“Oṣù Kẹsan 21–27. ‘Iṣẹ́ Ìyanu àti Àjèjì’: Ìsàíàh 13–14; 22; 24–30; 35,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹsan 21–27. ‘Iṣẹ́ Ìyanu àti Àjèjì,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026
Igbó Ṣúúrú Mímọ́, láti ọwọ́ Brent Borup
Oṣù Kẹsan 21–27: “Iṣẹ́ Ìyanu àti Àjèjì”
Ìsàíàh 13–14; 22; 24–30; 35
Ohun kan tí Olúwa wí fún àwọn wòlíì láti ṣe ní láti kìlọ̀ nípa àwọn àbájáde ti ẹ̀ṣẹ̀. Fún àwọn wòlíì Májẹ̀mú Láéláé, èyí nfì ìgbàgbogbo túmọ̀ sí sísọ fún àwọn alákóso ìjọba alágbára pé wọ́n nílò láti ronúpìwàdà. Iṣẹ́ tí ó léwu ni, ṣùgbọ́n Ìsàíàh kò bẹ̀rù, àwọn ìkìlọ̀ rẹ̀ sí àwọn ìjọba ọjọ́ rẹ̀—pẹ̀lú Ísráẹ́lì, Juda, àti àwọn orílẹ̀-èdè àyíká—ní ìgboyà (wo Ìsàíàh 13–23).
Bí ó ti wù kí ó rí, Ìsàíàh pẹ̀lú ní ọ̀rọ̀ ìrètí kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìparun tí a sọtẹ́lẹ̀ náà dé sórí àwọn ìjọba wọ̀nyí, Ìsàíàh ti fojúsọ́nà tẹ́lẹ̀ fún ìmúpadàbọ̀sípò àti àtúnṣe. Olúwa yíò pe àwọn ènìyàn Rẹ̀ láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Òun yíò sọ “ilẹ̀ gbígbẹ … di adágún omi, ilẹ̀ tí òùngbẹ ngbẹ di orísun omi” (Ìsàíàh 35:7). Òun ó ṣe “iṣẹ́ ìyani-lẹnu àti ìyanu kan” (Ìsàíàh 29:14), ní mímú àwọn ìbùkún tó ti ṣèlérí fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì padàbọ̀sípò. Kìí ṣe Ìsàíàh tàbí ẹnikẹ́ni míràn tó wà láàyè ní ìgbà náà ló gbé ayé láti rí iṣẹ́ ìyani-lẹ́nu yìí. Ṣùgbọ́n a nrí í ní òní. Ní tòótọ́, gbogbo wa sì jẹ́ ara rẹ̀.
Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ
Ìsàíàh 13:1–11; 19–22; 14:1– 20
Ìgbéraga àti ohun ayé yíò kùnà.
Nínú ọ̀rọ̀ Ìsàíàh, Bábílónì jẹ́ ìjọba alágbara pẹ̀lú aláàkóso alágbára. Báyìí Bábílónì jẹ́ ìwé-ìtàn àtijọ́. Nítorínáà kínìdí tí ọ̀rọ̀ sí Bábílónì, nínú Ìsàíàh 13–14, ṣe pàtàkì sí wa ní òní? Nítorí pé Bábílónì ṣe àpẹrẹ ìgbéraga, ìwọra, àti ẹ̀ṣẹ̀, àwọn nkan tó yí wa ká ní òní. Ẹ ronú nípa ṣíṣe àpẹrẹ yí bí ẹ ṣe nka Ìsàíàh 13:1–11, 19–22; 14:1–20. Ẹ lẹ̀ yẹ àwọn ìbéèrè bi wọ̀nyí wò:
-
Irú àfiwé wo lẹ rí ní àárín ìgbéraga ọba Bábílónì àti ìgbéraga Sátánì? (wo Ìsàíàh 14:4–20; Mósè 4:1–4). Àwọn ìkìlọ̀ wo ni ẹ rí fúnra yín nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí?
-
Báwo ni Olùgbàlà ṣe pèsè “ìsinmi kúrò nínú ìbànújẹ́ yín, àti kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù yín”? (Ìsàíàh 14:3).
“Yíò gbé ikú mì nínú ìṣẹ́gun” (Ìsàíàh 25:8).
Ìsàíàh 22:22–23; 24:21–23; 25:6–8; 26:19; 28:16
Jésù Krístì ni Mèssíàh tí a ṣe ìlérí.
Àwọn ìkọ́ni Ìsàíàh máa ntọ́ka sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà léraléra, pẹ̀lú ẹbọ ètùtù Rẹ̀, Àjínde, àti Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì. Àwọn ara iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ wo ló wá sí ọkàn yín bí ẹ ṣe nka àwọn ẹsẹ wọ̀nyí: Isaiah 22:22–23; 24:21–23; 25:6–8; 26:19; 28:16? Àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ míràn wo ni ó nrán yín létí nípa Olùgbàlà?
Fún àwọn akẹkọ ni ànfàní láti jẹri nípa Jésù Krístì. “Láti jẹ́ olùkọ́ni ìhìnrere Jésù Krístì túmọ̀ sí láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní òye àti láti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Rẹ̀, agbára ìràpadà, àti ìfẹ́ pípé” (Ìkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà, 8). Ọ̀nà kan tí ó rọrùn láti ṣe èyí ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá nkọ́ni ni láti bèèrè ìbéèrè bíi “Kíni ẹ rí nínú àwọn ìwé mímọ́ ní ọ̀sẹ̀ yí tí ó kọ́ yín ní ohunkan nípa Olùgbàlà?” Lẹ́hìnnáà, ẹ jẹ́ kí àwọn akẹkọ ṣe àbápín àwọn ìrírí wọn kí wọ́n sì fún ìgbàgbọ́ ara wọn lókun.
Ìsàíàh 24:1–12; 28:1–8; 29:7–13; 30:8–14
Yíyípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa nmú ewu ti ẹ̀mí wa.
Nínú àánú Rẹ̀, Olúwa rán Ìsàíàh láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn májẹ̀mú tí wọ́n ti ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀. Ẹ wo bóyá ẹ lè rí àwọn àmì ìkìlọ̀ ti ẹ̀mí ti èyí nínú Ìsàíàh 24:5; 29:13; 30:8–12. Kínìdí tí ìwà àti ìṣe wọ̀nyí fi léwu nípa ti ẹ̀mí?
Láti kìlọ̀ nípa àbájáde yíyípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa, Ìsàíàh lo àwọn àfiwé mánigbàgbé kan. Bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò wọn, ẹ bi ara yín léèrè bí yíyípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa ṣe dà bíi:
-
Ìbànújẹ́, ayé òfo (Ìsàíàh 24:1–12).
-
Ìmutípara (Ìsàíàh 28:7–8).
-
Ebi ati òùngbẹ (Ìsàíàh 29:7–10).
-
Ògiri fífọ́ tàbí ohun-èlò (Isaiah 30:13–14).
Kínìdí tì ó fi ṣe pàtàkì fún yín láti dúró ní sísún mọ́ Olúwa?
Ìsàíàh 29; 30:18–26; 35
Olúwa lè dá ohun tí ó sọnù tàbí tí ó bàjẹ́ padàbọ̀sípò.
Njẹ́ ẹ ti pàdánù nkan tí ẹ rò pé ẹ̀yin kò lè rí mọ́? Tàbí bóyá ohun kan fọ́, tí ẹ sì dààmú pé kò ṣeé túnṣe rara. Nígbàtí a bá yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa, Sátánì nfẹ́ kí a ronú pé a kò lé padà tàbí kí á gba ìmú láradá. Bíótiwùkíórí, Ìsàíàh ṣe àwọn àpèjúwe kan lára àwọn ohun ìyanilẹ́nu tí Olúwa yíò ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Kíni ẹ kọ́ látinú Ìsàíàh 29:13–24; 30:18–26; 35 nípa Olúwa, ìfẹ́ Rẹ̀, àti agbára Rẹ̀? Bóyá ẹ lè wa gbolohun ọ̀rọ̀ kan nínú àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí ó nfún yín ní ìrètí nígbàtí ẹ nílò ìwòsàn. Ẹ tún lè wo inú ọ̀rọ̀ Arábìnrin Amy A. Wright “Krístì Wo Èyí Tí Ó Bàjẹ́ Sàn” (Làìhónà, Oṣù karun 2022, 81–84).
Ọ̀nà kan tí Olúwa gbà nfi agbára àti àánú Rẹ̀ hàn nípasẹ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Rẹ̀. Ìsàíàh 29 ní onírurú àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ tí ó ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò nínú. Fún àpẹrẹ:
-
Ṣe àfiwé Ìsàíàh 29:11–12 pẹ̀lú 2 Néfì 27:6–26 àti Ìtàn—Joseph Smith 1:63–65.
-
Ẹ ṣe àfiwé Isaiah 29:13–14 pẹ̀lú Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 4 àti Ìwé-ìtàn—Joseph Smith 1:17–19.
-
Ẹ ṣe àfiwé Isaiah 29:18–24 pẹ̀lú ojú-ewé àkọlé Ìwé ti Mọ́mọ́nì.
Ní èrò yín, kínìdí tí “ìyanu” àti “ìyanilẹ́nu” (Ìsàíàh 29:14) àwọn ọ̀rọ̀ dídára láti ṣe àpèjúwe Olúwa tí ó nmú ìhìnrere Rẹ̀ padàbọ̀sípò? Báwo ẹ ṣe lè ṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìmúpadàbọ̀sípò náà ṣẹ? Fún àwọn èrò, wo inú ọ̀rọ̀ Alàgbà Gerrit W. Gong “Gbogbo Orílẹ̀ èdè Àwọn Ìbátan àti Ahọ́n” (Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2020, 38–41).
Bákannáà wo “Ìmúpadàbọ̀sípò Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhinrere Jésù Krísti: Ìkéde Igba Ọdún Kan Sí Àgbáyé” (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere); “Òwúrọ̀ ṣí,” Àwọn Orin, nọ́mbà 1.
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde àwọn ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọmọdé .
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Ìsàíàh 14:3; 25:8–9; 28:16
Jésù Krístì lè gbàmí là kúrò nínú Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ikú.
-
Báwo ní ẹ yíò ṣe ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti rí Olùgbàlà nínú àwọn ìwé Ìsàíàh? Ẹ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ tó máa nrán wọn létí Rẹ̀ nínú Ìsàíàhh 14:3; 25:8; or 28:16. Wọ́n tún lè bá àwọn ẹsẹ Ìsáíàh wọ̀nyí dọ́gba pẹ̀lú àwọn ẹsẹ míràn tí o´ nkọ́ni nípa Olùgbàlà, bíi Máttéù 11:28–30; 1 Kọ́ríntì 15:53–57; Hẹ́lámánì 5:12. Àwọn ohun nlá wo ni Olúwa ti ṣe fún wa?
-
Lẹ́hìn kíka Ìsàíàh 25:8–9 ẹ lè wo àwọn àworan Olùgbàlà ní Gẹ́tsémánì, lórí àgbélèbú, àti lẹ́hìn Àjínde Rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín sọ̀rọ̀ nípa ohun tó nṣẹlẹ̀ nínú àwọn àwòrán àti ìdí tí wọ́n fi fẹ́ràn Jésù tí wọ́n sì “nyọ̀ nínú ìgbàlà rẹ̀” (ẹsẹ 9).
-
Ẹ lè yàn láti sọ fún àwọn ọmọ yín nípa ìbànújẹ́ tí ẹ ní nígbàtí ẹnìkan tí ẹ ẹ́ràn bá kú. Ẹ jẹri ìtùnú tí ẹ gbà nítorí Jésù Krístì. Bóyá àwọn ọmọ yín lè ya ojú tó nsunkún kí ẹ sì nu omijé náà kúrò bí ẹ ṣe nka Ìsàíàh 25:8 papọ̀.
Ìfẹ́ Tìrẹ Ni Kí a Ṣe, láti ọwọ́ Ken Spencer
Ìsàíàh 25:4–6
Jésù fún mi ní “ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì.”
-
Njẹ́ ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín ti ní ìrírí ìbùkún ti ibi ààbò ní àkókò ìjì tàbí ibojì ní ọjọ́ ooru tí ó gbóná bí? Tàbí ẹ ti gbádùn oúnjẹ tó dára nígbàtí ebi npa yín? Ẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìrírí wọ̀nyí bí ẹ ṣe nka Isaiah 25:4–6. Báwo ni Jésù ṣe nrí irú àwọn ohun wọ̀nyí?
Ìsàíàh 29:11–18, 24
Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere jẹ́ “iṣẹ́ ìyanu.”
-
Bí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín ṣe nka Ìsàíàh 29:14, ẹ ṣe àbápín àwọn ọ̀rọ̀ míràn tí ó túmọ̀ sí irúkannáà pẹ̀lú ara yín “ìyanu” àti “ìyanilẹ́nu.” Ẹ jẹ́ kí wọ́n ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti wá àwọn nkan tàbí àwọn àwòrán tí ó rọ́pò àwọn kan nínú àwọn iṣẹ̀ ìyanu Olúwa ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Ìwọ̀nyí lè ní ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan, àwòrán tẹ́mpìlì kan, tàbí àwòrán Ìran Àkọ́kọ́ (ọ̀kan wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìlàkalẹ̀ yìí). Lẹ́hìnnáà àwọn ọmọ yín lè yan ohun kan kí wọ́n sì sọ ìdí tó fi jẹ́ ìyanu fún wọn.
-
Orin kan nípa Ìmúpadàbọ̀sípò Ìhìnrere lè lọ dáradára pẹ̀lú Ìsàíàh 29, bíi “Ní Àkókò Ìrúwé Wúrà kan” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 88). Ó sì lè jẹ́ pé ìrírí araẹni lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti ní òye ohun tí ìmúpadàbọ̀sípò túmọ̀ sí. Fún àpẹrẹ, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tí ẹ pàdánù àti bí ẹ ṣe rí i. Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti fi èyí wé Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere. Gẹ́gẹ́bí Ìsàíàh 29:13–15, kínìdí tí a fi nílò Ìmúpadàbọ̀sípò náà? Àwọn iṣẹ́ ìyanu wo ni Olúwa nṣe láti mú ìhìnrere Rẹ̀ padàbọ̀sípò? (wo ojú-ìwé ìṣe ṣiṣe ti ọsẹ yii).
Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde iwé-ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .