Come, Follow Me
Oṣù kọkànlá 2–8. “Ẹ̀mí Titun Ni Èmi Ó Fi Sínú Yín”: Èsèkíẹ́lì 1–3; 33–34; 36–37; 47


“Oṣù kọkànlá 2–8. ‘Ẹ̀mí Titun Ni Èmi Ó Fi Sínú Yín’: Èsèkíẹ́lì 1–3; 33–34; 36–37; 47,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù kọkànlá 2–8. ‘Ẹ̀mí Titun Ni Èmi Ó Fi Sínú Yín,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026

olùṣọ́ lórí ilé ìṣọ́

Oṣù kọkànlá 2–8: “Ẹ̀mí Titun Ni Èmi Ó Fi Sínú Yín”

Èsèkíẹ́lì 1–3; 33–34; 36–3747

Èsèkíẹ́lì jẹ́ wòlíì kan nígbèkùn. Pẹ̀lu àwọn ará Ìsráẹ́lì míràn, a ti mú un a sì ti ran lọ sí Bábílónì. Ní Jerúsálẹ́mù, Èsèkíẹ́lì ì bá ti jẹ́ àlùfáà tó nsìn nínú tẹ́mpìlì. Ní Bábílónì, ó wà lára “àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn,” ó sì “jókòó ní ibi tí wọ́n jókòó” (Èsèkíẹ́lì 3:15), ní ọgọ́gọ̀ọ̀rún kìlómítà sí ilé àyànfẹ́ Ọlọ́run àti pẹ̀lú ìrètí láti padà wá. Nígbànáà ni ọjọ́ kan Èsèkíẹ́lì rí ìran kan. Ó rí “ògo Olúwa” (Èsèkíẹ́lì 1:28)—kì í ṣe nínú tẹ́mpìlì ní Jerúsálẹ́mù bí kò ṣe ní Bábílónì ní àárín àwọn tí a kó ní ìgbèkùn. Ìwà búburú ní Jerúsálẹ́mù, tí ó kọ́, ti le tóbẹ́ẹ̀ tí wíwà Ọlọ́run kò sí níbẹ̀ mọ́ (wo Èsèkíẹ́lì 8–11; 33:21).

Àti pé síbẹ̀ ohunkan wà tó jẹ́ ìrètí nípa ọ̀rọ̀ Èsèkíẹ́lì. Bótilẹ̀jẹ́pé àwọn ènìyàn májẹ̀mú náà ti ṣubú, Ọlọ́run kò pa wọ́n tì pátápátá. Bí wọ́n bá “gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa” (Èsèkíẹ́lì 37:4), ohun tó ti kú nígbà kan rí lè sọ jí. Ọkàn “òkúta wọn” ni a lè fi “ọkàn titun” rọ́pò” (Èsèkíẹ́lì 36:26). Àti ní ọjọ́ iwájú, Olúwa yíò gbé tẹ́mpìlì titun àti Jerúsálẹ́mù Titun kalẹ̀, “àti pé orúkọ ìlú náà láti ọjọ́ náà yíò jẹ́, Olúwa nbẹ níbẹ̀” (Èsèkíẹ́lì 48:35).

Fún àlàyé ṣókí nípa ìwé Èsékíẹ́lì, wo “Èsèkíẹ́lì” nínú Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ

Èsèkíẹ́lì 334

Olúwa npè mí láti bọ́ àgùtàn Rẹ̀.

Nínú Èsèkíẹ́lì 3 àti 34, Olúwa tọ́ka sí àwọn olùdarí àwọn ènìyàn Rẹ̀ gẹ́gẹ́bí olùṣọ́ àti olùṣọ́-àgùtàn. Bí ẹ ṣe nka àwọn orí wọ̀nyí, ẹ yẹ ò ohun tí àkọ́lé wọ̀nyí dábàá nípa ohun tí ó túmọ̀ sí láti jẹ́ olùdarí.

Àwọn wo ni “àgùntàn” tí Olúwa fẹ́ kí ẹ máa bọ́? Kíni ẹ rí nínú Èsèkíẹ́lì 34 tó lè ran ẹnìkan lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ láti sìn míṣọ̀n, títọ́ àwọn ọmọ dàgbà, tàbí mímú ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ kan ṣẹ? Báwo ni ẹ ṣe lè tẹ̀lé àpẹrẹ Olùgbàlà gẹ́gẹ́bí olùṣọ́-àgùtàn wa? (wo àwọn ẹsẹ 11–31).

Ẹ tún lè ronú nípa àmì tí ẹ ri nínú ori yí. Kíni “pápá ìjẹko rere” àti “agbo rere” náà lè dúró fún ní ẹsẹ 14? Kíni ìyàtọ̀ ní àárín àgùntàn tó “sọnù” àti ẹnití “a lé lọ”? (ẹsẹ 16). Àwọn àmì míràn wo ni ẹ rí?

Bákannáà wo Jòhánnù 21:15–17; Gerrit W. Gong, “Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́,” Làìhónà, Oṣù karun 2023, 16–19.

Èsèkíẹ́lì 33:10–19

Olúwa nfẹ́ kí ẹ dáríjì.

“Bí àwọn … ẹ̀ṣẹ̀ wa bá wà lórí wa,” yíò ya àwọn ọmọ Ìsráẹ́lì tó wà ní ìgbèkùn lẹ́nu, “báwo ni ó ṣe yẹ ká wà láàyè nígbànáà?” (Èsèkíẹ́lì 33:10). Ní ìfèsì, Olúwa kọ́ wọn nípa ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì. Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí lè ràn yín lọ́wọ́ láti ronú lórí ohun tí Ó kọ́ni:

  • Kíni ẹ rò pé ó túmọ̀ sí láti “gbẹ́kẹ̀lé òdodo [ara] rẹ”? (wo Èsèkíẹ́lì 33:12–13).

  • Kíni ẹ yíò sọ fún ẹnìkan tí ó ní ìmọ̀lára pé àwọn ènìyàn nínú Èsèkíẹ́lì 33:12–19 ni a kò ṣesí dáadáa? (Bákannáà wo Máttéù 21:28–31; Lúkù 18:9–14).

  • Kíni ẹ rí nínú àwọn ẹsẹ yìí tó jẹ́ kí ẹ ní òye ohun tí ó túmọ̀ sí láti ronúpìwàdà? Àwọn àfikún ìwòye wo ni ẹ rí nínú Èsèkíẹ́lì 36:26–27 àti Álmà 7:14–16?

Èsèkíẹ́lì 37

àmì sẹ́mínárì
Olúwa nkó àwọn ènìyàn Rẹ̀ jọ ó sì nfún wọn ní ayé titun.

Kíkórajọ Ísráẹ́li jẹ́ àfihàn nínú Èsèkíẹ́lì 37 nípasẹ̀ àwọn àmì méjì. Bí ẹ ṣe nka nípa àkọ́kọ́ yí—àwọn egungun òkú tí a mú padàbọ̀ sí ìyè (wo àwọn ẹsẹ 1–14)—ẹ jíròrò nípa ohun tí ó dá àbá sí yín nípa kíkójọ Ísráẹ́lì jọ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú náà (bákannáà wo Èsèkíẹ́lì 36:24–30). Ẹ lẹ̀ yẹ àwọn ìbéèrè bi wọ̀nyí wò:

  • Kíni Olúwa ngbìyànjú láti ṣe nípasẹ̀ ìkójọ Ísráẹ́lì?

  • Báwo ni Ó ṣe nṣe àṣeyọrí ré?

Ẹ lè bèèrè lọ́wọ́ ara yìn àwọn ìbèèrè kannáà bí ẹ ṣe nkà nípa àmì kejì, nínú àwọn ẹsẹ 15–28. Àmì yí pẹ̀lú àwọn igi méjì, èyítí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ṣe ìtúmọ̀ sí bí àwọn pákó kikọ onígi tí ó darapọ̀ mọ́ ìgun kan. Ọpá Júdàh lè rọ́pò Bíbélì (níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé púpọ̀ lára Bíbélì ni a ti kọ́ nípasẹ̀ àwọn ìrandíran Júdàh), igi Jósẹ́fù sì lè rọ́pò Ìwé ti Mọ́mọ́nì (níwọ̀n ìgbà tí ẹbí Léhì jẹ́ ìràndíran Jósẹ́fù ti Egypt). Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, kíni àwọn ẹsẹ wọ̀nyí kọ́ yín nípa ipa tí Ìwé Mímọ́ kó nínú kíkójọ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì?

Ẹ ronú nípa bí Bíbélì àti Ìwé Mọ́mọ́nì ti ṣiṣẹ́ papọ̀ nínú ìgbésí-ayé yín—ní pàtàkì, láti ràn yín lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ Krístì. Àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ wo ni ó nítumọ̀ sí yín gan-an?

Bákannáà 2 Néfì 3:11–13; 29:14; “Ísráẹ́lì, Ísráẹ́lì, Ọlọ́run Npè,” Àwọn orin, nọ́mbà 7; Àwọn Àkọlé àti Ìbèèrè, “Bíbélì,” “Ìwé Mọ́mọ́nì,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere; “Ìwé ti Mọ́mọ́nì Nkó Isráẹ́lì Tí a fọ́nká Jọ” (fídíò), Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.

1:31

The Book of Mormon Gathers Scattered Israel

Òkun Kíkú tí aṣálẹ̀ yí ká

Nínú ìran kan, Èsèkíẹ́lì rí odò kan tó nṣàn láti inú tẹ́mpìlì tó sì wo Òkun Kíkú sàn.

Èsèkíẹ́lì 47:1–12

Mo lè rí ìwòsàn nínú ilé Olúwa.

Bí ẹ ṣe nka Èsèkíẹ́lì 47:1–12, ẹ lè ṣe ìrànlọ́wọ́ láti mọ̀ pé Òkun Kíkú ní iyọ̀ dé bi pé ẹja àti ewéko kò lè gbé inú rẹ̀. Kíni ó wọ̀ yín lọ́kan nípa omi tí a ṣe àpèjúwe nínú àwọn ẹsẹ 1–12? (bákannáà wo Ìfihàn 22:1). Kíni omi wọ̀nyí lè ṣe àpẹrẹ? Kíni àwọn igi tí a ṣe àpèjúwe nínú ẹsẹ 12 rọ́pò?

Kíni ọ̀rọ̀ Alàgbà Dale G. Renlund “Ìtàn Ẹbí àti Iṣẹ́ Tẹ́mpìlì: Èdidì àti Ìwòsàn” fikún òye yín? (wo Làìhónà, Oṣù Karun 2018, 47–48). Ẹ jíròrò nípa bí ẹ ṣe rí ìyè ti ẹ̀mí àti ìwòsàn nítorí tẹ́mpìlì.

ìpín àmì àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Èsèkíẹ́lì 3:17; 33:1–5

Àwọn wòlíì dàbí àwọn olùṣọ́ tí ó nkìlọ̀ fún wa nípa ewu.

  • Àwọn ọmọdé lè gbádùn ṣíṣe ohun tó bá lọ pẹ̀lú Èsèkíẹ́lì 3:17. Fún àpẹrẹ, wọ́n lè tọ́ka sí ojú, etí, àti ẹnu wọn nígbàtí ẹ bá ka àwọn ọ̀rọ̀ náà “olùṣọ́,” “gbọ́,” àti “ẹnu.” Wọ́n tún lè fẹ́ láti lọ rin ìrìn-àjò kan—ti ìta gbangba tàbí ní àyíká yàrá náà. Bí wọ́n ṣe nrìn, ẹ kìlọ̀ fún wọn nípa àwọn nkan tó wà lójú ọ̀nà, bí àwọn odò tí wọ́n máa nfo orí rẹ̀, ẹ̀ka tó wà lábẹ́, tàbí àwọn ẹranko láti yẹra fún (tòótọ́ tàbí díbọ́n). Èyí lè yọrí sí bíbárasọ̀rọ̀ nípa bí wòlíì Olúwa ṣe kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ewu tí a kò lè rí.

  • Ní ìhín ni ọ̀nà míràn láti ṣe àpèjúwe Èsèkíẹ́lì 3:17; 33:1–5. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ yín lè díbọ́n bí ẹni tó jẹ́ “olùṣọ́” nípa wíwo ojú fèrèsé, kí ó sì sọ ohun tó nṣẹlẹ̀ níta fún gbogbo ènìyàn. Ẹ tún lè wo fídíò “Olùṣọ lórí Ilé ìṣọ́” (ChurchofJesusChrist.org). Báwo ni wòlíì wa alààyè ṣe dàbí olùṣọ́ fún wa?

    4:17

    Watchman on the Tower

Èsèkíẹ́lì ndi àkájọ ìwé méjì mú

Wòlíì Èsèkíẹ́lì náà, láti ọwọ́ Lyle Beddes

Èsèkíẹ́lì 37:15–23

Bíbélì àti Ìwé Mọ́mọ́nì ṣe ìrànlọ́wọ́ láti “ṣe ìkójọ” wá sọ̀dọ́ Jésù Krístì.

  • Lẹ́hìn kíka Èsèkíẹ́lì 37:15–23 ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè rí igi méjì kí ẹ sì kọ sí ára ọ̀kan pé Fún Júdàh (Bíbélì) àti ní orí òmíràn Fún Jósẹ́fù (Ìwé ti Mọ́mọ́nì). Lẹ́hìnnáà ẹ lè ṣe àbápín àwọn ìtàn tàbí àwọn ìwé mímọ́ látinú Bíbélì àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì tí ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti ní ìmọ̀lára ìsúnmọ́ Olùgbàlà àti láti di “ènìyàn [Rẹ̀]” (ẹsẹ 23). Kínìdí tí ó fi dára láti ní méjèèjì àwọn ìwé mímọ́ méjì wọ̀nyí?

Ẹ máṣe gbìyànjú láti bo ohun gbogbo mọ́lẹ̀. Ẹ lè má le ṣe àwárí gbogbo òtítọ́ nínú Èsèkíẹ́lì pẹ̀lú àwọn ọmọ yín. Ẹ fi pẹ̀lú àdúrà gbé ohun tí wọ́n nílò láti ní òye yẹ̀ wò, kí ẹ sì wá ìtọ́sọ́nà ti ẹ̀mí láti pinnu ohun tí wọ́n máa kọjúsí. (Wo Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà17.)

Èsèkíẹ́lì 47:1–12

Ọkàn àti ẹbí wa lè rí ìwòsàn nínú ilé Olúwa.

  • Èsèkíẹ́lì 47 ṣe àpèjúwe ìran Esékíẹ́lì nípa omi tí ó nṣàn láti inú tẹ́mpìlì tí ó sì nwo Òkun Kíkú sàn—òkun tí ó níyọ̀ débi pé ẹja àti ewéko kò lè gbé inú rẹ̀. Bóyá àwọn ọmọ yín lè fa ohun kan tàbí méjì yọ látinú ìran náà, bí tẹ́mpìlì, odò, aṣálẹ̀, Òkun Kíkú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja, tàbí igi eléso. Lẹ́hìnnáà, bí ẹ ṣe nka àwọn ẹsẹ 1–12 papọ̀, wọ́n lè ṣe àbápín yíyàwòrán wọn nígbàtí a bá mẹ́nuba nkan náà. Àwọn ìbùkún wo ló wá látinú omi nínú ìran yìí? Ẹ ràn àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti rí bí àwọn ìbùkún wọ̀nyí ṣe rí bí àwọn ìbùkún tí Olùgbàlà nfún àwọn tí wọ́n pa májẹ̀mú tẹ́mpìlì mọ́. Fídíò náà, “Odò náà Yíò sì Dàgbà” (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere) lè ṣe ìrànlọ́wọ́.

    3:43

    And the River Will Grow

  • Ẹ tún lè kọ orin kan papọ̀ tí ó ṣe àpèjúwe àwọn ìbùkún, bíi “Awọn Ẹbí Lè Wà Papọ̀ Títíláé” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 188). Kíni orin yìí kọ́ nípa bí Olúwa ṣe nbùkún wa nínú ilé mímọ́ Rẹ̀?

Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .

odò tó nṣàn látinú tẹ́mpìlì Jerúsálẹ́mù

“Kíyèsi i, omi njáde láti abẹ́ àbáwọlé ilé náà. … Gbogbo nkan ni yíò sì máa gbé níbi tí odò náà bá ti wá” (Èsèkíẹ́lì 47:1, 9). Àwòran ìwé-àṣẹ nípasẹ̀ goodsalt.com

Ojú-ewé ìṣe ṣíṣe alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti Bíbélì “kó wa” jọ sọ́dọ̀ Jésù Krístì.