“Oṣù Kẹ́jọ 10–16. ‘Síbẹ̀ Èmi Ó Máa Gbẹ́kẹ̀lé E’: Jóbù 1–3; 12; 19–24; 40; 42,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹ́jọ 10–16. ‘Síbẹ̀ Èmi Ó Máa Gbẹ́kẹ̀lé E,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Àwọn Ìdájọ́ Jóbù, nípasẹ̀ Joseph Brickey
Oṣù Kẹ́jọ 10– 16:“Síbẹ̀ Èmi Ó Máa Gbẹ́kẹ̀lé E”
Jóbù 1–3; 12–14; 19; 21–24; 38–40; 42
Ó bá ọ́gbọ́n mu láti ní ìyàlẹ́nu ìdí tí àwọn ohun búburú fi nṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rere—tàbí, ní ti ọ̀ràn náà, ìdí tí ohun rere fi nṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn búburú. Kínìdí tí Ọlọ́run tó jẹ́ olódodo yíò fi fàyè gba èyí? Ìwé Jóbù ṣe ìwákiri àwọn ìbéèrè bíi wọ̀nyí. Jóbù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn rere tí ọ̀pọ̀ nkan burúkú ṣẹlẹ̀ sí. Nítorí àdánwò Jóbù, ó ya àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́nu bóyá òun jẹ́ ẹni rere lẹ́hìnnáà. Jóbù fi òdodo ara rẹ̀ múlẹ̀ ó sì ní ìyàlẹ́nú bóyá lootọ ni Ọlọ́run jẹ́ dídára lẹ́hìnnáà. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìjìyà àti ìyàlẹ́nu rẹ̀, Jóbù di òtítọ́ inú àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jésù Krístì mú. Nínú ìwé Jóbù, a bi ìgbàgbọ́ léèrè a sì dán an wò ṣùgbọ́n a kò pa á tì pátápátá. Èyí kò túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn ìbéèrè ni a dáhùn. Ṣùgbọ́n ìwé Jóbù kọ́ni pé títí dìgbà tí wọ́n bá rí ìdáhùn, àwọn ìbéèrè lè wà papọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Àti pé láìka ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò yí sí, a lè sọ nípa Olúwa wa, “Síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e“ (Jóbù 13:15).
Fún àlàyé ṣókí nípa ìwé Jóbù, wo “Jóbù” nínú ìtọ́sọ́nà sí Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere).
Àwọn Èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ
Jóbù 1–3; 12–13
Mo lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run nínú gbogbo ipò.
Àwọn orí tó bẹ̀rẹ̀ àtẹnumọ́ Jóbù, ní ọ̀nà ewì, ojúṣe tí Sátánì nkó gẹ́gẹ́bí ọ̀tá tàbí olùfisùn wa; wọn kò ṣe àpèjúwe ìbárasọ̀rọ̀ gan laa ní àárín Ọlọ́run àti Sátánì. Bí ẹ ṣe nka ohun tí Sátánì sọ nípa Jóbù (see Jóbù 1:9–11; 2:4–5), ẹ lè bi ara yín léèrè, “Kínìdí tí mo fi dúró nínú òtítọ́ sí Ọlọ́run?” Kíni ó dé tí ó fi léwu láti ṣe ìgbọràn sí Olúwa nìkan fún èrèdí tí Sátánì dá àbá?
Kíni ó wọ̀ yín lọ́kàn nípa èsì Jóbù sí àwọn àdánwò rẹ̀? (wo Jóbù 1:20–22; 2:9–10).
Àwọn ọ̀rẹ́ Jóbù dá àbá pé Ọlọ́run nfì ìyà jẹ òun (wo Jóbù 4–5; 8; 11). Àwọn ìṣòro wo ni ẹ rí pẹ̀lú èrò yí? Ẹ ka ìdáhùn Jóbù ní àwọn orí 12–13. Kíni Jóbù mọ̀ nípa Ọlọ́run tó mú kó ṣeé ṣe fún un láti máa nígbàgbọ́ síi? Kíni ẹ mọ̀ nípa Ọlọ́run tó nràn yín lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro?
Jóbù 19
Jésù Krístì ni Olùràpadà mi.
Nígbà míràn a nkọ́ àwọn òtítọ́ tó ṣe pàtàkì jùlọ́ ní àwọn àkókò tí ó nira jùlọ. Ẹ jíròrò nípa àwọn àdánwò tí Jóbù ṣe àpèjúwe nínú Jóbù 19:1–22 àti àwọn òtítọ́ tí ó kéde ní àwọn ẹsẹ 23–27. Báwo ni ẹ ṣe mọ̀ pé Olùràpadà yín nbẹ láàyè? Ìyàtọ̀ wo ni ìmọ̀ yí ṣe nínú ìgbésí-ayé yín?
Ẹ yẹ kíkọrin tàbí fífi etí sí orin ìsìn nípa Jésù Krístì wò, bíi “Mo Mọ̀ Pé Olùràpadà Mi Wà “I Know That My Redeemer Lives” (Hymns, no. 136). Àwọn ọ̀rọ̀ wo nínú orin yìí ni ó fi ìmọ̀lára yín nípa Rẹ̀ hàn?
Bákanáà wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 121:1–12; 122.
Jóbù 21–24
“Nígbàtí ó bá ti dán mi wò, Èmi ó jáde wá bí wúrà.”
Nínú Jóbù 21–24, ẹ̀yin yíò ka àríyànjiyàn ní àárín Jóbù àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Nínú àríyànjiyàn yìí ni ìbéèrè kan tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti béèrè pé: Kínìdí tí àwọn olódodo fi máa njìyà nígbàmíràn?
Bíótilẹ̀jẹ́pé a kò ní gbogbo àwọn ìdáhún, nínú ìhìnrere Jésù Krístì tí a múpadàbọ̀sípò, a ní àwọn òtítọ́ kan tí ó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti ní òye ìpọ́njú àti ìjìyà. Nísàlẹ̀ ni àwọn Ìwé Mímọ́ ọjọ́ ìkẹhìn tí ó ní díẹ̀ lára àwọn òtítọ́ wọ̀nyí nínú. Kíni àwọn ìwé mímọ́ wọ̀nyí kọ́ yín nípa Baba Ọ̀run àti ètò Rẹ̀?
Ẹ tún lè ka ìkọ́ni Ààrẹ Spencer W. Kimball nípa ìpọ́njú nínú “Ìjàmbá tàbí Kádàrá?” (Ìkọ́ni ti Àwọn Ààrẹ Ìjọ: Spencer W. Kimball [2011]), 11–21).
Dídálórí ohun tí ẹ ti ṣe àṣàrò, báwo ní ẹ ṣe lè dáhùn ìbéèrè bíi “kínìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba àwọn olódodo láti jìyà?”
Fífarabalẹ̀ àti Àwọn Ìràwọ̀, láti ọwọ́ Yongsung Kim. Àwòrán ní ìtẹríba ti havenlight.com
Jóbù 38–40; 42
Ìrísí Ọlọ́run tóbi ju ti èmi lọ.
Ó ní ìjákulẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀sùn àwọn ọ̀rẹ̀ rẹ̀ (wo Jóbù 16:1–5; 19:1–3), Jóbù bèèrè léraléra lọ́wọ́ Ọlọ́run ìdí tí òun fi níláti jìyà tóbẹ́ẹ̀ (wo Jóbù 19:6–7; 23:1–9; 31). Olúwa kò fúnni ní ìdí kan tí ó dájú nínú ìwé Jóbù. Ṣùgbọ́n Ó kọ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì kan ní àwọn orí 38–40. Báwo ni ẹ̀yin yíò ṣe ṣe àkópọ̀ ọ̀rọ̀ náà? Fún àpẹrẹ, kíni ẹ kọ́ nínú àwọn ìbéèrè Olúwa nínú Jóbù 38:1–7, 18–24?
Ẹ̀yin yíò ṣe àkíyèsí pé Olúwa sọ fún Jóbù nípa díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ àti àwọn iṣẹ́ agbára míràn (wo Jóbù 38–39). Ẹ lè wo díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀dá (tàbí àwọn àwòràn wọn). Báwo ni àwọn nkan wọ̀nyí ṣe ràn yín lọ́wọ́ láti ronú yàtọ̀ nípa Ọlọ́run? nípa àwọn ìdánwò yín? Báwo ni wọ́n ṣe yí ìrísí Jóbù padà? (wo Job 42:1–6; bákanáà wo Mósè 1:8–10).
Ní ìhín ni àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò méjì tí ó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ láti yí ìrísí wa padà: Tamara W. Runia, “Rírí Ẹbí Ọlọ́run nípasẹ̀ Àkópọ̀ Àwọn Jígí” (Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2023, 62–69); Russell M. Nelson, “Ronú Sẹ̀lẹ́stíà!” (Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2023, 117–20). Nínú ọ̀rọ̀ méjèèjì, ẹ wá ohun tí ẹ̀yin yíò fẹ́ láti rántí nígbàmíràn ti àwọn ìdánwò yín bá dàbí ohun tí ó lágbára. Báwo ni ẹ ó ṣe rán ara yín létí ohun tí ẹ kọ́?
Ẹ jẹ́ alátinúdá. Kikọ́ ẹ̀kọ́ kò ní láti wà pẹ̀lú kíkà nìkan, ìrònú, àti sísọ̀rọ̀ nìkan. Nígbàmíràn kíkọ́ ẹ̀kọ́ tí ó ṣe oníìrántí jùlọ nwá látinú àwọn ọ̀nà ìṣe ti ara. Fún àpẹrẹ, nígbàtí ẹ bá kà nípa bí Olúwa ṣe yí ìrísí Jóbù padà nínú Jóbù 38–40, ẹ lè rìn ìrìn kan kí ẹ sì wo díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀dá Olúwa, nlá àti kékeré. Tàbí ẹ lè wo ohun kan láti oríṣiríṣi àwọn ìrísí—láti òkè, ìsàlẹ̀, súnmọ́, jìnnà, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde àwọn ìwé-ìròhìn oṣù yí tì Làìhónà àti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Jóbù 1–2; 12; 19
Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì yíò ràn mí lọ́wọ́ ní àwọn àkókò líle.
-
Ẹ gba àwọn ọmọ yín níyànjú láti sọ ohun tí wọ́n mọ̀ nípa Jóbù fún yín. Bí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́, ẹ lè tọ́ka sí Jóbù 1:1, 13–22; 2:7–10 tàbí sí “Jóbù” (nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 145–47). Báwo ni jóbù ṣe dáhùn sí àwọn ìpèníjà? (wo Jóbù 1:21; 2:10).
1:55Job
-
Jóbù jẹ́ olootọ nínú àwọn ìpèníjà rẹ̀ nítorí ohun tí ó mọ̀ nípa Olúwa. Bóyá ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè wo àwòrán Jésù Krístì tó nbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ (bií èyí tó wà nísàlẹ̀ tàbí àwọn àwòrán inú Ìwé Ọnà Ìhìnrere). Ẹ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ẹ mọ̀ nípa Rẹ̀ àti ohun tí ó jẹ́. Ní ìhín ni díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ tí ó fi ohun tí Jóbù mọ̀ nípa Olúwa hàn: Jóbù 12:10, 13, 16; 19:25–27. Kínìdí tí ó fi ṣe pàtàkì láti mọ nkan wọ̀nyí nípa Rẹ̀?
Ó wo Gbogbo wọn Sàn, Láti ọwọ́ Michael Malm
Jóbù 14:14
Nítorí Jésù Krístì, èmi yìó yè lẹ́ẹ̀kan si lẹ́hìn tí mo bá kú.
-
Jóbù béèrè ìbéèrè pàtàkì kan nínú Jóbù 14:14. Bóyá ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè máa ṣe àbápín bí ẹ ṣe máa dáhùn fún Jóbù ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ẹ lè wá àwọn èrò nínú Álmà 11:42–44, nínú fídíò “Ní Ọjọ́ Tó Nbọ̀” (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere), tàbí nínú orin kan nípa Àjínde, bíi “Njẹ́ Jésù Wà Láàyè Lódodo Lẹ́ẹ̀kansi?” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 64).
#BECAUSEofHIM: An Easter Message of Hope and Triumph
Jóbù 16:1–5; 22:5
Àwọn ọ̀rẹ́ rere máa ngbé ara wọn ga, wọ́n sì máa ngba ara wọn níyànjú.
-
Nígbàtí Jóbù banújẹ́, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wípé Ọlọ́run nfìyà jẹ ẹ nítorí pé ó ti dẹ́ṣẹ̀ (wo Jọ́bù 22:5). Bí ó bá jẹ́ ọ̀rẹ́ Jóbù ni wá, báwo ni a ṣe máa gbìyànjú láti ràn án lọ́wọ́? Báwo ni ọ̀rọ̀ wa ṣe lè ran àwọn míràn lọ́wọ́ nígbàtí inú wọn bá bàjẹ́? (wo Jóbù 16:5). Ẹ yẹ fífi àwòrán kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àtòkọ èrò yì hàn bí ẹ ṣe nsọ́rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wò.
-
Ẹ yẹ níní kí àwọn ọmọ yín ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ànímọ́ kan ti ọ̀rẹ́ rere kan wo àti láti dárúkọ ọ̀rẹ́ kan tí ó ní àwọn ànímọ́ wọ̀nyí. Lẹ́hìnnáà ẹ lè wo àwòrán Jésù Krístì kan. Irú ọ̀nà wo ni Jésù fi jẹ́ ọ̀rẹ̀ rere sí ẹnikọ̀ọ̀kan wa? Ẹ lẹ̀ ronú nípa ẹnìkan tí ó nla àkókò líle kọjá. Ẹ ṣe ètò bí ẹ̀yin yíò ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ bí Krístì sí wọn.
Jóbù 19:23–27
Jésù Krístì ni Olùràpadà mi.
-
Lẹ́hìn kíka Jóbù 19:23–27, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ ṣe mọ̀ pé Olùràpadà wa nbẹ láàyè. Ẹ lè ṣiṣẹ́ papọ̀ láti fi ẹ̀rí yín (tàbí àwọn àwòrán Olùgbàlà) sínú ìwé kan (wo ẹsẹ 23).
-
Ẹ tún lè kọ orin kan tó jẹri nípa Olùgbàlà, bíi “Mo Mọ̀ Pé Olùràpadà Mi wà Láàyè” (Àwọn Orin, nọ́mbà 136). Ẹ ṣe àbápín àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ láti inú orin ìsìn tí ó fún ìgbàgbọ́ yín lókun nínú Rẹ̀. Kínìdí tó fi ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé Jésù Krístì wà láàyè?
Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .