“Oṣù Kẹwa 12–18. ‘Olùràpadà Yíò Sì Wá Sí Síón’: Ìsàíàh 58–66,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹwa 12–18. ‘Olùràpadà Yíò Sì Wá Sí Síón,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Jésù nínú Sínágọ́gù ní Násárẹ́tì, láti ọwọ́ Greg Olsen
Oṣù Kẹwa 12–18: “Olùràpadà Yíò Wá Sí Síónì”
Ìsàíàh 58–66
Ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀, Jésù Krístì ṣe ìbẹ̀wò sí sínágọ́gù kan ní Násárẹ́tì, níbi tí wọ́n tí tọ́ Ọ dàgbà. Ó dúró níbẹ̀ láti ka àwọn ìwé mímọ́, ó ṣí ìwé Ìsàíàh, ó sì ka ohun tí a mọ̀ nísisìyí bí Ìsàíàh 61:1–2. Ó sì kéde pé, “Ní òní ni ìwé mímọ́ yí di mímúṣẹ ní etí yín.” Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìkéde títọ́ jùlọ tí Olùgbàlà kéde pé Òun ni Ẹni Àmì Òróró, ẹni tí yíò “mú àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn lára dá” tí yíò sì “wàásù ìtúsílẹ̀ fún àwọn ondè” (wo Lúkù 4:16–21). Ìwé mímọ́ yí ti di mímúṣẹ nítòótọ́ ní ọjọ́ náà. Àti, gẹ́gẹ́bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míràn ti Ìsàíàh, ó tún di mímúṣẹ ní ọjọ́ wa. Olùgbàlà ntẹ̀síwájú láti wo àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn tí wọ́n wá sọ́dọ̀ Rẹ̀ sàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ondè ṣì wà tí wọ́n nílò ìdàndè. Àti pé ọjọ́ iwájú ológo kan wà láti múrasílẹ̀ fún—àkókò tí Olúwa yíò “ṣẹ̀dá ọ̀run titun àti ilẹ̀ ayé titun” (Ìsàíàh 65:17) tí yíò sì “ mú kí òdodo àti ìyìn rú jáde níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè” (Ìsàíàh 61:11). Kíka Ìsàíàh ṣí ojú wa sí ohun tí Olúwa ti ṣe tẹ́lẹ̀, ohun tí O nṣe, àti ohun tí Òun yíò tún ṣe fún àwọn ènìyàn Rẹ̀.
Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ
Ìsàíàh 53:3–12
Àwẹ̀ ngbé agbára ẹ̀mí ga, ó sì nbùkún àwọn ènìyàn tí wọ́n wà nínú àìní.
Kínìdí tí ẹnìkẹ́ni yíò fi àtinúwá lọ láìsí oúnjẹ nígbàtí oúnjẹ bá wà? Bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò Ìsàíàh 58:3–12, ẹ lè ronú nípa àwọn èrèdí yín fún àwẹ̀—àti àwọn èrèdí tí Olúwa fi fúnni ní òfin yìí. Ní ìhín ni àwọn ìbèèrè díẹ̀ kan láti jíròrò:
-
Kínìdí tí a fi rí àwẹ̀ nígbàmíràn bí ẹrù ju ìbùkún lọ? (wo Ìsàíàh 58:3–5). Báwo ni àwọn ẹ̀kọ́ Olúwa nínú orí yìí ṣe yí ojú ìwòye náà padà fún yín?
-
Kíni ó lè túmọ̀ sí láti “tú àwọn ìdè ìwà ibi” àti láti “fọ́ gbogbo àjàgà”? (Ìsàíàh 58:6). Báwo ni àwẹ̀ ṣe lè bùkún àwọn ẹlòmíràn? (wo ẹsẹ 7).
-
Báwo ni àwẹ̀ ṣe ti mú àwọn ìbùkún wá fún yín tí a ṣe àpèjúwe nínú Ìsàíàh 58:8–12?
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ “Njẹ́ Èyí kì í ṣe Àwẹ̀ tí Mo Ti Yàn?” (Làìhónà, Oṣù Karun 2015, 22–25), Ààrẹ Henry B. Eyring ṣe àbápín ọ̀pọ̀ àpẹrẹ bí àwọn ènìyàn ṣe ti jẹ́ alábùkún-fún nípasẹ̀ gbígbàwẹ̀ àti ọrẹ àwẹ̀. Báwo ni ẹ ṣe rí irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀ nínú ìgbésí ayé yín?
Bákannáà wo “Bùkún Àwẹ̀ wa, A Gbàdúrà,” Àwọn orin, nọ́mbà. 138; Àwọn Àkọlé àti Ìbéèrè, “Gbígbàwẹ̀ àti Ọrẹ Àwẹ̀,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.
Mọ àwọn ènìyàn tí ẹ nkọ́. “Jíjẹ́ oníwàbíi Krístì pẹ̀lú mímọ àwọn ènìyàn tí ẹ nkọ́ àti títiraka láti ní òye ohun tí ó wà nínú ọkàn wọn. … Ẹ lè wádìí bí wọ́n ṣe nkọ́ ẹ̀kọ́ dídárajùlọ. Ẹ lè bèèrè àwọn ìbéèrè, fetísílẹ̀ dáradára, kí ẹ sì ṣe àkíyèsí. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ lè gbàdúrà fún oyé tí Ẹ̀mí nìkan lè fúnni. Bí ẹ bá ṣe mọ ènìyàn kan tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ìtumọ̀ ti araẹni àti agbára nínú ìhìnrere ti Jésù Krístì. Ni kété tí ẹ bá ní òye ènìyàn tí o´ npòhùngbẹ, Ẹ̀mí náà lè kọ́ yín bí ẹ ṣe lè ṣe ìrànlọ́wọ́ láti pa á pẹ̀lú omi ìyè Olùgbàlà” (Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà, 13).
Ìsàíàh 53:13–14
Bíbọlá fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi nmú ayọ̀ wá.
Njẹ́ ọjọ́ Sábóátì jẹ́ “adùn” fún yín? Bó ẹ ṣe nṣe àṣàrò Ìsàíàh 58:13–14, ẹ gbèrò nípa bí ẹ ó ṣe túbọ̀ ní ayọ̀ ní ọjọ́ Olúwa. Fún àpẹrẹ, kíni ó lè túmọ̀ sí láti yí kúrò “ní ṣíṣe ìgbádùn rẹ ní ọjọ́ mímọ́ [Rẹ̀]”? Kíni ìyàtọ̀ tó wà ní àárín “dídunnú ara yín nínú Olúwa” àti “ ṣíṣe àwọn ọ̀nà ti yín”?
Bákannáà wo Russell M. Nelson, “Ọjọ́ Ìsinmi Jẹ́ Ìdùnnú,” Làìhónà, Oṣù Karun 2015, 129–32.
Ìsàíàh 59:9–21; 61:1–3; 63:7–9
Jésù Krístì ni Olùgbàlà àti Olùràpadà mi.
Ìsàíàh 58–66 ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtọ́kasí sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ètùtù Jésù Krístì. Ẹ wá wọn bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò. Ní pàtàkì, ṣe àkíyèsí àwọn àkọ́lé àti àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò láti ṣe àpèjúwe Olùgbàlà. Fún àpẹrẹ:
-
Kíni ó wọ̀ yín lọ́kàn nípa àpèjúwe ti “alágbàwí” nínú Ìsàíàh 59:16–21? Báwo ní Olùgbàlà ṣe borí àwọn ipò tí a ṣe àpèjúwe nínú ẹsẹ 9–15?
-
Nígbàtí Jésù Krístì kéde fún àwọn ará Násárétì pé òun ni Mèssíàh, Ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìsàíàh 61:1–3 (wo Lúkù 4:16–21; bákannáà wo fídíò náà “Jésù kéde pé Òun ni Mèssíàh,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere). Báwo ni Jésù Krístì ṣe bùkún ẹ̀yin àti àwọn míràn lọ́nà tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí? Báwo ni Ó ṣe fi ẹwà dípò eérú?
3:24Jesus Declares He Is the Messiah
-
Àwọn “Ìfẹ́ni-Inúrere Olúwa” ṣe ẹ lè “mẹ́nubà”? (wo Ìsàíàh 63:7–9).
-
Àwọn ìtọ́ka sí Olùgbàlà míràn wo ni ẹ rí nínú Ìsàíàh 58–66?
Bákannáà wo Mòsíàh 3:7; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 133:46–53.
Ẹ̀bùn Ìmọ́lẹ̀ Kan, láti ọwọ́ Eva Timothy
Ìsàíàh 60; 62
“Olúwa yíò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ àìnípẹ̀kun fún yín.”
Ìsàíàh 60 àti 62 sọ̀rọ̀ ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn, ojú àti ríran láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa bí ìhìnrere Jésù Krístì yíò ṣe bùkún ayé ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Ẹ wá àwọn èrò wọ̀nyí nínú Ìsàíàh 60:1–5, 19–20; 62:1–2. Bí ẹ ṣe nka àwọn orí wọ̀nyí, ẹ jíròrò bí Ọlọ́run ṣe nkó àwọn ọmọ Rẹ̀ jọ kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀. Kíni ipa yín nínú iṣẹ́ yí?
Bákannáà wo 1 Néfì 22:3–12; 3 Néfìi 18:24; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 14:9; Bonnie H. Cordon, “Kí Wọn Kí Ó Lè Rí,” Làìhónà, Oṣù Karun 2020, 78–80.
Ìsàíàh 64:1–5; 65:17–25; 66
Krístì yíò jọba lórí ilẹ̀ ayé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún.
Ìsàíàh sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ kan nígbàtí “a ó gbàgbé àwọn wàhálà titẹ̀lẹ́” (Ìsàíàh 65:16). Bótilẹ̀jẹ́pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmúṣẹ, ní ìtumọ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀, ọjọ́ náà ṣì nbọ̀—nígbà tí Jésù Kristi yíò padà dé. Ìsàíàh ṣe àpèjúwe ọjọ́ iwájú nínú Ìsàíàh :1–5; 65:17–25; 66. Ẹ ṣe àkíyèsí bí ó ṣe nlo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “ayọ” àti “yíyọ̀” léraléra. Kínìdí tí ìpadàbọ̀ Olùgbàlà yíò jẹ́ ọjọ yíyọ̀ fún yí? Kíni ẹ lè ṣe láti múrasílẹ̀ fún bíbọ̀ Rẹ̀?
Bákannáà wo Nkan Ìgbàgbọ́ 1:10; Russell M. Nelson, “Ọ̀jọ́ iwájú ti Ìjọ: Ìmúrasílẹ̀ Ayé fún Wiwa Lẹ́ẹ̀kejì Olùgbàlà,” Ẹ́nsáìn, Oṣù Kẹ́rin 2020, 13–17.
Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde àwọn ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Làìhónà àti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ àwọn ìwé ìròhìn ti oṣù yìí.
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Ìsàíàh 58:6–11
Àwẹ̀ nbùkún fún mi àti àwọn míràn nínú àìní.
-
Bóyá ọ̀nà tó dára jù lọ láti gba àwọn ọmọ yín níyànjú láti gbàwẹ̀—nígbàtí wọ́n bá ṣetán—ni láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní òye àwọn èrò Olúwa fún òfin yìí. Ẹ yẹ kíka Ìsàíàh 58:6–11 papọ̀ láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: Kínìdí tí a fi ngbàwẹ̀? Báwo ní a ṣe ngbàwẹ̀? Ẹ tún lè wò inú “Àwẹ̀, Gbígbàwẹ̀” nínú Ìtọ́sọ́nà sí Ìwé Mímọ́.
-
Bí ẹ bá ti ní ìrírí tí ó nítumọ̀ pẹ̀lú àwẹ̀, ẹ ṣe àbápín pẹ̀lú àwọn ọmọ yín. Ẹ tún lè bèèrè lọ́wọ́ wọn bí wọ́n yíò ti ṣe àlàyé fún ọ̀rẹ́ kan ìdí tí Olúwa fi fún wa ní òfin yí.
Ìsàíàh 53:13–14
Ọjọ́ Ìsinmi lè jẹ́ adùn sí mi.
-
Lẹ́hìn kíka Ìsàíàh 58:13–14, ẹ lè tọ́ka sí àwọn ọjọ́ ọ̀sẹ̀ nínú kàlẹ́ndà kan kí ẹ sì pe àwọn ọmọ yín láti sọ àwọn ọjọ́ náà pẹ̀lú yín. Nígbàtí ẹ bá dé Ọjọ́ Ìsinmi, ẹ sọ fún wọn pé kí wọn pe ọjọ́ náà ní “adùn kan.” Ẹ sọ fún wọn ìdí tí Ọjọ́ Ìsinmi fi jẹ́ adùn fún yín.
-
Ẹ ṣe àbápín àwọn ọ̀nà míràn tí ẹ lè “ní adùn arayín nínú Olúwa” ní Ọjọ́ Ìsinmi pẹ̀lú ara yín. Bóyá àwọn ọmọ yín lè ya àwọn èrò wọ́n kí wọ́n sì fi wọ́n sínú “àpótí àwọn ìdùnnú Ọjọ́ Ìsinmi” kan. Lẹ́hìnnáà, nígbàtí wọ́n bá nílò àwọn èrò nípa àwọn ohun láti ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi, wọ́n lè fa èrò kan yọ láti inú àpótí.
Ìmọ́lẹ̀ Wa, láti ọ̀dọ̀ Dan Wilson
Ìsàíàh 60:1–3
Olùgbàlà dàbí ìmọ́lẹ̀ fún mi.
-
Ẹ lè pe àwọn ọmọ yín láti pa ojú wọn dé bí ẹ ṣe nka Ìsàíàh 60:1–3. Ẹ sọ fún wọn kí wọ́n la ojú wọn nígbàtí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “ìmọ́lẹ̀” kí wọ́n tún pà wọ́n dé nígbàtí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “òkùnkùn.” Ẹ ṣe àlàyé pé Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ dàbí ìmọ́lẹ̀ tí ó nṣe ìrànwọ́ fún wa láti rí ọ̀nà wa padà sí ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run.
Ìsàíàh 65:17–25
Nígbàtí Jésù bá padà wá, Òun yíò mú àlàfíà àti ayọ̀ wá.
-
Ìsàíàh 65:17–25 nṣe àpèjúwe bí ilẹ̀-ayé yíò ti rí nígbàtí Olùgbàlà bá padà wá. Bí ẹ ṣe nka àwọn ẹsẹ wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wo bí ìgbésí-ayé ṣe máa yàtọ̀ nínú “ilẹ̀ ayé titun” tí Ìsàíàh ṣe àpèjúwe. Kínìdí tí èyí yíò fi jẹ́ àkókò fún “ayọ̀ àti adùn títí láé”? (ẹsẹ 18).
-
Ẹ tún lè kọrin kan papọ̀ nípa Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì “Nígbàtí Olùgbàlà Bá Padà Wá” (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere). Ẹ ṣe àbápín ohun tí ẹ nretí nípa ìpadàbọ̀ Olùgbàlà pẹ̀lú ara yín. Kíni a lè ṣe láti múrasílẹ̀ de ọjọ́ náà?
Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde ìwé ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .