“Oṣù Kẹ́jọ 17–23. ‘Olúwa Ni Olùṣọ́-àgùntàn Mi’: Orin Dáfídì 1–2; 8; 19–33; 40; 46,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹ́jọ 17–23. ‘Olúwa Ni Olùṣọ́-àgùntàn Mi,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Olúwa Ni Olùṣọ́-àgùntàn Mi, láti ọwọ́ Yongsung Kim. Àwòrán ní ìtẹríba ti havenlight.com
Oṣù Kẹ́jọ 17– 23: “Olúwa Ni Olùṣọ́-àgùntàn Mi”
Orin Dáfídì 1–2; 8; 19–33; 40; 46
A kò mọ ẹnití ó kọ Orin Dáfídì dájú. Àwọn kan ni a kà sí fún Ọba Dáfídì, ṣùgbọ́n fún púpọ̀ jùlọ lára wọn, àwọn olùkọ̀wé náà ni a kò mọ orúkọ wọn. Síbẹ̀ lẹ́hìn kíka Orin Dáfídì, a máa nní ìmọ̀lára bí ẹni pé a mọ ọkàn àwọn onísáàmù, àní bí a kò tilẹ̀ mọ orúkọ wọn. A mọ̀ pé Orin Dáfídì jẹ́ ara pàtàkì kan nínú ìjọsìn ní àárín àwọn ọmọ Ísráẹ́lì, a sì mọ̀ pé Olùgbàlà máa nṣe ayọsọ wọn lọ́pọ̀ ìgbà. Nínú Orin Dáfídì, a gba fèrèsé kan sínú ọkàn àwọn ènìyàn Ọlọ́run àtijọ́. A rí bí wọ́n ṣe ní ìmọ̀lára nípa Ọlọ́run, ohun tí wọ́n ndààmú nípa àti bí wọ́n ṣe rí àláfíà. Gẹ́gẹ́bí onígbàgbọ́ ní ónì, káàkiri gbogbo ayé, a ṣì nlo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nínú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dà bíi pé àwọn tó kọ Sáàmù ní fèrèsé sínú ọkàn wa, nítorí pé wọ́n sọ bí a ṣe ní ìmọ̀lára nípa Ọlọ́run, ohun tí a ndààmú nípa, àti bí a ṣe rí àláfíà.
Fún àlàyé ṣókí nípa ìwé Orin Dáfídì, wo “Orin Dáfídì” nínú Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.
Àwọn ìmọ̀ràn fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ
Orin Dáfídì 1; 23; 26–28; 46
“Èmi ti ní igbẹ́kẹ̀lé … nínú Olúwa.”
Bí ẹ ṣe nka Orin Dáfídì, ẹ lè kíyèsí bí àwọn olùkọ̀wé náà ṣe nsọ̀rọ̀ ẹ̀rù, ìbànújẹ́, tàbí àníyàn léraléra tó. Irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun tí ó tọ́, àní fún àwọn ènìyàn ìgbàgbọ́ pàápàá. Ṣùgbọ́n ohun tí ó mú kí Orin Dáfídì ní ìwúrí ni pé wọ́n tún nfúnni ní àtúnṣe, pẹ́lú ìgbẹ́kẹ̀lé pípé nínú Olúwa. Bí ẹ ṣe nka Orin Dáfídì 1; 23; 26–28; 46, kọ sílẹ̀:
-
Àwọn ìfìwépè láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
-
Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe àpèjúwe Rẹ̀.
-
Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe àpèjúwe àláfíà, agbára, àti àwọn ìbùkún míràn tí Ó pèsè.
-
Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe àpèjúwe àwọn ènìyàn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé E.
Bákannáà ṣọ́nà fún àwòrán tí ó hàn gbanggba àti àwọn àmì tí Orin Dáfídì nlò láti kọ́ni nípa Olùgbàlà. Fún àpẹẹrẹ, ní Orin Dáfídì 23, kí ni àwọn gbólóhùn bíi “dùbúlẹ̀ ní pápá oko tútù” tàbí “omi dídákẹ́ rọ́rọ́” (ẹsẹ 2) mú wá sí ọkàn? Kíni “ọ̀pá” and “ọ̀gọ” ìtùnù náà lè (ẹsẹ 4) ṣàpẹrẹ? Kíni ó túmọ̀ sí kí “ago” wa (ẹsẹ 5) kún àkúnwọ́sílẹ̀?
