Come, Follow Me
Oṣù Kẹwa 19–25. “Kí Èmi Tó Dá Ọ ní Inú Èmi ti Mọ̀ Ọ́”: Jeremíàh 1–3; 7; 16–18; 20


“Oṣù Kẹwa 19–25. ‘Kí Èmi Tó Dá Ọ ní Inú Èmi ti Mọ̀ Ọ́’: Jeremíàh 1–3; 7; 16–18; 20,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Kẹwa 19–25. ‘Kí Èmi Tó Dá Ọ ní Inú Èmi ti Mọ̀ Ọ́,’” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026

Jeremíàh nwo arákùnrin míràn

Jeremíàh, nípasẹ̀ Walter Rane

Oṣù Kẹwa 19–25: “Kí Èmi Tó Dá Ọ ní Inú Èmi ti Mọ̀ Ọ́”

Jeremíàh 1–3; 7; 16–1820

Ní àkọ́kọ́, Jeremíàh kò ròpé òhun lè jẹ́ wòlíì rere “Sá wò ó, èmi kò mọ̀ ọ̀rọ̀ ìsọ,” ó fi ẹ̀hónú hàn (Jeremíàh 1:6). Ṣùgbọ́n Olúwa fi í lọ́kàn balẹ̀ pé, “Èmi fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu” (ẹsẹ 9). Jeremíàh ní ìmọ̀lára pé “ọmọ” (ẹsẹ 6), tí kò ní ìrírí ni òun ṣùgbọ́n Olúwa ṣe àlàyé pé nítòótọ́ òun ti múrasílẹ̀ ju bí ó ti rò lọ—ó ti yàn án sí ìpè yìí àní kí a tó bí i (wo ẹsẹ 5). Nítorínáà Jeremíàh fi ẹ̀rù rẹ̀ sílẹ̀ ó sì gba ìpè náà. Ó kìlọ̀ fún àwọn ọba àti àlùfáà Jerúsálẹ́mù pé ìdíbọ́n jíjẹ́mímọ́ wọn kò ní gbà wọ́n là. “Ọmọ” náà tí ó rò pé òun kò lè sọ̀rọ̀ wá ní ìmọ̀lára ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “nínú ọkàn [rẹ̀] bí iná tí ó njó” kò sì lè dákẹ́ (Jeremíàh 20:9).

Ìtàn Jeremíàh tún jẹ ìtàn yín. Ọlọ́run mọ yín, pàápàá, ṣaájú kí á tó bí yín ó sì pèsè yín sílẹ̀ fún iṣẹ́́ ìránṣẹ́ ryín ní ayé. Lára àwọn ohun míràn, iṣẹ́ ìránṣẹ́ náà pẹ̀lú ohun kan tí Jeremíàh rí tẹ́lẹ̀: kíkó àwọn ènìyàn Ọlọ́run jọ, lọ́kọ̀ọ̀kan, láti “mú [wọn] wá sí Síónì” (Jeremíàh 3:14). Àti pé bí ẹ kò bá tilẹ̀ mọ ohun tó yẹ kí ẹ ṣe tàbí ohun tí ẹ máa sọ, ẹ lè “máṣe bẹ̀rù … ; nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ, ni Olúwa wí” (Jeremíàh 1:8, 19).

Fún àlàyé ṣókí nípa ìwé Jeremíàh, wo “Jeremíàh” nínú Ìwé-ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ

Jeremíàh 1:4–19; 7:1–7; 20:8–9

A pe àwọn wòlíì láti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Jẹ́ ká sọ pé o nbá ọ̀rẹ́ yín kan tí kò tíì gbọ́ nípa àwọn wòlíì rí, tí ẹ sì pinnu láti ṣàlàyé kókó náà nípa lílo ìpè Jeremíàh láti jẹ́ wòlíì nínú Jeremíàh 1:4–19. Kíni ẹ rí nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí tí ó kọ́ni ní nkan kan nípa àwọn wòlíì Ọlọ́run? Ẹ tún lè wo Jeremíàh 7:1–7; 20:8–9 àti orin kan bí “A Nfetí sí Ohùn Wòlíì” (Àwọn orin, nọ́mbà 22).

Ẹ tún lè fẹ láti kọ́ ọ̀rẹ́ yín nípa wòlíì alààyè ti òde òní. Njẹ́ ohunkóhun wà nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí tí ó lè ṣe ìrànlọ́wọ́? Fún àpẹrẹ, kíni àwọn wòlíì ní ọjọ́ wa “ntú jáde” tàbí “fà sílẹ̀”? Kíni wọ́n “nkọ́” àti “gbìn”? (Jeremíàh 1:10). Báwo ni ẹ ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run ló pé wòlíì alààyè wa?

