Come, Follow Me
Àwọn Èrò láti Tọ́jú sí Ọkàn: Àwọn Wòlíì àti Ìsọtẹ́lẹ̀


“Àwọn Èrò láti Tọ́jú sí Ọkàn: Àwọn Wòlíì àti Ìsọtẹ́lẹ̀,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Àwọn Wòlíì àti Ìsọtẹ́lẹ̀,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026

àmì èrò

Àwọn Èrò láti Tọ́jú sí Ọkàn

Àwọn Wòlíì àti Ìsọtẹ́lẹ̀

Nínú àwọn ẹ̀yà ti àṣà Krìstẹ̀ẹ́nì ti Májẹ̀mú Láéláé, ìpín tí ó kẹ́hìn (Ìsàíàh sí Málákì) ni à pè ní àwọn Wòlíì. Ìpín yí, bí idamẹrin Májẹ̀mú Láéláé, ní àwọn ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí a fún ní àṣẹ nínú, ẹni tí ó bá Olúwa sọ̀rọ̀ àti lẹ́hìnnáà sọ̀rọ̀ fún Un , ní ṣíṣe àbápín ọ̀rọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní àárín bíi 900 àti 500 BC.

Àwọn Wòlíì Sọ̀rọ̀ Ìfẹ́ Ọlọ́run

Àwọn Wòlíì àti ìsọtẹ́lẹ̀ kó ipa pàtàkì káàkiri inú Májẹ̀mú Láéláé. Ábráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù rí ìran wọ́n sì bá àwọn ìránṣẹ́ ti ọ̀run sọ̀rọ̀. Mósè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lójúkojú ó sì sọ ìfẹ́ Rẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì. Ìwé àkọ́kọ́ àti ìkejì ti àwọn Ọba ròhìn àwọn iṣẹ́ mánigbàgbé àti iṣẹ́ tí wòlíì Èlíjàh àti Èlíṣhà ṣe. Májẹ̀mú Láéláé tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn wòlíì obìnrin bíi Míríámù àti Dèbórà, pẹ̀lú àwọn obìnrin míràn tí a bùkún pẹ̀lú ẹ̀mí àsọtẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́bí Rèbékà àti Hánnà. Pàápàá bótilẹ̀jẹ́pé kì í ṣe àwọn wòlíì aláṣẹ ló kọ orin Dáfídì, àwọn náà kún fún ẹ̀mí àsọtẹ́lẹ̀, nípàtàkì bí wọ́n ṣe ntọ́ka sí bíbọ̀ Mèssíàh náà.

Kò sí èyí tí ó wá bí ìyàlẹ́nu sí àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ní tòótọ́, ìhìnrere Jésù Krístì tí a mú padàbọ̀sípò kọ́ wa pé àwọn wòlíì kì í ṣe àwọn olókìkí ti ìtàn lásán ṣùgbọ́n ara pàtàkì nínú ètò Ọlọ́run. Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn kan lè rí àwọn wòlíì gẹ́gẹ́bí àìlẹ́gbẹ́ sí àwọn àkokò Májẹ̀mú Láéláé, tí a rí wọn bí ohunkan tí a ní ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àkókò Májẹ̀mú Laelae.

Ṣùgbọ́n kíka orí kan látinú Ìsàíàh tàbí Èsèkíẹ́lì lè dàbí ìyàtọ̀ sí kíka ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò láti ọ̀dọ̀ Ààrẹ Ìjọ lọ́wọ́lọ́wọ́. Nígbàmíràn ó ṣòro láti ri pé àwọn wòlíì àtijọ̀ ní nkan láti sọ fún wa. Lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, ayé tí a ngbé ní òní yàtọ̀ pátápátá sí ayé tí wọ́n wàásù tí wọ́n sì sọtẹ́lẹ̀. Àti pé òtítọ́ náà pé a wòlíì alààyè lè gbé ìbéèrè kan dìde: Kínìdí tí ó fi yẹ fún ìgbìyànjú—àti pé ó gba ìtiraka—láti ka àwọn ọ̀rọ̀ ti àwọn wòlíì àtijọ́?

kíkọ wòlíì àtijọ́

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Àwọn Àkokò, láti ọwọ́ Greg Olsen

Àwọn Wòlíì àtijọ́ Ní Ohun kan Láti Sọ fún Wa

Fún púpọ̀ jùlọ, àwọn ènìyàn ní òní kìí ṣe olùgbọ́ àkọ́kọ́ ti àwọn wòlíì Májẹ̀mú Láéláé. Àwọn wòlíì wọnnì ní àwọn àníyàn tí wọ́n nyanjú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní àkókò àti ààyè wọn—gẹ́gẹ́bí àwọn wòlíì ọjọ́-ìkẹhìn wa ti nyanjú àwọn àníyàn wa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní òní.

Ní àkókò kannáà, àwọn wòlíì tún lè rí kọ̀jà àwọn ìfiyèsí ẹsẹ̀kẹsẹ. Wọ́n nkọ́ni ní àwọn òtítọ́ ayérayé, tí ó bá àkókò àti ibi èyíkéyìí mu. Wọ́n gbàbùkún pẹ̀lú ìfihàn, wọ́n rí ìwòye gbígbòòrò iṣẹ́ Ọlọ́run. Bí àpẹrẹ, Ìsàíàh kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn nígbà ayé rẹ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó tún kọ̀wé nípa ìdándè àwọn ọmọ Ísráẹ́lì tí yíò gbé fún igba ọdún ní ọjọ́ iwájú. Ní àkókò kannáà, ó kọ́ni nípa ìdándè tí gbogbo àwọn ènìyàn Ọlọ́run nwá. Ó sì kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pé, àní ní òní pàápàá, a ṣì ndúró de ìmúṣẹ—gẹ́gẹ́bí àwọn ìlérí “ilẹ̀ ayé titun kan” (Ìsàíàh 65:17) tí yíò “kún fún ìmọ̀ Olúwa” (Ìsàíàh 11:9), níbití àwọn ẹ̀yà Ísráẹ́lì tó ti sọnù yíò ti kóra jọ àti níbi tí “àwọn orílẹ̀-èdè” kì yíò ti “kọ́ ogun mọ́” (Isaiah 2:4). Ara ayọ̀ àti ìmísí tí ó nwà láti inú kíka àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn wòlíì Májẹ̀mú Láéláé bíi Ìsàíàh ni mímọ̀ pé a ṣe ojúṣe kan nínú ọjọ́ ológo tí wọ́n rò.

Nítorínáà nígbàtí ẹ bá nka àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àtijọ́, ó lè ṣèrànwọ́ láti kẹkọ nípa àyíká ọ̀rọ̀ tí a ti kọ wọ́n—ṣùgbọ́n ó tún yẹ kí ẹ rí ara yín nínú wọn, tàbí “fi wọ́n wé [ara yín]” (1 Néfì 19:24; bákannáà wo ẹsẹ 23). Nígbàmíràn èyí túmọ̀ sí mímọ Bábílónì gẹ́gẹ́bí àmì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìgbéraga, kìí ṣe gẹ́gẹ́bí ìlú nlá àtijọ́. Ó lè túmọ̀ sí níní óye Ísráẹ́lì gẹ́gẹ́bí ènìyàn Ọlọ́run ní àkókò àti ibikíbi. Tàbí ó lè túmọ̀ sí rírí Síónì gẹ́gẹ́bí èrèdí ọjọ́ ìkẹhìn tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run gbá mọ́ra, dípò rírí i gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ míràn fún Jerúsálẹ́mù.

A lè fi àwọn ìwé mímọ́ wé ìgbésí ayé wa nítorí a ní òye pé àsọtẹ́lẹ̀ kan lè ní ìmúṣẹ ní ọ̀nà púpọ̀. Àpẹrẹ rere ni àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìsàíàh 40:3: “Ohùn ẹni tí nkígbe ní aginjù, Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe.” Sí àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì, ọ̀rọ̀ yìí lè ti tọ́ka sí Olúwa tó pèsè ọ̀nà àbájáde láti ìgbèkùn àti padà sí Jerúsálẹ́mù. Sí Máttéù, Máàkù, àti Lúkù, àsọtẹ́lẹ̀ yí tọ́kà sí Jòhánnù Onítẹ̀bọmi, ẹni tí ó pèsè ọ̀nà sílẹ̀ fún iṣẹ́́ ìrànṣẹ́ ayé ikú Olùgbàlà.. Joseph Smith sì gba ìfihàn pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣì nṣẹ lónìí ní ìmúrasílẹ̀ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún ti Krístì. Ní àwọn ọ̀nà tí a ṣì ngbà ní òye, tí àwọn wòlíì àtijọ́ wa sọ̀rọ̀. Wọ́n sì kọ́ni ní ọ̀pọ̀ òtítọ́ iyebíye, àwọn òtítọ́ ayérayé tí ó jẹ́ pàtàkì sí wa gẹ́gẹ́bí wọ́n ti jẹ́ fún Ísráẹ́lì àtijọ́.

Àwọn Wòlíì Àtijọ́ Jẹ́rìí nípa Jésù Krístì

Bóyá pàápàá ó ṣe pàtàkì ju rírí ara yín ní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Májẹ̀mú Láéláé ní rírí Jésù Krístì nínú wọn. Bí ẹ bá wá A, ẹ yíò rí I, pàápàá tí a kò bá dárúkọ Rẹ̀ nípasẹ̀ orúkọ. Ó lè ṣèrànwọ́ láti fi sọ́kàn pé Ọlọ́run Májẹ̀mú Láéláé, Jèhófà Olúwa, ni Jésù Krístì. Nígbàkúgbà tí àwọn wòlíì bá ṣàpèjúwe ohun tí Olúwa nṣe tàbí ohun tí yíò ṣe, wọ́n nsọ ti Olùgbàlà.

Jésù olùjínde nnawọ́ jáde sí ọkùnrin kan

Olúwa Nfarahàn fún Ábráhámù, nípasẹ̀ Keith Larson

Ẹ̀yin yíò tún rí àwọn ìtọ́kasí sí Ẹni Àmì Òróró kan, Olùràpadà, àti Ọba ọjọ́ iwájú láti ìlà Dáfídì. Ìwọ̀nyí ni gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù Krístì. Ní gbogbo rẹ̀ síi, ẹ̀yin yíò kà nípa ìdándè, ìdáríjì, ìràpadà, àti ìmúpadàbọ̀sípò. Pẹ̀lú Olùgbàlà nínú ọkàn àti iyè, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí yíò tọ́ka yín níti àmì àdánidá sí Ọmọ Ọlọ́run. Lẹ́hìnnáà, ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti ní òye àsọtẹ́lẹ̀ ní láti ní “ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀,” èyítí Jòhánnù sọ fún wa ni “ẹ̀rí Jésù” (Ìfihàn 19:10).

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Ìsàíàh, Jeremíàh, Èsèkíẹ́lì, àti Dáníẹ́lì sábà máa ntọ́ka sí gẹ́gẹ́bí Àwọn Wòlíì Gíga Jùlọ nítorí gígùn àwọn ìwé wọn. Àwọn wòlíì yòókù (Hóséà, Jóẹ́lì, Ámósì, Ọbadíàh; Jónàh, Míkàh, Náhúmù, Hábákúkù, Sefaníà, Hágáì, Sekaríà, àti Málákì) ni wọ́n npè ní Wòlíì Kékeré nítorí pé ìwé wọn kúrú. Ẹkún Jeremíàh ni a kà sí ọ̀kan lára Àwọn Ìwé, kì í ṣe àwọn Wòlíì.

  2. A kò mọ bí a ṣe ṣe àkójọpọ̀ àwọn ìwé ti wòlíì náà. Ní àwọn ọ̀ràn kan, wòlíì kan lè ti bójú tó àkójọ àwọn ìwé àti àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Ní àwọn ọ̀ràn míràn, àwọn ìkọ́ni rẹ̀ ni a lè tí ṣe àkọsílẹ̀ àti àkójọ lẹ́hìn ikú rẹ̀.

  3. Wo Ẹksódù 15:20; Àwọn Onídàájọ́ 4.

  4. Wo Gẹ́nẹ́sísì 25:21–23; 1 Sámúẹ́lì 1:20–28; 2:1–10.

  5. Kàn ronú nípa ìdùnnú àti síṣe kíákíá ti gbogbo rẹ̀: gbogbo wòlíì tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ádámù ti rí ọjọ́ tiwa. Olukúlùkù wòlíì sì ti sọ nípa ọjọ́ wa , nígbàtí Ísráẹ́l yíò di kíkójọ tí ayé yío sì di mímúra sílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olùgbàlà. Ronú nípa rẹ̀! Nínú gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n ti gbé rí ní orí ilẹ̀ ayé, àwa ni ẹni náà tí ó le kópa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìkójọ nlá, àti ti ìkẹhìn yi. Bí èyíinì ti jẹ́ dídùnmọ́ni to!” (Russell M. Nelson, “Ìrètí Ísráẹ́lì” [ìfọkànsìn àwọn ọ̀dọ́ jákèjádò ayé, Ọjọ́ Kẹ́ta Oṣù kẹfà, 2018], Ibi Ìkàwé Ìhìnrere). Bákannáà wo Ronald A. Rasband, “Ìmúṣẹ Àsọtẹ́lẹ̀,” Làìhónà, Oṣù karun 2020, 75–78.

  6. Olùgbàlà, sísọ̀rọ̀ nípa Ìsàíàh, wípé, “Gbogbo ohun tí ó ti sọ ti jẹ́ yíò jẹ́ àti pé yíò sì jẹ́, àní gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ” (3 Néfì 23:3; àfikún ìtẹnumọ́).

  7. Wo Máttéù 3:1–3; Máàkù 1: 2–4; Lúkù 3: 2–6.

  8. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 33:10; 65:3; 88:66.

  9. Wo Ìsàíàh 9:6–7; 61:1; Hóséà 13:14; Sekaríà 9:9.