“Oṣù Kẹ́jọ 3–9. ‘Ìwọ́ Ti Wá … nítorí Àkókò Báyìí’: Ẹ́sítérì,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹ́jọ 3–9. ‘Ìwọ́ Ti Wá … nítorí Àkókò Báyìí,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Ẹ́stérì Ayaba Gbà Àwọn Ènìyàn Jèhófà là, láti ọwọ́ Sam Lawlor
Oṣù Kẹ́jọ 3–9: “Ìwọ́ Ti Wá … nítorí Àkókò Báyìí”
Ẹ́stérì
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú ìwé Ẹ́stérì lè dà bíi oríire tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ lásán. Báwo ni ẹ tún ṣe lè ṣe àlàyé bí ọmọbìnrin Júù kan tó jẹ́ aláìníòbí ṣe di ayaba Páṣíà ní àkokò tó yẹ láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là lọ́wọ́ ìpakúpa? Kíni àyè tí ó wà pé Módékáì tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Ẹ́sítérì lè gbọ́ ètò ìdìtẹ̀sí láti pa ọba? Ṣé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ lásán, tàbí wọ́n jẹ́ ara ètò àtọ̀runwá? Alàgbà Ronald A. Rasband ṣe àkíyèsí pé: “Ohun tí ó lè dà bí ipò ààyè lásán ni, nítòótọ́, nṣe a`bójútó nípasẹ̀ olùfẹ́ni Baba ní Ọ̀run. … Olúwa wà nínú àwọn àlàyé kékeré ti ìgbésí-ayé wa” (“Nípasẹ́ Àwòṣe Àtọ̀runwá,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2017, 56). A lè má ṣe ìdámọ̀ ipa Olúwa nígbàgbogbo nínú “àwọn àlàyé kékeré wọ̀nyí.” Ṣùgbọ́n a kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìrírí Ẹ́stérì pé Ó lè ṣe amọ̀nà ipa ọ̀nà wa kí a sì múra wa sílẹ̀ “fún irú àkókò bẹ́ẹ̀” (Ẹ́stérì 4:14) nígbàtí a lè jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Rẹ̀ láti mú àwọn èrò Rẹ̀ ṣẹ.
Fún àlàyé ṣókí nípa ìwé Ẹ́stérì, wo “Ẹ́stérì, ìwé ti” nínú Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.
Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ
Ẹ́stérì
Olúwa fi mí sínú àwọn ipò níbití mo ti lè bùkún àwọn ẹlòmíràn.
Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf kọ́ni pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa “ndúró ní ibi aláìláfiwé kan a sì ní iṣẹ́ pàtàkì kan tí [àwa] nìkan lè ṣe. … Olúwa fún yín ní àwọn ojúṣe yín fún èrèdí kan. Àwọn ènìyàn àti àwọn ọkàn lè wà tí ó jẹ́ wípé ẹ̀yin níkan ni ẹ lè nawọ́ láti fọwọ́kàn. Bóyá kò sí ẹlòmíran tí ó lè ṣe ní irú ọ̀nà kannáà” (“Gbé Níbi Tí O Dúró,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2008, 56).
Bó ẹ ṣe nka ìtàn Ẹ́stérì, ẹ jíròrò nípa bí ọ̀rọ̀ náà ṣe wúlò sí i. Ẹ wá àwọn ọ̀nà tí Olúwa fi mú ṣeéṣe fún un láti gba àwọn Júù là (wo, fún àpẹrẹ, Ẹ́stérì 2:21–23; 3:10–14; 4:14–16). Lẹ́hìnnáà ronú lórí bí Ó ṣe fún yín ní àwọn ànfàní láti bùkún àwọn ẹlòmíràn. Kíni díẹ̀ nínú àwọn ipò tàbí àwọn ìbáṣepọ̀ tí Ó ti tọ́ yín sọ́nà sí “fún àkókò báyìí”? (Ẹ́stérì 4:14). Bí ẹ bá ti ní ì̀bùkún ti babanlá kan, ẹ yẹ kíkà rẹ̀ láti kọ́ ẹkọ síi nípa iṣẹ́ tí Olúwa ní fún yín láti ṣe. Kíni ẹ lè ṣe láti ṣe àṣeyọrí iṣẹ́ yi?
Bákannáà wo “Fún Irú Àkókò bí Èyí” (fídíò), ChurchofJesusChrist.org.
For Such a Time as This
A kọ́ ẹkọ síi nípa ṣíṣe ju nípa gbígbọ́ lọ. Alàgbà David A. Bednar gba àwọn olùkọ́ nímọ̀ràn pé: “Èrò-inú wa kò yẹ kí ó jẹ́ ‘Kíni kí nsọ fún wọn?’ Dípò bẹ́ẹ̀, àwọn ìbéèrè tó yẹ ká bi ara wa ni ‘Kíni mo lè pè wọ́n láti ṣe? Àwọn ìbéèrè onímìísí wo ni mo lè béèrè pé, bí wọ́n bá fẹ́ láti dáhùn, yíò bẹ̀rẹ̀ sí í pe Ẹ̀mí Mímọ́ sínú ìgbésí-ayé wọn?’” (nínú Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà, 25). Bí ẹ bá nkọ́ ẹbí yín tàbí kíláàsì kan nípa Ẹ́stérì, kíni ẹ lè ní kí wọ́n ṣe tí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ ẹkọ?
“Nígbàtí Hámánì ri pé Mọ́dékáì kò tẹríba … nígbànáà ni Hámánì kún fún ìbínú” (Ẹ́stérì 3:5).
Ẹ́stérì 3; 5:9–14; 7
Ìgbéraga àti ìbínú lè fa ìṣubú.
Nínú ìwé Ẹ́stérì, a kọ́ ẹ̀kọ́ látinú ìṣòtítọ́ ti Ẹ́stérì àti Mọ́dékáì, ṣùgbọ́n a tún kọ́ ẹ̀kọ́ látinú ìgbéraga àti ìbínú Hámánì Bí ẹ ṣe nka Ẹ́stérì 3; 5:9–14, ẹ ṣe àkíyèsí ìmọ̀lára, ọ̀rọ̀, àti ìṣe Hámánì. Kíni wọ́n fi hàn nípa rẹ̀ àti àwọn ìwúrí tẹ̀? Àwọn àbájáde wo ni ó dojúkọ? (wo Ẹ́stérì 7). Kíka nípa Hámánì lè ṣí yín létí láti ṣe àyẹ̀wò ohun tó nwú àwọn ìmọ̀lára àti ìṣe yín. Njẹ́ ẹ nní ìmísí láti ṣe àwọn àyípadà èyíkèyí? Báwo ní ẹ ṣe lè yípadà sí Baba Ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́?
Bákannáá wo Ìwé Òwe 16:32; Álmà 5:28.
Ẹ́stérì 3–4; 5:2–3; 8:11–12
Àwẹ̀ fihàn wípé mo gbẹ́kẹ̀lé àti gbójúlé Olúwa.
Kíyèsí ìdí tí Ẹ́stérì àti àwọn Júù yòókù fi pinnu láti gbàwẹ̀ (wo Ẹ́sítérì 3:13; 4:1–3, 10–17). Báwo ni ààwẹ̀ ṣe bùkún wọn? (see Ẹ́stérì 5:2–3; 8:11–12). Kínìdí tí Olúwa fi ní ká gbàwẹ̀? (wo Àwọn Àkòrí àti Ìbéèrè, “Gbígbàwẹ̀ àti Ọrẹ Àwẹ̀,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere). Gbéró bí ẹ ṣe lè sọ àwẹ̀ di ìbùkún nlá nínú ìgbésí ayé yín.
