“Oṣù Kẹsan 28–Oṣù kẹ́wàá 4. ‘Ẹ tu Ènìyàn Mi Nínú’: Ísáíàh 40–49,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹsan 28–Oṣù kẹ́wàá 4. ‘Ẹ tu Ènìyàn Mi Nínú,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Wíwo Ọkùnrin Afọ́jú Sàn, láti ọwọ́ Carl Heinrich Bloch, ní Ilé Àkójọ Nkan Frederiksborgnípa Ìwé-ìtàn Orílẹ̀-èdè
Oṣù Kẹsan 28–Oṣù kẹ́wàá 4: “Ẹ tu Ènìyàn Mi Nínú”
Ísáíàh 40–49
“Ìtùnú” ni ọ̀rọ̀ ìkínní ti Ísáíàh orí 40. Ó sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ohùn orin míràn, ìtẹnumọ́ míràn nínú ọ̀rọ̀ wòlíì. Àwọn ìwé tí Ìsàíàh kọ ṣáájú ti kìlọ̀ fún Ísráẹ́lì àti Júdà nípa ìparun àti ìgbèkùn tí yíò dé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àtẹ̀hìnwá wọ̀nyí túmọ̀ sí láti tu àwọn Júù ní 150 ọdún ó lè ní ọjọ́ iwájú—lẹ́hìn tí a pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́mpìlì run tí a sì kó àwọn ènìyàn náà ní ìgbèkùn ní Bábílónì. Bíótiwùkíórí, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ti gbòòrò dé ọjọ́ iwájú ju ti àwọn ọmọ Israeli tí a ṣẹ́gun, tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá. Wọ́n nbá wa sọ̀rọ̀, tí wọ́n tún nní ìmọ̀lára ìjákulẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì, tí wọ́n sì pàdánù pàápàá.
Ọ̀rọ̀ Ìsàíàh sí àwọn ènìyàn rẹ̀ àti sí wa rọrùn: “Má bẹ̀rù” (Ìsàíàh 43:1) Gbogbo rẹ̀ kò sọnu. Olúwa kò gbàgbé yín, àti pé Ó ní agbára lórí àwọn ipò tí ó dàbí ẹnipé kò sí ní ìṣàkóso yín. Njẹ́ kìí ṣe Olúwa, ni ẹni “tí ó dá àwọn Ọ̀run” (Ìsàíàh 42:5), tí ó lágbára ju Bábílónì lọ, ju ẹ̀ṣẹ̀ lọ, ju ohunkóhun tí ó mú yín ní ìgbèkùn lọ? “Padà sọ́dọ̀ mi,” Ó bẹ̀bẹ̀, “nítorí mo ti rà ọ́ padà” (Ìsàíàh 44:22). Ó lè wò mí sàn, múpadàbọ̀sípò, fún lókun, dáríjì, àti tùní-nínú—ohunkóhun tí a nílò rẹ̀, nínú ọ̀ràn tiwa, láti rí ìràpadà.
Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ
Ísáíàh 40–49
Jésù Krístì lè tùmí nínú kí Ó sì fún mi ní i`rètí.
Nígbàtí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì, ó ti lè ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́nu bóyá wọ́n ti pàdánù ipò wọn títíláé gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, a`wọn ènìyàn májẹ̀mú. Bí ẹ ṣe nka Ìsàíàh 40–49, ẹ wá àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ tí ó lè ti pèsè ìtùnú àti ìrètí. Fún ẹsẹ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tí ẹ rí, ẹ jíròrò kí ẹ sì ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí Olúwa lè ti máa wí fún yín nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí. Ní ìhín ni díẹ̀ tí ẹ lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú:
-
40:11, 29–31:
-
41:10–13, 17–18:
-
42:6–7:
-
43:1–7, 25:
-
44:1–4, 21–24:
-
46:3–4:
-
49:7–16:
Kíni ẹ ní ìmọ̀lára pé Olúwa fẹ́ kí ẹ mọ nípa Rẹ̀?
Ẹ ṣe àkíyèsí pé orin “Bí Ìpìlẹ̀ Le” (Àwọn orin ìsìn, nọ́mbà 85) tí a mú jáde láti àwọn ọ̀rọ̀ Ìsàíàh nínú Ìsàíàhh 41:10; 43:2–5; 46:4. Ẹ yẹ kíkọrin tàbí fetísílẹ̀ sí orin ìsìn yìí, ní wíwá ìbámu ní àárín àwọn ọ̀rọ̀ orin àti àwọn ẹsẹ wọ̀nyí láti ọ̀dọ̀ Ìsàíàh. Báwo ni Olúwa ṣe mú àwọn ìlérí tí ó wà nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí ṣẹ nínú ìgbésí-ayé yín?
Bákannáà wo Patrick Kearon, “O ti Jínde Pẹ̀lú Ìwòsàn Ní Ìyẹ́ Apá Rẹ̀: Àwa Lè Ju Àwọn Aṣẹ́gun Lọ,” Làìhónà, Oṣù karun 2022, 37–40.