Bákannáà Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ 1:6, 9; “Kínìdí tí a fi ní àwọn wòlíì?” (fídíò), ChurchofJesusChrist.org.

1:37

Why Do We Have Prophets?

Jeremíàh 1:5

àmì sẹ́mínárì
Ọlọ́run mọ̀ mí kí á tó bí mi.

Ṣùgbọ́n kíni Jeremíàh kọ́ nípa ara rẹ̀ ní Jeremíàh 1: 5? Bí wòlíì titun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ pè, kínìdí tí àlàyé náà yíò fi ṣe pàtàkì fún un láti mọ́?

Ọ̀pọ̀ ohun tí Jeremíàh kọ́ nípa ararẹ̀ nínú Jeremíàh 1:5 tún jẹ́ òtítọ́ nípa rẹ. Ọlọ́run tún mọ yín ṣaájú kí á tó bí yín ó sì ti pèsè yín sílẹ̀ fún àwọn ìṣẹ pàtàkì. Láti kọ́ ẹ̀kọ́ síi nípa ìgbésí-ayé yín kí a tó bí yín, ẹ ka Álmà 13:1–4; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138:53–56; àti Ábráhámù 3:22–23. Ẹ lè ṣe àtòkọ àwọn òtítọ́ tí ẹ wárí. Kínìdí tí ìwífúnni yí fi ṣe pàtàkì fún yín láti mọ̀?

Láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa bí àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ṣe kan ìgbésí ayé Alàgbà Ahmad S. Corbitt, ẹ ṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ rẹ̀ “Ẹ Lè Kó Ìsráẹ́lì Jọ!” (Làìhónà, Oṣù karun 2021, 61–63). Báwo ni mímọ̀ nípa ìgbésí-ayé ṣaájú ayé ikú yín ṣe nípa lórí ọ̀nà tí ẹ gbà ngbé ìgbésí-ayé kíkú yín?

Ní ìhín ni ohun tí Ààrẹ Russell M. Nelson sọ nípa ìgbésí-ayé ṣáájú ayé ikú yín:

“Baba yín Ọ̀run ti mọ̀ yín fún ìgbà pípẹ́ gan. Ẹ̀yin, bí ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin Rẹ̀, ni a yàn láti ọwọ́ Rẹ̀ láti wá sí ilẹ̀ ayé ní àkokò yí ní pàtó, láti jẹ́ olùdarí ninu iṣẹ̀ nlá Rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé.” A kò yàn yín fún ìwà ti ara yín ṣùgbọ́n fún àwọn ìhùwàsí ti ẹ̀mí , bí ìgboyà, ìgbójú, òtítọ́ ọkàn, òùngbẹ fún òtítọ́, ebi fún ọgbọ́n, àti ìfẹ́ láti sin àwọn ẹlòmíràn.

“Ẹ ti gbèrú díẹ̀ nínú àwọn ìhùwàsí wọ̀nyí ṣaájú ayé ikú. Àwọn míràn tí ẹ lè mú gbèrú ní ìhín lórí ilẹ̀-ayé bí o ṣe nwa wọn láìyẹsẹ̀” (“Àwọn Ìpinnu Ayérayé,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2013, 107).

Ẹ ronú nípa àwọn ipò kan tí ẹ lè dojúkọ nínú èyí tí yíò ṣe pàtàkì láti rántí àwọn òtítọ́ wọ̀nyí nípa ìṣáájú ayé ikú yín. Kíni ẹ lè ṣe láti rán arayín létí àwọn òtítọ́ wọ̀nyí?

Bákannáà wo Russell M. Nelson, “Àwọn Ìpinnu Ayérayé,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2013, 106–9; Àwọn Àkọlé àti Ìbéèrè, “Ìṣàkóso Ìṣaájú,” “Ìṣaájú Ayé Ikú,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.

ní apá òsì, ẹnìkan tí ó dúró nínú kànga nlá kan tí ó ṣófo; ní ọ̀tún,  ìsọsílẹ̀omi

Jeremíàh 2:13, Olúwa fi ipò ti ẹ̀mí àwọn ènìyàn náà wé “àwọn ìkùdu tí ó fọ́” ó sì fi Ararẹ̀ wé “ìsun omi ìyè.”

Jeremíàh 2; 7

“Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀ orísun omi ìyè.”

Ní ẹkùn ilẹ̀ gbígbẹ tí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ngbé, àwọn ènìyàn máa ntọ́jú omi iyebíye sínú àwọn kòtò ìṣàn omi abẹ́lẹ̀ tí wọ́n npè ní ìkùdu. Kíni ẹ rò pé “àwọn ìkùdu tí ó fọ́” tí a mẹ́nuba ní Jeremíàh 2:13 àwọn ìkùdu tí ó fọ́ ṣe àmì? Kínìdí tí gbígbà omi láti orísun yíò fi sàn ju gbígbẹ́kẹ̀lé ìkùdu lọ? Kíni ó túmọ̀ sí láti pa “ìsun omi ìyè tì”? Bí ẹ ṣe nka Jeremíàh 2 àti 7, ẹ ṣe àkíyèsí bí àwọn ènìyàn náà ṣe npa omi ìyè Olúwa tì (wo, fún àpẹrẹ, Jeremíàh 2:26–28; 7:2–11). Kínìdí tí “omi ìyè” fi jẹ́ àmì dídára fún ohun tí Olùgbàlà fi fún yín? Ẹ ronú nípa bí ẹ ṣe ngba omi ìyè.

Jeremíàh 7 ni a sọ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n nwọnú “ilé Olúwa … láti jọ́sìn Olúwa,” ṣùgbọ́n tí ìṣe wọn kò bá ìfọkànsìn ti ode wọn mu (wo àwọn ẹsẹ 2–11). Àwọn ọ̀rọ̀ wo ní ẹ ní ìmọ̀lára pé Olúwa lè ní fún yín nínú àwọn 21–23?

Ẹ lo àwọn ohun ẹ̀kọ́. Àwọn wòlíì Olúwa sábà máa nfi òtítọ́ ti ẹ̀mí wé àwọn ohun tí wọ́n mọ̀. Ẹ yẹ ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe nkọ́ ẹ̀kọ́ tí ẹ sì nkọ́ni ní ìhìnrere wò. Fún àpẹrẹ, láti fojú inú wo Jeremíàh 2:13, ẹ lè fi omi sínú àpótí sísán tàbí fífọ́ tàbí mu láti inú orísun mímu kan. Báwo ni Jésù ṣe dà bí “orísun omi ìyè”? (Jeremíàh 2:13). Báwo ni a nṣe nmu látinú omi ìyè Rẹ̀?

Jeremíàh 3:14–18; 16:14–21

Olúwa yìó kó àwọn ènìyàn Rẹ̀ jọ.

Nínú Jeremíàh 16:14–15, Jeremíàh fi kíkójọ Ísráẹ́lì ní awọn ọjọ́ ìkẹhìn wé ìjádelọ Ísráẹ́lì láti Egypt. Ní ọ̀rọ̀ tiyín, kínìdí tí kíkójọ náà fi ṣe pàtàkì fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run ju Ìjádelọ náà lọ?

Kíni Jeremíàh 3:14–18; 16:14–21 dá àmọ̀ràn nípa bí ìkójọ náà ṣe nṣẹlẹ̀?

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ “Ìrètí Ísráẹ́lì,” Ààrẹ Russell M. Nelson, bíi Jeremíàh, kọ́ni pé kíkójọ Ísráẹ́lì “jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó nṣẹlẹ̀ ní ayé ní òní” (ìfọkànsìn àwọn ọ̀dọ́ jákèjádò ayé, Ọjọ́ Kẹ́ta Oṣù kẹfà, 2018, Ibi Ìkàwé Ìhìnrere). Ẹ kà tàbí fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí ẹ ri bóyá ẹ lè ṣe àwárí (a) bí Ààrẹ Nelson ṣe túmọ̀ kíkójọ Ísráẹ́lí, (b) bí ó ṣe ṣe àpèjúwe pàtàkì rẹ̀, àti (d) bí ẹ ṣe lè jẹ́ ara kíkójọ náà.

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde àwọn ìwé-ìtòhìn oṣù yí ti Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọmọdé .

ìpín àmì àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Jeremíàh 1:5

Baba Ọ̀run mọ̀ mí ká tó bí mi.

  • Láti ṣe àfihàn òtítọ́ pàtàkì tí a kọ́ ní Jeremíàh 1:5, ẹ lè fi àwòrán ọmọdé hàn àwọn ọmọ yín (tàbí, tí ó bá ṣeéṣe, ẹ lè wo àwọn àwòrán ti àwọn ọmọ yín nígbàtí wọ́n wà ní ìkókó). Ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ yín bóyá wọ́n mọ ibi tí wọ́n gbé ṣaájú kí a tó bí wọn. Ẹ tún lè kọ orin kan papọ̀ tí a nkọ nípa ìṣaájú ayé ikú, bíi “Mo Ngbé ní Ọ̀run” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 4).

  • Bí àwọn ọmọ yín bá fẹ́ kọ́ ẹ̀kọ́ sí i, ẹ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí “Ìṣaájú Ayé Ikú” nínú Ìtọ́sọ́nà sí Ìwé Mímọ́ Wọ́n lè wá ìdáhùn sí “tani,” “nígbàwo,” àti “kíni” àwọn ìbéèrè nípa ìṣáájú ayé ikú.

ọmọbìnrin ndi ọmọ mú

Jeremíàh 1: 4– 19

Àwọn wòlíì ni à pè láti sọ̀rọ̀ Olúwa.

  • Ẹ yẹ ìfihàn àwọn àwòrán wòlíì alààyè tàbí àwọn wòlíì láti inú àwọn ìwé mímọ́ wò (ẹ lè rí díẹ̀ nínú Ìwé Ìròhìn Ìjọ, náà Ìwé Ọnà Ìhìnrere, àti Wá, Tẹ̀lé Mi). Ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ yín ohun tí wọ́n mọ̀ nípa àwọn wòlíì wọ̀nyí.

  • Láti kọ́ni nípa ohun tí àwọn wòlíì nṣe, ẹ lè yan àwọn ẹsẹ ṣíṣèrànwọ́ díẹ̀ láti inú Jeremíàh 1, bíi àwọn ẹsẹ 5, 7, 10, àti 19. Àwọn ọmọ yín lè yan ọ̀kan lára ​​àwọn ẹsẹ náà, kà á, kí wọ́n sì ṣe àbápín ohun kan tí wọ́n kọ́ nípa àwọn wòlíì.

Jeremíàh 16:14–16

Mo lè ran àwọn ọmọ Baba Ọ̀run lọ́wọ́ láti padà wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

  • Nígbàtí ẹ bá nka Jeremíàh 16:16, àwọn ọmọ yín lè ṣe bí ẹni pé wọ́n “npẹja” tàbí “ṣọdẹ” àwọn nkan tó yí yàrá náà ká. Ààrẹ Russell M. Nelson ti fi àwọn apẹja àti ọdẹ nínú ẹsẹ yìí wé àwọn ìránṣẹ́ṣẹ́ ìhìnrere (wo “Kíkójọ Isráẹ́lì Tó Fọ́nká,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2006, 81). Kíni àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere máa nṣe? Báwo ni a ṣe lè ṣèrànwọ́ láti “pẹja” àti láti “ṣọdẹ” fún Ísráẹ́lì fífọ́nká? (wo “Ọ̀rọ̀ Kan fún Àwọn ọmọdé láti ọwọ́ Ààrẹ Russell M. Nelson” [fídíò], ChurchofJesusChrist.org).

    3:30

    Video: A Message for Children from President Russell M. Nelson

Jeremíàh 18: 1– 6

Mo lè jẹ́ kí Olúwa ṣe ìtọ́sọ́nà ìgbésí-ayé mi, bí amọ̀kòkò tó nmọ amọ̀.

  • Láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, ẹ lè sọ̀rọ̀ tàbí ṣe àfihàn bí a ṣe nmọ ìkòkò (wo àwòrán tó wà ní ìparí ìlànà yìí). Ọ̀rọ̀ wo ni Olúwa ní fún wa nínú Jeremíàh 18:1–6? Kíni ó túmọ̀ sí láti jẹ́ amọ̀ ní ọwọ́ Olúwa? (Bákanáà wo Ìsàíàh 64:8). Fún ìtàn míràn tí ó ṣe àfiwé wa sí amọ̀ amọ̀kòkò, wo ọ̀rọ̀ Alàgbà Alàgbà Richard J. Maynes “Ayọ̀ Gbígbé Ìgbé-ayé Oókan-Krístì” (Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2015, 27–30).

Fún púpọ̀ sí i, wo ìtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .

ọwọ́ nmọ ìkòkò níbi kẹ̀kẹ́

“Kíyèsi i, gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ti rí ní ọwọ́ amọ̀kòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Ísráẹ́lì” (Jeremíàh 18:6).

Ojú-ewé ìṣe ṣíṣe alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Mo lè ran àwọn ọmọ Baba Ọ̀run lọ́wọ́ láti padà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.