Come, Follow Me
Oṣù kọkànlá 9–15. “Nítorí Kòsí Ọlọ́run Míràn Tí Ó Lè Gbani”: Daniel 1–7


“Oṣù kọkànlá 9–15. ‘Nítorí Kòsí Ọlọ́run Míràn Tí Ó Lè Gbani’: Ìsàíàh 1–7,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù kọkànlá 9–15. ‘Nítorí Kòsí Ọlọ́run Míràn Tí Ó Lè Gbani,’” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026

Nebukadnéssárì ntẹ́tísí Dáníẹ́lì pẹ̀lú ìfarabalẹ̀

Dáníẹ́lì túmọ̀ àlá Nebukadnéssárì, nípasẹ̀ Grant Romney Clawson

Oṣù kọkànlá 9–15: “Nítorí Kòsí Ọlọ́run Míràn Tí Ó Lè Gbani”

Dáníẹ́lì 1–7

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kò sí ẹnìkan tí yíò halẹ̀ láti sọ yín sínú iná ìléru tàbí ihò kìnìún nítorí ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Kristi. Ṣùgbọ́n kò sí ọ̀kan nínú wa tí ó nla ayé yí láìsí ìdánwó ìgbàgbọ́. Nítorínáà, gbogbo wa lè jẹ èrè látinú àpẹrẹ àwọn ènìyàn bíi Dáníẹ́lì, Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò, tí wọ́n kó ní ìgbèkùn gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́mọkùnrin nípasẹ̀ alágbára Ilẹ̀ Ọba Bábílónì (wo 2 Ọba 24:10–16). Ní yíyíká nípasẹ̀ àṣà àìmọ̀ pẹ̀lú àwọn iyì tí ó yàtọ̀, wọ́n kojú àwọn ìdánwò nlá láti pa àwọn ìgbàgbọ́ àti àwọn àṣà òdodo wọn tì. Síbẹ̀ wọ́n dúróṣinṣin ti àwọn májẹ̀mú wọn. Báwo ni wọn ṣe ṣe é? Nípa ṣíṣe àwọn kékeré àti rírọrùn wọ̀nnì tí Ọlọ́run nbéèrè lọ́wọ́ gbogbo wa—àdúrà, ààwẹ̀, yíyan àwọn ọ̀rẹ́ rere, ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀, àti jíjẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Bíi ti Jósẹ́fù ní Egypt àti Ẹ́sítérì ní Páṣíà, Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní Bábílónì pa ìgbàgbọ́ wọn mọ́ nínú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣì nmísí àwọn onígbàgbọ́ títí di òní.

Fún àlàyé ṣókí nípa ìwé Dáníẹ́lì, wo “Dáníẹ́lì” nínú Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ

Dáníẹ́lì 1; 36

àmì sẹ́mínárì
Mo lè gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbàtí a bá dán ìgbàgbọ́ mi wò.

Ní ọgbọ́n kan, gbogbo wa la ngbé ní Bábílónì. A máa ndojúkọ àwọn àdánwò láti ṣe àdàlù àwọn òṣùwọ̀n wa kí a sì yípadà kúrò nínú ìgbàgbọ́ nínú Krístì. Bí ẹ ṣe nka Dáníẹ́lì 1, 3, àti 6, ẹ ṣe àkíyèsí àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi fi ipá mú Dáníẹ́lì, Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò láti ṣe àwọn ohun tí wọ́n mọ̀ pé kò tọ́. Báwo ni wọ́n ṣe dáhùn sí àwọn ipò wọ̀nyí? (wo Dáníẹ́lì 1:10–13; 3:15–18; 6:10). Kíni àbájáde ìgbàgbọ́ wọn? Kíni ẹ kọ́ nlátinú àwọn ìrírí wọ̀nyí tó lè ràn yín lọ́wọ́ láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbàtí ẹ bá dojúkọ àtakò? Ẹ tún gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò:

  • Nígbàwo ní ẹ ti ní ìmọ̀lára ìtẹ̀mọ́ra láti ṣe nkan tí ẹ mọ̀ pé kò tọ́? Báwo ni Olúwa ṣe bùkún yín fún pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́?

  • Bí ìgbàgbọ́ yín kò bá darí sí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ẹ nwá? (fún àpẹrẹ kan, wo Álmà 14:8–13). Ní dídálé ohun tí ẹ kà nínú Dáníẹ́lì 3:13–18, báwo ni ẹ ṣe rò pé Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò ì bá ti dáhùn ìbéèrè yìí? Báwo ni àpẹrẹ wọn ṣe lè nípa lórí bí ẹ ṣe nkojú àwọn ìdánwò yín?

  • Báwo ni àwọn yíyàn òdodo ṣe lè darí àwọn ẹlòmíràn sí ìgbàgbọ́ títóbi nínú Olúwa? (wo Dáníẹ́lì 2:47; 3:28–29). Ẹ jíròrò nípa ipa tí àwọn yíyàn yín lè ní lórí àwọn ẹlòmíràn.

Bákannáà Dieter F. Uchtdorf, “Ma Bẹ̀rù, Gbàgbọ́ Nìkan,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2015, 76–79.

Gbìyànjú láti kópa gbogbo ènìyàn. Olùgbàlà “pe … gbogbo ènìyàn láti wá sọ́dọ̀ òun kí wọ́n sì ṣe alabapin nínú oore rẹ̀” (2 Néfì 26:33). Bí ẹ bá nkọ́ ẹbí yín tàbí kílásì kan, ẹ jíròrò àwọn ọ̀nà tí ẹ lè fi fún gbogbo ènìyàn ní ànfàní láti kópa ní ọ̀nà kan. Fún àpẹẹrẹ, ẹ lè fún ẹni kọ̀ọ̀kan ní àyọkà ìwé mímọ́ kan, apákan ti ìfiránṣẹ́ ìpàdé àpapọ̀ kan, tàbí ẹsẹ kan láti inu orin kan láti ronú jinlẹ̀ nípa àsọyé. Ẹ máṣe fi agbára mú ẹnikẹ́ni làti kópa, ṣùgbọ́n fún wọn ní ànfàní.

Ṣédrákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dinígò, àti ẹni kẹ́rin nínú iná ìléru

Ṣédrákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dinígò àti ẹni kẹ́rin nínú iná ìléru, láti owó William Maughan

Dáníẹ́lì 2

Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn jẹ́ ìjọba Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé.

Nípasẹ̀ ìfihàn, Dáníẹ́lì rí i pé àlá Nebukadinésárì sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìjọba ayé ọjọ́ iwájú, àti ìjọba Ọlọ́run ọjọ́ iwájú, èyí “tí a kì yíò parun láéláé” (Dáníẹ́lì 2:44). “Ìjọ ni ìjọba ọjọ́ ìkẹhìn náà tí a sọtẹ́lẹ̀,” Alàgbà D. Todd Christofferson kọ́ni pé, “kì í ṣe ènìyàn ni ó dá ṣùgbọ́n a gbékalẹ̀ láti ọwọ́ Ọlọ́run ọ̀run ó sì nyí bí òkúta ‘tí a gé kúrò ní òkè ńlá láìsí ọwọ́’ láti kún ilẹ̀ ayé” (“Kínìdí Ìjọ náà,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2015, 111). Ẹ ronú nípa ìjọba Ọlọ́run ọjọ́ ìkẹhìn bí ẹ ṣe nka àwọn àpèjúwe òkúta náà nínú Dáníẹ́lì 2:34–35, 44–45. Kíni ojúṣe yín nínú ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ?

Bákannáà wo “Gbọ́, Gbogbo Ẹ̀yin Orílẹ̀-Èdè!,” Àwọn orin, nọ́mbà 264; “Ọlọ̀run Fún Wọn Ní Ìmọ̀” (fídíò), ChurchofJesusChrist.org.

13:49

God Gave Them Knowledge

Dáníẹ́lì 2:1–30

Gbígba ìfihàn bèèrè fún ìmúrasílẹ̀ ti ẹ̀mí.

Bí ẹ ṣe nṣe àtúnyẹ̀wò Dáníẹ́lì 2:1–15, ẹ yẹ bí ẹ yíò ṣe ní ìmọ̀lára bí ẹ bá rí ara yín ní ipò Dáníẹ́lì. Kíni Dáníẹ́lì ṣe? (wo Dáníẹ́lì 2:16–18). Kíni ẹ lè kọ́ nínú Dáníẹ́lì 1:17 nípa bí Ọlọ́run ṣe múra Dáníẹ́lì sílẹ̀? Kíni ẹ lè kọ́ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe Dáníẹ́lì lẹ́hìn tó rí ìrànlọ́wọ́ Olúwa gbà? (wo Dáníẹ́lì 2:19–30).

Dáníẹ́lì 7:13–14

Jésù Krístì ni Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Baba Ayérayé.

Ní àkokò iṣẹ́ ìrànṣẹ́ ilẹ̀ ayè Olùgbàlà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù yẹ àkọ́lé náà “Ọmọ ènìyàn” wo nínú Dáníẹ́lì 7:13 láti tọ́kasí Mèssíàh tó nbọ̀. Kíni ẹ kọ́ nípa Mèssíàh nínú Dáníẹ́lì 7:13–14? (bákannáà wo Mósè 6:57).

Olùgbàlà ntọ́ka sí ara rẹ̀ nígbàkugbà gẹ́gẹ́ bí “Ọmọ ènìyàn.” Ẹ yẹ ṣíṣe àtúnyẹ̀wò àwọn àpẹrẹ kan: Máttéù 25:31; Máàkù 9:31; 10:45. Kíni Ó nkọ́ni nípa ara Rẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí? Nínú Máàkù 14:61–64, Jésù lo àkọ́lé yí ní ọjọ́ ìkẹhìn ayé ikú Rẹ̀. Ẹ ṣe àkíyèsí ìdáhùnsí láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n gbọ́ ìkéde Rẹ̀. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa Ọmọ ènìyàn ṣe nípa lórí ìmọ̀lára yín nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nínú Máàkù 15?

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe kórìíra Jésù fún kíkéde pé òun jẹ́ “Ọmọ ènìyàn,” ẹ̀yin náà lè dojúkọ inúnibíni fún kíkéde òtítọ́. Ẹ ṣe àfiwé àsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà nínú Dáníẹ́lì 7:13–14 pẹ̀lú àwọn ìlérí nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 121:29, 46.

Bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 49:6; Ìtọ́sọ́nà sí Ìwé mímọ́, “Ọmọ Ènìyàn,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.

ìpín àmì àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Dáníẹ́lì 1; 36

Jésù yiò ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́ pàápàá nígbàtí ó bá le.

  • Láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kẹọ́ ẹ̀kọ́ nínú àwọn ìtàn ìmísí nínú ìwé Dáníẹ́lì, ẹ lè rí àwọn àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ náà nínú Dáníẹ́lì 1, 3, àti 6 (wo ojú ewé ìṣe ṣíṣe ti ọ̀sẹ̀ yìí tàbí Ìwé Ọnà Ìhìnrere, nọ́mba 23, 2526). Lẹ́hìnnáà ẹ lẹ̀ gbé àwọn àwòrán kọjú sísàlẹ̀ kí ẹ pe ọmọ kan láti yí ọ̀kan padà kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa ìtàn tí ó rọ́pò. (Fún ìrànlọ́wọ́, wo “Dáníẹ́lì àti àwọn Ọ̀rẹ̀ Rẹ̀,” “Ṣ̣édrákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò,” àti “Dáníẹ́lì àti Ihò Kìnìún” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 154–56, 160–62, 163–65.)

    1:39

    Daniel and His Friends

    1:39

    Shadrach, Meshach, and Abed-nego

    1:45

    Daniel and the Lions’ Den

  • Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú àwọn ipò nígbàtí a lè fi agbára mú wọn láti ṣe yíyàn tí kò tọ́, gẹ́gẹ́bí Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ̀ rẹ ti wà nínú Dáníẹ́lì 1, 3, and 6. Ẹ ṣe àbápín pẹ̀lú ara yín bí ẹ ti di alábùkún fún ṣíṣe yíyàn tí ó tọ́ pàápàá nígbàtí ó bá le. Ẹ tún lè kọ orin kan papọ̀ tí ó jọ àkọ́lé yí, bíi “Ṣe Yíyàn Títọ́” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, nọ́mba 239).

àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin nkọ̀ láti jẹ ẹran

Gbígbẹ́kẹ̀lé Ọgbọ́n Ọ̀rọ̀ náà

Dáníẹ́lì 1:1–17

Baba Ọ̀run fẹ́ kí ntọ́jú ara mi.

  • Kíka ìtàn nípa Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n kọ ẹran àti wáìnì ọba le mú ìbárasọ̀rọ̀ ìmísí kan wá nípa òfin ìlera tí Baba Ọ̀run fún wa ní òní (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 89). Bóyá ẹ lè wá àwọn ìbùkún tí Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ gba kí ẹ sí ṣe àfiwé wọn sí àwọn ìbùkún tí a ṣe ìlérí nínú Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n (wo Dáníẹ́lì 1:15–17 àti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 89:18–21).

Dáníẹ́lì 2

Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn jẹ́ ìjọba Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé.

  • Bí ẹ ṣe nka Dáníẹ́lì 2:31–35, 44–45 pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, ẹ lè pè wọ́n láti ya àwòrán àlá Nebukadinésárì. Ẹ ran wọn lọ́wọ́ láti ní òye pé òkútà tí ó wà nínú àlá rọ́pò Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Kíni a kọ́ nípa Ìjọ láti inú àlá yìí? Àwọn ọmọ yín lè dárúkọ àwọn ohunkan tí Baba Ọ̀run ṣe láti gbé Ìjọ Rẹ̀ kalẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Bí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́, ẹ lè fi àwọn àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ hàn látinú Ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ (wo Ìwé Ọnà Ìhìnrere, nọ́mbà 90–95).

Dáníẹ́lì 6

Baba Ọ̀run fẹ kí ngbàdúrà léraléra.

  • Kínìdí tí gbígbàdúrà sí Bàbá Ọ̀run fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ sí Dáníẹ́lì? Bóyá ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè sọ̀rọ̀ nípa ìbéèrè náà bí ẹ ṣe nka Dáníẹ́lì 6 papọ̀. Lẹ́hìnnáà, ẹ lè sọ ìdí tí àdúrà fi ṣe pàtàkì sí yín. Àwọn ọmọ yín lè gbádùn yíya àwòrán ara wọn tí wọ́n ngbàdúrà ní àwọn ipò oríṣiríṣi. Wọ́n lè lo àwọn àwòrán wọn láti kọ́ ara wọn pé a lè gbàdúrà sí Baba Ọ̀run níbikíbi yíówù kí a lè wà tàbí ohun tí a nílò.

Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .

Dáníẹ́lì ndúró níwájú àwùjọ àwọn kìnìún

Dáníẹ̀lì nínú ihò Kìnìún, láti ọwọ́ Briton Rivière

Ojú-ewé ìṣe ṣíṣe alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Ọlọ́run yíò bùkún mi bí mo ṣe nyàn láti tẹ̀lé Jésù Krístì