“Oṣù Kẹ́jọ 24–30. ‘Èmi O Sọ Ohun Tí Ó Ṣe Fún Ọkàn Mi: Orin Dáfídì 49–51; 66; 69–72; 77; 85,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹ́jọ 24–30. ‘Èmi O Sọ Ohun Tí Ó Ṣe Fún Ọkàn Mi,’” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Gbígba Èyí Tí O Sọnù Là, láti ọwọ́ Michael Malm
Oṣù Kẹ́jọ 24–30: “Èmi O Sọ Ohun Tí Ó Ṣe Fún Ọkàn Mi”
Orin Dáfídì 49–51; 61–66; 69–72; 77–78; 85–86
Àwọn olùkọ̀wé Orin Dáfídì ṣe àjọpín ìmọ̀lára araẹni nínú ewì wọn. Wọ́n kọ nípa ìmọ̀lára ìrẹ̀wẹ̀sì, ìbẹ̀rù, àti ikabamọ. Nígbà míràn, wọ́n máa nrò pé Ọlọ́run ti pa wọ́n tì, àwọn orin Dáfídì kan sì máa nsọ̀rọ̀ ìjákulẹ̀ tàbí àìnírètí. Bí ẹ bá ti ẹ̀ ti ní ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ rí, kíka orin Dáfídì lè ràn yín lọ́wọ́ láti mọ̀ pé kì í ṣe ẹ̀yin nìkan. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yio tún rí àwọn orin Dáfídì tí ó lè fún yín ní ìyànjú nígbàtí ẹ bá ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀, nítorí pé àwọn onísáàmù náà nyin Olúwa fún oore Rẹ̀, ẹnu yà wọ́n sí agbára rẹ̀, wọ́n sì nyọ̀ nínú àánú rẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé ìwà ibi àti ẹ̀ṣẹ̀ nbà wá lọ́kàn jẹ́ ṣùgbọ́n pé Olúwa jẹ́ “ẹni rere, ó sì ṣetán láti dáríjini” (Orin Dáfídì 86:5). Wọ́n ní òye pé níní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa kò túmọ̀ sí pé ẹ̀yin kì yio ní ìlàkàkà pẹ̀lú àníyàn, ẹ̀ṣẹ̀, tàbí ìbẹ̀rù. Ó túmọ̀ sí pé ẹ̀ mọ ẹni tí ẹ lè yípadà sí.
Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ
Orin Dáfídì 49; 62:5–12
Ìràpadà nwá nípasẹ̀ Jésù Krístì nìkan.
Orin Dáfídì 49 ní ọ̀rọ̀ kan fún “méjèèjì kékerè àti gíga, ọlọ́rọ̀ àti tálákà” (ẹsẹ 2). Kíni ẹ ó wípé ọ̀rọ̀ yí jẹ́? Kíni ẹ ní ìmọ̀lára rẹ pé Orin Dáfídì 62:5–12 fikún ọ̀rọ̀ náà?
Kíka àwọn orin Dáfídì wọ̀nyí lè fún yín ní ìmísí láti jíròrò lórí àwọn ọ̀nà tí a gba àdánwò láti gbẹ́kẹ̀lé ohun míràn sàn ju Ọlọ́run fún ìràpadà (wo Orin Dáfídì 49:6–7). Báwo ni ẹ̀rí yín ṣe nípa lórí ìgbésí-ayé yín pé “Ọlọ́run yíò ra ọkàn [yín] padà lọ́wọ́ agbára ibojì”? (Orin Dáfídì 49:15).
Orin Dáfídì 51; 85–86
Nítorí àánú Olùgbàlà, a lè dáríjì mí.
Ọba Dáfídì kọ Orin Dáfídì 51 lẹ́hìn tó mọ̀ pé òun nílò ìdáríjì—ohun kan tí gbogbo wa nílò. Àwọn ẹsẹ wo ni ó ṣe àpèjúwe àwọn ìmọ̀lára tí ẹ ti ní? Kíni ẹ rí nínú orin Dáfídì yí tí ó nfún yín ní ìrètí fún ìdáríjì?
Ẹ tún lè wa Orin Dáfídì 51 fún àwọn ìtọ́ka nípa kíni ó túmọ̀ sí láti ronúpìwàdà. Ẹ ṣe àtòkọ ohun tí ẹ rí. Ẹ wo bóyá ẹ lè ṣe àfikún sí àtòkọ yín nípa wíwá ọ̀rọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson “A Lè Ṣe Dáradára Síi Kí A Sì Jẹ́ Dáradára Síi” (Làìhónà, Oṣù karun 2019, 67–69).
Báwo ni ẹ̀yin yíò ṣe ṣe àpèjúwe ohun ti ó jọ láti gba ìdáríjì nípasẹ Krístì? Bí ẹ bá nílò ìrànlọ́wọ́ láti ṣe àpèjúwe ìmọ̀lára tí ẹ ní, ẹ lè wo Psalms 51:1–2, 7–12; 85:2–9. Àwọn ènìyàn kan fẹ́ràn láti ya tàbí wá àwọn àwòrán láti fi àwọn ìmọ̀lára wọn hàn; ẹ lè gbìyànjú èyí. Ẹ tún lè kọrin tàbí fetísí orin kan nípa Olùgbàlà, gẹ́gẹ́bí “Mo Dúró Ní Gbogbo Ìyanu” (Àwọn orin ìsìn, nọ́mbà 193).
Láti ronúpìwàdà, a nílò ìgbàgbọ́ kìí ṣe pé Jésù Krístì lè wẹ̀ wá mọ́ níkan ṣùgbọ́n pé Òun yíò ṣeé. Kíni ẹ rí nínú Orin Dáfídì 86:5, 13, 15 tó ràn yín lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Olùgbàlà lágbára àti pé ó ṣetán láti dáríjì?
Bákannáà wo Álmà 36; Peter F. Meurs, “Ó Lè Wòmí Sàn!,” Làìhónà, Oṣù karun 2023, 39–41.
Orin Dáfídì 51:13–15; 66:5–20; 71:15–24
Ẹ̀rí mi nípa Jésù Krístì lè rànmí lọ́wọ́ láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Ẹ jíròrò nípa bí o ṣe jèrè ẹ̀rí rẹ nípa Jésù Krístì àti agbára ètùtù Rẹ̀. Lẹ́hìnnáà, báwo ni ẹ ṣe nṣe àṣàrò Orin Dáfídì 51:13–15; 66:5–20; 71:15–24, ẹ ronú nípa bí ẹ ṣe lè pe àwọn ẹlòmíràn láti “wá wo àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run” (Orin Dáfídì 66:5) Bí ẹ̀yin yíò bá “kéde ohun tí [Olúwa] ti ṣe fún ọkàn [yín]” (Orin Dáfídì 66:16), kíni ẹ yíò kéde?
Kíni ó túmọ̀ sí fún yín láti “sọ̀rọ̀ òdodo [Rẹ̀] títí ní ọjọ́ gbogbo”? (Orin Dáfídì 71:24).
Bákannáà wo Álmà 26.
“Wá, kí o sì gbọ́, … èmi yíò sì ròhìn ohun tí [Ọlọ́run] ti ṣe fún ọkàn mi” (Orin Dáfídì 66:16).
Orin Dáfídì 63; 69; 77–78
Olúwa yíò ràn mí lọ́wọ́ nígbà àìní mi.
Oríṣiríṣi àwọn Orin Dáfídì ṣe àpèjúwe ohun tí ó dàbí láti ní ìmọ̀lára jíjìnnà sí Ọlọ́run tí a sì nílò ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ taratara (wo Orin Dáfídì 63:1, 8; 69:1–8, 18–21; 77:1–9). Nínú Orin Dáfídì 63; 69; 77–78, kí ni ẹ rí tí ó fún àwọn onísáàmù náà ní ìdánilójú?
Nígbàtí ìdààmú bá báa yín, báwo ni ó ṣe nràn yín lọ́wọ́ láti “rántí àwọn iṣẹ́ Olúwa” àti “àwọn iṣẹ́ àgbàyanu ìgbà àtijọ́ Rẹ̀”? (Orin Dáfídì 77:11). Àwọn kan lára àwọn ìṣẹ ìyanu wọnnì ni a ṣe àpèjúwe nínú Orin Dáfídì 78. Bí ẹ ṣe nkà nípa wọn, ẹ jíròrò ohun tí ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti “fi ìrètí [yín] sínú Ọlọ́run” (ẹsẹ 7).
Fún púpọ̀ si, ẹ wo àtẹ̀jáde àwọn ìwé-ìròhìn oṣù yi ti Làìhónà àti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ̀ .
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Nítorí pé Ọjọ́ Ìsinmi yí jẹ́ Ọjọ́ Ìsinmi karun oṣù, a gba àwọn olùkọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ níyànjú láti lo àwọn ìṣe kíkọ́ ẹ̀kọ́ nínú “Àlẹ̀mọ́ B: Ìmúrasílẹ̀ Àwọn Ọmọdé fún Ọjọ́ Gígùn Ní Ọ̀nà Májẹ̀mú Ọlọ́run.”
Orin Dáfídì 51; 86:5, 13, 15
Nígbàtí mo ba ṣe àṣìṣe yíyan kan, Jésù lè ràn mí lọ́wọ́ láti yípadà.
-
Láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe àwárí àwọn òtítọ́ nípa ìrònúpìwàdà nínú Orin Dáfídì 51, ẹ lè ya ọkàn nlá. Lẹ́hìnnáà, ẹ lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ àwọn ohun búburú tí Sátánì nfẹ́ ká ṣe sínú ọkàn wọn. Báwo ni a ṣe lè mú àwọn nkan wọ̀nyí kúrò nínú ọkàn wa? Ẹ ní kí àwọn ọmọ yín wá ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” nínú Orin Dáfídì 51:10, 17. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí àwọn ẹsẹ wọ̀nyí kọ́ni nípa ìrònúpìwàdà. Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín pa àwọn ọ̀rọ̀ inú ọkàn rẹ́ kí wọ́n sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ titun tó nṣe àpèjúwe àwọn ọ̀nà tí Jésù fi lè gbà yí wa padà nígbàtí a bá ronúpìwàdà.
-
Ẹ lè fẹ́ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ní “ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà” (Orin Dáfídì 51:17). Wọ́n lè máa fọ́ ohunkan tí ó ní ìkarahun líle láti ṣí ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, bí irú ẹyin tàbí ẹ̀pà. Ẹ lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn láti ṣe àfiwé ìkarahun náà sí àwọn ohun tí kò jẹ́ kí á ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Baba Ọ̀run. Báwo ni ṣe lè ṣí ọkàn wa sí I?
-
Ẹ tún lè wo àwòrán Olùgbàlà papọ̀ kí ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ yín àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n yìó lò làti ṣe àpèjúwe Rẹ̀. Ẹ pè wọ́n láti wá àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe àpèjúwe Rẹ̀ nínú Orin Dáfídì 86:5, 13, 15. Kínìdí tí ó fi ṣe pàtàkì láti mọ nkan wọ̀nyí nípa Rẹ̀?
Orin Dáfídì 61:2–3
Jésù Krístì ni àpáta mi.
-
Àwọn ọmọ yín lè gbádùn yíya àwòrán àwọn àmì tó wà nínú Orin Dáfídì 61:2–3. Báwo ni Jésù Krístì ṣe dà bí “àpáta” gíga (ẹsẹ 2), “àgọ́ kan,” àti “ìṣọ́ alágbára”? (ẹsẹ 3).
“Ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò fún mi, àti ilé-ìṣọ́ agbára” (Orin Dáfídì 61:3).
Orin Dáfídì 66:16; 77:11; 78:6–7
“Èmi yíò rántí iṣẹ́ Olúwa.”
-
Ẹ ní kí àwọn ọmọ yín ṣe àbápín àwọn kan lára àwọn ìtàn ìwé mímọ́ tí wọ́n fẹ́ràn (àwọn àwòrán látinú Ìwé àwòrán Ìhìnrere lè ṣe ìrànwọ́). Kíni àwọn ìtàn wọ̀nyí kọ́ wa nípa Olúwa? Ẹ lè ka Orin Dáfídì 66:16 papọ̀ kí ẹ sì máa dáhùn ìbéèrè náà “Kíni Olúwa ṣe fún ọkàn mi”?
-
Bí ẹ ṣe nka Orin Dáfídì 77:11; 78:6–7 papọ̀, ẹ lè ṣe àbápín pẹ̀lú ara yín bí ẹ ṣe ngbìyànjú láti “rántí àwọn iṣẹ́ Olúwa” (Orin Dáfídì 77:11), pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ Rẹ̀ nínú ìgbésí-ayé yín. Báwo ni oúnjẹ Olúwa ṣe nràn wá lọ́wọ́ láti “rántí nígbàgbogbo”? (Mórónì 4:3; 5:2).
Orin Dáfídì 71:8
Mo lè sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Jésù Krístì.
-
Lẹ́hìn kíka Orin Dáfídì 71:8 pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, pè wọ́n láti ya ẹnu nlá. Ẹ bèèrè lọ́wọ́ wọn láti ṣe ìrànwọ́ fún yín láti “kun” ẹnu pẹ̀lú àwọn àwòrán tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó nṣe àfihàn àwọn ohun tí a lè sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Jésù Krístì.
-
Ẹ lè yí àwòrán Jésù Krístì káàkiri. Ẹnití ó ndi àwòrán náà mú lè sọ ohun kan tí wọ́n mọ̀ nípa Rẹ̀. Báwo ni a ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ nkan wọ̀nyí?
Àwọn ọmọdé ní púpọ̀ láti pín. “Bí àwọn ọmọdé bá kọ́ ẹ̀kọ́ ohun titun, wọ́n máa nfẹ́ láti ṣe àbápín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ẹ gba ìfẹ́inú yí níyànjú nípa fífún àwọn ọmọdé ní ànfàní láti kọ́ àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere sí ara wọn, àwọn ọmọ ẹbí wọn, àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Ẹ tún ní kí wọn ṣe àbápín àwọn èrò, ìmọ́lára, àti àwọn ìrírí wọ́n tí ò ní íṣe pẹ̀lú àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ tí ẹ̀ nkọ́. Ẹ̀yin yíò rí i pé wọ́n ní ìjìnlẹ̀ ìwòye tí ó rọrùn, mímọ́, àti alágbára” (Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà, 32).
Orin Dáfídì 86:17
Baba Ọ̀run ngbọ́ ó sì ndáhùn àwọn adúrà mi
-
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orin Dáfídì náà dàbí àdúrà sí Ọlọ́run. Bí ẹ ṣe nka Orin Dáfídì pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, ẹ lè fi àwọn nkan ti a lè lò láti bá àwọn ènìyàn tó jìnnà sọ̀rọ̀ hàn wọ́n, bíi irú fóònù kan tàbí lẹ́tà kan. Nígbànáà ẹ ka Orin Dáfídì 86:7. Báwo ni a nṣe “nké pe” Baba Ọ̀run? Báwo ni Ó ṣe ndá wa lóhùn?
-
Ẹ lè kọ orin kan papọ̀ nípa àdúrà, bíi irú “Àdúrà Ọmọdé” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọ, 12–13; bákanáà wo Susan H. Porter, “Gbàdúrà, Ó Wà Níbẹ̀,” Làìhónà, Oṣù karun 2024, 77–79). Ẹ sọ fún ara yín nípa àwọn àkókò tí Ọlọ́run dáhùn àdúrà yín.
Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .
Wá sí ọ́dọ̀ Jésù, láti ọwọ́ Casey Childs