Orin Dáfídì 2; 22
Jésù Krístì ní Mèssíàh tí a ṣèlérí.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orin Dáfídì náà tọ́ka sí ìgbé-ayé ikú ti Jésù Kristi. Àwọn Krìsténì ni àwọn àkókò Májẹ̀mú Titun rí àwọn ìsopọ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú. Ẹ yẹ kíka àwọn ìtọ́kasí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí wo. Wá àwọn ìsopọ̀ ní àárín àwọn ọ̀rọ̀ inú àwọn orin Dáfídì wọ̀nyí àti ìgbésí-ayé Olùgbàlà:
-
Orin Dáfídì 2:1–3 àti Ìṣe àwọn Àpóstélì 4:24–28
-
Orin Dáfídì 2:7 àti Ìṣe àwọn Àpóstélì 13:30–33
-
Orin Dáfídì 22:1 àti Máttéù 27:45–46
-
Orin Dáfídì 22:7–8 àti Máttéù 27:39–43
-
Orin Dáfídì 22:16 àti Lúkù 23:32–33
-
Orin Dáfídì 22:18 àti Máttéù 27:35
-
Orin Dáfídì 31:5 àti Lúkù 23:46
Kíni ẹ kọ́ nípa ṣíṣe àṣàrò àwọn ìsopọ̀ wọ̀nyí? Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ àti àwọn ìlérí wo ni kò tíì di mímúṣẹ síbẹ̀? Kí ni ẹ rí nínú àwọn ìlérí wọ̀nyí tí ó nfún yín ní ìrètí fún ọjọ́ iwájú?
Orin Dáfídì 8; 19; 33
“Ilẹ̀-ayé kún fún inúrere Olúwa.”
Kika Orin Dáfídì 8; 19; 33 lè mísí yín láti yẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ a`wọn ìṣẹ̀dá àgbàyanu ti Olúwa. Ẹ fi iyè sí ìmọ̀lára yín bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ tún lè fẹ́ kọrin tàbí jíròrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ orin kan tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn orin Dáfídì wọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí “Báwo ni O Ṣe Titóbi Tó” (Àwọn orin, 86). Báwo ni àwọn ìṣẹ̀dá Olúwa ṣe “kéde ògo Ọlọ́run” fún yín? (Orin Dáfídì 19:1).
Ní ìhín ni díẹ̀ nínú àwọn orin míràn tí ó ní ìmísí láti inú Orin Dáfídì:
-
Orin Dáfídì 23: “Olúwa Ni Olùsọ́-àgùtàn Mi” (Àwọn orin,, nọ́mbà 108)
-
Orin Dáfídì 23:6; 150: “Ọpẹ́ ni fún Olúwa, Olódùmarè” (Àwọn orin, nọ́mbà 72)
-
Orin Dáfídì 26:8: “A nifẹ Ilè Rẹ, Ọlọ́run” (, nọ́mba 247)
-
Orin Dáfídì 27:1: “Olúwa Ni Ìmọ́lẹ̀ Mi” (Orin Dáfídì, nọ́mbà 89)
-
Orin Dáfídì 33:1–6; 95:1–6: “Fún Ẹwà Ayé” (Àwọn Orin, nọ́mbà 92)
-
Orin Dáfídì 37:3–9: “Duro, Ọkàn mi” (Àwọn Orin, nọ́mbà 124)
-
Orin Dáfídì 148: “Gbogbo Ẹ̀dá Ọlọ́run àti Ọba wa” (Àwọn Orin, nọ́mbà 62)
Lo Orin. Ààrẹ Dallin H. Oaks wípé: “Kíkọ àwọn orin jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó dárajùlọ láti fi ara wa sípò pẹ̀lú Ẹ̀mí Olúwa. … Orin mímọ́ ní agbára aláìlẹ́gbẹ́ láti sọ àwọn ìmọ̀lára ìfẹ́ wa fún Olúwa. Irú ìbárasọ̀rọ̀ yi jẹ́ ìrànwọ́ àgbàyanu fún ìjọsìn wa. … Àwọn orin wa ni àwọn ẹ̀kọ́ oníwàásù tí kò ní afiwe, tí ó kọjá nípasẹ̀ àwọn ìwé mímọ́ nìkan nínú òtítọ́ wọn àti ipa ewì” (“Ìjọsìn Nípasẹ̀ Orin,” Ẹ́nsáìn, Oṣù kọkànlá 1994, 10, 11). Àwọn orin tí ó bá Orin Dáfídì mu ni ẹ lè gbọ́ tàbí kọ láti mú ìsìn yín dára si ní ọ̀sẹ̀ yi?
Orin Dáfídì 19:7–11; 29
Ọ̀rọ̀ Olúwa lágbára, “ó nmú ọkàn yọ̀.”
Nínú Orin Dáfídì, àwọn ọ̀rọ̀ bíi ẹ̀rí, ìlànà, òfin, àti ìdájọ́ lè tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Olúwa. Ẹ pa èyí mọ́ sí ọkàn bí ẹ ṣe nka Orin Dáfídì 19:7–11. Kíni àwọn ẹsẹ yi dábàá fún yín nípa àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa? Kíni Orin Dáfídì 29 kọ yín nípa ohùn Rẹ̀? Nínú ìrírí yín, báwo ni ọ̀rọ̀ náà tàbí ohùn Olúwa ṣe bá àwọn àpèjúwe wọ̀nyí mu?
Orin Dáfídì 24; 26–27
Olùgbàlà lè rànmílọ́wọ́ láti jẹ́ mímọ́ kí èmi lè wọ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Nítorí pé a kọ́ tẹ́mpìlì ní Jérúsálẹ́mù sí orí òkè, gbólóhùn ọ̀rọ̀ “orí òkè Olúwa” (Orin Dáfídì 24:3) lè tọ́kasí tẹ́mpìlì tàbí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Kíni èyí fikún òye ti Orin Dáfídì 24? Kíni ó túmọ̀sí fún yin láti ní “ọwọ́ mímọ́, àti àyà funfun”? (ẹsẹ 4). Bí ẹ ṣe nka Orin Dáfídì 26–27, kí ni ohun míràn tí ẹ tún kọ́ nípa ilé Olúwa?
Nígbà míràn, a lè ní ìrẹ̀wẹ̀sì láti gbọ́ pé a nílò láti jẹ́ mímọ́ láti wọ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Lẹ́hìnnáà, gbogbo wa ṣá ntiraka, kò sì sí ọ̀kan nínú wa tí ó jẹ́ pípé. Ìrètí wo ni ẹ ri nínú ọ̀rọ̀ Alàgbà David A. Bednar “Ọwọ Mímọ́ àti Ọkàn Mímọ́”? (Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2007, 80–83). Báwo ni ẹ ṣe lè lo ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti ran ẹnìkan tí ó nfẹ́ láti jẹ́ ẹni pípé lọ́wọ́? Ẹ yẹ bí ẹ ṣe lè rí ìrànlọ́wọ́ Olùgbàlà gbà nínú ìtiraka yín láti ní “ọwọ́ mímọ́, àti ọkàn mímọ́ wò.”
Bákannáà wo Bradley R. Wilcox, “Jíjẹ́ yíyẹ Kìí Ṣe Àìlábàwọ́n,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2021, 61–67.
Fún díẹ̀ si, ẹ wo àwọn ìwé ìròhìn àtẹ̀jáde oṣù yi ti Làìhónà àti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ̀ .
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Orin Dáfídì 23; 27–28; 32; 46
Olúwa fún mi ní àláfíà, okun, àti ìtọ́sọ́nà.
-
Ẹ yẹ kíkọ Olúwa ni wo … Ẹ pe àwọn ọmọ yín láti wá àwọn ọ̀nà láti parí gbólóhùn náà ní lílo àwọn ìwé mímọ́ bíi ìwọ̀nyí: Orin Dáfídì 23:1; 27:1; 28:1; 28:7; 32:7; 46:1. Kíni àwọn ẹsẹ yi kọ́ wa nípa bí Olúwa ṣe lè rànwálọ́wọ́?
-
Ẹ lè jíròrò pẹ̀lú àwọn ọmọ yín ohun ti ọ̀dọ́-àgùtàn nílò láti wà ní àìléwu àti ìlera. Lẹ́hìnnáà, bí ẹ ṣe nka Orin Dáfídì 23, papọ̀, ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti fi ohun tí olùṣọ́-àgùntàn ṣe fún ọ̀dọ́-àgùntàn wé ohun tí Jésù ṣe fún wa. Kíni a nílò láti ṣe kí á lè wà ní àìléwu àti ìlera nípa ti ẹ̀mí? Ẹ kọ orin kan papọ̀ tí ó lè fún wọn ní àwọn èrò, gẹ́gẹ́bí “Mo Ní Ìmọ̀lára Ìfẹ́ Olùgbàlà Mi” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 74–75).
Tẹ́mpìlì Concepción Chile
Orin Dáfídì 24: 3–4
Láti wọ tẹ́mpìlì, a nílò “ọwọ mímọ́ àti ọkàn mímọ́.”
-
Bí ẹ ṣe nka Orin Dáfídì 24:3 papọ̀, àwọn ọmọ yín lè wá àwọn ọ̀rọ̀ tó ràn wọn létí nípa tẹ́mpìlì. Wọ́n tún lè wo àwòrán Jésù nípa tẹ́mpìlì kan. Lẹ́hìnnáà ẹ lè ka ẹsẹ 4 papọ̀ láti kọ́ nípa ẹni tí ó lè wọ tẹ́mpìlì. Ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa bí ọwọ́ ṣe ndọ̀tí àti bí a ṣe nsọ́ di mímọ́. Báwo ni a ṣe lè dọ̀tí nípa ti ẹ̀mí? Báwo ni Olùgbàlà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti di mímọ́ nípa ti ẹ̀mí?
Orin Dáfídì 30:5
Jésù Krístì lè sọ ìbànújẹ́ di ayọ̀.
-
”Bí ẹ bá ní àwọn ọmọdé, ẹ lè pè wọ́n láti díbọ́n bí ẹni pé wọ́n nsunkún nígbàtí ẹ bá nka látinú Orin Dáfídì 30:5, “Bí ẹkún pẹ́ di alẹ́ kan.” Nígbànáà ẹ wí fún wọn kí wọ́n fi ayọ̀ hàn bí ẹ ṣe nka, “Ṣùgbọ́n ayọ̀ nbọ̀ ní òwúrọ̀.” Ẹ tún gbólóhùn yi sọ fún ìgbà díẹ̀.
-
Ṣe àfihàn àwòrán Olùgbàlà, kí ẹ sì sọ fún àwọn ọmọ yín ohun tí Ó ti ṣe fún yín tí ó nmú ayọ̀ wá fún yín. Ẹ tún lè fún ọmọ kọ̀ọ̀kan ní ààyè láti di àwòrán náà mú kí ẹ sì ṣe àbápín ohun tí Jésù ti ṣe tó múnú wọn dùn.
Orin Dáfídì 46:10
“Dúró Jẹ́ẹ́, Kí O Sì Mọ̀ Pé Èmi Ni Ọlọ́run”
-
Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ ìlà àkọ́kọ́ sórí nínú Orin Dáfídì 46:10: “Dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run.” Kíni ló lè túmọ̀ sí láti “dúró jẹ́ẹ́”? Bóyá ẹ lè lo àkókò díẹ̀ láti ṣe ìgbáradì dídúró jẹ́ẹ́. Ẹ tún lè ṣe àbápín ìrírí fún ara yín pẹ̀lú nígbàtí ẹ bá “ndúró jẹ́ẹ́” nfún àjọṣe yín pẹ̀lú Ọlọ́run lágbára sí i. Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn àkókò ní ọ̀sán nígbàtí wọ́n lè “dúró jẹ́ẹ́” láti ní ìmọ̀lára sísún mọ́ Baba Ọ̀run.
Fún díẹ̀ sí i, woìwé-ìròhìn àtẹ̀jáde oṣù yí ti Fríẹ́ndì .