Ẹ lo afikun Ìwé mímọ. Nígbàmíràn a lè ní òye Májẹ̀mú Láéláé dídára jùlọ tí a bá ṣe àfikún àṣàrò wa pẹ̀lú àwọn ẹsẹ láti inù Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Fún àpẹrẹ, Ìwé ti Mọ́mọ́nì wòlíì Néfì àti Jákọ́bù ní ààyè sí àwọn ìwé Isaiah lórí àwo idẹ (wo 1 Néfì 19:22–23), wọn sì lo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí láti kọ́ni nípa Olùgbàlà. Láti kọ́ bí Néfì àti Jákọ́bù ṣe fi Ìsàíàh 48–49 wé àwọn ènìyàn wọn, wo 1 Néfì 22. Èyí lè ràn yín lọ́wọ́ láti fi àwọn orí wọ̀nyí wé ìgbésí ayé yín.
Nípa ṣíṣe ìgbọràn sí Olúwa, a lè ní “àláfíà … bí odò” (Ìsàíàh 48:18).
Ísáíàh 40–49
“Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi.”
Ní gbogbo Ìsàíàh 40–49 Olúwa sọ̀rọ̀ nípa “ìránṣẹ́” Rẹ̀ àti “ẹlẹ́rìí Rẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lè tọ́ka sí Jésù Krístì (wo Ìsàíàh 42:1–7), sí ilé Ísráẹ́lì (wo Ìsàíàh 45:4), àti sí Ọba Kírúsì, ẹni tí ó gba àwọn Júù láyè láti padà sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n sì tún tẹ́mpìlì kọ́ (wo Ìsàíàh 44:26–28; 45:1–4). Ẹ tún lè yẹ bí àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ náà ṣe wúlò sí yín gẹ́gẹ́bí ìránṣẹ́ àti ẹlẹ́rìí Olúwa wo. Fún àpẹrẹ, ẹ yẹ àwọn ìbéèrè bi ìwọ̀nyí wò:
Ìsàíàh 40:1–3; 9–11; 43:9– 12. Ní ọ̀nà wo ni a jẹ́ ẹlẹ́rìí Jésù Krístì? Kíni “ìhìnrere” tí ẹ lè ṣe àbápín gẹ́gẹ́bí ẹlẹ́rìí Rẹ̀? Ẹ lè ròó pé wọ́n ti pè yín wá síbi ìdúró àwọn ẹlẹ́rìí ní ilé ẹjọ́. Nínú ìgbẹ́jọ́ yìí, a ti fẹ̀sùn kan Jésù Kristi pẹ̀lú gbígbà tí a kọ̀ sílẹ̀ nínú Ìsàíàh 43:11. Ẹ̀rí wo lẹ lè jẹ́ láti fi ti gbígbà Jésù lẹ́hìn? Ẹ̀rí wo nínú ayé yín lẹ lè fi sílẹ̀?
Ìsàíàh 41:8–13; 42:6; 44:21. Kíni Olúwa pè yín láti ṣe? Ẹ yẹ àwọn ìpè ìjọ wò àti àwọn ànfàní míràn láti sìn Ín. Báwo ni Ó ṣe “dá” tàbí múra yín sílẹ̀ láti di ìránṣẹ́ Rẹ̀? Báwo ni Ó ṣe ṣe àtìlẹhìn fún yín bí ẹ ṣe nsìn?
Ìsàíàh 49:1–9 Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni ẹ rí nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí tó lè ṣèrànwọ́ nígbàtí ìtiraka yín àti iṣẹ́ ìsìn bá dàbí “àìsí, àti nínú asán”? (ẹsẹ 4).
Ìsàíàh 40:3–8; 15–23; 42:15– 16; 47:7–11.
Agbára Ọlọ́run tóbi ju agbára ti ayé lọ.
Ìsàíàh rán àwọn ènìyàn rẹ̀ létí léraléra nípa agbára tí kò láfiwé tí Ọlọ́run ní, àní ní ìfiwé sí agbára ayé ìninilára tó yí wọn ká. Ẹ wá ọ̀rọ̀ yí bí ẹ ṣe nka Ìsàíàh 40:3–8, 15–23; 42:15–16; àti 47:7–11 (ẹ kíyèsí pé orí 47 sí ẹni tí ó kó Ísráẹ́lì nígbèkùn, Bábílónì). Kíni àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ yí kọ́ọ yín nípa àwọn nkan ti ayé? Kíni wọ́n kọ́ yín nípa Ọlọ́run? Ẹ jíròrò nípa ìdí tí ọ̀rọ̀ yí fi lè ṣe iyebíye sí àwọn Júù tó wà ní ìgbèkùn. Kínìdí tí o ṣe jẹ́ iyebíye fún yín?
Ìsàíàh 48: 10; 49:13– 16
Olúwa lè tún mi ṣe nínú àwọn ìpọ́njú mi.
Bí ẹ ṣe nka Ìsàíàh 48:10, ẹ jíròrò lórí “ìléru ìpọ́njú ti ara yín.” Báwo ni Olúwa ṣe “ntú yín ṣe”? Báwo ni Ìsàíàh 49:13–16 ṣe nràn yín lọ́wọ́ nígbàtí ẹ bá njìyà ìpọ́njú?
Bákanáà wo “Iná Olùtúnṣe” (fidíò), Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.
The Refiner's Fire
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde àwọn ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọmọdé .
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Ìsàíàh 40:3–5
Mo lè ṣe ìrànwọ́ láti múra “ọ̀nà Olúwa” sílẹ̀.
-
Ẹ ronú nípa àwọn ọ̀nà kan láti ṣe àkàwé ohun tí ó lè túmọ̀ sí láti “múra … ọ̀nà Olúwa sílẹ̀,” gẹ́gẹ́bí a ti ṣe àpèjúwe rẹ̀ nínú Ìsàíàh 40:3–5. Fún àpẹrẹ, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè tún ohun kan tí ó wọ́ ṣe, pa ilẹ̀ dídọ̀tí mọ́, tàbí ṣe ọ̀nà kedere ní ilẹ̀ àpáta. Ẹ tún lè fi àwọn àwòrán Jòhánnù Onítẹ̀bọmi àti Joseph Smith hàn (wo Ìwé Ọnà Ìhìnrere, àwọn nọ́mbà 35, 87). Báwo ni wọ́n ṣe nmúra ọ̀nà sílẹ̀ fún bíbọ̀ Olúwa? (wo Lúkù 3:2–18; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 135:3). Báwo ni a ṣe lè ṣe ìrànlọ́wọ́? Èyí lè jẹ́ ànfàní láti sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn tó di Oyè Àlùfáà Árónì ṣe nṣe ìrànlọ́wọ́ láti múra ọ̀nà Olúwa sílẹ̀ (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 84:26–28).
Ìsàíàh 43:10
Èmi lè jẹ́ ẹlẹri ti Olúwa
-
Lẹ́hìn kíka Ìsàíàh 43:10 papọ̀, ẹ lè sọ nípa ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́rìí. Ẹ ṣe àbápín pẹ̀lú ara yín nípa àwọn ohun tí ẹ ti ní ìrírí pé ẹ lè jẹ́ “ẹlẹri” ti—fún àpẹrẹ, oúnjẹ tí ẹ ti tọ́wò, ibi tí ẹ ti ṣe àbẹ̀wò sí, tàbí ẹni tí ẹ mọ̀. Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ ẹlẹ́rìí Olúwa? Kíni a lè sọ fún àwọn ènìyàn míràn nípa Rẹ̀?
Ìsàíàh 44:3–4; 45:8
Olúwa yíò “tú” ìbùkún Rẹ̀ lé mi lórí.
-
Lẹ́hìn kíka àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, àwọn ọmọ yín lè bomi rin ọ̀gbìn kan kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún tí Olúwa ti tú lé wọn lórí. Kíni yìó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀gbìn nígbàtí a bá bu omi si? Báwo ni àwọn ìbùkún Olúwa ṣe nràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà?
Òdodo “wa [lè] dàbí ìgbì òkun” (Ìsàíàh 48:18).
Ìsàíàh 53:3–5
Pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ nmú àláfíà wá.
-
Àwọn àwòrán tàbí fídíò odò àti ìgbì òkun lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti fojú inú wo Ìsàíàh 48:18 (gẹ́gẹ́bí àwọn àwòrán tó wà nínú ìlànà yìí). Àwọn ọmọ yín lè gbádùn gbígbé ọ́wọ àti apá wọn bíi odò àti ìgbì omi òkun. Báwo ni àláfíà ṣe lè dà bí odò? Báwo ni òdodo ṣe lè dàbí ìgbì? Ẹ sọ̀rọ̀ nípa bí pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ṣe ti ràn yín lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára àláfíà bí odò tàbí tí ó lágbára bí ìgbì.
-
Ẹ kọ orin kan papọ̀ nípa àwọn òfin, bií “Pa Àwọn Òfin Mọ” (Ìwé Orin Àwọn ọmọde, 146–47). Kíni orin yí kọ́ wa nípa ìdí tó fi yẹ ká pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́?
Ìsàíàh 49:14–16
Olúwa kò ní gbàgbé mi láé.
-
Ìsàíàh 49:14–16 lè jẹ́ ìtùnú nlá fún àwọn ọmọ yín fún ọ̀pọ̀ ọdún tó nbọ̀. Bí ẹ ṣe nka ẹsẹ 14, ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó lè mú kí àwọn ènìyàn ní ìmọ̀lára ìgbàgbé tàbí kíkọ̀sílẹ̀. Báwo ni a ṣe nmọ̀ pé Olúwa kò gbàgbé wa?
-
Láti ṣe àfihàn àwọn ẹsẹ 15–16, ẹ lè bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ yín nípa ẹnìkan tí wọn kì yíò gbàgbé láé, bíi ọmọ ẹbí tàbí ọ̀rẹ́. Gẹ́gẹ́bí Ìsàíàh 49:15–16, kínìdí tí Olúwa kò fi lè gbàgbé wa láé? Lẹ́hìnáà ẹ lè ṣe àbápín ìmọ̀lára tí ẹ ni nípa Jésù Krístì pẹ̀lú ara yín.
Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .