Come, Follow Me
Oṣù kọkànlá 16–22. “Èmi Yíò Fẹ́ Wọn Lọfẹ”: Hosea 1–6; 10–14; Joel


“Oṣù kọkànlá 16–22. ‘Èmi Yíò Fẹ́ Wọn Lọfẹ’: Hóséà 1–6; 10–14; Jóẹ̀lì,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù kọkànlá 16–22. ‘Èmi Yíò Fẹ́ Wọn Lọfẹ,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026

tọkọ-taya àṣẹ̀ṣẹ̀-gbéyàwó ní òde tẹ́mpìlì kan

Oṣù kọ́kànlá 16– 22: “Èmi Yíò Fẹ́ Wọn Lọfẹ”

Hóséà 1– 6; 10–14; Jóẹ̀lì

Májẹ̀mú Ísráẹ́lì pẹ̀lú Olúwa níláti jinlẹ̀ kí ó sì nítumọ̀ pé Olúwa ṣe àfiwé rẹ̀ pẹ̀lú ìgbéyàwó. Májẹ̀mú náà, bíiti ìgbéyàwó, pẹ̀lú ìfarajìn ayérayé, àwọn ìrírí pínpín, gbígbé ìgbé-ayé ga papọ̀, ìṣòótọ́ ìyàsọ́tọ̀, àti, ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìfẹ́ àtọkànwá. Ó bani-nínújẹ́, pé àwọn ọmọ Ísráẹ́lì kò jẹ́ olootọ sí májẹ̀mú wọn. Síbẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn kì í ṣe “Èmi yíò kọ̀ yín títí láé.” Dípò bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ “èmi yíò pè ọ́ padà” (wo Hóséà 2:14–15). “Èmi ó sì fẹ́ ọ fún ara mi ní òdodo,” Ó kéde nípasẹ̀ wòlíì Hóséà (Hóséà 2:19). “Èmi yíò wo ìpadà wọn sàn, Èmi yíò fẹ́ wọn lọfẹ” (Hosea 14:4). Èyí ni ọ̀rọ̀ kannáà tí Ó fún wa loni bí a ṣe nwá láti gbé àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfọkànsìn.

Jóẹ́lì ṣe àbápín irú ọ̀rọ̀ kannáà: “Ẹ yípadà sí Olúwa Ọlọ́run yín: nítorítí ó pọ̀ ní oore ọ̀fẹ́, ó sì kún fún àánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì ṣeun púpọ̀” (Jóẹ̀lì 2:13). Kíka àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì wọ̀nyí lè ṣí yin létí láti jíròrò nípa ìbáṣepọ̀ yín pẹ̀lú Olúwa—láti ronú nípa bí ìṣòtítọ́ Rẹ̀ sí yín ṣe nmísí yín láti jẹ́ olootọ sí I.

Fún àlàyé ṣókí nípa àwọn ìwé Hóséà àti Jóẹ̀lì, wo “Hóséà, tàbí Hóshéà” àti “Jóẹ̀lì” nínú Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ

Hóséà 1–314

Olúwa npè mí nígbàgbogbo láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Ìyàwó Hóséà, Gómérì, jẹ́ aláìṣòótọ́ sí i, Ọlọ́run sì tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ yìí láti kọ́ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì bí ó ti ní ìmọ̀lára nípa wọn àti àwọn májẹ̀mú tí wọ́n bá a ṣe. Bí ẹ ṣe nka Hóséà 1–3, ẹ jíròrò bí Olúwa ṣe nwo ìbáṣepọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ̀. Báwo ni dídá májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa ṣe dà bí wíwọlé sínú ìgbéyàwó? Báwo ni kíkùnà láti pa májẹ̀mú náà mọ́ ṣe dàbí jíjẹ́ aláìṣòótọ́ sí ọkọ tàbí aya? (wo Hóséà 2:5–7, 13). Kí ni Hóséà 2:14–23 kọ́ yín nípa ìfẹ́ àti àánú Olúwa? Báwo ni ẹ ṣe nfi ìfẹ́ àti ìdúróṣinṣin yín hàn Án?

Nínú Hóséà 14, ẹ wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlérí ẹlẹ́wà tí Olúwa ṣe fún àwọn tí ó padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Kíni gbólóhùn náà “fẹ́ wọn lọfẹ” túmọ̀ sí fún yín? (ẹsẹ 4). Kíni àfiwé ohun ọ̀gbìn nínú ẹsẹ 5–8 kọ́ yín nípa àwọn ìbùkún Olúwa, pẹ̀lú àwọn ìbùkún ìrònúpìwàdà? Gẹ́gẹ́bí ara ṣíṣe àṣàrò yín, ẹ yẹ kíkọrin tàbí fítfetísí orin nípa àánú Olùgbàlà, bíi “Wá sọ́dọ̀ Jésù” (Àwọn orin, nọ́mbà 117).

obìnrin oníròbìnújẹ́

Gómérì, ẹni tí ó dúró fún ilé Ísráẹ́lì àti àwọn májẹ̀mú tí wọ́n já, ni Olúwa fi ìràpadà fún. Àpèjúwe nípasẹ̀ Deb Minnard, gbà ìwé àṣẹ láti goodsalt.com

Hóséà 6:4–7; Jóẹ̀lì 2:12–13

Ìfọkànsìn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀lára nínú, kì í ṣe ìtumọ̀ ìta lásán.

Àwọn ènìyàn ìgbà ayé Hóséà nrú ẹbọ ẹranko, ṣùgbọ́n wọ́n nrú àwọn òfin tó ṣe pàtàkì jù lọ. Kíni ẹ rò pé ó túmọ̀ sí pé Olúwa “nfẹ́ àánú, kìí ṣe ẹbọ, àti pé ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ-ẹbọ sísun lọ”? ((Hóséà 6: 6). Kíni ẹ rò pé ó túmọ̀ sí pé kí òdodo dàbí ìkùukùu tàbí bí ìrì? (wo Hóséà 6:4). Báwo ni ó yẹ kí òdodo wá dàbí? (wo Ìsàíàh 48:18; 1 Néfì 2:9–10).

Bákanáà ẹ lè ka Máttéù 9:10–13; 12:1–8 láti ri bi Olùgbàlà ṣe lo Hóséà 6:6 ní àkokò iṣẹ́ ìrànṣẹ́ Rẹ̀. Báwo ni àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe ràn yín lọ́wọ́ láti lóye àwọn ọ̀rọ̀ Hóséà?

Nígbàtí a bá nka Jóẹ̀lì 2:12–13, ó lè ṣèrànwọ́ láti mọ̀ pé yíya tàbí yíya aṣọ ẹni jẹ́ àmì ìta ti ọ̀fọ̀ tàbí ìbànújẹ́. Báwo ni yíya ọkàn wa ṣe yàtọ̀ sí yíya ẹ̀wù wa?

Jóẹ̀lì 2

àmì sẹ́mínárì
“Èmi yíò tú ẹ̀mí mi jáde sí ara ènìyàn gbogbo.”

Àwọn jíjọra wo ni ẹ rí ní àárín ọjọ́ wa àti ọjọ́ tí Jóẹ́lì ti rí tẹ́lẹ̀? (Nípàtàki wo Jóẹ̀lì 2:1–2, 11, 18–32). Kíni ó wọ̀ yín lọ́kàn nípa àwọn ìbùkún ti Olúwa ti ṣe ìlérí nínú ẹsẹ 18–32? Kínidì tí àwọn ìbùkún wọ̀nyí ṣe lè níyelórí nípàtàkì ní oní?

Ó lè dùn mọ́ni láti ka ohun tí Mórónì sọ nípa Jóẹ̀lì 2 nígbàtí ó ṣe àbẹ̀wò sí Joseph Smith ní ọdún 1823 (wo Ìtàn—Joseph Smith 1:41). Báwo ló ṣe rí lára ​​rẹ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nínú Jóẹ̀lì 2:28–32 ti ndi mímúṣẹ ní ọjọ́ wa? (Bákanáà wo Ìṣe Àwọn Àpóstélì 2:1–21). Kíni ẹ rò pé ó túmọ̀ sí pé Olúwa yíò “tú ẹ̀mí [rẹ̀] sí ara ènìyàn gbogbo”? (Jóẹ̀lì 2:28).

Ẹ lè jíròrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti ọwọ́ Ààrẹ Russell M. Nelson: “Ní àwọn ọjọ́ tó nbọ̀, kò ní ṣeé ṣe láti lye nípa ti ẹ̀mí láìsí ìtọ́sọ́nà, ìdarí, ìtùnú, àti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ léraléra” (“Ìfihàn fún Ìjọ, Ìfihàn fún Ìgbésí-ayé Wa,” Làìhónà, Oṣù karun 2018, 96). Kínìdí tí ìfihàn fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ sí yíyè wa ní ti ẹ̀mí?

Kíni ẹ lè ṣe tí ẹ bá lérò pé ẹ kì ngba ìtújáde náà? Níbí ni àwọn àpẹrẹ tí ó lè ṣèrànwọ́. Kíni àwọn ènìyàn inú ìwé mímọ́ wọ̀nyí ṣe láti gba ìtújáde Ẹ̀mí Olúwa?

Bí ẹ ṣe nka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti ọ̀dọ̀ Alàgbà David A. Bednar, ẹ ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí ó túmọ̀ sí fún yín láti ní ìmọ̀lára ìtújáde Ẹ̀mí Mímọ́ nínú ìgbésí-ayé yín ojoojúmọ́:

“A sábà máa nmu ṣòro fún arawa láti gba ìfihàn araẹni. Nípa èyí mo nsọ pé ìlérí májẹ̀mú ni kí a bu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú wa, a lè ní Ẹ̀mí Mímọ́ nígbàgbogbo láti jẹ́ ojúgbà wa léraléra. Ṣùgbọ́n a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àti pé a sì ntọ́jú rẹ̀ bí ẹnipé gbígbọ́ ohùn Olúwa nípasẹ̀ Ẹ̀mí Rẹ̀ jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣọ̀wọ́n. … Ó yẹ kí [Ẹ̀mí] máa wà pẹ̀lú wa nígbàgbogbo. Kìí ṣe gbogbo ìṣẹ́jú-akàn, ṣùgbọ́n bí ẹnìkan lóbìnrin tàbí lọ́kùnrin bá nsa ipá dídárajùlọ—ẹ̀yin kò ní láti jẹ́ pípé— ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin àti èmi bá nsa ipá wa dídárajùlọ̀ tí a kò sì dá ẹ̀ṣẹ̀ líle, nígbànnáà a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ndarí wa. …

“… A dàbí ẹni pé a ngbàgbọ́ pé Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ ìyàlẹ́nú àti nlá àti òjijì, nígbàtí ó jẹ́ jẹ́jẹ́ àti kékeré ní àlékún lórí àkókò” (“Ìbárasọ̀rọ̀ Alàgbà David A. Bednar” [alẹ pẹlu Alaṣẹ Gbogbogbo, Feb. 7, 2020], broadcasts.ChurchofJesusChrist.org).

Bákanáà wo Gary E. Stevenson, “Àwọn Ìṣílétí ti Ẹ̀mí,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2023, 42–45; “Agbègbè Ọ̀tá” (fídíò), Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.

3:38

Enemy Territory

Ẹ dá àyíká ti ẹ̀mí kan sílẹ̀. “Kíni ẹ ti ṣe àkíyèsí tí ó ndásí àyika ti ẹ̀mí fún ìkọ́ni ìhìnrere? Kíni ó jẹ́ ìyọnilẹ́nu kúrò níbẹ̀? … Ẹ ronú nípa àgbékalẹ̀ náà níbi tí ẹ ti máa nkọ́ni jùlọ léraléra [tàbí kẹ́kọ̀ọ́]. Báwo ni ẹ ṣe nní ìmọ̀lára nígbàtí ẹ bá wà níbẹ̀? Báwo ni ẹ ṣe lè pe Ẹ̀mí pẹ̀lú dáadáa láti wà níbẹ̀?” (Ìkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà7).

ìpín àmì àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Hóséà 2:19–20

Mo lè pa àwọn májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú òtítọ́.

  • Nínú ìwé Hóséà, Olúwa fi àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Rẹ̀ wé ìgbéyàwó. Láti kọ́ ẹ̀kọ́ nínú ìfiwéra yìí, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè wo àwòrán aya àti ọkọ kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa bí Baba Ọ̀run ṣe fẹ́ kí ọkọ àti aya máa tọ́jú ara wọn. Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti rí àwọn ọ̀rọ̀ inú Hóséà 2:19–20 tí ó ṣe àpèjúwe ojú tí Olúwa fi nwo wa. Báwo ni a ṣe lè fi hàn Olúwa pé a fẹ́ràn Rẹ̀ àti pé a yíò jẹ́ olootọ sí I?

