“Oṣù Kẹsan 7–13. ‘Òun Ó Sì Tọ Ipa-ọ̀nà Rẹ̀’: Ìwé Òwe 1–4; 15–16; 22; 31; Oníwàásù 1–3; 11–12,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹsan 7–13. ‘Òun Ó Sì Tọ Ipa-ọ̀nà Rẹ̀,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Jésù pẹ̀lú àwọn ọmọdé, nípasẹ̀ Dilleen Marsh
Oṣù Kẹsan 7– 13: “Òun Ó Sì Tọ Ipa-ọ̀nà Rẹ̀”
Ìwé Òwe 1–4; 15–16; 22; 31; Oníwàásù; 1–3; 11–12
Ẹ lè ronú nípa ìwé Òwe gẹ́gẹ́bí àkójọpọ̀ ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ (wo Ìwé Òwe 1:8). Kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé tí ẹ bá wá ọgbọ́n—nípàtàkì ọgbọ́n Ọlọ́run—ayé yíò lọ dáradára. Ṣùgbọ́n Oníwàásù tẹ̀lé Ìwé Òwe, èyí tí ó dà bíi pé ó sọ pé, “Kò rọrùn bẹ́ẹ̀.” Oníwàásù ti a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ninu Ìwé Oníwàásù ṣe akiyesi pe ó “fi ọkàn [rẹ̀] fúnni láti mọ̀ ọgbọ́n” ṣùgbọ́n síbẹ́ ṣì ri “ìbínú ẹ̀mí” àti “ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́” (Oníwàásù 1:17–18). Ní onírurú àwọn ọ̀nà, ìwé náà béèrè pé, “Njẹ́ ìtumọ̀ gidi lè wà nínú ayé kan tí ohun gbogbo ti dà bí asán, fún ìgbà díẹ̀, tí kò sì dáni lójú?”
Àti síbẹ̀, nígbàtí àwọn ìwé méjèèjì wo ìgbésí-ayé láti àwọn oríṣiríṣi ìrísí, wọ́n nkọ́ àwọn òtítọ́ tó jọra. Oníwàásù kéde pé: “Òpin gbogbo ọ̀rọ̀ náà tí a gbọ́ ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run, kí o sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́: nítorí èyí ni ojúṣe ènìyàn” (Oníwàásù 12:13). Èyí jẹ́ ìlànà kan náà tí a rí nínú Ìwe Òwe: “Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀lé Olúwa” (Ìwé Òwe 3:5; bákanáà wo verse 7). Ayé dára nígbàgbogbo—tí kìí bá ṣe pípé ìgbàgbogbo—nígbàtí a bá gbẹ́kẹ̀lé tí a sì tẹ̀lé Olúwa Jésù Krístì.
Fún àlàyé ṣókí nípa àwọn ìwé yí, wo “Ìwé Òwe, ìwé ti” àti “Oníwàásù” nínú Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.
Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ
Ìwé Òwe 1–4; 15–16; Oníwàásù; 1–3; 11–12
“Ẹ fetí yín sí ọgbọ́n.”
Àwọn ìwé Òwe àti Oníwàásù kún fún àwọn ìwòye nípa ọgbọ́n. Ẹ yẹ sísàmì sí ọ̀rọ̀ náà “ọgbọ́n” àti àwọn ọ̀rọ̀ tó jọra, bíi “ìmọ̀” àti “òye,” bí ẹ ṣe rí wọn nínú Ìwé Òwe 1–4; 15–16; Oníwàásù 1–3; 11–12. Báwo ni àwọn orí wọ̀nyí ṣe npa ọ̀nà tí ẹ fi nronú nípa ọgbọ́n lára? Lórí ohun tí ẹ rí, báwo ni ẹ ṣe nṣe àpèjúwe ọgbọ́n tí “Olúwa nfi fúnni”? (Ìwé Òwe 2:6). Àwọn ìbùkún wo ni ó nwá látinú ọgbọ́n Ọlọ́run?
Bákannáà wo Máttéù 7:24–27; 25:1–13.
Ẹ ran àwọn akẹkọ lọ́wọ́ láti ṣe àbápín ohun tí wọ́n nkọ́. “Ẹ fún àwọn akẹkọ ní ànfàní láti ṣe àbápín pẹ̀lú ara wọn ohun tí wọ́n nkọ́ nípa Olùgbàlà àti ìhìnrere Rẹ̀. Ṣíṣe èyí yíò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú àwọn òtítọ́ tí a nkọ́ wọn sọ́kàn, kí wọ́n sì sọ wọ́n jáde. Yíò tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jèrè ìgbẹ́kẹ̀lé nínú okun wọn láti ṣe àbápín àwọn òtítọ́ nínú àwọn àgbékalẹ̀ míràn” (Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà, 26). Fún àpẹrẹ, ẹ lè pe àwọn akẹkọ láti kọ àwọn ìtọ́kasí kan sílẹ̀ látinú Ìwé Òwe tàbí Oníwàásù níbi tí wọ́n ti rí ìwòye nípa ọgbọ́n Ọlọ́run. Lẹ́hìnnáà ẹ pe àwọn akẹkọ láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n kọ́.
Ìwé Òwe 1:7; 2:5; 3:7; 15:33; 16:6; 31:30; Oníwàásù 12:13
“Máṣe gbọ́n ní ojú ara rẹ: bẹ̀rù Olúwa.”
Àkórí míràn tí á rí ní gbogbo Ìwé Òwe àti Oníwàásù ni “ìbẹ̀rù Olúwa.” Ẹ wo gbólóhùn yí bí ẹ ṣe nkà. Kíni ẹ rò pé ó túmọ̀ sí láti bẹ̀rù Olúwa? Wá àwọn òye nínú ifiránṣẹ́ Elder David A. Bednar “Nítorínáà Wọ́n Tẹ Ẹ̀rù Wọn Mọ́lẹ̀” (Làìhónà, Oṣù karun 2015, 46–49). Báwo ni ìbẹ̀rù Olúwa ṣe yàtọ̀ sí irú ìbẹ̀rù míràn?
Bákannáà wo Ìwé Òwe 8:13.
Ìwé Òwe 3:5–7; 4
“Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.”
Báwo ni ẹ̀yin yíò ṣe gba ẹnìkan níyànjú pé ó sàn láti “gbẹ́kẹ̀lé Olúwa” ju kí a “tẹ̀ … sí òye ara [wa]”? (Ìwé Òwe 3:5). Àwọn àfiwé tàbí àwọn nkan ẹ̀kọ́ wo ni ẹ̀yin yíò lò? Bí ẹ ṣe nronú jinlẹ̀ Ìwé Òwe 3:5–7, ronú nípa àwọn ọ̀nà tí o lè gbà parí àwọn gbólóhùn bí ìwọ̀nyí: Gbígbẹ́kẹ̀lé Oluwa dàbí … Títẹ̀sí òye ara wa dàbíi …
Kínìdí tí kò fi mọ́gbọ́n wá láti tẹ̀tí òye ti ara wa? Báwo ni ẹ ṣe ri pé Olúwa ṣeé gbẹ́kẹ̀lé?
Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, ó lè ṣòro fún wa láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbà míràn. Kínìdí ìyẹn? Alàgbà Gerrit W. Gong dámọ̀ràn àwọn èrèdí kan, papọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ràn ríràn-nilọ́wọ́, nínú “Gbẹ́kẹ̀lé Lẹ́ẹ̀kansi” (Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2021, 97–99). Àwọn ìtan tàbí àwọn ìkọ́ni wo ni ẹ rí nínú ọ̀rọ̀ yí tí o le ran ẹnìkan lọwọ lati mu ìgbẹ́kẹ̀lé wọn padàbọ̀sípò ninu Oluwa?
Méjèèjì Ìwé Òwe 3:6 àti Ìwé Òwe 4 fi ayé wé “ipa-ọ̀nà kan” tàbí “ọ̀nà kan.” Kíni ẹ rò pé ó túmọ̀ sí láti jẹ́ kí Olúwa “darí ipa-ọ̀nà [wa]”? (Ìwé Òwe 3:6). Kíni ẹ rí nínú orí 4 tó ràn yín lọ́wọ́ láti “jíròrò ipa-ọ̀nà ẹsẹ̀ [yín]”? (ẹsẹ̀ 26). Fún àpẹrẹ, kíni àwọn ẹsẹ 11–12 àti 18–19 kọ́ni nípa àwọn ìbùkún títẹ̀lé ipa-ọ̀nà títọ́? Kíni àwọn ẹsẹ 26–27 túmọ̀ sí fún yín?
Bákanáà wo 2 Néfì 31:18–21; “Olúwa, Èmi Ó Tẹ̀lé Yín,” Àwọn Orin, nọ́mbà 220.
Ìwé Òwe 15; 16:24–32
“Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ a máa yí ìbínú padà.”
Àwọn kan lára èrò inú Ìwé Òwe 15–16 lè fún yín ní ìmísí láti mú ọ̀nà ìbárasọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn míràn pọ̀ si, nípàtàkì àwọn olùfẹ́. Fún àpẹrẹ, ẹ ronú nípa àwọn àkókò kan nígbàtí “ìdáhùn pẹ̀lẹ́” ṣe ìrànwọ́ láti “[yí] ìbínú padà” (Ìwé Òwe 15:1).
Ẹ tún lè ronú àwọn àkókò nígbàtí Olùgbàlà ṣe àpẹrẹ àwọn ìkọ́ni nínú Ìwé Òwe 15:1–4, 18 (wo Márkù 12:13–17; Jòhánnù 8:1–11). Báwo ni ẹ ṣe lè tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀ bí ó ṣe nlò pẹ̀lú àwọn míràn?
Báwo ni ìmọ̀ràn tó wà nínú Ìwé Òwe 15; 16:24–32 ṣe wúlò sí ìbárasọ̀rọ̀ díjítà òní? Ẹ wò bóyá ẹ lè rí ẹsẹ kan nínú àwọn orí wọ̀nyí tí ẹ lè ṣe àtúnwí bí ìmọ̀ràn nípa ìbárasọ̀rọ̀ lórí ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn tàbí nípasẹ̀ àtẹ̀jíṣẹ́.
Bákannáà wo Neil L. Andersen, “Títẹ̀lé Jésù: Jíjẹ́ Onílàjà kan,” Làìhónà, Oṣù karun 2022, 17–20; Ronald A. Rasband, “Àwọn Ọ̀rọ̀ ṣe Pàtàkì,” Làìhónà, Oṣù karun 2024, 70–77; Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́: Ìtọ́nisọ́nà kan fún Ṣíṣe àwọn Àṣàyàn (2022), 11–12.
Tani Yíò Rí Obìnrin Oníwà rere? II, láti ọwọ́ Louise Parker
Ìwe Òwe 31:10-31
“Obìnrin kan tí ó bẹ̀rù Olúwa, òun ni a ó yìn.”
Ìwé Òwe 31:10–31 ṣe àpèjúwe “obìnrin oníwà rere,” tàbí obìnrin tí ó ní okun ti ẹ̀mí nla, agbàra, àti ipa. Ẹ lè gbìyànjú láti ṣe àkópọ̀ ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ wọ̀nyí sọ nípa àwọn obìnrin oníwà rere. Èwo nínú àwọn ìwà wọ̀nyí ni ẹ lè farawé?
Oníwàásù 1–3; 12
Ìgbé-ayé ikú jẹ́ ìgbà díẹ̀.
Kínìdí tó fi jẹ́ iyebíye fún yín láti rántí pé púpọ̀ nínú ayé yí, gẹ́gẹ́bí Oníwàásù 1–2 ṣe sọ, jẹ́ “asán” (tàbí fún ìgbà díẹ̀ àti pé kì í ṣe pàtàkì)? Kíni ẹ rí ní Oníwàásù 12 tó nfúnni ní ìyè ayérayé?
Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde àwọn ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Làìhónà àti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn Ìrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Ìwé Òwe 1:7; 2:5; 15:33; 16:6; Oníwàásù 12:13
Láti “bẹ̀rù Ọlọ́run” túmọ̀ sí láti fẹ́ràn àti gbọràn si I.
-
Láti ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀ nípa bíbẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ lè fi ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀rù” rọ́pò ọ̀rọ̀ bí ọ̀wọ̀, ìfẹ́, tàbí ìgbọràn (bákànnáà wo Hébérù 12:28). Báwo ni èyí ṣe lè pa bí ẹ ṣe nronú nípa àwọn ẹsẹ wọ̀nyí lára? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bẹ̀rù Olúwa?
Ìwé Òwe 3:5–7
Mo lè gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.
-
Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè ṣe àwọn ìṣe láti lọ pẹ̀lú Ìwé Òwe 3:5–7, bíi ṣíṣe ọkàn pẹ̀lú ọwọ yín, títẹ̀sí ẹ̀gbẹ́ kan, rínrìn ní ààyè, àti títọ́ka sí ojú yín. Báwo ni a ṣe lè fihàn pé a gbẹ́kẹ̀lé Jésù Krístì pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa?
-
Láti fihàn ohun tí ó túmọ̀ sí láti “máṣe tẹ̀sí òye ara rẹ” (Ìwé Òwe 3:5), ẹ yẹ pípe àwọn ọmọ yín láti tẹ̀sí sẹgbẹ ohunkan tí ó lágbára tí ó sì dúró ṣinṣin, bíi ògiri wò. Lẹ́hìnnáà wọ́n lè gbìyànjú láti tẹ̀sí nkan tí kò lágbára, bíi ìgbálẹ̀. Tàbí kí wọ́n gbìyànjú láti tẹ̀sí igi tàbí lẹ́ẹ̀dì ní ẹ̀gbẹ́ àwọn nkan tí ó lágbára yàtọ̀ síra, bí irú ìwé kan tàbí ẹ̀là bébà kan. Kínìdí tí ó fi ṣe pàtàkì láti “gbẹ́kẹ̀lé Olúwa” (ẹsẹ 5) kìí ṣe “òye tiwa”?
Kíkọ́-ẹ̀kọ́ láti Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, láti ọwọ́ Kathleen Peterson
Ìwé Òwe 15:1, 18
Èmi lè lo àwọn ọ̀rọ̀ rere.
-
Bóyá ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè ronú nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nígbàtí ẹ̀yin tàbí àwọn lè ní ìmọ̀lára ìbínú. Ẹ ka Ìwé Òwe 15:1 papọ̀, kí ẹ sì ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí lò lórí àwọn ipò tí wọ́n ronú lé lórí. Bóyá wọ́n lè ṣe àdáṣe àwọn nkan nínú “àwọn ìdáhùn rírọ̀.” Orin kan nípa inúrere, bíi “Ìfẹ Ni À Nsọ̀rọ̀ Rẹ̀ Nihin” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 190–91), lè fi kún ìlànà yí.
-
Láti kọ́ ohun tí ó túmọ̀sí láti “lọ́ra láti bínú” (Ìwé Òwe 15:18), ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè ṣe àbápín àkokò nígbàtí ẹ̀yin (tàbí ẹnìkan tí ẹ mọ̀) ní ìmọ̀lára ìbínú ṣùgbọ́n tí ó yan láti ṣe inúrere. Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ohun tí a lè tètè ṣe bí a bá “lọ́ra láti bínú.” Fún àpẹrẹ, a lè yára láti ronú nípa Jésù, láti bèèrè lọ́wọ́ Baba Ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́, láti ronú nípa orin alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kan, tàbí, tí ó bá ṣeéṣe, láti rìn kúrò.
Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .