn tó tẹ̀lé E.

  • Nínú Sẹfaníàh 3:14–20, àwọn ọmọ yín lè wá ohun kan tó mú kí wọ́n fẹ́ “kọrin, … ẹ dunnú, kí ẹ sì yọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn.” Bóyá ẹ lè kọ àwọn orin ìdùnnú tàbí orin papọ̀ kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa ayọ̀ tí ẹ rí nínú ìhìnrere Jesu Kristi.

Fún púpọ̀ sí i, wo ìtẹ̀jáde ìwé ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .

Jésù nrẹrin sí ẹgbẹ́ àwọn ọmọdé

Ó sì Mú Àwọn Ọmọdé Ní Ọ̀kọ̀ọ̀kan, láti ọwọ́ Casey Childs

Ojú-ìwé ìṣe ṣíṣe alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Ẹ wá Olúwa