Come, Follow Me
“Oṣù kéje 27–Oṣù Kẹ́jọ 2. “Èmi Nṣe Iṣẹ́ Nlá Kan”: Ẹ́srà 1; 3–7; Nehemíàh 2; 4–6; 8


“Oṣù kéje 27–Oṣù Kẹ́jọ 2. ‘Èmi Nṣe Iṣẹ́ Nlá Kan’: Ẹ́srà 1–3; Nehemíàh 2: 4–6; 8,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù kéje 27–Oṣù Kẹ́jọ 2. ‘Èmi Nṣe Iṣẹ́ Nlá Kan,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026

a ntú odi Jérúsálẹ́mù kọ́

Èmi Nṣe Iṣẹ́ Nlá Kan, láti ọwọ́ Tyson Snow

Oṣù kéje 27–Oṣù Kẹ́jọ 2: “Èmi Nṣe Iṣẹ́ Nlá Kan”

Ẹ́srà 1; 3–7; Nehemíàh 2; 4–68

Àwọn Júù ti wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì fún nkan bí àádọ́rin ọdún. Wọ́n ti sọ Jerúsálẹ́mù àti tẹ́mpìlì nù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ti gbàgbé ìpinnu wọn sí òfin Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò gbàgbé wọn. Ní tòótọ́, Ó ti kéde nípasẹ̀ wòlíì Rẹ̀ pé, “ Èmi yíò bẹ̀ yín wò, èmi yíò sì mú ọ̀rọ̀ rere mi ṣẹ sí yín, ní mímú yín padà” (Jeremíàh 29:10). Ní òtítọ́ sí àsọtẹ́lẹ̀ yìí, Olúwa ṣe ọ̀nà kan fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ láti padà—méjèèjì sí Jerúsálẹ́mù àti, ní pàtàkì, sí àwọn májẹ̀mú wọn. Ó sì gbé àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n ṣe “iṣẹ́ nlà kan” dìde (Nehemíàh 6:3): Gómìnà kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Serubábélì ló bójútó àtúnkọ́ ilé Olúwa náà. Ẹ́srà, àlùfáà àti akọ̀wé, ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti yí ọkàn wọn padà sí òfin Olúwa. Nehemíàh sì darí àtúnkọ́ odi ààbò yí Jerúsálẹ́mù. Wọn kojú àtakò, ṣùgbọ́n wọ́n tún gba ìrànlọ́wọ́ láti àwọn orísun àìròtẹ́lẹ̀. Àwọn ìrírí wọn lè sọ àti ṣíwa létí nítorí pé àwa náà nṣe iṣẹ́ nlá kan. Àti gẹ́gẹ́bí tiwọn, iṣẹ́ wa pọ̀ láti ṣe pẹ̀lú ilé Olúwa, òfin Olúwa, àti ààbò ẹ̀mí tí a rí nínú Rẹ̀.

Fún àlàyé ṣókí nípa àwọn ìwé Ẹ́srà àti Nehemíàh, wo “Ẹ́srà” àti “Nehemíàh” nínú ìwé ìtumọ̀ ìwé mímọ́.

àmì àṣàrò

Àwọn ìrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ

Ẹ́srà 1

Olúwa ngba ènìyàn níyànjú láti mú àwọn ìpinnu Rẹ̀ ṣẹ.

Lẹ́hìn tí Páṣíà ṣẹ́gun Bábílónì, Olúwa mí sí ọba Páṣíà, Cyrus, láti rán ẹgbẹ́ àwọn Júù kan lọ sí Jerúsálẹ́mù láti tún tẹ́mpìlì náà kọ́. Bí o ṣe nka Ẹ́srà 1, ṣàkíyèsí ohun tí Cyrus ṣe láti ti àwọn Júù lẹ́hìn nínú iṣẹ́ pàtàkì yìí. Báwo ní ẹ ṣe ri pé Olúwa nṣiṣẹ́ nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin ní àyíká yín, pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí kìí ṣe ọmọ Ìjọ Rẹ̀? Kíni àwọn èyi dábàá fún yín nípa Olúwa àti iṣẹ́ Rẹ̀?

Bákanáà wo Ìsàíàh 44:24–28.

Ẹ́srà 3:8–13; 6:16–22

Ilé Olúwa jẹ́ ibi ayọ̀ kan.

Nígbàtí àwọn ara Bábílónì gbógun ti Jérúsálẹ́mù, wọ́n kọ́ tẹ́mpìlìnáà, wọ́n sì sun ún délẹ̀ (wo 2 Àwọn Ọba 25:1–10; 2 Króníkà 36:17–19). Báwo ni ẹ ṣe rò pé ẹ máa ní ìmọ̀lára bí ẹ bá ti ọ̀kan lára àwọn Júù tó rí èyí? (wo Orin Dáfídì 137). Kíyèsí bí ​​àwọn Júù ṣe ní ìmọ̀lára, ní àwọn díkédì lẹ́hìnnáà, nígbàtí a gbà wọ́n láàyè láti padà wá kí wọ́n sì tún tẹ́mpìlì kọ́ (wo Ẹ́sra 3:8–13; 6:16–22). Èyí lè ṣí yín létí láti jíròrò lórí ìmọ̀lára ti arayín nípa Olúwa àti ilé Rẹ̀. Kínìdí tí kíkọ́ tẹ́mpìlì fi jẹ́ èrèdí fún àjọyọ̀?

àwọn àlùfáà ní òde tẹ́mpìlì Serubábélì

Tẹ́mpìlì Serubábélì; ìjúwe láti ọwọ́ Sam Lawlor

Ẹ́srà 4–7; Nehemíàh 2; 46

àmì sẹ́mínárì
Ọlọ́run ní iṣẹ́ pàtàkì kan fún mi láti ṣe.

Iṣẹ́ Olúwa kìí lọ láìsí àtakò. Èyí jẹ́ òtítọ́ nípa ìgbìyànjú tí Serubábélì àti Nehemíàh ṣe. Nihin ni ọ̀nà tí ó rọrùn tí ó lè ṣèrànlọ́wọ́ fún yín láti kẹkọ láti àwọn ìtàn wọ̀nyí kí ẹ gbèrò bí ẹ ṣe lè ṣe iṣẹ́ Olúwa láìbìkítà àtakò:

Iṣẹ́ Ọlọ́run fún Serubábélì (Ẹ́srà 4:3): (Ẹ́sírà 4:3):

Iṣẹ́ Ọlọ́run fún Nehemíàh (Nehemíàh 2:17–18):

Iṣẹ́ Ọlọ́run fún mi:

Àtakò tí Serubábélì dojúkọ (Ẹ́srà 4:4–24):

Àtakò tí Nehemíàh dojúkọ (Nehemíàh 2:19; 4:1–3, 7–8; 6:1–13):

Àtakò tí mo dojúkọ:

Báwo ni Serubábélì ṣe dáhùn (Ẹ́srà 5:1–2):

Báwo ni Nehemíàh ṣe dáhùn (Nehemíàh 2:20; 4:6, 9; 6:3–15):

Báwo ni mo ṣe lè dáhùn:

Fún ìrànlọ́wọ́ láti ṣe àfiwé ìrírí Nehemíàh sí ìgbésí-ayé yín, ẹ lè ṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf “A Nṣe Iṣẹ́ Nla kan àti pé A kò lè Wálẹ̀” (Làìhónà, Oṣù karun 2009, 59–62), nípàtàkì àwọn ìpín méjì tí ó kẹ́hìn. Bí ẹ ṣe nronú nípa iṣẹ́ tí Ọlọ́run fún yín, ẹ lè ṣe àṣàrò “Àkòrí Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin” tàbí “Àkòrí Iyejú Oyèàlùfáà Árónì” (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere). Tàbí ẹ lè wo orin i`sìn bíi “Bíi Arábìnrin ní Síónì” (Àwọn orin, nọ́mba 309) tàbí “Ẹ̀yin Alàgbà Ísráẹ́lì” (Àwọn orin, nọ́mbà 319).

Kíni ẹ rò pé ó túmọ̀ sí láti ní “ọkàn láti ṣiṣẹ́” nínú iṣẹ́-ìsìn Olùgbàlà? (Nehemíàh 4:6). Kíni ó lè túmọ̀ sí láti ní “Ọwọ́ rere ti … Ọlọ́run lórí [yín]” bí ẹ ṣe nṣe iṣẹ́ Rẹ̀? (Nehemíàh 2:8; bákanáà wo Nehemíàh 2:18; Ẹ́srà 7:6, 9, 27–28). Báwo ni ẹ ṣe nrí ọwọ́ Rẹ̀ nínú ìgbìyànjú yín láti sìn Ín?

Nehemíàh 8

Alábùkún ni mí nígbàtí mo bá ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́.

Fún àwọn ìrandíran tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, àwọn Júù ní ìwọ̀nba ààyè sí “ìwé òfin Mósè” (Nehemíàh 8:1). Nínú Nehemíàh 8, Ẹ́srà ka òfin náà fún àwọn ènìyàn. Kíni ẹ rí nínú orí yìí tó fi bí Ẹ́srà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣe ní ìmọ̀lára nípa Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ hàn? (Ní pàtàkì wo àwọn ẹsẹ 1–12). Kíni ó fihàn bí ẹ ṣe ní ìmọ̀lára nípa Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ní ìgbésí-ayé yín?

Bákanáà wo Ìkọ́ni Àwọn Ààrẹ Ìjọ: Ezra Taft Benson (2014), 115–24.

Fún púpọ̀ sí i, wo àtẹ̀jáde àwọn ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .

ìpín àmì àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Ẹ́srà 3:8–13; 6:16–22

Ilé Olúwa jẹ́ ibi ayọ̀ kan.

  • Láti kọ́ àwọn ọmọ yín ní ẹ̀kọ́ nípa ayọ̀ tí àwọn Júù ní nígbàtí wọ́n tún tẹ́mpìlì wọn kọ́, ẹ lè fi àwòrán kan hàn wọ́n bí èyí tó wà nísàlẹ̀. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe lè ní ìdùnnú láti wà nílé Olúwa. Ẹ tún lè sọ fún àwọn ọmọ yín ìdí tí tẹ́mpìlì fi jẹ́ ibi ayọ̀ fún yín. Báwo ni tẹ́mpìlì ṣe ràn yín lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára sísunmọ́ Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà?

  • Bí ẹ ṣe nka Ẹ́srà 3:10–13 pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tó fi bí ​​àwọn Júù ṣe ní ìmọ̀lára nígbàtí wọ́n ntún tẹ́mpìlì kọ́. Nígbàtí ẹ bá dé òpin ẹsẹ 13, bóyá ẹ lè paruwo fún ayọ̀ papọ̀. Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn èrèdí tí ó fi yẹ kí a yọ̀ wípé Olúwa ti fún wa ní àwọn tẹ́mpìlì. Báwo ni a ṣe lè fi ayọ̀ náà hàn?

  • E yẹ kíkọ orin kan nípa tẹ́mpìlì pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, bíi ẹsẹ kejì ti “Káàbọ̀ Sílé” (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere). Lẹ́hìn ìlà kọ̀ọ̀kan, ẹ lè dánudúró díẹ̀ láti bèèrè lọ́wọ́ ọmọ kan láti ṣe àbápín ohunkan tí ó fẹ́ràn lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin nípa tẹ́mpìlì. Ẹ tún lè wo àwọn àwòràn tẹ́mpìlì nígbàtí ẹ nkọrin.

ẹbí tó nrẹrin nrìn nítòsí tẹ́mpìlì

Nehemíàh 2:17–20; 6:1–9

Olúwa yíò ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe “iṣẹ́ nlá” Rẹ̀.

  • Ẹ ṣe àbápín ìtàn Nehemíàh pẹ̀lú àwọn ọmọ yín (wo Nehemíàh 2:17–20; 6:1–9; tàbí “Nehemíàh” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 173–74). Bí ẹ ṣe nka Nehemíàh 2:20, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè “dìde” kí wọ́n sì ṣe bí ẹni pé àwọn nṣe ìrànlọ́wọ́ láti kọ́ odi Jerúsálẹ́mù. Tàbí àwọn ọmọ yín lè gbádùn kíkọ́ odi kan pẹ̀lú àwọn búlọ́kì tàbí àwọn nkan míràn. Bí wọ́n ṣe nṣée, ẹ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ohun pàtàkì tí Baba Ọ̀run fẹ́ ká ṣe.

    1:38

    Nehemiah

  • Bí ẹ ṣe nka Nehemíàh 6:9, ẹ pe àwọn ọmọ yín láti gbé ọwọ́ wọn sókè nígbàtí wọ́n bá gbọ́ tí ẹ nsọ wípé “fún ọwọ́ mi lókun.” Ẹ sọ fún àwọn ọmọdé nípa àkókò kan tí wọ́n ní ìmọ̀lára tí Ọlọ́run fún ọwọ́ yín lókun láti ṣe iṣẹ́ Rẹ̀.

Nehemíàh 8:1–12

Àwọn ìwé mímọ́ jẹ́ ìbùkún.

  • Ẹ ka àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan sókè látinú Nehemíàh 8:2–3, 5–6, 8–9, 12 tó ṣe àpèjúwe ohun tí áwọn ènìyàn náà ṣe nígbàtí Ẹ́srà nka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Bí ẹ ṣe nkàá, àwọn ọmọ yín lè ṣe eré àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Lẹ́hìnnáà, ẹ lè ṣe àbápín ìmọ̀lára ti ẹ ní bí ẹ ṣe nka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà tàbí tí ẹ gbọ́ pẹ̀lú arayín.

  • Bí ẹ ṣe nka Nehemíàh 8:8, papọ̀ ẹ lè bi àwọn ọmọ yín léèrè ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní òye àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Ẹ fi bí wọ́n ṣe nlo àwọn ìrànlọ́wọ́ àṣàrò ìwé ìwé mímọ́ hàn wọ́n bíiti Ìtọ́sọ́nà sí Ìwé Mímọ́ àti Àwọn Àkòrí àti Ìbéèrè (Ibi Ìkàwé Ìhìnrere). Ẹ pe àwọn ọmọdé láti ṣe àbápín nkan tí wọ́n ti kọ́ nípa Olùgbàlà làti inú àwọn ìwé mímọ́.

Ẹ wá òtítọ́ ayérayé nínú àwọn ìwé mímọ́. “Àwọn ìwé mímọ́ … ni ó kún fún àwọn òtítọ́ ìhìnrere, ṣùgbọ́n nígbàmíràn ó máa ngba ìdámọ̀ ìtiraka láti wá wọn. Bí ẹ ṣe nkọ́ ẹ̀kọ́ papọ̀ látinú àwọn ìwé mímọ́, ẹ dúró kí ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn wọnni tí ẹ nkọ àwọn òtítọ́ ìhìnrere tí wọ́n ṣe àkíyèsí. Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí bí àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ṣe bá ètò ìgbàlà ti Bàbá Ọ̀run mu. Nígbàmíràn àwọn òtítọ́ ayérayé ni a sọ nínú àwọn ìwé mímọ́, àti nígbàmíràn wọ́n ṣe àpèjúwe nínú àwọn ìtàn àti ìgbésí-ayé àwọn ènìyàn tí a kà nípa rẹ̀. Ó tún lè ṣe ìrànwọ́ láti ṣe àyẹ̀wò ìpìlẹ̀ ìtàn ti àwọn ẹsẹ tí ẹ nkà, àti ìtumọ̀ àwọn ẹsẹ náà àti bí wọ́n ṣe wúlò sí wá ní òní” (Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà22).

Fún púpọ̀ sí i, wo ìtẹ̀jáde ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .

Ẹ́srà nka àkájọ ìwé kan

Ẹ́srà ní Ẹnu-ọ̀na Omi, © © Providence Collection/ìwé-àṣẹ láti ọwọ́ goodsalt.com

Ojú-ewé ìṣe ṣíṣe Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Àwọn ìwé mímọ́ jẹ́ ìbùkún