“Oṣù Kẹwa 26–Oṣù kọkànlá 1. ‘Èmi Ó Sọ Ọ̀fọ̀ Wọn di Ayọ̀’: Jeremíah 31–33; 36–39; Ẹkún Jeremíàh 1; 3” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹwa 26–Oṣù kọkànlá 1. ‘Èmi Ó Sọ Ọ̀fọ̀ Wọn di Ayọ̀,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Jeremíàh Nsọkùn Ìparun Jérúsálẹ́mù, nípasẹ̀ Rembrandt van Rijn
Oṣù Kẹwa 26–Oṣù kọkànlá 1: “Èmi Ó Sọ Ọ̀fọ̀ Wọn di Ayọ̀”
Jeremíàh 31–33; 36–39; Ẹkún Jeremíàh 1; 3
Nígbàtí Olúwa kọ́kọ́ pe Jeremíàh láti jẹ́ wòlíì, ó sọ fún un pé iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ yíò jẹ́ “láti fà tu, àti láti wó lulẹ̀” (Jeremíàh 1:10)—àti pé ní Jerúsálẹ́mù, ọ̀pọ̀ ìwà ibi wà láti fà tu àti láti wó lulẹ̀. Ṣùgbọ́n èyí jẹ́ ara kan iṣẹ́ ìránṣẹ́ Jeremíàh—a tún pè é “láti kọ́, àti láti gbìn” (Jeremíàh 1:10). Kí ni a lè kọ́ tàbí gbìn sínú ahoro tí a fisílẹ̀ nípa ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ènìyàn májẹ̀mú? Ẹ bèèrè ọ̀nà míràn, nígbàtí ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìpọ́njú ti fi ayé wa sílẹ̀ sínú ìparun, báwo ni a ṣe lè tun kọ́ kí a sì gbìn lẹ́ẹ̀kansi? Ìdáhùn náà wà nínú “Ẹ̀ka òdodo” (Jeremíàh 33:15), Mèsáíàh tí a ṣe ìlérí. Ó mú “májẹ̀mú titun” (Jeremíàh 31:31)—èyí tó béèrè ju ìrísí ìta ìfọkànsìn lọ. Òfin rẹ̀ gbọ́dọ̀ wà “nínú ìhà inú [wa],” tí a kọ̀wé sí “nínú ọkàn [wa].” Èyí ni ohun tí ó túmọ̀ sí fún Olúwa láti “jẹ́ Ọlọ́run [wa]” àti fún wa láti “jẹ́ ènìyàn [Rẹ̀]” (Jeremíàh 31:33). Ó jẹ́ ìlànà ìgbé-ayé, àti pé a yíò ṣì ṣe àwọn àṣìṣe kí a sì ní ìdí láti ṣọ̀fọ̀ láti ìgbà dé ìgbà. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Olúwa ṣe ìlérí, “Èmi ó sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀” (Jeremíàh 31:13).
Fún àlàyé ṣókí nípa Ẹkún Jeremíàh, wo “Ẹkún Jeremíàh, Ìwé ti” nínú ìtọ́sọ́nà sí àwọn Ìwé Mímọ́.
Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ
Jeremíàh 31; 33
Olúwa yìó kó àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ̀ jáde kúrò nínú ìgbèkùn.
Nínú Jeremíàh 31; 33 Jèhófàh jẹ́wọ́ “ẹkún, àti ẹkún kíkorò” (Jeremíàh 31:15) tí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì yíò ní ìrírí nínú ìgbèkùn. Bíótiwùkíórí, òhun tún fúnnni ní àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú àti ìrètí. Ẹ wá wọn bí ẹ ṣe nka àwọn orí wọ̀nyí. Àwọn ìlérí wo ni ẹ rí tí ó wúlò fún yín?
Jeremíàh 31–31; 32:37–42
“Wọn yíò sì máà jẹ́ ẹnìyàn mi, èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn.”
Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ti já májẹ̀mú wọn, Jeremíàh sọ tẹ́lẹ̀ pé yíò Olúwa yíò tún ṣe ìgbékalẹ̀ “májẹ̀mú titun” àti “àìlópin” kan pẹ̀lú wọn (Jeremíàh 31:31; 32:40). Kíni májẹ̀mú náà? Ẹ gbèrò wíwá àwọn ìwòye nínú Ìtọ́sọ́nà sí Ìwé Mímọ́, “Májẹ̀mú Titun ati Àìlópin,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.
Bí ẹ ṣe nka Jeremíàh 31–31; 32:37–42, ẹ jíròrò:
-
Ohun tí ó túmọ̀ sí fún yín láti jẹ́ ara ti àwọn ènìyàn májẹ̀mú Ọlọ́run.
-
Ohun tí ó túmọ̀ sí láti kọ òfin rẹ̀ sí ọkàn yí.
-
Ohun tí Olúwa ṣe ìlérí nígbàtí ẹ bá dá májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀.
-
Báwo ní ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú yín pẹ̀lú Olúwa ṣe nyí yín padà.
Àwọn ìlérí wo ni ẹ ti ṣe fún Ọlọ́run bí ẹ ti nṣe alábàápín nínú àwọn ìlànà mímọ́? Báwo ni Ó ṣe nmú àwọn ìlérí Rẹ̀ ṣẹ fún yín?
Bákannáà wo David A. Bednar, “Ẹ máa Gbé Inú Mi, àti Emi Nínú Yín, Nítorínáà Ẹ Rìn pẹ̀lú Mi,” Làìhónà, Oṣù karun 2023, 123–26.
Jeremíàh 1:36
Àwọn ìwé-mímọ́ ní agbára láti yí mi padà kúrò nínú ibi.
Gẹ́gẹ́bí Jeremíàh 36:2–3, kínìdí tí Olúwa fi pàṣẹ fún Jeremíàh láti kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀? Bí ẹ ṣe nka Jeremíàh 36, ṣàkíyèsí bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe nímọ̀lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí:
-
Olúwa (Wo àwọn ẹsẹ 1–3, 27–31)
-
Jeremíàh (Wo àwọn ẹsẹ 4– 7, 32)
-
Bárúkù (wo àwọn ẹsẹ 4, 8–10, 14–18)
-
Jéhúdì àti Ọba Jéhóíákìm (wo àwọn ẹsẹ 20–26)
-
Elnatánì, Dèláíàh, àti Gemaríàh (wo ẹsẹ 25)
Ẹ jíròrò nípa ìmọ̀lára tí ẹ ní nípa àwọn Ìwé Mímọ́. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín làti yípadà kúrò nínú ibi?
Jeremíàh 37– 39
Ẹ dúró ṣinṣin ní títẹ̀lé àwọn wòlíì Ọlọ́run.
Nínú Jeremíàh 37:1–3, 15–21; 38:1–6, 14–28, ẹ̀rí wo lẹ rí pé Ọba Sedekíà gbà pé Jeremíàh ni wòlíì tòótọ́? Ẹ̀rí wo lẹ rí pé Sedekíà kò gbà gbọ́? Kíni ẹ kọ́ látinú àfiwé yí? Bí ẹ ṣe nka Jeremíàh 39, ẹ jíròrò lórí ìyàtọ̀ tí ìbá ti ṣe bí Sedekíà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ bí wọ́n bá ti tẹ̀lé wòlíì náà tí wọ́n sì pa àwọn òfin Olúwa mọ́. (Ẹ ṣe àfiwé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Sedekíàh pẹ̀lú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ẹbí Léhì nínú 1 Néfì 1–2.)
Jeremíàh 38:6–13; 39:15–18
Èmi lè gbójú kí nsì dúró fún ohun tí ó tọ́.
Àwọn ìjòyè ọba nímọ̀lára pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jeremíàh mú kí àwọn ọmọ ogun wọn má ṣe fẹ́ láti jagun, nítorínáà wọ́n ju Jeremíàh sínú ihò ẹlẹ́gbin (wo Jeremíàh 38:1–4). Nínú Jeremíàh 38:6–13, kí ló wú yín lórí nípa ìfèsì Ebedi-mélékì ará Etiópíà? Ẹ tún ṣe àkíyèsí ìbùkún tí Olúwa fún Ebedi-mélékì nínú Jeremíàh 39:15–18?
Báwo lẹ ṣe lè tẹ̀lé àpẹrẹ Ebedi-mélékì?
Igbe ti Jeremíàh
Ẹkún Jeremíàh 1; 3
Olúwa lè tu ìbànújẹ́ tí mo ní ìrírí nitorí ẹ̀ṣẹ̀ lára.
Ìwé Ẹkún Jeremíàh jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì tí a kọ lẹ́hìn ìparun Jerúsálẹ́mù àti tẹ́mpìlì rẹ̀. Kínìdí tí ẹ fi rò pé ó ṣe pàtàkì pé a tọ́jú wọn? Ẹ yẹ ohun tí àwọn àkàwé inú Ẹkún Jeremíàh 1 àti 3 ràn yín lọ́wọ́ láti ní òye nípa ìbànújẹ́ nlá tí Ísráẹ́lì ní ìmọ̀lára wò. Àwọn ọ̀rọ̀ ìrètí nínú Krístì wo ni ẹ rí? (ní pàtàkì wo Ẹkún Jeremíàh 3:20–33; bákannáà wo Máttéù 5:4; Jákọ́bù 4:8–10; Álmà 36:17–20).
Ààrẹ M. Russell Ballard mẹ́nuba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipò tí ó lè mú kí àwọn kan pàdánù ìrètí, ó sì fúnni ní ìmọ̀ràn nípa ibi tí wọ́n ti lè rí ìrètí:
“Díẹ̀ nínú wa lè rí ìgbé-ayé wa tí o kún fún ìbànújẹ́, ìjákulẹ̀, àti ìkorò. Ọ̀pọ̀ lè ní ìmọ̀lára àìní-ìrànlọ́wọ́ láti kojú ìdàrúdàpọ̀ tó dà bí ẹni pé ó gbilẹ̀ nínú ayé. Àwọn míràn nṣe àníyàn nítorí àwọn ọmọ ẹbí tí wọ́n nkó lọ sísàlẹ̀ nínú ìyára, tó nru sókè nísisìyí ti àwọn iyì àìlera àti òṣùwọ̀n àwọn ìwà ndínkù. … Ọ̀pọ̀lọpọ̀ pàápàá ti fi ara wọn sílẹ̀ láti gba ìwà búburú àti ìwà ìkà ayé bí èyítí kò ní àtúnṣe. Wọn ti sọ ìrètí nù. …
“… Díẹ̀ nínú wa lè ti pàdánù ìrètí gbogbo nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá. Ẹnìkan lè rì bọ́ inú àwọn ọ̀nà ayé débi pé kò rí ọ̀nà àbájáde tí kò sì nírètí mọ́. Ẹ̀bẹ̀ mi íi gbogbo àwọn tí ó ti ṣubú sínú pàkúté ọ̀tá yí ní láti ma juwọ́ sílẹ̀! Láìka bí àwọn nkan àìnírètí ṣe lè dàbí tàbí bí àìnírètí wọ́n ṣe lè dà síbẹ̀síbẹ̀, ẹ jọ̀wọ́ ẹ gbá mí gbọ́, ẹ lè ní ìrètí nígbàgbogbo. Nígbàgbogbo” (“Mímúṣẹ Ayọ̀ ti Ìrètí,” Ẹ́nsáínì, Oṣù kọkànlá 1992, 31–32).
Bákannáà “Wá, Ẹ̀yin Ọlọ́kànàìbalẹ̀,” Àwọn Orin, nọ́mbà 115.
Ẹ ran àwọn elòmíràn lọ́wọ́ láti gba ojúṣe fún ikẹkọ ti arawọn. Nígbà míràn ó dàbí pé ọ̀nà tí ó rọrùn jùlọ láti kọ́ni ni láti sọ fún àwọn akẹkọ ohun tí a rò pé ó yẹ kí wọ́n mọ̀. Bíótiwukíórí, ọ̀nà tí ó rọrùn jùlọ kìí ṣe ọ̀nà tí ó dára jùlọ nígbàgbogbo. Alàgbà David A. Bednar kọ́ni: “Èrò-inú kò yẹ kí ó jẹ́ ‘Kíni kí nsọ fún wọn?’ Dípò bẹ́ẹ̀, àwọn ìbéèrè tó yẹ kí a bi ara wa ni ‘Kí ni mo lè pè wọ́n láti ṣe? Àwọn ìbéèrè onímìísí wo ni mo lè béèrè pé, bí wọ́n bá fẹ́ láti dáhùn, yíò bẹ̀rẹ̀ sí í pe Ẹ̀mí Mímọ́ sínú ìgbé-ayé wọn?’” (ìrọ̀lẹ́ pẹ̀lú Alaṣẹ Gbogbogbo kan, Oṣù kejì 7, 2020, broadcasts.ChurchofJesusChrist.org; bàkannáà wo Ìkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà, 25). Àwọn ọ̀nà púpọ̀ wà láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn akẹkọ láti gba ojúse fún ikẹkọ wọn. Fún àpẹrẹ, nínú ìlànà yìí a pe àwọn akẹkọ láti ṣe àwárí, jíròrò, ṣe àtòkọ, wo àwọn àwòrán, kópa nínú àwọn ohun ẹ̀kọ́, ya àwòrán, kí wọ́n sì ṣe àbàpín kí wọ́n sìlo ohun tí wọ́n kọ́.
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Jeremíàh 31:3
Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì fẹ́ràn mi “pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin.”
-
Bí ẹ ṣe nka Jeremíàh 31:3 pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, wọ́n lè ràn yín lọ́wọ́ láti rí àwọn nkan (tàbí àwòrán àwọn nkan) tí wọ́n máa nlò fún àkokò pípẹ́, irú bí ẹyọ owó irin, àti àwọn míràn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀, irú bí ẹ̀là èso kan. Ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa ohun tí “àìlópin” túmọ̀ sí, kí ẹ sì ṣe àbápín pẹ̀lú ara yín bí ẹ ẹ ti ní ìmọ̀lára “ìfẹ́ àìlópin” ti Baba Ọ̀run. Ẹ tún lè kọ orin kan papọ̀ bíi “Ọlọ́run Nṣe Ìtọ́jú Gbogbo Rẹ̀” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 229).
Jeremíàh 31:31–34; 32:38–41
Ọlọ́run yìó rànmílọ́wọ́ láti pa àwọn májẹ̀mú mi mọ́.
-
Àwọn ọmọ yín lè gbádùn kí wọ́n ya ọkàn sórí bébà kan kí wọ́n sì máa kọ àwọn ohun tí wọ́n kọ́ nínú ọkàn látinú Jeremíàh 31:31–34 nípa dídá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ lè fẹ́ ṣe àtúnyẹ̀wò májẹ̀mú tí wọ́n dá nígbà ìrìbọmi (wo Mòsíàh18:10, 13) kí ẹ sì jíròrò ohun tí ó túmọ̀ sí láti kọ àwọn ìlérí wọ̀nyí sínú ọkàn wọn.
Jeremíàh 36: 1–4
Àwọn ìwé mímọ́ jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
-
Ojú-ewé ṣíṣe ọ̀sẹ̀ yìí lè ran àwọn ọmọ ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Jeremíàh, Bárúkù, àti Ọba (wo Jeremíàh 36). Wọ́n tún lè ṣe àwọn ìṣe tó bá àwọn ọ̀rọ̀ inú Jeremíàh 36:4–10mu, bíi kíkọ sínú ìwé (wo ẹsẹ 4) àti kíka àwọn ìwé mímọ sí àwọn ènìyàn (wo àwọn ẹsẹ 8, 10).
-
Ẹyin àti àwọn ọmọ yín lè wo ìwé àwọn ọmọdé àti ẹ̀dà kan nípa àwọn Ìwé Mímọ́ kí ẹ sì sọọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ìwé wọ̀nyí ṣe yàtọ̀ síra. Kí ló mú kí àwọn Ìwé Mímọ́ jẹ́ àkànṣe? Ó lè jẹ́ ìmísí láti ṣe àbápín àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí ó jẹ́ àkànṣe síi yín.
Jeremíàh 38: 6–13
Mo lè dúró fún ohun tí ó tọ́.
-
Ẹ lè lo àwòrán tó wà ní ìparí ìlànà náà láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti fojú inú wo ìtàn Ebedi-mélékì nínú Jeremíàh 38:6–13. Bóyá ẹ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ẹsẹ kan níbi tí Ebedi-mélékì ti ṣe ohun kan tí ó gbójú láti ran wòlíì Olúwa lọ́wọ́. Kí la lè ṣe láti fi hàn pé a mọ̀ pé wòlíì wa ní òní ni Ọlọ́run pè?
Ẹkún Jeremíàh 1:1–2, 2; 3:22–26
Olùgbàlà mu kó ṣeéṣe fún wa láti rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.
-
Láti ṣe àfihàn Ẹkún Jeremíàh, ẹ lè ṣàlàyé fún àwọn ọmọ yín pé nítorí pé àwọn ọmọ Ísráẹ́lì kò tíì ronúpìwàdà, Jerúsálẹ́mù àti tẹ́mpìlì di píparun. Ẹ lè ṣe àbápín pẹ̀lú arayín bí ẹ ti lè ní ìmọ̀lára tí ẹ bá ngbé níbẹ̀ ní àkókò náà (wo Ẹkún Jeremíàh 1:1–2, 16). Báwo ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ẹkún Jeremíàh 3:22–26 ṣe lè jẹ́ kí ẹ ní ìrètí?
-
Ẹ tún lè sọ fún ara yín nípa àwọn àkokò tí ẹ̀ nbà inú jẹ́ nípa yíyàn búburú kan tí ẹ ṣe. Kíni a rí nínú Ẹkún Jeremíàh 3:22–26 tí ó ràn wá lọ́wọ́ láti ní òye ìdáríjì tí Jésù Krístì fúnni?
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .