“Oṣù Kẹwa 5–11. ‘Ó Ti Ru Ìbànújẹ́ Wa , Ó Sì Gbé Ikaanu Wa lọ’: Ìsàíàh 50–57,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹwa 5–11. ‘Ó Ti Ru Ìbànújẹ́ Wa , Ó Sì Gbé Ikaanu Wa lọ,’” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Pípẹ̀gàn Krístì, láti ọwọ́ Carl Heinrich Bloch
“Oṣù Kẹwa 5–11: “Ó Ti Ru Ìbànújẹ́ Wa , Ó Sì Gbé Ikaanu Wa lọ”
Ìsàíàh 50–57
Nínú gbogbo iṣẹ́ ìrànṣẹ́ rẹ̀, Ìsàíàh sọ nípa olùdándè títóbi. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ì bá ti jẹ́ iyebíye fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ní ọ̀pọ̀ sẹ́ntúrì lẹ́hìn náà nígbàtí wọ́n wà nínú ìgbèkùn ní Bábílónì. Ẹnìkan tí o lè ya àwọn odi Bábílónì máa jẹ́ aṣẹ́gun nla nítòótọ́. Ṣùgbọ́n èyí kì í ṣe irú Mèssíàh tí Ìsáíàh ṣe àpèjúwe nínú àwọn orí 52–53: “A kẹ́gàn rẹ̀, a sì kọ̀ ọ́ ní ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn; ẹni ìkáánú, tí ó sì mọ ìbànújẹ́: ó sì dàbí ẹnipé ó mú kí á pa ojú wa mọ́ kúró lára rẹ̀. … Àwa kà á sí ẹni tí a ṣá, tí Ọlọ́run lù ú, tí a sì npọ́n lójú” (Ìsàíàh 53:3–4).
Nípa rírán irú olùdándè àìròtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́, Ọlọ́run kọ́ wa nípa ìdándè tòótọ́. Láti gbà wá là lọ́wọ́ ìnilára àti ìpọ́njú, Ọlọ́run rán Ẹnì náà tí a ni òun Fúnrarẹ̀ “lára, tí a sì … pọ́n lójú.” Níbití àwọn kan ti retí kìnìún, Ó rán ọ̀dọ́-àgùtàn kan (wo Ìsàíàh 53:7). Nítòótọ́, àwọn ọ̀nà Ọlọ́run kìí ṣe ọ̀nà tiwa (wo Ìsàíàh 55:8–9). Jésù Krístì gbà wá láàyè kìí ṣe nípa ṣíṣí túbú níkan ṣùgbọ́n nípa gbígba àyè wa níbẹ̀. Ó yọ wá kúrò nínú àwọn ẹ̀wọ̀n ìbànújẹ́ ti ìkáàánú àti ìkorò wa nípa gbígbé wọn Fúnrarẹ̀ (wo Ìsàíàh 53:4–5, 12). Kò gbà wá là láti ọ̀nà jíjìn. Ó njìyà pẹ̀lú wa, nínú àwọn ìṣe “inúrere àìnípẹ̀kun” ti “kì yíò kúrò lọ́dọ̀ rẹ” (Ìsàíàh 54:8, 10).
Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ
Ìsàíàh 50–52
Ọjọ́ iwájú jẹ́ mímọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn Olúwa.
Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ọmọ Ísráẹ́lì lo ọ̀pọ̀ ọdún nínú ìgbèkùn—àti pé pàápàáa bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbèkùn náà jẹ́ àbájáde àwọn yíyàn tí kò dára tiwọn ṣe fúnra wọn—Olúwa fẹ́ kí wọ́n fojúsọ́nà fún ọjọ́ iwájú pẹ̀lú ìrètí. Kíni ẹ rí nínú ọ̀rọ̀ Ìsàíàh tó fún yín ní ìrètí? Àwòrán kan bí èyí lè ṣe ìrànwọ́ fún yín láti ṣe àṣàrò:
|
Ohun tí mo kọ́ nípa Ọlọ́run (wo, fún àpẹrẹ, Ìsàíàh 50:2, 5–9; 51:3–8, 15–16; 52:3, 9–10) | |
|
Àwọn ọ̀rọ̀ Ìrètí (wo, fún àpẹrẹ, Ìsàíàh 50:9; 51:3–5, 11–12, 22–23; 52:9–10) | |
|
Ohun tí mo lè ṣe láti jẹ́ kí ìrètí di òtítọ́ (wo, fún àpẹrẹ, Ìsàíàh 50:10; 51:1–2, 6–9; 52:1–3, 9–11) |
Bákannáà wo Mòsíàh 12:20–24; 15:13–18; 3 Néfì 20:29–46; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 113:7–10; Russell M. Nelson, “Gba Ọjọ́ Iwájú Mọ́ra pẹ̀lú Ìgbàgbọ́,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2020, 73–76.
Nítorí Ìfẹ́, láti ọwọ́ Angela Johnson
Ẹ ran àwọn akẹkọ lọ̀wọ̀ láti wa sí ọ̀dọ̀ Jésù Krístì. “Kò sí ohun tí ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́bí olùkọ́ tí yíò bùkún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ju ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì kí wọ́n sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Wọn” (Ìkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà, 8). Bí ẹ ṣe nmúrasílẹ̀ láti kọ́ Ìsàíàh 50–57 sí àwọn ẹlòmíràn, ẹ yẹ bí ẹ ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ìsopọ̀ ní àárín àwọn ìpèníjà Ísráẹ́lì, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìsàíàh nípa Krístì, àti rírí ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá gbà pẹ̀lú àwọn ìjàkadì tiwọn wò.
Ìsàíàh 53
Jésù Krístì gba ẹṣẹ àti ìbànújẹ́ mi lè ara Rẹ̀.
Díẹ̀ nínú àwọn orí ìwé mímọ́ ṣe àpèjúwe bí ìṣẹ ìràpadà Jésù Krístì ti jẹ́ ẹlẹ́wà ju Ìsàíàh 53. Ẹ yẹ àwọn ìṣe ṣíṣe bí ìwọ̀nyí wò láti ní òye dáadáa kí ẹ sì mú àwọn ìkọ́ni alágbára wọ̀nyí lò:
-
Ẹ jíròrò tàbí sọ̀rọ̀ bí àwọn ìtàn àti àwọn eré ṣe nfi àwọn akọni tí ó gba àwọn ènìyàn là hàn. Ẹ ṣe ìfiwéra àwọn ìjúwe wọ̀nnì pẹ̀lú àwọn àpèjúwe Olùgbàlà nínú Ìsàíàh 53.
-
Lẹ́hìn kíka ẹsẹ kọ̀ọ̀kan, dáwọ́dúró láti ronú lórí ohun tí Olùgbàlà jìyà—àwọn “ìbànújẹ́,” “àwọn ìkoro,” àti “àwọn ìrékọjá” tí Ó ru—fún gbogbo ènìyàn àti ní pàtàkì fún ẹ̀yin. Ẹ lè rọ́pò àwọn ọ̀rọ̀ bíi “àwa” àti “wa” pẹ̀lú “èmi” àti “mi” bí ẹ ṣe nkàá. Àwọn ìmọ̀lára tàbí àwọn èrò wo ni àwọn ẹsẹ wọ̀nyí mísí inú yín?
-
Ẹ yẹ wíwo fídíò náà “Ìjọba Mi Kìí Ṣe Ti Ayé Yìí wò” (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere), kí ẹ sì jíròrò bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nínú Ìsàíàh 53 ṣe di mímúṣẹ. Kíni díẹ̀ nínú àwọn ìbànújẹ́ àti àwọn ìkorò tí Olùgbàlà nbá yín gbé?
5:25My Kingdom Is Not of This World
-
Ẹ wá àwọn àwòrán ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó yí Ètùtù Jésù Krístì ká (wo Ìwé Ọnà Ìhìnrere, àwọn nọ́mbà 56–60). Lẹ́hìnnáà ẹ lè wá àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ inú Ìsàíàh 53 tó ṣe àpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú àwọn àwòrán náà. Kíni àwọn ìkọ́ni wọ̀nyí mísí yín láti ṣe?
Bákannáà wo “Kíyèsí i Olùràpadà Nlá Kú,” Àwọn orin ìsìn, nọ́mbà 191.
Ìsàíàh 54; 57:15–19
Jésù Krístì fẹ́ kí npadà sí ọ̀dọ̀ Òun.
Gbogbo wa ní àwọn àkókò nígbàtí a bá ní ìmọ̀lára jíjìnà sí Olúwa nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tàbí àìlera wa. Àwọn kan tilẹ̀ ti jáwọ́ nínú ìrètí pé Òun yíò dáríjì wọ́n láé. Ìsàíàh 54 àti 57 jẹ́ àwọn orí nlá láti ka fún ìtúni-dálójú àti ìgbani-níyànjú ní irú àwọn àkokò bẹ́ẹ̀. Ní pàtàkì nínú Ìsàíàh 54:4–10; 57:15–19, àwọn ọ̀rọ̀ wo ló kọ́ yín bí Olùgbàlà ṣe ní ìmọ̀lára nípa yín sí? Kíni ìyàtọ̀ tí ó ṣe nínú ìgbésí ayé yín láti mọ nkan wọ̀nyí nípa Rẹ̀?
Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf kọ́ni:
“Kò jẹ́ nkankan bí ó ti wù kí ó dàbí pé ìgbé-ayé wa ti ṣègbé pátápátá tó. Kò jẹ́ nkankan bí ó ti wù kí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa pupa tó, bí kíkorò wa ṣe jinlẹ̀ tó, tí a dánìkan wà, ti a jẹ́ pípatì, tàbí bí ọkàn wa ṣe lè bàjẹ́ tó. Pàápàá àwọn wọnnì tí wọ́n wà lainí ìrètí, tí wọ́n ngbé nínú asán, tí wọ́n ti dalẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé, ti wọ́n ti ju ìwà òtítọ́ wọn sílẹ̀, tàbí yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run le di títúnṣe. …
“Ìròhìn aláyọ̀ ti ìhìnrere ni èyí: nítorí ètò ìdùnnú ayérayé tí Baba wa Ọ̀run olùfẹ́ni pèsè àti nípasẹ̀ ìrúbọ àìlópin ti Jésù Krístì náà, a kò lè ní ìràpadà nìkan látinú ipò ìṣubú wa kí a sì padàbọ̀sípò sí ìwà mímọ́, ṣùgbọ́n bákannáà a lè kọjá àwọn àfinúrò ti ayé ikú kí a sì di ajogún ìyè ayérayé àti alábápín ògo àìlèjúwe ti Ọlọ́run” (“Yío Gbé Ọ lé Èjìká Rẹ̀ yío sì Gbé Yín lọ Sílé,” Làìhónà, Oṣù karun 2016, 102).
Bákannáà wo Patrick Kearon, “Èrò-Inú Ọlọ́run Ni láti Mú Yín Wá Sílé,” Làìhónà, Oṣù Karun 2024, 87–89.
Ìsàíàh 55:–56
Olúwa pe gbogbo ènìyàn láti “di májẹ̀mú mi mú.”
Láti ìrandíran, a ti dá Ísráẹ́lì mọ̀ gẹ́gẹ́bí ènìyàn májẹ̀mú Ọlọ́run. Bíótiwùkíórí, ètò Ọlọ́run kì í ṣe orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo, nítorí “olúkúlùkù ẹni tí òùngbẹ ngbẹ” ni a pè láti “wá … sí ibi omi náà” (Ìsàíàh 55:1). Fi èyí sọ́kàn bí o ṣe nka Ìsàíàh 55 àti 56, kí ẹ sì nronú jinlẹ̀ lórí ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run. Kíni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìmọ̀lára pé “a ya wọn sọ́tọ̀ pátápátá” kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀? (Ìsàíàh 56:3). Ẹ yẹ fífi àmì sí àwọn ẹsẹ tí ó ṣe apejuwe ìhùwàsí àti ìṣe àwọn wọnnì tí wọ́n “di májẹ̀mú mi mú” (wo Ìsàíàh 56:4–7).
Fún púpọ̀ sí i, wo àwọn àtẹ̀jáde àwọn ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Làìhónà àti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Ìsàíàh 51–52
Olúwa pè mí láti “gbé agbára [mi] wọ̀.”
-
Ó lè jẹ́ ìgbádùn fún àwọn ọmọ yín láti ṣe àwárí àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ bíi “jí,” “dúró,” àti “gbé agbára rẹ wọ̀” nínú Ìsàíàh 51:9, 17; 52:1–2, 9 àti lẹ́hìnnáà ṣe ìṣe lórí àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ wọnnì. Lẹ́hìn ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹ lè sọ ohun tó túmọ̀ sí láti jí, dìde, kí a sì lo agbára nípa tẹ̀mí. Kíni Olúwa béèrè pé kí a ṣe nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí?
-
Àwọn ọmọ yín tún lè ka Ìsàíàh 51:1, 4, 7 kí wọ́n sì mọ ẹni tí Olúwa nsọ̀rọ̀ sí àti ohun tí Ó fẹ́ kí wọ́n ṣe. Kíni ó túmọ̀ sí láti “fetí sí” Olúwa? Báwo ni a ṣe lè i hàn Olúwa pé a “fetí sí” I?
Ìsàíàh 53:3–9
Jésù Krístì gbé ẹṣẹ àti ìbànújẹ́ mi sórí ara Rẹ̀.
-
Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè wo àwọn àwòrán púpọ̀ tí ó nṣe àfihàn ìjìyà àti ikú Jésù Krístì (wo, fún àpẹẹrẹ, Ìwé Ọnà Ìhìnrere, àwọn nọ́mbà 56, 57, 58). (wo, fun apẹẹrẹ, Iwe aworan Ihinrere, no. 56, 57, 58). Bí ẹ ṣe nka Orin Dáfídì 53:3–6, 9 papọ̀ kí ẹ sì wá àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe àpèjúwe ohun tó nṣẹlẹ̀ nínú àwọn àwòrán náà. Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye pé Ìsàíàh ṣe àbápín àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ní ọgọgọ́ọ̀rún ọdún ṣáájú kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀. Kínìdí tí yíò fi jẹ́ pàtàkì fún àwọn ènìyàn làti mọ nkan wọ̀nyí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún síwájú? (wo Álmà 39:15–19).
-
Lẹ́hìn kíkà látinú Ìsàíàh 53:4, “Ó ti ru ìbànújẹ́ wa, ó sì gbé ìkáàánú wa,” àwọn ọmọ yín lè gbìyànjú láti gbé ohun tó wúwo (tàbí dí díbọ́n pé ó gbé ọ̀kan). Ẹ sọ̀rọ̀ nípa bí “ìbànújẹ́” àti “ikaanu” tàbí ìbànújẹ́ ṣe lè wúwo àti líle láti gbé. Kínìdí tí Jésù fi ru “ìbànújẹ́,” “ikaanu,” àti “àwọn àìṣedéédé” tàbí ẹ̀ṣẹ̀ wa? (bákannáà wo Álmà 7:11–12).
Ìsàíàh 55:6
Mo lè wá Olúwa kí nsì ké pè É.
-
Láti kọ́ àwọn ọmọ yín nípa Ìsàíàh 55:6, ẹ lè fi àwòrán Jésù pamọ́ sí ibì kan nínú yàrá náà. Ẹ lè pe àwọn ọmọ yín láti wá àwòrán náà kí ẹ sì sọ ọ̀nà kan tí wọ́n fi lè “wá… Olúwa nígbàtí a lè ri.” Orin kan bíi “Ẹ Tètè Wá Olúwa” (Orin Àwọn Ọmọdé, 108) lè fún wọn ní èrò. Lẹ́hìnnáà ẹ lè jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn ọmọdé fi àwòrán pamọ́ kí ẹ tún ìṣe náà ṣe.
Ìsàíàh 55:8–9
Ọ̀nà Olúwa ga ju tèmi lọ.
-
Lẹ́hìn kíka Ìsàíàh 55:9, ó lè jẹ́ ohun ìgbádùn fún àwọn ọmọ yín láti dúró lórí àpótí kan kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa bí nkan ṣe rí nígbàtí ẹ bá “ga ju.” Tàbí kí wọ́n ya àwòrán ohun tí Ìsàíàh 55:9 túmọ̀ sí fún wọn. Lẹ́hìnnáà ẹ lè sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn ọ̀nà Olúwa tí ó ga ju àwọn ọ̀nà wa lọ. Bí àpẹrẹ, kíni ọ̀nà tí Ó gbà ntọ́jú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀? (wo Máàkù 2:15–17). Báwo ni ọ̀nà Rẹ̀ ṣe ndarí àwọn ẹlòmíràn? (wo Máttéù 20:25–28). Ẹ ṣe àbápín pẹ̀lú àwọn ọmọ yín bí ẹ ti nkọ́ láti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọ̀nà gígajù ti Olúwa àti àwọn èrò.
Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .