“Àwọn Èrò láti Tọ́jú sí Ọkàn: Kíka Ewì nínú Májẹ̀mú Láéláé,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Kíka Ewì nínú Májẹ̀mú Láéláé,” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Àwọn Èrò láti Tọ́jú sí Ọkàn
Kíka Ewì nínú Májẹ̀mú Láéláé
Nínú àwọn ìwé Májẹ̀mú Láéláé ti Gẹ́nẹ́sísì nípasẹ̀ Ẹ́stérì, a rí púpọ̀ jùlọ àwọn ìtàn—àlàyé àkọsílẹ̀ tí ó ṣe àpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti-ìtàn látinú ìrísí ti ẹ̀mí. Nóàh kan ọkọ̀, Mósè gbà Ísráẹ́lì là, Hánnàh gbàdúrà láti bí ọmọkùnrin, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Jóbù, a rí ọ̀nà ìkọ̀wé yíyàtọ̀. Nínú àwọn ìwé wọ̀nyí, àwọn olùkọ̀wé Májẹ̀mú Láéláé yíjú sí èdè ewì láti fi ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ hàn tàbí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nlánlà ní ọ̀nà mánigbàgbé.
A ti rí àwọn àpẹrẹ díẹ̀ ti ewì tí a fọ́n káàkiri gbogbo àwọn ìwé ìtàn ti Májẹ̀mú Láéláé. Látinú ìwé Jóbù síwájú, a ó rí púpọ̀ sí i nínú rẹ̀. Gbogbo àwọn ìwé Jóbù, Orin Dáfídì, àti Ìwé Òwe fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ewì pátápátá, gẹ́gẹ́bí àwọn apákan ìwé ti wòlíì bíi Ìsàíàh, Jeremíàh àti Ámósì. Nítorí pé ewì kíkà yàtọ̀ sí kíka ìtàn kan, òye rẹ̀ máa nbèèrè fún ọ̀nà yíyàtọ̀. Ní ìhín ni àwọn kan lára àwọn èrò tí ó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti wá ìtumọ̀ púpọ̀ síi nínú ewì Májẹ̀mú Láéláé.
Wíwá láti Mọ Ewì Hébérù
Ní Àkọ́kọ́, ó lè ràn yín lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ewì Hébérù nínú Májẹ̀mú Láéláé kò dá lórí orin àlùkọ, bí irú ewì míràn. Àti pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìró, eré-àsọyé, àti ìró àtúnwí jẹ́ ẹ̀yà tí ó wọ́pọ̀ nínú ewì Hébérù àtijọ́, àwọn nkan wọ̀nyí ni a máa nsábà pàdánù nínú ìtumọ̀. Ẹ̀yà kan ti ẹ̀yin yíò ṣe àkíyèsí, síbẹ̀síbẹ̀, ní títúnwí àwọn èrò tàbí àwọn ìmọ̀ràn, nígbàkan tí a pè ní “ìbájọra.” Ní ìhín ni àpẹrẹ tí ó rọrùn látinú Ìsàíàh:
Gbé okun rẹ wọ̀, A Síónì;
gbé aṣọ ẹwà rẹ wọ̀, A! Jerúsálẹ́mù. (Ìsàíàh 52:1)
Orin Dáfídì 29 ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlà ìbájọra—fún àpẹrẹ:
Ohùn Olúwa ní agbára;
ohùn Olúwa kún fún ọlánlá. (Orin Dáfídì 29:4)
Àti pé nihin ni àpẹrẹ ibití mímọ̀ pé ìlà kejì ní ìbájọra sí àkọ́kọ́ jẹ́ kí ẹ̀sẹ ọ̀rọ̀ náà rọrùn láti ní òye:
Mo sì ti fún ọ ní ẹyín mímọ́ tónítóní nínú gbogbo ìlú yín.
àti àìní oúnjẹ ní gbogbo àyè yín. (Ámósì 4:6)
Nínú àwọn àpẹrẹ wọ̀nyí, akéwì tún èrò kan ṣe pẹ̀lú àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀. Ìlànà yí lè tẹnumọ́ èrò títúnṣe àti láti lo àwọn ìyàtọ láti ṣe àpèjúwe ní kíkun tàbí ṣe ìdàgbàsókè rẹ̀.
Ní àwọn ọ̀ràn míràn, àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ ìbájọra tí ó báramu láti fúnni ní àwọn èrò yíyàtọ̀, gẹ́gẹ́bí inú àpẹrẹ yí:
Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ nyí ìbínú padà:
ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ lílè nrú ìbínú sókè. (Ìwé Òwe 15:1)
Irú ìbárajọ yí kò ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ ìjàmbá. Àwọn olùkọ̀wé mọ̀ọ́mọ̀ ṣe é. Ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sọ ìmọ̀lára ti ẹ̀mí tàbí òtítọ́ jáde pẹ̀lú agbára àti ẹwà. Nítorínáà nígbàtí ẹ bá ṣe àkíyèsí ìbájọra nínú kíkọ Májẹ̀mú Láéláé, ẹ bi ara yín léèrè bí ẹ ṣe ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti ní òye olùkọ̀wé ọ̀rọ̀ náà. Fún àpẹrẹ, kíni Ìsàíàh ti lè máa gbìyànjú láti sọ ní fífi “okun” pẹ̀lú “ẹ̀wù ẹlẹ́wà” àti “Síónì” pẹ̀lú “Jerúsálẹ́mù wéra”? (Ìsàíàh 52:1). Kíni a lè ní lọ́kàn nípa gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “ìdáhùn pẹ̀lẹ́” bí a bá mọ̀ pé “ àwọn ọ̀rọ̀ líle” ni òdìkejì rẹ̀? (Ìwé Òwe 15:1).
Ó Mú Ọkàn Mi Padàsípò, láti ọwọ́ Walter Rane
Ewì Hébérù bí Ọ̀rẹ́ Titun Kan
Àwọn míràn ṣe àfiwé ewì kíkà sí pípàdé ẹnìkan titun. Kíka àwọn ewì Májẹ̀mú Láéláé, nígbànáà, lè dà bí pípàdé ẹnìkan láti orílẹ̀-èdè jíjìnnà àti àṣà àjèjì kan tí wọ́n nsọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa—tí ó sì ti lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì. Ẹni yí yíò sọ àwọn nkan tí a kò lóye ní àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n èyí kò túmọ̀ sí pé wọ́n kò ní ohunkóhun tí ó jẹ́ iyebíye láti sọ. A kàn nílò láti lo àkokò pẹ̀lú wọn, ní ìgbìyànjú láti wo àwọn ohun látinú àmì ojú-ìwò wọn. A lè ri pé nínú ọkàn wa, a ní òye ara wa gan dáradára. Bí a bá sì fi sùúrù àti ìyọ́nú hàn, ojúlùmọ̀ wa titun lè di ọ̀rẹ́ àtàtà níkẹhìn.
Nítorínáà, nígbàtí ẹ bá ka ẹsẹ ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ kan láti inú Ìsàíàh, fún àpẹrẹ, ẹ jẹ́ kí ó jẹ́ àyẹ̀wò fífihàn yín àkọ́kọ́ sí ojúlùmọ̀ titun kan. Ẹ bèère fúnara yín, “Kíni ìwọnilọ́kàn wíwọ́pọ̀ mi?“ Báwo ni ẹsẹ ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ kí ẹ ní ìmọ̀lára sí—pàápàá bí ẹ kò bá ní òye gbogbo ọ̀rọ̀? Lẹ́hìnnáà kàá lẹ́ẹ̀kansi, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà tí ó bá ṣeéṣe. Ẹ yẹ kíkà á jáde sókè; àwọn ènìyàn kan nrí àfikún ìtumọ̀ ní ọ̀nà náà. Ẹ ṣe àkíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ kan tí Ìsàíàh yàn, ní pàtàkì àwọn ọ̀rọ̀ tí ó fi àwòrán hàn nínú ọkàn yín. Báwo ni àwọn àwòrán wọnnì ṣe njẹ́ kí ẹ ní ìmọ̀lára? Kíni wọ́n dámọ̀ràn nípa ìmọ̀lára Ìsàíàh? Bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò síi nípa àwọn ọ̀rọ̀ ti àwọn olùkọ̀wé Májẹ̀mú Láéláé wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ni ẹ̀yin yíò ri pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ yan àwọn ọ̀rọ̀ àti àwọn ètò láti ṣe àfihàn ọ̀rọ̀ ti ẹ̀mí tí ó jinlẹ̀.
Àwọn ewì lè jẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ àgbàyanu nítorí wọ́n nṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti ní òye àwọn ìmọ̀lára àti àwọn ìrírí wa. Àwọn ewì Májẹ̀mú Láéláé jẹ́ iyebíye ní pàtàkì nítorí pé wọ́n ràn wá lọ́wọ́ láti ní òye ìmọ̀lára àti ìrírí wa tí ó ṣe pàtàkì jùlọ—àwọn tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìbáṣpọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run.
Bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò ewì nínú Májẹ̀mú Láéláé, ẹ rántí pé àṣàrò ìwé mímọ́ jẹ́ iyebíye jùlọ nígbàtí ó bá ndarí wa lọ sí ọ̀dọ̀ Jésù Krístì. Ẹ wá àwọn àmì, àwòran, àti àwọn òtítọ́ tí ẹ kọ́ ìgbàgbọ́ yín sínú Rẹ. Ẹ fetísílẹ̀ sí ìmísí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò.
Ọgbọ́n Lítíráṣọ̀
Ọ̀kan lára ẹ̀ka ewì Májẹ̀mú Láéláé ni ohun tí áwọn ọ̀mọ̀wé pè ní “ọgbọ́n lítíráṣọ̀.” Jóbù, Ìwé Òwe, àti Oníwàásù bọ́ sínú ẹ̀ka yìí. Bí àwọn orin Dáfídì ṣe nsọ àwọn ìmọ̀lára ìyìn, ọ̀fọ̀, àti ìjọsìn, àwọn ọgbọ́n lítíráṣọ̀ dá lé ìmọ̀ràn tí kò ní àkokò tàbí jinlẹ̀, ìbéèrè ti ìmòyè. Bí àpẹrẹ, ìwé Jóbù sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run àti ohun tó fa ìjìyà ẹ̀dá. Òwe nfúnni ní ìmọ̀ràn nípa bí a ṣe lè máa gbé ìgbé-ayé rere, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tí a kójọ àti tí ó ti kọjá láti àwọn ìran ìṣaájú. Oníwàásù sì béèrè èrèdí ìgbésí-ayé fúnrarẹ̀—nígbàtí ohun gbogbo bá dàbí èyítí kò já mọ́ nkan kan, ibo ni a ó ti rí ìtumọ̀ tòótọ́? Ẹ lè ronú àwọn ọgbọ́n lítíráṣọ̀ bí àwọn ìbárasọ̀rọ̀ tí ó nírònú pẹ̀lú àwọn alágbàtọ́ onimisi tí wọ́n fẹ́ láti ṣe àbápín àwọn àkíyèsí nípa Ọlọ́run àti ayé tí Ó ṣẹ̀dá—àti bóyá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti ní òye nkan wọ̀nyí dáradára díẹ̀ ju ti ìṣaájú lọ.