Bákanáà wo Ìsàíàh 58:6–12; “Gbígbàwẹ̀: Wọ́ọ̀dù Ọ̀dọ́ Àdánìkanwà, Amanda” (fídíò), ChurchofJesusChrist.org.
Fasting: Young Single Adult Ward, Amanda
Ẹ́stérì 3:1–11; 4:10–17; 5:1–4; 9:17–19
Ṣíṣe ohun tó tọ́ sábà máa gba ìgboyà nlà.
Nígbàtí Módékáì àti Ẹ́stérì dìde dúró fún ìgbàgbọ́ wọn àti àwọn ènìyàn wọn, wọ́n fi ẹ̀mí wọn sínú ewu. Àwọn yíyàn wa lè ní àwọn àbájáde tí kò lágbára, ṣùgbọ́n ṣíṣe ohun tí ó tọ́ tún lè nílò ìgboyà. Kíni ẹ kọ́ látinú Ẹ́stéri 3:1–4; 4:10–17 nípa níní ìgboyà láti ṣe ohun tí ó tọ́? Ẹ kíyèsí àwọn àbájáde oríṣiríṣi tí Módékáì àti Ẹ́stérì ní ìrìírí lẹ́hìn fífi ìgboyà hàn (wo Ẹ́stérì 3:5–11; 5:1–4). Kíni Ẹ́stérì àti Módékáì ní láti mọ̀ nípa Ọlọ́run kí wọ́n tó lè ṣe yíyàn wọ́n?
Ẹ ronú nípa àwọn ipò níbití ẹ ti nílò ìgboyà láti dúró fún ohun tí ó tọ́. Kíni ẹ kọ́ lára Ẹ́stérì àti Módékáì tó lè ràn yín lọ́wọ́ láti ní ìgboyà nínú Olúwa?
Ìgbójú Ẹ́stérì darí sí “ọjọ́ aláyọ̀ kan” (wo Ẹ́stérì 9:17–19). Báwo ni ìgboyà bíi ti Kristi ṣe nfún yín ní “ọjọ́ aláyọ̀ kan”?
Bákannáà wo “Ìgboyà,” “Ṣe Àgbọdọ̀ láti Dá Dúró” (fídíò), Ibi Ìkàwé Ìhìnrere; “Òtítọ́ sí Ìgbàgbọ́,” Àwọn orin, nọ́mbà 254.
Courage
Dare to Stand Alone
Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde àwọn ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Làìhónà àti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Éstérì 2:5–7
Mo lè sin ẹbí mi.
-
Ẹ lè ní ìmọ̀lára ìmísí láti lo Ẹ́stérì 2:7 láti kọ́ àwọn ọmọ yín nípa ríran àwọn ọmọ ẹbí tí wọ́n wà nínú ìṣòro lọ́wọ́, bíi Módékáì ti ṣe fún Ẹ́stérì. Ẹ lè ka ẹsẹ náà papọ̀ tàbí ṣe àkópọ̀ rẹ̀ ní ọ̀rọ̀ tìyín. Lẹ́hìnnáà ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè ronú nípa àwọn ọmọ ẹbí tí wọ́n lè nílò ìrànlọ́wọ́ yín. Ẹ ṣe ètò láti ràn wọ́n lọ́wọ́.
Éstérì 3:1–11; 4:10–17
Olúwa lè ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìgbójú.
-
Àpẹrẹ Ẹ́stérì àti Mọ́dékáì lè ràn àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye pé ìgbójú túmọ̀ sí ṣíṣe ohun tí ó tọ́ pàápàá nígbàtí ẹ bá nbẹ̀rù. Ẹ yẹ kíkọ àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ Mọ́dékáì jẹ́ onígboyà nígbàtí ó … àti pé Ẹ́stérì náà ní ìgbóyà nígbàtí ó … . Bí ẹ ṣe nkọ́ ẹkọ ìtàn Ẹ́stérì papọ̀, àwọn ọmọ yín lè dámọ̀ràn àwọn ọ̀nà láti parí àwọn gbólóhùn náà. Ẹ tún lè ka Ẹ́stérì 3:1–11; 4:10–17 or “Ẹ́stérì” (nínú Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 166–70) tàbí wo àwọn àwòrán inú àtòkọ yi. Nígbànáà ẹ kọ Èmi yíò nígbòjú nípasẹ̀ … , àti pe ẹ pe àwọn ọmọ yín láti ṣe àtòkọ àwọn ohun tí Baba Ọ̀run nfẹ́ kí wọ́n ṣe tí ó nílò ìgboyà. Orin kan nípa ìgboyà, bíi “Gbójú láti Ṣe Ohun Tótọ́” (Ìwé Orin Àwọn ọmọdé, 158), lè ṣe ìrànlọ́wọ́.
2:45Queen Esther
-
Ẹ tún lè kọ́ ẹ́kọ́ nípa àwọn ìgbà tí Jésù Krístì jẹ́ onígboyà—fún àpẹrẹ, nígbàtí Ó jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wa ní Gẹ́tsémánì àti lórí àgbélèbú (wo Máttéù 26:36–39; 27:33–35). Ẹ ní kí àwọn ọmọ yín ṣe àbápín àkókò kan nígbàtí wọ́n gbójú, kí ẹ sì ṣe àbápín àwọn ìrírí tiyín pẹ̀lú.
Ẹ́stérì 4: 1–3, 10–17
Gbígbàwẹ̀ nmú ìbùkún Olúwa wá.
-
Kíka Ẹ́stérì 4:1–3, 10–17 lè ràn ẹyín lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ yín nípa gbígbàwẹ̀. Kínìdí tí Ẹ́stérì àti àwọn Júù fi gbàwẹ̀? Ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín ìdí tí ẹ fi ngbàwẹ̀. Ẹ tún lè bèèrè lọ́wọ́ wọn bí wọn yíò ti ṣe ṣàlàyé àwẹ̀ fún ọ̀rẹ́ kan tí kò tíì ṣeé rí. Báwo ni a ṣe lè ran àwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́wọ́ láti ní òye àwọn ìbùkún tó nwá látinú àwẹ̀?
-
Ẹ gba àwọn ọmọ yín níyànjú láti ronú nípa ohunkan tí wọ́n lè nílò ìrànlọ́wọ́ Olúwa fún. Ẹ dá àbá pé kí wọ́n mú èyí jẹ́ ara kan ti àwẹ̀ wọn ní àkokò ọjọ́ Ìsinmi àwẹ̀ tó nbọ̀.
Nítorí pé Ẹ́stérì jẹ́ onígboyà, ó ṣeé ṣe fún un láti gba àwọn ènìyàn Olúwa là.
Ẹ́stérì 4:14
Mo lè jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run.
-
Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye pé nígbàtí Ẹ́stérì bẹ̀rù, Módékáì gbà á níyànjú nípa ṣíṣe àlàyé pé Olúwa ti ràn án lọ́wọ́ láti di ayaba “fún irú àkókò bí èyí” (Ẹ́stérì 4:14). Kíni Módékáì ní lọ́kàn nípa èyí? Ẹ bá ara yín sọ̀rọ̀ nípa bí Ẹ́stérì ṣe jẹ́ ohun èlò fún Olúwa. Báwo ni ẹ ṣe lè jẹ́ ohun èlò fún Olúwa?
-
Báwo ni ẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye kíni ohun tí ohun-èlò jẹ́? Bóyá ẹ lè pe ẹnìkan láti fi ohun èlò ìkọrin kan kọ orin kan tàbí kí ẹ fi àwòrán ẹnìkan tí ó nlo irinṣẹ́ kan hàn. Lẹ́hìnnáà ẹ lè sọ nípa ohun tí ó túmọ̀ sí láti jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run.
Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .