“Oṣù Kẹsan 14–20. ‘Ọlọ́run Ni Ìgbàlà’: Ìsàíàh 1–12,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹsan 14–20. ‘Ọlọ́run Ni Ìgbàlà Mi,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Wòlíì Ísáíàh Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìbí Kristi, nípasẹ̀ Harry Anderson
Oṣù Kẹsan 14–20: “Ọlọ́run Ni Ìgbàlà mi”
Ísáíàh 1–12
Pàápàá bí èyí bá jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ẹ nka ìwé Ìsàíàh, ẹ lè rí àwọn àyọkà tí ó jẹ́ mímọ̀ dáadáa. Èyí nítorí pé, nínú gbogbo àwọn wòlíì Májẹ̀mú Láéláé, Ìsàíàh ní ẹnití a máá nse àyọsọ rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà nínú àwọn ìwé mímọ́ míràn, àti nípasẹ̀ Olùgbàlà Fúnrarẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ Ìsàíàh tún farahàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú àwọn orin ìsìn àti àwọn orin mímọ́ míràn.
Kínìdí tí Ísáíàh fi nṣe àyọsọ ọ̀rọ̀ léraléra? Dájúdájú èrèdí kan ni pé Ìsàíàh ní ẹ̀bùn fún fífi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run han ní gbangba, èdè mánigbàgbé. Ṣùgbọ́n ó ju bẹ́ẹ̀ lọ. Ìsàíàh ti mísí àwọn wòlíì fún ìrandíran nítorí àwọn òtítọ́ tí ó kọ́ni kọjá ìran tirẹ̀ (ní àárín 740 àti 701 BC). Ó kọ̀wé nípa iṣẹ́ ìràpadà nlá Ọlọ́run, tí ó tóbi púpọ̀ ju orílẹ̀-èdè kan tàbí sáà àkokò kan lọ. Láti ọ̀dọ̀ Ìsàíàh, Néfì kẹkọ pé òun àti àwọn ènìyàn òun, bíótilẹ̀jẹ́ pé wọ́n yapa kúrò nínú ìyókù Ísráẹ́lì, ṣì jẹ́ ara àwọn ènìyàn májẹ̀mú Ọlọ́run. Nínú Ìsàíàh, àwọn olùkọ̀wé Májẹ̀mú Titun rí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèssíàh tó di mímúṣẹ ní ojú wọn gan-an. Àti pé nínú Ìsàíàh, Joseph Smith rí ìmísí fún iṣẹ́ ọjọ́-ìkẹhìn ti kíkójọ Ísráẹ́lì àti gbígbé Síónì ga. Nígbàtí ẹ ba ka ìsàíàh, kíni ẹ̀yin yíò rí?
Fún àlàyé ṣókí nípa ìwé Orin Dáfídì, wo “Ìsàíàh” nínú Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́. Fún ìwífúnni nípa àkókò tí Ìsàíàh gbé, wo 2 Àwọn Ọba 15–20 àti 2 Króníkà 26–32.
Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ
Ísáíàh 1–12
Àwọn ọ̀rọ̀ Ìsàíàh yíò di múmúṣẹ.
Olùgbàlà kọ́ni pé “gbogbo ohun tí [Ìsàíàh] sọ ti jẹ́, yíò sì rí, àní gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ (3 Néfì 23:3). Bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò ìwé Ìsàíàh, gẹ yẹ ṣíṣe àtẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan tí ó ní àwọn àkọlé bí ìwọ̀nyí: Ọjọ́ Ìsàíàh, Iṣẹ́ ìrànṣẹ́ Ayé ikú Olùgbàlà, àti Àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Ẹ ṣe àkíyèsí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ìsàíàh ló ní ìmúṣẹ lọ́nà tó ju ẹyọ kan lọ (wo Ìtumọ̀ Ìwé mímọ́, “Ìsàíàh”).
Ààrẹ Oaks kọ́ni: “Ìwé Ìsàíàh pẹ̀lú àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí ó dà bíi pé ó ní ọ̀pọ̀ ìmúṣẹ. Ó dà bíi pé ẹnìkan ní íṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìgbà ayé Ìsàíàh tàbí àwọn nkan tó ṣẹlẹ̀ sí ìran tó kàn. Ìtumọ̀ míràn, tí ó nṣe àpẹẹrẹ nígbàkugbà, dà bí ẹni pé ó ntọ́ka sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní agbedeméjì àkókò, nígbàtí a pa Jerúsálẹ́mù run tí àwọn ènìyàn rẹ̀ sì fọ́nká lẹ́hìn tí wọ́n kàn Ọmọ Ọlọ́run mọ́ àgbélèbú. Síbẹ̀ ìtumọ̀ míràn tàbí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ kannáà dà bíi pé ó ní ìbámu sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wà ní Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olùgbàlà. Òtítọ́ náà pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí lè ní ìtumọ̀ púpọ̀ ntẹnumọ́ jíjẹ́pàtàkì wíwá ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ láti ràn wá lọ́wọ́ láti túmọ̀ wọn” (“Kíka Ìwé mímọ́ àti Ìfihàn,” Ẹ́nsáìn, Oṣù Kínní 1995, 8).
Òye Ìsàíàh. Olùgbàlà sọ pé, “Ẹ ṣe ìwákiri àwọn ohun wọ̀nyí pẹ̀lú aápọn; nítorípé àwọn ọ̀rọ̀ Ìsàíàh tóbi” (3 Néfì 23:1; bákanáà ẹsẹ 2–3). Síbẹ̀ lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀, Ìsàíàh lè ṣòro láti ní òyé. Àwọn èrò wọ̀nyí lè ṣèrànlọ́wọ́:
-
Ẹ jíròrò nípa àwọn àpẹrẹ àti àkàwé tí Ìsàíàh lò.
-
Ẹ bi ara yín léèrè pé, “Kíni mò nkọ́ nípa Jésù Krístì?” (wo 1 Néfì 19:23).
-
Ẹ wá àwọn àkọlé tí ẹ lérò pé ó wúlò fún àkókò wa.
-
Ẹ lo àwọn ìrànlọ́wọ́ áṣárò, gẹ́gẹ́bí ìwé-ìtumọ̀, àwọn àkọsílẹ̀ ìsàlẹ̀, àwọn àkọ́lé orí, àti Ìtọ́sọ́nà sí Ìwé mímọ́.
Ìsàíàh 1; 3–5
Àwọn wòlíì kìlọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ àti ìlérí ìrètí nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà.
Gẹ́gẹ́bí àwọn wòlíì gbogbo ìgbà, Ìsàíàh máa nkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà nípa ipò ti ẹ̀mí wọn. Bí ẹ ṣe nka Ìsàíàh 1; 3; 5, wá àwọn gbólóhùn tí ó ṣe àpèjúwe bí àwọn ènìyàn náà ṣe nṣe nípa ti ẹ̀mí (wo, fún àpẹrẹ, Ìsàíàh 1:2–4, 21–23; 3:9, 16–17; 5:11–12, 20–23). Àwọn ìṣòro irúkannáà wo lẹ rí ní àkókò wa? Ẹ tún lè wá àwọn ẹsẹ tó kìlọ̀ nípa àwọn àbájáde ipò ti ẹ̀mí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì (bíi Ìsàíàh 1:7; 3:17–26; 5:5–7, 13–15).
Ní àfikún sí àwọn ìkìlọ̀, Ìsàíàh fúnni ní àwọn ọ̀rọ̀ ìrètí fún ìràpadà nípasẹ̀ Olùgbàlà (wo, fún àpẹrẹ, Ìsàíàh 1:16–19, 25–27; 3:10; 4). Kíni ẹ kọ́ nípa Olúwa látinú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí? Báwo ni ọ̀rọ̀ Olúwa nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí ṣe yàtọ̀ sí ohun tí Sátánì fẹ́ ká gbàgbọ́?
Bíi ti Ìsàíàh, àwọn wòlíì ní òní kìlọ̀ fún wa nípa ẹ̀ṣẹ̀ àti àbájáde rẹ̀, wọ́n sì npèsè àwọn ọ̀rọ̀ ìrètí nípasẹ̀ Jésù Kristi. Àwọn àpẹrẹ wo ni ẹ lè ronú nípa rẹ̀? Ẹ lè fẹ́ láti ṣe àtúnyẹ̀wò ọ̀rọ̀ kan látinú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tí ó kọjá, ní wíwá irú àwọn ìkìlọ̀ àti àwọn ìlérí bẹ́ẹ̀.
Ìsàíàh 2; 4; 11–12
Ọlọ́run yíò ṣe iṣe nlá ní àwọn ọjọ́-ìkẹhìn.
Ọpọ̀lọpọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìsàíàh ní ìtumọ̀ pàtó fún ọjọ́ wa. Láti wá wọn, ẹ wá àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe ọjọ́ iwájú (bíi “yíò jẹ́” tàbí “yíò lọ”). Fún àpẹrẹ, ẹ wá àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe wọ̀nyí bí ẹ ṣe nka Ìsàíàh 2; 4; 11–12. Pàápàá ẹ lè gbìyànjú láti rọ́pò wọn pẹ̀lú àwọn ọrọ-iṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ (bíi sí tàbí ó nlọ). Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo ló mísí yín nípàtàkì? Kíni ẹ kọ́ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí nípa Síónì, kíkọ́ tẹ́mpìlì, àti kíkójọ Ísráẹ́lì?
Ìsàíàh 2:2–3 nípàtàkì ṣe kókó fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ṣe ndi mímúṣẹ? Kíni ẹ kọ́ nípa àwọn “ọ̀nà Olúwa” àti “àwọn ipa-ọ̀nà” nínú ilé Rẹ̀? (ẹsẹ 3).
Bákannáà wo Ìsàíàh 5:26; “Lórí Òkè Ténté,” Àwọn orin, nọ́mbà 5.
Ìsàíàh 61:6.
Àwọn wòlíì ni a pè láti ọwọ́ Ọlọ́run.
Nínú Ìsàíàh 6, Ìsàíàh ṣe àtúnsọ ìpè rẹ̀ láti jẹ́ wòlíì. Bí ẹ ṣe nka orí yìí, kí ló wú yín lórí nípa ìrírí Ìsàíàh? Báwo ni orí yi ṣe ní ipa lórí ọ̀nà tí ẹ fi nronú nípa Olúwa, àwọn wòlíì Rẹ̀, àti iṣẹ́ tí a pè wọ́n láti ṣe?
“Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fún wa” (Isaiah 9:6).
Ísáíàh 7–9
Ọlọ́run ṣe ìlérí láti rán Jésù Krístì láti jẹ́ Olùgbàlà mi.
Ní ìgbà iṣẹ́ ìrànṣẹ́ Isaiah, Ísráẹ́lì dá àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Síríà láti dá ààbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ Ásíríà. Ísráẹ́lì àti Síríà fẹ́ fi agbára mú Áhásì ọba Júdà láti darapọ̀ mọ́ wọn. Ṣùgbọ́n Ìsàíàh sọ tẹ́lẹ̀ pé àjọ náà yíò kùnà ó sì gba Áhásì ní ìmọ̀ràn láti gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa (Ìsàíàh 7:7–9; 8:12–13).
Nígbàtí Ìsàíàh ngba Áhásì ní ìmọ̀ràn, ó sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn ènìyàn mọ̀ dáadáa, bí irú èyí tí a rí nínú Ìsàíàh 7:14; 8:13–14; 9:2, 6–7. Ohun èyíówù kí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí fún Áhásì, wọ́n wúlò sí Jésù Krístì ní kedere (bákannáà Máttéù 1:21–23; 4:16; 21:44; Lúkù 1:31–33). Kínìdí tí “Ìmmánuẹ́lì” jẹ́ àkọ́lé rere fún Olùgbàlà? (wo Máttéù 1:23). Báwo ni Ó ṣe jẹ́ “Olùdámọ̀ràn” tàbí “Ọmọ-Aládé Àláfíà” fún yín? (Ìsàíàh 9:7). Kíni ohun míràn tí ẹ kọ́ nípa Olùgbàlà láti àwọn ẹsẹ wọ̀nyí?
Fún púpọ̀ sí i, wo àwọn àtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Làìhónà àti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Ìsàíàh 1:2–4, 16:19
Nítorí Jésù Krístì, mo lè ronùpìwàdà ki nsì di mímọ́.
-
Nínú Ìsàíàh 1:2–4, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè rí àwọn èrèdí tí inú Olúwa kò fi dùn sí àwọn ènìyàn náà. Ẹ ṣe àkíyèsí ìfiwéra pẹ̀lú àwọn ẹranko ní ẹsẹ 3—tani “olùkọ́ni wa”? Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a mọ̀ Ọ́?
-
Láti fi ojú inú wò Ìsàíàh 1:16–18, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yìn lè wo ohun pupa kan dídán àti ohun funfun kan àìlábàwọ́n. Tàbí bóyá ẹ lè ṣiṣẹ́ pàpọ́ láti wẹ ohunkan. Báwo ni a ṣe lè di aláìmọ́ nípa ti ẹ̀mí? Báwo ni Jésù ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti di mímọ́? Kíni a kọ́ nípa Olùgbàlà láti inú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí? Ẹ ṣe àbápín bí ẹ ṣe nímọ̀lára nípa Rẹ́ àti ohun tí Ó ti ṣe fún yín pẹ̀lú àwọn ọmọ yín.
Ìsàíàh 2:2–4
Nínú tẹ́mpìlì, èmi nkọ́ nípa Jésù Krístì.
-
Ìsàíàh rí ìgbà kan tẹ́lẹ̀ nígbàtí “òkè ńlá ilé Olúwa” yíò fa àwọn ènìyàn wá láti “gbogbo orílẹ̀-èdè” (Ìsàíàh 2:2). Báwo ni ẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí inú wọn dùn nípa lílọ sí ilé Olúwa? Ẹ lè pè wọ́n láti ya àwòrán ilé wọn. Lẹ́hìnnáà ẹ ka Ìsàíàh 2:2papọ̀, kí ẹ sì pè wọn láti ya àwòrán “ilé Olúwa,” èyí tí ó jẹ́ tẹ́mpìlì. Ẹ ka Ìsàíàh 2:3 papọ̀. Ẹ pè wọ́n láti ṣe àfikún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá sí tẹ́mpìlì, pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn.
-
Tún lè ka Ìsàíàh 2:2–3 papọ̀ kí ẹ sì dá ohun kan tó mọ̀ tí ó mísí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín láti lọ sí tẹ́mpìlì. Nígbànáà, lẹ́hìn kíka Ìsàíàh 2:4–3 papọ̀, ẹ lè sọ̀rọ̀ bí tẹ́mpìlì ṣe nmú àláfíà wá fún wọn. Ẹ yẹ kíkọ orin kan nípa tẹ́ńpìlì, bíi irú “Mo Fẹ́ láti Rí Tẹ́mpìlì” (Ìwé Orin Ọmọdé, 95). Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti wa àwọn ọ̀rọ̀ nínú orin tí ó kọ ohun tí tẹ́mpìlì jẹ́ àti ohun tí a nṣe níbẹ̀.
Tẹ́mpìlì Salt Lake
Ìsàíàh 7:14; 9:6–7
Jésù Krístì wá sí ayé láti jẹ́ Olùgbàlà mi.
-
Láti ṣe àlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìsàíàh nípa Krístì, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn orúkọ oyè ènìyàn, bí ààrẹ, bíṣọ́pù, tàbí olùkọ́. Kíni àwọn àkọlé wọ̀nyí sọ fún wa nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti rí àwọn àkọ́lé Jésù Krístì nínú Ìsàíàh 7:14 àti 9:6–7 (bákannáà wo ojú-ewé ìṣe ṣíṣe ti ọ̀sẹ̀ yí pẹ̀lú). Kíni àwọn àkọlé wọ̀nyí kọ́ wa nípa Rẹ? Kíni a tún kọ́ nípa Jésù Krístì látinú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí?
-
Ẹ tún lè ṣe àbápín pẹ̀lú àwọn ọmọ yín “Wòlíì Ìsàíàh” (nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 150–51). Ẹ sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti béèrè ohun tí Ìsàíàh mọ̀ nípa Jésù Krístì ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí I. Lẹ́hìnnáà ẹ lè lo Máttéù 1:21–23; Lúkù 1:31–33 láti sọ̀rọ̀ nipa bí àsọtẹ́lẹ̀ Ìsàíàh nínú Ìsàíàh 7:14; 9:6–7 ṣe di mímúṣẹ
1:18Isaiah the Prophet
Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde Fríẹ́ndì ìwé ìròhìn ti oṣù yí.