Come, Follow Me
Oṣù kẹ́jọ 31–Oṣù Kẹsan 6. “Jẹ́ kí Ohun Gbogbo Tí ó Ní Ẹ̀mí Yin Olúwa”: 102–103; 110; 116–119; 127–128; 135–139; 146–150


“Oṣù kẹ́jọ 31–Oṣù Kẹsan 6. ‘Jẹ́kí Ohun Gbogbo Tí ó Ní Ẹ̀mí Yin Olúwa’”: Orin Dáfídì 102–103; 119; 127–128; 135; 146,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù kẹ́jọ 31–Oṣù Kẹsan 6. ‘Jẹ́kí Ohun Gbogbo Tí ó Ní Ẹ̀mí Yin Olúwa,’” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026

Jésù Krístì nàwọ láti ran obìnrin kan lọ̀wọ̀

Ìpadàbọ̀ Ọ̀wọ̀, láti ọwọ́ Kelsy and Jesse Lightweave

Oṣù kẹ́jọ 31–Oṣù Kẹsan 6: “Jẹ́ kí Ohun Gbogbo Tí ó Ní Ẹ̀mí Yin Olúwa”

Orin Dáfídì 102–103; 110; 116–119; 127–128; 135–139; 146–150

Orúkọ àṣà àwọn Júù fún ìwé Orin Dáfídì ni Tehillim, ọ̀rọ̀ Hébérù kan tó túmọ̀ sí “ìyìn.” Ó ní í ṣe pẹ̀lú ìkéde hallelujah (tí ó túmọ̀ sí “yìn Jèhófà” tàbí “yìn Olúwa”). Bí ẹ bá ní láti yan ọ̀rọ̀ kan láti ṣe àkópọ̀ ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ Orin Dáfídì, ìyìn yíò jẹ́ yíyàn dídára. Àwọn orin Dáfídì kan ní ìfipè tààrà láti “yìn Olúwa” (ní pàtàkì wo Orin Dáfídì 146–50), gbogbo wọn sì lè fi ìmísí sínú ìjọsìn àti ìyìn. Orin Dáfídì pè wá láti jẹ́wọ́ agbára Olúwa, àánú Rẹ̀, àti àwọn ohun nlá tí Ó ti ṣe. A kò lè san án padà fún Un fún eyikeyi lára èyí, ṣùgbọ́n a lè yìn Ín. Ìyìn náà lè gba oríṣiríṣi ọ̀nà fún onírurú àwọn ènìyàn—ó lè kan kíkọrin, gbígbàdúrà, tàbí jíjẹ́rìí. Nígbàgbogbo o ndarí sí ìfarajì sí Olúwa àti láti títẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Rẹ̀. Ohunkóhun ti “ẹ yin Olúwa” bá túmọ̀ sí nínú ìgbésí-ayé yín, ẹ lè rí ìmísí làti ṣe bí ẹ ṣe nkàá tí ẹ sì njíròrò àwọn Orin Dáfídì.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ

Orin Dáfídì 102–3116

Olúwa lè tùmí nínú nínú ìjìyà mi.

Ẹ ṣe àkíyèsí bí Orin Dáfídì 102:1–11 ti ṣe àpèjúwe ìmọ̀lára àníyàn àti ìdààmú tí ó sábà máa nwá ní àkókò ìpèníjà. Bóyá ẹ̀yin tàbí àwọn míràn tí ẹ mọ̀ ti ní irú àwọn ìmọ̀lára ìrírí náà. Bí ẹ ṣe nka Orin Dáfídì 102:12–28; 103116, ẹ wa àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó fún yín ní ìgboyà láti “pe orúkọ Olúwa” nínú àwọn ìdánwò yín (Orin Dáfídì 116:13). E lè fẹ́ sàmìsí, ṣe àkọ́sórí, tàbí ṣe àbápín pẹ̀lú àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ míràn tí ó nfún yín ní ìrètí nínú Rẹ̀.

Bákanáà wo Ìsàíàh 25:8; Hébérù 2:17–18; Álmà 7:11–13; Camille N. Johnson, “Jésù Ni Ìtura,” Làìhónà, Oṣù karun 2023, 81–83; “Níbo Ni Mo Lè Yípadà fún Àláfíà?” (Àwọn Orin, nọ́mbà 129).

Jésù nran ọkùnrin aláìsàn afọ́jú kan lọ́wọ́.

Carl Heinrich Bloch (1834-1890), Krístì Nwo Aláìsàn Ní Bethesda Sàn, 1883, epo lórí kánfásì, 100 3/4 × 125 1/2 inches. Ilé Ọnọ̀ ti Unifásítì Brigham Young, tí a rà pẹ̀lú àwọn owó tí Jack R. àti Mary Lois Wheatley pèsè ní, 2001.

Orin Dáfídì 110; 118

Jésù Krístì mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Orin Dáfídì ṣẹ.

Orin Dáfídì pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tọ́ka sí ìgbésí-ayé àti iṣẹ́ ìrànṣẹ́ Jésù Krístì. Ní ìhín ni àwọn àpẹrẹ díẹ̀:

  • Orin Dáfídì 110:1–4 (wo Máttéù 22:41–45; Hébérù 5:4–10; 6:20)

  • Orin Dáfídì 118:22 (wo Máttéù 21:42; Ìṣe àwọn Àpóstélì 4:10–11; 1 Pétérù 2:7)

  • Orin Dáfídì 118:25–26 (wo Máttéù 21:9)

Kíni àwọn ẹsẹ yìí kọ́ yín nípa Jésù Krístì? Kínìdí tí ó ṣe pàtàkì láti mọ èyí nípa Rẹ̀?

Orin Dáfídì 119

àmì sẹ́mínárì
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yíò pa mí mọ́ ní ọ̀nà Rẹ̀.

Psalm 119 ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe àfiwé ìgbésíayé wa sí ìrìn-àjò padà sí Baba Ọ̀run nínú. Bí ẹ ṣe nka ìwé náà, ẹ wá àwọn ọ̀rọ̀ bíi “rìn,” “ipa ọ̀nà,” “ọ̀nà,” “ẹsẹ̀,” àti “ṣáko lọ.” Ẹ jíròrò nípa ìrìn-àjò ìgbésí-ayé tiyín—ibi tí ẹ ti dé, ibi tí ẹ wà báyìí, àti ibi tí ẹ nlọ. Kíni ẹ kọ́ nínú orin Dáfídì yí nípa ìrìnàjò yín padà sílé? Kíni ẹ ti kọ́ nípa wíwo àwọn ipa-ọ̀nà àwọn elòmíràn? Gẹ́gẹ́bí orin Dáfídì yí ṣe sọ, kíni Ọlọ́run pèsè láti ràn yín lọ́wọ́ láti dúró ní ipa ọ̀nà Rẹ̀?

Ẹ ronú nípa àkókò kan nígbàtí títọ ipa-ọ̀nà kan tàbí máàpù kan ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti rin ìrìn-àjò lọ sí ibìkan pẹ̀lú àṣeyọrí. Kíni ìrírí náà kọ́ yín nípa títẹ̀lé ipa-ọ̀nà Ọlọ́run?

Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé-mímọ́ míràn, Olúwa àti àwọn wòlíì Rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà kan. Ní ìsàlẹ̀ ni àwọn àpẹrẹ díẹ̀. Gbèro wíwá àwọn ẹsẹ wọ̀nyí kí ẹ kọ́ sílẹ̀ tàbí ṣe àbápín pẹ̀lú àwọn míràn ohun tí ẹ kọ.

Ìwé mímọ́

Ohun tí mo kọ́ nípa ipa-ọ̀nà sí Ọlọ́run

Ìwé mímọ́

Òwe 4:11–19

Ìwé mímọ́

Máttéù 7:13–14

Ìwé mímọ́

1 Néfì 8:20–28

Ìwé mímọ́

2 Néfì 31:17–21

Ìwé mímọ́

Álmà 7:9, 19– 20

Ìwé mímọ́

Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 25:2

Báwo ni àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ṣe lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti dúró ní ipa-ọ̀nà Ọlọ́run?

Àwọn àfikún ìwòye wo ni ẹ le kọ́ látinú ìmọ̀ràn wọ̀nyí láti ọ̀dọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson?

“Bí ìrìn-àjò wa nínú ayé bá ní láti jẹ́ àṣeyọrí, a nílò láti tẹ̀lé dídarí àtọ̀runwá. Olúwa wípé, Wò mí nínú gbogbo èrò; ẹ má ṣe iyèméjì, ẹ má bẹ̀rù’ [Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:36]. Onísáàmù náà sì kọ̀wé pé, ‘Ọ̀rọ̀ Rẹ ni fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa-ọ̀nà mi’ [Orin Dáfídì 119:105]. …

“Ní ìrìn-àjò yín nínú ayé, ẹ ó pàdé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìdènà ẹ sì nṣe àwọn àṣìṣe. Ìtọ́sọ́nà Ìwé-mímọ́ nràn yín lọ́wọ́ láti ṣe ìdámọ̀ àṣìṣe àti láti ṣe àtúnṣe tí o ṣeéṣe. Ẹ dúró ní lílọ sí ọ̀nà tí kò tọ. Ẹ farabalẹ̀ ṣe àṣàrò máàpù ojú-ọ̀nà Ìwé Mímọ́. Lẹ́hìnnáà ẹ tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìrònúpìwàdà àti ìsanpadà tí a nílò láti wà ní ‘ipa-ọ̀nà híhá ati tóóró tí ndarí wá lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun’ [2 Néfì 31:18]” (“Gbígbé nípasẹ̀ Ìtọ́sọ́nà Ìwé-Mímọ́,” Ẹ́nsáìn, Oṣù kọkànlá 2000, 17).

Bákanáà wo Dieter F. Uchtdorf, “Ọmọ Oninakuna àti Ọ̀nà Tó Darí Sílé,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2023, 86–88.

Orin Dáfídì 134–36

Olúwa ní agbára ju òrìṣà gbogbo lọ.

Ẹ ṣe àkíyèsí ìdí, gẹ́gẹ́ bíi Orin Dáfídì 135:15–18, ó jẹ́ ìwà òmùgọ̀ láti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọlọ́run èké. Kíni ó lè jẹ́ kí ẹ fi ọkàn tán èyí tí ó jọ òrìṣà? Ẹ lè ṣe àtòkọ ti àwọn ohun ti Olúwa lè ṣe, gẹ́gẹ́ bí àwọn oníwàásù ti ṣe ní Orin Dáfídì 134–36. Kíni àwọn ohun alágbára tí Ó ti ṣe fún yín?

Orin Dáfídì 139

Olúwa mọ ọkàn mi.

Kíni ẹ rí nínú Orin Dáfídì 139 tó nràn yín lọ́wọ́ láti ní òye pé Olúwa mọ̀ nípa yín—èrò àti ìṣe, àwọn agbára àti àìlera yín? Báwo ní òtítọ yi ṣe ní ipa lórí ìgbésí-ayé yín àti àwọn yíyàn yín?

Orin Dáfídì 146–50

“Ẹ yin Olúwa.”

Bí ẹ ṣe nka àwọn orin Dáfídì ìkẹhìn ti ìyìn wọ̀nyí, ẹ ronú nípa àwọn èrèdí tí ẹ ní láti yin Olúwa. Kínìdí tí ó fi ṣe pàtàkì láti yìn Ín? Àwọn ọ̀nà wo ni ẹ lè gbà yìn Ín?

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde àwọn ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Làìhónà àti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ̀ .

ìpín àmì àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Orin Dáfídì 102:1–2

Olúwa tùmí nínú Ó sì fún mi ní ìrètí.

  • Ẹ̀yin tàbí ọ̀kan lára ​​àwọn ọmọ yín lè ka Orin Dáfídì 102:1–2, ní wíwò bí Olúwa ṣe ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro wa. Báwo ni a ṣe lè rí irànlọwọ́ Rẹ̀? Ẹ tún lè ṣe àbápín fún ara yín ìgbà tí ẹ nílò ìrànlọ́wọ́ tí ẹ sì nímọ̀lára pé Ọlọ́run ngbọ́ àdúrà yín.

Orin Dáfídì 119:105

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dàbí ìmọ́lẹ̀ kan

  • Àwọn ọmọ yín lè gbádùn sísọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó jọ láti wà nínú òkùnkùn. Tàbí kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ṣòro láti ṣe nínú òkùnkùn. Ẹ lè pè wọ́n láti ṣe nkan pẹ̀lú ojú wọn ní pípadé, gẹ́gẹ́bí yíya àwòrán kan. Kíni a kọ́ láti Orin Dáfídì 119:105 nípa ìmọ́lẹ̀ àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

  • Ẹ wá ohun kan tí Baba Ọ̀run ti fún wa láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti dúró ní ipa-ọ̀nà Rẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí: Orin Dáfídì 119:47–48; 119:105; 1 Néfì 11:25; 2 Néfì 31:20 Kíni a lè ṣe láti dúró ní ipa-ọ̀nà Ọlọ́run?

  • Àwọn ọmọ yín lè gbádùn wíwo àwòrán àwọn ohun tí a mẹ́nubà nínú Orin Dáfídì 119:105. Wọ́n lè fi àwọn àwòrán náà lélẹ̀ ní títò bí wọ́n ṣe nka ẹsẹ náà. Ẹ tún lè kọ orin kan tó báramu, bíi “Kọ́ Mi Láti Rìn Nínú Ìmọ́lẹ̀” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 177) tàbí “Èmi Yíò Rìn Pẹ̀lú Jésù” (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere).

baba nkàwé fún ọmọ

Orin Dáfídì 139:1– 3, 23–24

Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì mọ̀ mí wọ́n sì fẹ́ràn mi.

  • Ẹ gbèrò ṣíṣe àwọn àtòkọ kúkurú ti àwọn nkan tí ẹ mọ̀ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ yín. Bí ẹ ṣe nka àwọn àtòkọ náà ní ẹ̀ẹ̀kan, ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ láti ṣe àròsọ ẹnití o nṣe àpèjúwe. Lẹ́hìnnáà, lẹ́hìn kíka Orin Dáfídì 139:1–3 papọ̀, ẹ lè to àwọn ohun tí Baba Ọ̀run àti Jésù mọ̀ nípa wa.

  • Ẹ kọ àwọn ọ̀rọ̀ Orin Dáfídì 139:23–24 sórí ẹ̀là ìwé tàbí pákó kan. Ẹ pè àwọn ọmọ yín láti fàlà sí abẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe àpèjúwe àwọn ohun tí Ọlọ́run lè ṣe fún wa. Kínìdí tí a fi fẹ́ kí Ọlọ́run ṣe àwọn nkan wọ̀nyí?

Orin Dáfídì 146: 1, 5–9

Mo lè yin Olúwa.

  • Bóyá àwọn ọmọ yín lè ṣe àbàpín àwọn ìrírí ìgbàtí ẹnìkan yìn wọ́n tàbí sọ fún wọn pé wọ́n ṣe iṣẹ́ tí ó dára. Ẹ ṣe àbápín díẹ̀ nínu àwọn ohun rere látinú Orin Dáfídì 146:6–9 tí Olúwa ti ṣe (ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀ tí kò yé wọn). Ẹ pè àwọn ọmọ yín láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn nkan míràn tí Ó ṣe fún wa. Báwo ni a ṣe lè yìn Ín fún àwọn nkan wọnni?

Ẹ kọ́ ẹkọ nílé; ẹ ṣe àbápín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé ilé gbọ́dọ̀ jẹ́ “oókan ẹ̀kọ́ ihinrere” (“Dída Àwòkọ́ṣe Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn,” Làìhónà, Oṣù kọ́kànlá 2018, 13). Kíni ẹ lè ṣe ní ọ̀sẹ̀ yí láti mú kí ṣíṣe àṣàrò Orin Dáfídì araẹni tàbí ẹbí yín jinlẹ̀ sí i? Lẹ́hìn ṣíṣe àṣàrò yín, ẹ ronú nípa ṣíṣe àbápín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ohun tí ẹ kọ́ àti ohun tí ẹ ní ìmọ̀lára. Ẹ lè ṣe èyí nínú ìbárasọ̀rọ̀, nípasẹ àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí ìbákẹ́gbẹ́ àwùjọ, tàbí ní ìjọ.

Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Ọ̀rẹ́ .