Come, Follow Me
Oṣù kọkànlá 23–29. “Ẹ Wá Olúwa, Ẹ̀yin Ó Sì Yè”: Ámósì; Ọbadíàh; Jónàh


“Oṣù kọkànlá 23–29. ‘Ẹ Wá Olúwa, Ẹ̀yin Ó Sì Yè’: Ámósì; Ọbadíàh; Jónàh,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù kọkànlá 23–29. ‘Ẹ Wá Olúwa, Ẹ̀yin Ó Sì Yè,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026

Jónàh wẹ̀ ní etí òkun

Jónàh lórí Òkun ní Nínéfè, nípasẹ̀ Daniel Lewis

Oṣù kọkànlá 23– 29: “Ẹ Wá Olúwa, Ẹ̀yin Ó Sì Yè”

Ámósì; Ọbadíàh; Jónàh

Jónàh wà nínú ọkọ̀ ojú omi kan tó nlọ sí Táṣíṣì. Kò sí ohun tó burú nínú rírìn lọ sí Táṣíṣì, bí kò ṣe pé ó jìnnà sí Nínéfè, níbití Jónàh ní láti lọ wàásù ìhìnrere Ọlọ́run. Nígbàtí ọkọ̀ ojú omi náà dojú kọ ìjì nlá, Jónàh mọ̀ pé ó jẹ́ nítorí àìgbọràn òun. Nígbàtí Jónàh ntẹnu mọ́ ọn, àwọn atukọ̀ ojú omi ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sọ ọ́ sínú ibú òkun láti dá ìjì náà dúró. Ó dà bí òpin Jónàh àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Olúwa kò fi Jónà sílẹ̀—gẹ́gẹ́bí kò ti fi àwọn ará Nínéfè sílẹ̀, ilé Ísráẹ́lì, tàbí ẹnikẹ́ni nínú wa.

Nítorínáà, Ó nrán àwọn wòlíì nìṣó—bíi Jónà, Ámósì, Ọbadíàh, àti àwọn wòlíì wa lónìí—pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà pé bí a bá ronúpìwàdà, a kì yíò ta wá nù títíláé. Nínú gbogbo “àwọn àṣírí” tí Ọlọ́run fihàn (wo Ámọ́sì 3:7), ọ̀kan yí wà ní àárín àwọn iyebíye jùlọ: pé nítorí Jésù Krístì, kò pẹ́ jù láti yípadà. Ó ṣì nfẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú tí a dá pẹ̀lú Rẹ̀, Ó sì múra tán láti fún wa ní ààyè míràn.

Fún àlàyé ṣókí nípa àwọn ìwé yí, wo “Ámọ́sì,” “Ọbadíàh,” àti “Jónàh” nínú Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ

Ámọ́sì 3:1–8; 7:10–15

àmì sẹ́mínárì
Olúwa nfi òtìtọ́ hàn nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀.

Nínú Ámọ́sì 3:3–6, wòlíì Àmòsí fi àpẹrẹ àwọn ìparí tí a lè fà jáde láti inú àwọn àmì tí a gbọ́ tàbí tí a rí: nígbàtí kìnìún bá gbó, ó gbọ́dọ̀ ti mú ohun ọdẹ; bí pámpẹ́ bá mú ẹyẹ, ìdẹ̀ gbọ́dọ̀ ti wà níbẹ̀. Nínú àwọn ẹsẹ 7–8, Ámósì lo ọgbọ́n ìrònú yìí sí àwọn wòlíì. Àwọn ìparí wo ni a lè ṣe nígbàtí wòlíì kan bá sọtẹ́lẹ̀? Kíni ohun míràn tí ẹ kọ́ nípa àwọn wòlíì látinú Ámọ́sì 7:10–15?

Kí ni Olúwa fi hàn yín nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀?

Alàgbà Ulisses Soares wí pé “níní àwọn wòlíì jẹ́ àmì ìfẹ́ Ọlọ́run” (“Àwọn Wòlíì Nsọ̀rọ̀ nípa Agbára Ẹ̀mí Mímọ́,” Làìhónà, Oṣù karun 2018, 99). Ẹ yẹ bí ẹ ṣe lè parí gbólóhùn yìí: “Mo mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ mi, nítorí pé Ó nrán àwọn wòlíì tí wọ́n …” Ní ìhín ni díẹ̀ nínú àwọn ìwé mímọ́ tí ó lè ṣèrànwọ́: Deuterónómì 18:18; Èsèkíẹ́lì 3:16–17; Éfésù 4:11–14; 1 Néfì 22:2; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 21:4–6; 84:36–38; 107:91–92.

Kíni ẹ o sọ fún ẹnìkan tí ó ní ìmọ̀lára pé a kò nílò àwọn wòlíì ní òní?

Bákannáà wo Àwọn Àkọ́lé àti Àwọn Ìbèèrè, “Àwọn Wòlíì” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.

Ámọ́sì 4– 5

“Ẹ wá Olúwa, ẹ̀yin ó sì yè.”

Gẹ́gẹ́bí Ámọ́sì 4:6–13, kí ni ohun tí Olúwa retí pé yíò ṣẹlẹ̀ lẹ́hìn ìdánwò àwọn ọmọ Ísráẹ́lì? (Bàkannáà wo Hẹ́lámánì 12:3). Nígbàtí àwọn ìdánwò yín lè má jẹ́ wíwá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, báwo ni wọ́n ṣe nfún yín ní ayé láti yípadà sí I?

Bí ẹ ṣe nka Ámósì 5:4, 14–15, ẹ jíròrò bí Olúwa ṣe nṣe àánú yín. Báwo ni wíwá A ṣe nmú ìyè wá?

Ámọ́sì 8:11–12

Ọ̀rọ̀ Olúwa lè tẹ́ ebi ti ẹ̀mí àti òùngbẹ lọ́rùn.

Bí ẹ ṣe nka Ámósì 8:11–12, ẹ ronú nípa ìdí tí ìyàn fi jẹ́ àfiwé dáradára fún gbígbé láìsí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (bákannáà wo Jòhánnù 6:26–35; 2 Néfì 9:50–51; 32:3; Énósì 1:4–8). Báwo ni ẹ ṣe mọ̀ nígbàtí ebi ti ẹ̀mí bá npa yín?

Àwọn ẹsẹ wọ̀nyí tún lè wúlò sí Ìyapa-Nla-kúrò-nínú-ìgbàgbọ́ náà (wo Àwọn Àkọlé àti Ìbéèrè, “Ìyapa-kúrò-nínú-ìgbàgbọ́,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere). Báwo ni “ìyàn” ti ẹ̀mí ṣe nípa lórí àwọn ọmọ Ọlọ́run? Báwo ni Ìmúpadàbọ̀sípò ṣe tẹ́ ebi tẹ̀mí yín lọ́rùn?

Bákannáà wo “Ìyapa-Nla-kúrò-nínú-ìgbàgbọ́” (fídíò), Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.

16:36

The Great Apostasy

Ọbadíàh 1:21

Àwọn wo ni “àwọn olùgbàlà … lórí Òkè Síónì”?

Ní títọ́kasí Obadíàh 1:21, Ààrẹ Gordon B. Hinckley ṣàlàyé pé a di olùgbàlà lórí Òkè Síónì nígbàtí a gba àwọn ìlànà fún àwọn òkú nínú tẹ́mpìlì (wo “Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìparí,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2004, 105). Báwo ni ṣíṣe iṣẹ́ náà ṣe jọra—bí ó bá jẹ́ ní ọ̀nà kékeré—sí ohun tí Olùgbàlà ṣe fún wa? Báwo ni ṣíṣe iṣẹ́ yìí ṣe ràn yín lọ́wọ́ láti nímọ̀lára sísunmọ́ Olùgbàlà?

Bákannáà wo “Àwọn Tẹ́mpìlì Mímọ́ lórí Òkè Síónì,” Àwọn Orin, nọ́mbà 289.

ẹgbẹ kan ti ọ̀dọ̀ ìta tẹ́mpìlì

Jónàh 1–4

Olúwa nṣe àànù fún gbogbo àwon tí ó yípadà sí I.

Nínéfè jẹ́ ọ̀tá Ísráẹ́lì tí a mọ̀ wọ́n sí ìwà ipá àti ìkà. Sí Jónàh, ó dà bíi pé kò bọ́gbọ́n mu pé wọ́n ṣetán láti ronúpìwàdà. Ẹ lè dùnmọ́ni láti fi ìwà Jónàh wé (wo Jónàh 1; 3–4) sí ìmọ̀lára Álmà àti àwọn ọmọ Mòsíàh (wo Mòsíàh 28:1–5; Álmà 17:23–25). Kíni ẹ kọ́ látinú Jónà 3 tí ó fún yín ní ìmísí láti ṣe àbápín ìhìnrere pàápàá pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ó lè dàbí ẹnipé wọn ti ṣetán láti yípadà?

Bí ẹ ṣe nka Jónàh, ẹ wá àwọn àpẹrẹ ti àánú Olúwa. Kínìdí tí ẹ fi ní ìmọ̀lára pé Jónàh kò ní “inú dídùn” àti pé o “ bínú gan” (Jónàh 4:1) nígbà tí Olúwa fi àánú hàn sí áwọn ará Nínéfè? Kíni ìmọ̀lára tí ẹ ní pé Olúwa ngbìyànjú láti kọ́ ọ nínú orí 4? Ẹ jíròrò bí ẹ ti ní ìrírí àánú Rẹ̀ ní ìgbésí-ayé yín. Kíni ẹ kọ́ láti ara Jónà tó lè ràn ẹyín lọ́wọ́ láti túbọ̀ jẹ́ alaanu?

ìpínn àmì àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Nítorí pé Ọjọ́ ìsinmi yìí jẹ́ Ọjọ́ ìsìnmi karùn oṣù, a gba àwọn olùkọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ níyànjú láti lo àwọn ìṣe ṣíṣe ikẹkọ nínú “Àlẹ̀mọ́ B: Mímúra Àwọn Ọmọdé Sílẹ̀ fún Ìgbésí-ayé Ní Ipa-ọ̀nà Májẹ̀mú Ọlọ́run.”

Ámósì 3:7

Àwọn wòlíì jẹ́ ìránṣẹ́ Jésù Krístì.

  • Láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ yín láti ní òye Ámósì 3:7, ẹ lè sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí ọ̀kan nínú wọn kí ẹ sọ fún wọn láti ṣe àbápín ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àwọn ọmọ míràn. Báwo ni ìránṣẹ́ náà ṣe dà bí wòlíì nínú ìṣe ṣíṣe yìí? Kínìdí tí Olúwa fi fún wa ní àwọn wòlíì?

  • Láti kẹkọ sí i nípa ohun tí àwọn wòlíì nṣe, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ aipẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ààrẹ Ìjọ lọ́wọ́lọ́wọ́. Ẹ tún lè kọ orin kan bíi “Tẹ̀lé Wòlíì náà” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 110–11). Ẹ ṣe àbápín pẹ̀lú ara yín ìdí tí ẹ fi yàn láti tẹ̀lé wòlíì Ọlọ́run.

Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn Ìwé Mímọ́ sórí. Alàgbà Richard G. Scott ṣe àbápín: “Lati kọ́ Ìwé Mímọ́ sórí ni láti dá ọ̀rẹ́ titun sílẹ̀. Ó dà bí ṣíṣe àwárí ẹnìkọ̀ọ̀kan titun tí ó lè ṣèrànwọ́ ní àkokò àìní, fún ìmísí àti ìtùnú, tí ó sì jẹ́ orísun ìwúrí fún ìyípadà tí a nílò” (“Agbára Ìwé Mímọ́,” Ẹ́nsáìn, Oṣù kọkànlá 2011, 6). Láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ gbogbo tàbí ara ti Ámósì 3:7sórí, ẹ lè kọ ọ́ sílẹ̀ kí ẹ sì tún un sọ papọ̀. Lẹ́hìnnáà ẹ lè parẹ́ tàbí bo àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ ní àkokò kan títí tí àwọn ọmọ yín yíò fi tún gbogbo ẹsẹ náà sọ látinú ìrántí.

Ámọ́sì 8:11–12

Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere parí ìyàn ìyapa-kúrò-nínú-ìgbàgbọ́.

  • Ẹ pe àwọn ọmọ yín láti ṣe bí ẹni pé ebi npa wọ́n bí ẹ ṣe nka Ámósì 8:11–12. Báwo ni ó ṣe nrí lára wa nígbàtí ebi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá npa wá? Bóyá àwọn ọmọ yín lè díbọ́n bí wọ́n ṣe njẹun bí ẹ ṣe nṣe àbápín díẹ̀ lára àwọn Ìwé Mímọ́ tí ẹ fẹ́ràn.

  • Ẹ lè lo Ìtọ́sọ́nà Ìwé Mímọ́, “Ìyapa-kúrò-nínú-ìgbàgbọ́” (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere), tàbí “Lẹ́hìn Májẹ̀mú Titun” (nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Titun, 167–70) láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye “ìyàn” tí ó wá látinú Ìyapa Nlá-kúrò-nínú-ìgbàgbọ́ àti bí ó ṣe parí pẹ̀lú Ìmúpadàbọ̀sípò. Ẹ ṣe àbápín pẹ̀lú àwọn ìdí tí ẹ fi dúpẹ́ pé Olúwa mú ìhìnrere Rẹ̀ padàbọ̀sípò ní ọjọ́ wa.

    2:52

    After the New Testament

Jónàh 1–3

Olúwa yíò ràn mí lọ́wọ́ láti gbọ́ran sí I, pàápàá nígbàtí ó bá le.

  • Láti ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti kẹọ́ ẹ̀kọ́ ìtàn Jónà, ẹ lè ṣe àtúnyẹ̀wò “Jónà Wòlíì náà” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé; bákanáà wo ojú-ewé ìṣe ṣíṣe ti ọ̀sẹ̀ yí). E lè bèèrè lẹ́hìnnáà:

    • Kíni ó ṣẹlẹ̀ nígbàtí Jónà kò gbọ́ran sí Olúwa? (wo Jónà 1:4–17).

    • Kíni Jónà ṣe láti ronúpìwàdà? (wo Jónàh 1:10–12; 2:1–4, 9; 3:1–4).

    • Kíni ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jónà gbọ́ran? (wo Jónàh 3:5).

    2:30

    Jonah the Prophet

  • Àwọn ọmọ yín lè gbádùn títún ìtàn Jónàh sọ tàbí fífi ṣeré síta. Ẹ ṣe àbápín díẹ̀ nínú àwọn ìrírí nígbàtí Olúwa fẹ́ kí ẹ ṣe nkan tí ó le fún yín pẹ̀lú ara yín. Báwo ni Ó ṣe ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ran Sí I?

Jónà 1–4

Olúwa pọ̀ ní àànù fún gbogbo àwọn tí wọ́n yípadà sí I.

  • Bóyá àwọn ọmọ yín lè ṣe bí ẹnipé wọ́n nfi ọ̀rọ̀ wá Jónàh lẹ́nu wò nípa ìrírí rẹ̀. Àwọn ìbéèrè wo ni wọ́n máa bi í? Ẹ gbà wọ́n níyànjú láti béèrè ìbéèrè kí wọ́n lè mọ ohun tí Jónàh kọ́ nípa Olúwa. Bí àpẹrẹ, kíni Jónàh lè sọ nípa àánú Olúwa? (wo, fun apẹẹrẹ, Jónàh 2:7–10; 3:10; 4:2).

Jésù dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan tí wọ́n ngbékalẹ̀ láti orí òrùlé

Krístì àti Ọkùnrin Alárùn ẹ̀gbà, láti ọwọ́ J. Kirk Richards

  • Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn àpẹrẹ nígbàtí Olùgbàlà fi àánú hàn sí àwọn ẹlòmíràn, bíi Máàkú 2:3–12; Lúkù 23:33–34; àti Jòhánnù 8:1–11. Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè wá àwọn àwòrán ti àwọn àpẹrẹ wọ̀nyí. Àwọn ànfàní wo ni a ní láti ṣe àánú fún àwọn ẹlòmíràn?

Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .

Nígbàtí wọ́n ju Jónàh látinú ọkọ̀ ojú omi sínú òkun, níbití òjìji ẹja nlá kan kò ti ṣeé rí

Jónà lórí Òkun ní Nínéfè, láti ọwọ́ Kevin Carden

Oju-èwe ìṣe ṣíṣe alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Olúwa yíò ràn mí lọ́wọ́ láti gbọ́ran sí I, àní nígbàtí ó bá le.