Hóséà 10:12

“Ó tó àkókò láti wá Olúwa.”

  • Hóséà 10:12 ntọ́ka sí fífúrúgbìn, kíkórè, àkokò, àti òjò láti pè wá láti wá Olúwa. Bi ẹ ṣe nka ẹsẹ yi, àwọn èrò ẹ̀dà wo ni ó wá sí ọkàn tí ó lè mísí àwọn ọmọdé láti wá A? Fún àpẹrẹ, bóyá àwọn ọmọ yín lè ya aago kan kí wọ́n kọ àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè fi wá Olúwa ní àwọn àkokò oríṣiríṣi ní gbogbo ọjọ́. Orin bíi “Nígbàkúgbà, Níbikíbi” (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere) lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti kọ́ pé ó jẹ́ àkokò tí ó dára nígbàgbogbo láti wá Olúwa.

  • Tàbí àwọn ọmọ yín lè ṣe àwọn ìṣe tí ó rọrùn tí ó lọ pẹ̀lú ẹsẹ náà, gẹ́gẹ́bí dídíbọ́n láti fúrúgbìn àwọn èso, sa àwọn ẹ̀fọ́, tàbí dúró nínú òjò. Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe àfiwé fífúrúgbìn àti kíkórè oúnjẹ dídára sí gbígbé nínú òdodo àti gbígba àwọn ìbùkún Olúwa. Lẹ́hìnnáà ẹ lè sọ fún arayín nípa àwọn ìbùkún tí Olúwa ti rọ̀ sórí yín bí ẹ ṣe ti ngbìyànjù láti wá A.

Hóséà 13: 4, 14

Jésù Krístì ni Olùgbàlà àti Olùràpadà mi.

  • Láti tẹnu mọ́ òtítọ́ nínú Hóséà 13:4 pé kò sí Olùgbàlà bí kò ṣe Jésù Krístì, ẹ lè fi àwòrán àwọn ènìyàn bíi mélòó kan hàn àwọn ọmọ yín, pẹ̀lú Jésù. Àwọn ọmọ yín lè máa tọ́ka níkọ̀ọ̀kan sí ẹni tí ó ní agbára láti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ẹ ṣe àbápín ẹ̀rí Jésù Krístì yín àti Ètùtù Rẹ̀.

  • Àwọn ọmọ yín lè wá àwọn ọ̀rọ̀ nínú Hóséà13:4, 14 tí ó ṣe àpèjúwe Jésù Krístì. Kíni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kọ́ wa nípa Rẹ? Ẹ gbèrò ríran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti lo Ìtọ́sọ́nà sí Ìwé Mímọ́ láti wá àwọn ìwé mímọ́ míràn tí ó kọ́ni pé Jésù ni Olùgbàlà àti Olùràpadà wa. Ẹ ṣe àbápín ìmọ̀lára tí ẹ ni nípa Jésù Krístì pẹ̀lú arayín.

ọmọdékùnrin kan ngbàdúrà

Jóẹ̀lì 2:28–29

Ẹ̀mí Mímọ́ lè tọ́ mi sọ́nà.

  • Bóyá ẹ lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye Jóẹ̀lì 2:28–29 nípa jíjẹ́ kí wọ́n da omi kí wọ́n sì fi ìtànṣán si pẹ̀lú rírin omi tàbí ẹ̀tàn. Kí ló lè túmọ̀ sí pé kí a “tú” Ẹ̀mí sórí wa?

  • Bí ẹ ṣe nka Jóẹ́lì 2:28–29 papọ̀, ẹ lè pe àwọn ọmọ yín láti fi orúkọ ara wọn sí ipò gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “àwọn ọmọkùnrin yín” àti “àwọn ọmọbìnrin yín.” Lẹ́hìnnáà, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá àwọn Ìwé Mímọ́ bíi Jòhánnù 14:16; Mórónì 10:5; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 42:17 láti wá bí Ẹ̀mí ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́

Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde ìwé ìròhìn oṣù ti Fríẹ́ndì .

Jésù npe ní ẹnu ọ̀nà kan

Olùgbàlà, láti ọwọ́ Kelly Pugh

Ojú ewé ìṣe ṣíṣe Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Ẹ̀mí Mímọ́ lè tọ́ mi sọ́nà.