Come, Follow Me
Oṣù Kéje 20–26. “Ojú Wa Wà lára Rẹ”: 2 Króníkà 14–20; 26; 30


“Oṣù Kéje 20–26. ‘Ojú Wa Wà lára Rẹ’: 2 Króníkà 14–20; 26; 30,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Kéje 20–26. ‘Ojú Wa Wà lára Rẹ,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026

Ọba Jèhóṣáfátì ngbàdúrà

Àdúrà Ọba Jèhóṣáfátì, láti ọwọ́ Keeley Rae

20– 26:“Ojú Wa Wà lára Rẹ”

2 Króníkà 14–20; 26 30

Ìjọba Júdàh ni a yíká. Àwọn ọmọ-ogun láti àwọn orílẹ̀-èdè alágbára mẹ́ta gbogbo wọn nbọ́ wá ní ẹ̀ẹ̀kan, tí wọ́n ti múra ogun sílẹ̀. Nínú àkokò ìnílò àìnírètí yí, Jèhóṣáfátì, Ọba Júdàh, yípadà sí Ọba ọ̀run òun ayé. Jèhóṣáfátì kó àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ ní tẹ́mpìlì ó sì gbàdúrá. Ó dá àìlera ti ẹ̀nìyàn wọn mọ̀ ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìdándè. In Ní ìfèsì, Olúwa ṣe ìlérí ààbò Rẹ̀: “Máṣe bẹ̀rù, tàbí kí ẹ fòyà” (2 Króníkà 20:17).

A lè má tilẹ̀ ní ọmọ-ogun apanirun ní ẹnu-ọ̀nà wa tí ó nṣẹ̀rùbà láti pa wá run, ṣùgbọ́n nígbàmíràn à nní ìmọ̀lára yíyíká nípa ìpọ́njú àti ibi. Ipa ọ̀nà wa sí ìdándè jẹ́ ọ̀kannáà tí Jèhóṣáfátì wá, àti pé àdúrà wa lè dàbí tirẹ̀ pẹ̀lú: “Áà Ọlọ́run, … àwà kò ní agbára láti dojúkọikọ̀ nlá yí tí nbọ̀ wá kọlù wá; àwa kò sì mọ èyí tí àwa ó ṣe: ṣùgbọ́n ojú wa nbẹ lára rẹ” (2 Króníkà 20:12).

Nínú 2 Króníkà 14–30, Ẹ yíò kà nípa Jèhóṣáfátì àti àwọn ọba míràn ní Júdàh. Ẹ ṣe àyẹ̀wò bí àwọn àtúnṣe, àwọn ìṣẹ́gun, àti àwọn ìpènijà wọn tí ìgbàgbọ́ ndarí-ṣe lè wúlò sí ìgbé ayé ti ara yín.

Fún àkópọ̀ ìwé 2 Króníkà, wo “Àwọn Króníkà” nínú Ìtumọ̀ Bíbélì.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Kíkọ́ni ní Ilé àti Ìjọ

2 Króníkà 14– 16

Gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run yíò mú àlàáfíà wá fún mi.

Nígbàtí Ásà jẹ́ ọba Júdàh, ó kojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpènijà—gẹ́gẹ́bí gbogbo wa ti nṣe ní òní. Bé ẹ ti nkà nípa àwọn àdánwò tí ó kojú, ẹ kíyèsí ibití ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sí àti bí èyí ṣe yípadà ní ìgbà díẹ̀.

Atọ́ka

Àwọn ìpènijà tí Ásà kojú

Ibi tí Ásà fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sí

Atọ́ka

2 Króníkà 14:14–12

Atọ́ka

2 Króníkà 15:1–8

Atọ́ka

2 Króníkà 16: 1–10

Kínni ìdí tí a máa nfi ìgbàmíràn dáwọ́dúró ní gbígbẹ́kẹ̀lé Olúwa? Kínni ohun míràn tí ẹ kọ́ láti inú ìgbésí ayé Ásà?

Wo D. Todd Christofferson, “Ìbáṣepọ̀ Wa pẹ̀lú Ọlọ́run,” Làìhónà, Oṣù Kárun 2022, 78–80.

2 Króníkà 18

Mo lè dúró fún òtítọ́, àní nígbàtí kò bá ní òkìkí.

Wòlíì Míkáíàh gbọ́dọ̀ ti ní ìmọ̀lára ìtẹ̀mọ́lẹ̀ púpọ̀ láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìyege fún àwọn ọba Jèhóṣáfátì àti Áhábù nínú ogun wọn ní ìdojúkọ Síríà. Ẹ wá ẹ̀rí ìtẹ̀mọ́lẹ̀ náà nínú 2 Króníkà 18:1–12. Kínni ẹ̀rí tí ẹ rí nípa ìgboyà àti òtítọ́ inú Míkáíàh nínú àwọn ẹsẹ 13–27? (Ṣe àkíyèsí pé nínú ẹsẹ 14, Míkáíàh fúnnni ní èsì ègérì; ìdáhùn rẹ̀ tòótọ́ wà nínú ẹsẹ 16.) Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ Míkáíàh ṣe di mímúṣẹ nínú àwọn ẹsẹ 28–34?

Kínni àwọn ìpò kan nínú èyí tí ẹ ti lè kojú ìtẹ̀mọ́lẹ̀ bí Míkáíàh ṣe kojú? Kínni ó fún yín ní ìgboyà láti dúró fún Olúwa àti àwọn ìkọ́ni Rẹ̀?

àwòrán ti Júdàh

Ní àwọn ọjọ́ ti Ọba Jèhóṣáfátì, àwọn orílẹ̀-èdè mẹta kọlu Jérúsálẹ́mù.

2 Króníkà 20: 1–25

àmì sẹ́mínárì
Ní àwọn àkokò ìṣòro, mo lè yípadà sí Ọlọ́run àti àwọn wòlíì Rẹ̀.

Bí ẹ ti nka 2 Króníkà 20:1–12, ẹ wá ohun tí Ọba Jèhóṣáfátì ṣe nígbàtí àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ wá láti kọlu Júdàh. Báwo ni ẹ ṣe lè lo àwọn ìṣe rẹ̀ ní pípe àwọn ipò tí ẹ nkojú níjà?

Èsì Olúwa sí àdúrà Jèhóṣáfátì ni a rí nínú àwọn ẹsẹ 14–17. Kínni àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ẹ rí níbẹ̀ tí ó lè tù yín nínú tàbí ẹnìkan tí ẹ mọ̀ ní àwọn àkokò ìṣòrò?

Ní ọjọ́ tó tẹ̀lé, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù jáde lọ láti pàdé àwọn ọmọ-ogun alátakò. Bí ẹ ti nka 2 Króníkà 20:20, ẹ wá ọ̀rọ̀ tí Jèhóṣáfátì fi fún àwọn ènìyàn ti Jérúsálẹ́mù. Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe di mímúṣẹ? (wo àwọn ẹsẹ 22–23). Báwo ni Ọlọ́run ṣe bùkún yín fún gbígbàgbọ́ nínú Rẹ̀ àti títẹ̀lé àwọn wòlíì Rẹ̀?

Ààrẹ Russell M. Nelson wípé: “Ìrírí mi ni pé nígbàtí ẹ bá dúró ní fífi àmì ìbèèrè sí ẹ̀hìn àwọn ẹ̀là ọ̀rọ̀ ti wòlíì kí ẹ sì fi àwọn àmì igbe dípò bẹ́ẹ̀, àti láti ṣe é, àwọn ìbùkún náà ṣàn lásán. Èmi kò bi ara mi léèrè rí, ‘Nígbà wo ni wòlíì nsọ̀rọ̀ bí wòlíì kan àti nígbà wo ni kìí sọ̀rọ̀?’ Ìdùnmọ́ mi ti jẹ́, ‘Báwo ni mo ṣe lè dàbíi rẹ̀?’” (nínú Lane Johnson, “Russell M. Nelson: Ẹ̀kọ́ kan nínú Ìgbọ́ran,” Ẹ́nsáìnì, Ọsù Kẹjọ. 1982,24).

Bákannáà wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 21:4–6; “Ìmúdúró Ìdákòró kan” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere; “Ṣe àwọn Àṣàyàn Ìmísí,” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ (2022), 4–5.

3:37

A Secure Anchor

Àwọn ẹ̀là ọ̀rọ̀ ìdánimọ̀ rírọrùn ti òtítọ́. Alàgbà Neal A. Maxwell kọ́ni: “Àwọn ìwé mímọ́ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun iyebíye jùlọ ti ẹ̀kọ́. Àti nígbàtí ìmọ́lẹ̀ ti Ẹ̀mí bá ṣéré lórí oríṣiríṣi àwọn ẹ̀ka wọn, wọ́n á tàn pẹ̀lú ọgbọ́n sẹ̀lẹ́stíà wọn a sì ṣe ìtànná sí ipa ọ̀nà tí à níláti tẹ̀lé” (“Gẹ́gẹ́bí Ifẹ́-inú ti Ọkàn [Wa],” Ẹ́nsáìnì, Oṣù Kọkanlá. 1996, 21). Bí ẹ ti nṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́, ẹ ṣe àyẹ̀wò lílo àkokò láti ṣe ìdámọ̀, ìfàmìsí, àti ìjíròrò ní kúkúrú síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ alágbára. Àwọn àpẹrẹ tí a lè rí nínú 2 Króníkà 14:11; 15:7; 18:13; 20:15; 26:5. Kínni “ohun iyebíye jùlọ ti ẹ̀kọ́” tí ẹ lè rí?

2 Króníkà 26: 3–21

Ìgbéraga ndarí sí ìparun.

Bíiti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọba Júdàh míràn, àkóso Ussíà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣeyọrí nlá ṣùgbọ́n ó parí pẹ̀lú àjálù. Ẹ wá àwòṣe yí nínú 2 Króníkà 26. Kínni ẹ yíò sọ pé ó jẹ́ àmì ìyípadà ní ayé Ussíà?

Bí ẹ ti nka àwọn ẹsẹ 16–23, ẹ ṣe ìpamọ́ ní inú yín pé ní àkokò yí, àwọn àlùfáà nìkan ni a fi ààyè gba láti jó tùràrí nínú tẹ́mpìlì. Kínni ìdí tí ẹ fi rò pé Ọba Ussíà ṣe àìgbọ́ran sí Ọlọ́run? Kínni ẹ kọ́ láti inú ìrírí olóró yí?

Báknanáà wo “Ẹ Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 130.

2 Króníkà 30

Èmi lè jẹ́ onílàjà kan.

Nínú 2 Króníkà 30, Hesekíàh jẹ́ ọba Júdàh. Ó pe orogún Ìjọba ti Ísráẹ́lì láti kórajọ ní Jérúsálẹ́mù láti ṣe àṣeyẹ Ìrékọjá—ohun kan tí àwọn ará Ísráẹ́lì kò tíì lè ṣe fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún (wo àwọn ẹsẹ 1–12). Kínni ìwọnilọ́kàn tí ẹ ní nípa ìfipè àti bí ẹ ṣe gbà á—méjèèjì nípa àwọn àlejò ará Ísráẹ́lì àti nípa àwọn olùgbàlejò wọn ní Júdàh?

Nítorí ó ti pẹ́ gan, àwọn àlejò sí Jérúsálẹ́mù ni a kò faramọ́ pẹ̀lú àwọn àlàyé kíníkíní ti bí a ó ṣe kópa nínú Ìrékọjá. Bí ẹ ti nka 2 Króníkà 30:18–27, kínni ẹ kọ́ láti inú èsi Hesekíàh àti àbájáde èsì rẹ̀?

Wo Russell M. Nelson, “A Nílò Àwọn Onílàjà,” Làìhónà, Oṣù Karun 2023, 98–101.

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde òṣù yí ti àwọn ìwé ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .

àmì ìpín àwọn ọmọdé

Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé

2 Króníkà 14–16;20

Mo lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run.

  • Láti fi èrò ti gbígbẹ̀kẹ̀lé Olúwa hàn, ẹ lè fi ohun kan tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé láti pa yín mọ́ ní gbígbẹ nígbàtí òjò bá rọ̀ han àwọn ọmọ yín, bíi agboòrùn tàbí jákẹ́tì. Ẹ jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí a fi lè gbẹ́kẹ̀lé àwọn ohun wọ̀nyí. Lẹ́hìnnáà ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi iyẹn wé ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Olúwa. Kínni ìdí tí a fi ngbẹ́kẹ̀lé E láti pa wá mọ́ làìléwu níti ẹ̀mí?

  • Ẹ lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe àwárí bí Ọba Ásà àti Ọba Jèhóṣáfátì ti fèsì sí àwọn ìpènijà nípa níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa (wo 2 Króníkà 14:11; 20:3–5, 12). Ẹ pín pẹ̀lú ara yín àwọn ọ̀nà tí ẹ fi lè fihan Olúwa pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé E.

2 Króníkà 20: 1–29

Ọlọ́run yíò gbọ́ yíò sì dáhùn àwọn àdúrà mi.

  • Ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe ọ̀sẹ̀ yí lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye ìtàn nípa àdúrà Jèhóṣáfátì àti ìdáhùn Olúwa. Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè pín àwọn àkokò nígbàtí Ọlọ́run ti gbọ́ tí ó sì dáhùn áwọn àdúrà yín. Ẹ yẹ àwọn àkokò wò pẹ̀lú ìgbàtí àwọn ìdáhùn ti wá ní àwọn ọ̀nà tàbí àkokò tí ẹ kò rò. Orin kan nípa àdúrà, bí irú “Mo Gbàdúrà nínú Ìgbàgbọ́” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 14), lè ṣèrànwọ́ láti gbé ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ yín ga.

2 Króníkà 26: 3–23

Mo lè ní ìrẹ̀lẹ̀.

  • Láti kọ́ nípa àwọn ewu ti ìgbéraga, àwọn ọmọ yín lè kọ́ ilé ìṣọ́ pẹ̀lú búlọ́kì tàbí àwọn ago kékéré. Bí wọ́n ṣe ndi búlọ́kì kọ̀ọ̀kan tàbí ago sí orí ilé ìṣọ́ gíga, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yẹ ọ̀kan lára àwọn àṣeyọrí Ussíà wò láti inú 2 Króníkà 26:3–15. Lẹ́hìn tí wọ́n bá parí ilé ìṣọ́ gíga náà, ẹ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ yín bí Ussíà ṣe lè paámọ́ ní gíga àti lílágbára. Kínni ó lè mú un ṣubú? Lẹ́hìnnáà, bí ẹ ti nka ẹsẹ 16, ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó túmọ̀ sí láti ní ọkàn wa ní “gbígbé sókè sí ìparun [wa].” Ẹ pín ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Ussíà pẹ̀lú àwọn ọmọ yín nínú àwọn ẹsẹ 16–23. Ẹ jẹ́ kí wọ́n wó ilé ìṣọ́ gíga wọn lulẹ̀ Ẹ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí a lè ṣe láti dúró ní ìrẹ̀lẹ̀.

Hesekíàh yin Ọlọ́run

Ọba Hesekíàh àti àwọn Ènìyàn Dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, © Lifeway Collection/licensed láti goodsalt.com

2 Króníkà 30

Èmi lè jẹ́ onílàjà kan.

  • Àwòrán òkè ṣe àfihàn ìgbàtí Hesekíàh pe àwọn aládùúgbò Júdàh láti inú Ìjọba Ísráẹ́lì láti ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá pẹ̀lú wọn. Ẹ lè wo àwòrán yí pẹ̀lú àwọn ọmọ yín kí ẹ sì ka 2 Króníkà 30:18–19, èyí tí ó ṣe àlàyé pé àwọn àlèjò kan ti wẹ ara wọn gẹ́gẹ́bí òfin Mósè. Kínni Hesekíàh ṣe? Báwo ni èyí ṣe mú kí àwọn àlejò náà ní ìmọ̀lára? Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú nípa bí wọ́n ṣe lè dàbí Hesekíàh ní ọ̀nà tí ó fi tọ́jú àwọn ẹlòmíràn.

Fún púpọ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .

Ussíà jẹ́ lílé kúrò ní tẹ́mpìlì bí ẹ̀tẹ̀ ṣe farahàn ní orí rẹ̀

Ìgbéraga àti Ìjìyà Ussíà, láti ọwọ́ A. M. Boon

Ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Ọlọ́run yíò gbọ́ yíò sì dáhùn àwọn àdúrà mi