“Oṣù Kéje 6–12. ‘Wòlíì Kan Wà Ní Ísráẹ́lì’: 2 Àwọn Ọba 2–7,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kéje 6–12. ‘Wòlíì Kan Wà Ní Ísráẹ́lì,’” Wá, Tẹ̀lé Mî Májẹ̀mú Láéláé 2026
Ní Etí Odò, láti ọwọ́ Annie Henrie Nader
Oṣù Kéje 6–12: “Wòlíì Kan Wà Ní Ísráẹ́lì”
2 Àwọn Ọba 2-7
Kókó iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti wòlíì ni láti kọ́ni kí wọ́n sì jẹ́ ẹ̀rí nípa Olùgbàlà Jésù Krístì. Àkọsílẹ̀ wa nípa wòlíì Èlíṣà, bákannáà, kò pẹ̀lú ọ̀pọ̀ lára ìkọ́ni tàbí jíjẹ́ ẹ̀rí rẹ̀. Nkan tí àkọsílẹ̀ wà pẹ̀lú ni iṣẹ́ ìyanu tí Élíṣà ṣe, pẹ̀lú jíjí ọmọ kan dìde kúrò nínú òkú (wo 2 Àwọn Ọba 4:18–37), bíbọ́ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn pẹ̀lú oúnjẹ kékeré (wo 2 Àwọn Ọba 4:42–44), àti wíwo adẹ̀tẹ̀ sàn (wo 2 Àwọn Ọba 5:1–14). Nítorínáà a kò ní àwọn ọ̀rọ̀ Èlíṣà nípa Krístì, a ní iṣẹ́ ìrànṣẹ́ àti iṣẹ́ ìyanu Èlíṣà, èyí tí jẹ́ ẹ̀rí Krístì. Wọ́n jẹ́ ìfihàn alágbára fífúnni ní ìye, ṣíṣìkẹ́, àti agbára ìwòsàn ti Olúw, Àwọn iṣẹ́ ìyanu nṣẹlẹ̀ léraléra nínú ayé wa ju bí a ti ndamọ̀ nígbàmíràn. Láti rí wọn, a nílò lát wá ìgbàgbọ́ tí Èlíṣà ní nígbàtí ó gbàdúrà ní ìtìlẹhìn ti ìránṣẹ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí ó nbẹ̀rù: “Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, là á ní ojú, kí ó lè ríran” (2 Àwọn Ọba 6:17).
Fún ìwífúnni síi nípa 2 Àwọn Ọba, wo “ìwé ti, Àwọn Ọba” nínú Ìtumọ̀ Bíbélì.
Àwọn èrò fún Kíkọ́ni ní Ilé àti Ìjọ
2 Àwọn Ọba 2-6
Ọlọ́run lè ṣe iṣẹ́ ìyanu nínú ayé mi.
Àwọn iṣẹ́ ìyanu nfi agbára Ọlọ́run hàn wá. Wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro ti ayé ikú—bíiti ilẹ̀ ṣíṣá tí ó nílò omi mímọ́ (wo 2 Àwọn Ọba 2:19–22) tàbí àáké sísọnù tí ó nílò láti di wíwárí (wo 2 Àwọn Ọba 6:4–7). Ṣùgbọ́n nípàtàkì jùlọ, àwọn iṣẹ́ ìyanu lè yí wa padà sí Olúwa. Bí ẹ ti nka 2 Àwọn Ọba 2–6, ẹ yẹ ṣíṣe ìtòsílẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ẹ rí, kí ẹ sì jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ ti ẹ̀mí tí ẹ kọ́ láti inú ọ̀kọ̀ọ̀kan.
Bákannáà ẹ lè ṣe àfiwé àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Èlíṣà ṣe pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù Krístì ṣe (wo 2 Àwọn Ọba 4:8–37 àti Lúkù 7:11–16; 2 Àwọn Ọba 4:42–44 àti Jòhánnù 6:1–13; 2 Àwọn Ọba 5:1–15 àti Lúkù 17:11–19). Kínni àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí kọ́ yín nípa Olùgbàlà àti àwọn wòlíì Rẹ̀?
Bákannáà wo 2 Néfì 26:12–13; 27:23; Mórónì 7:35–37; ìpín náà “Ẹ wá kí ẹ sì retí àwọn iṣẹ́ ìyanu” nínú Russell M. Nelson, “Agbára Ipa Ti-ẹ̀mí,” Làìhónà, Ọṣù Karun 2022, 99–100.
Èlíṣà Ngbé Ọmọ Ṣúnámáìtì Dìde, láti ọwọ́ Frederic Leighton
2 Àwọn Ọba 4:8–17; 7:1–16
Olúwa yíò mú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣẹ tí a fúnni nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀.
Olúwa mísí Èlíṣà láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí ó nbọ̀—nígbàgbogbo, àwọn ohun tí ó dàbí kò ní ṣẹlẹ̀. Bí ẹ ti nka 2 Àwọn Ọba 4:8–17; 7:1–16, ẹ ronú nípa bí ẹ ṣe nfèsì sí ọ̀rọ̀ Olúwa nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀ ní òní. Kínni àwọn ìkọ́ni, àsọtẹ́lẹ̀, tàbí àwọn ìlèrí tí ẹ ti gbọ́ ní ẹnu àwọn wòlíì alààyè? Kínni ẹ̀ nṣe láti ṣe ìṣe ìgbàgbọ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ wọn?
Bákannáà wo 3 Néfì 29:6; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 1:37–38; “Ìkọ́ni ti àwọn Ààrẹ” àpapọ̀, Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
2 Àwọn Ọba 5
Bí mo ti nní ìrẹ̀lẹ̀ àti igbọ́ran, Jésù Krístì lè wò mi sàn.
Bí ẹ ti nka 2 Àwọn Ọba 5, ẹ yẹ fífi wé ẹ̀tẹ̀ Náámánì pẹ̀lú ìpènija tí ẹ̀ nkojú.
Ṣe ẹnìkan wà bíiti “ọmọ-ọ̀dọ̀ kékeré” nínú ayé yín, tí ó ngbà yín níyànjú láti wá ìtọ́sọ́nà nípa ìpènijà yín láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Olúwa? (wo àwọn ẹsẹ 2–3, 13).
Kínni Olúwa npè yín láti ṣe ohun tí ó lè dàbí o´ rọrùn jù—bíiti “wíwẹ̀, àti jẹ́ mímọ́”? (verse 13). Kínni ó lè máa pa yín mọ́ kúrò ní títẹ́wọ́gba àwọn ìfipè ìrọ̀rùn?
Báwo ni ẹ ṣe lè fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn bí Náámánì ti ṣe?
Ẹ kíyèsí bí ìrírí Náámánì ṣe ní ipá lórí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run Ísráẹ́l (wo ẹsẹ 15). Kínni ẹ lè kọ́ láti inú èyí?
Bákannáà wo Lúkù 4:27; 1 Pétérù 5:5–7; Álmà 37:3–7; Étérì 12:27; L. Whitney Clayton, “Ohunkóhùn Tí Ó Bá Wí fún Yín, Ẹ Ṣe É,” Láìhónà, Oṣu Karun 2017, 97–99; “Náámánì àti Èlíṣà” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Naaman and Elisha
Fífi àwọn ìwé-mímọ́ ṣe àfiwé ìgbésí ayé yín. Nígbàmíràn ó rọrùn jù láti wá ìtumọ̀ araẹni nínú àwọn ìwé mímọ́ nígbàtí ẹ bá ṣe àfiwé àwọn ohun ti ara nínú ìtàn kan pẹ̀lú àwọn ohun ti ẹ̀mí nínú ayé yín. Fún àpẹrẹ, nígbàti ẹ bá nṣe àṣàrò 2 Àwọn Ọba 2–7, ẹ lè ṣe àfiwe àwọn ipò nínú ayé yín sí àwọn ohun bíi ẹ̀tẹ̀, àáké yíyá, Odò Jọ́dánì, tàbí àwọn ọmọ ogun àkógunjà. Kínni àwọn ẹ̀kọ́ tí Olúwa ní fún yín nínú àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí?
2 Àwọn Ọba 6:8-23
“Àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú wọn.”
Bí ẹ ti ngbìyànjú láti tẹ̀lé Krístì, ṣe ẹ ti nímọ̀lára rí biiti ìránṣẹ́ kékeré ti Èlíṣà—tí ó kọjá-oye àti ẹlẹ́rù? Ẹ ròó bí ẹ bá wà ní ààyè rẹ̀ bí ẹ ti nka 2 Àwọn Ọba 6:8–23. Báwo ni ìtàn yí ṣe nyí ọ̀nà tí ẹ fi nronú tí ẹ sì fi nní ìmọ̀lára nípa àwọn àdánwò yín, ojúṣe yín, tàbí ìtiraka yín láti gbé ìhìnrere padà.
Bí ẹ ti njíròrò, ẹ yẹ àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Henry B. Eyring wò: “Bíiti ìránṣẹ́ Èlíṣà náà, àwọn púpọ̀ wà pẹ̀lú yín ju àwọn wọnnì tí ẹ lè rí tí wọ́n ntakò yín. Àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú yín kò ní jẹ́ rírí sí ojú ayé ikú yín. Olúwa yíò gbé yín sókè àti ní ìgbàmíràn yíò ṣeé nípa pípe àwọn ẹlòmíràn láti dúró pẹ̀lú yín” (“Áà Ẹ̀yin Tí Ẹ Bẹ̀rẹ̀,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2008, 58).
Ẹ yẹ ṣíṣe ìtòsílẹ̀ kan nípa “àwọn tí ó wà pẹ̀lú [yín]” (ẹsẹ 16)—àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run fi sí ayé yín láti tì yín lẹ́hìn. Ẹ lè ní kí Ó ràn yín lọ́wọ́ láti mọ̀ wọ́n nípa ṣíṣí ojú ti ẹ̀mí yín. Bóyá ó ti fi yín sí ayé àwọn ẹlòmíràn bákannáà láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Báwo ni ẹ ṣe lè fa okun àti àtìlẹhìn láti ọ̀dọ̀ ara yín?
Nígbàtí ẹ bá ní ìmọ̀lára àtìlẹhìn Olúwa tí a ṣe àpèjúwe nínú Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 84:88?
Ẹ lè ṣe àṣàrò ọ̀rọ Arábìnrin Michelle D. Craig bákannáà “Ojú láti Rí” (Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2020, 15–17). Ẹ bèèrè lọ́wọ́ arayín, “Kínni Ọlọ́run fẹ́ kí n rí?”
Títọ́ka sí ìtàn náà nínú 2 Àwọn Ọba 6:8–23, Alàgbà Ronald A. Rasband wípé: “A lè tàbí má tilẹ̀ ní àwọn kẹ̀kẹ́ iná tí a rán láti tú ẹ̀rù wa ká àti láti ṣẹgun àwọn èṣù wa, ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ náà hàn kedere. Olúwa wà pẹ̀lú wa, ó nrònú nípa wa ó sì nbùkún wa ní àwọn ọ̀nà tí ó jẹ́ pé Òun nìkan ní ó le ṣeé. Àdúrà lè pè okun àti ìfihàn tí a nílò láti fi àwọn èrò wa sórí Jésù Krístì àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ sọ̀kalẹ̀. Olúwa mọ̀ pé ní ìgbàmíràn a ó ní ìmọ̀ ẹ̀rù. Mo ti débẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ náà. … Nínú Ìjọ yí a lè jẹ́ díẹ̀ ní oye nípa ọ̀nà tí ayé fi nka ipa, ṣùgbọ́n nígbàtí ojú ti-ẹ̀mí wa bá ṣí, ‘àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú wọn’ [2 Àwọn Ọba 6:16]” (“Ẹ Máṣe Dààmú,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2018, 18, 19). Báwo ni ẹ ṣe lè lo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti ran ẹnìkan tí ó nní ìmọ̀lára ìtàra tàbí ẹ̀rù lọ́wọ́?
Bákannáà wo “Ẹ̀yin Ọmọ Ọ̀wọ́n, Ọlọ́run Wà Nítòsí Yín,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 96.
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé
2 Àwọn Ọba 4
Ọlọ́run lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu nínú ayé mi.
-
Lẹ́hìn ríran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye ohun tí iṣẹ́ ìyanu jẹ́, ẹ pè wọ́n láti ṣe ìtòsílẹ̀ àwọn àpẹrẹ púpọ̀ bí ẹ ti lè ṣe. Àwọn àwòrán nínú Ìwé Ọnà Ìhìnrere tàbí Wá, Tẹ̀lé Mi lè ṣèrànwọ́. Lẹ́hìnnáà ẹ lè wá àwọn iṣẹ́ ìyanu nínú 2 Àwọn Ọba 4:1–7, 14–17, 32–35, 38–44. Kínni àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí kọ́ nípa Baba Ọ̀run?
-
Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn nípa àwọn iṣẹ́́ ìyanu. Bákannáà ẹ lè kọ orin kan papọ̀ bí irú “Ìfẹ́ Oore ti Ọlọ́run” (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere).
Dúró bi Ẹlẹ́rìí kan, láti ọwọ́ Kwani Povi Winder
2 Àwọn Ọba 5:1–15
Mo lè yàn láti ṣe ohun tí Ọlọ́run pàṣẹ nípasẹ̀ wòlíì Rẹ̀.
-
Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ ìtàn náà nínú 2 Àwọn Ọba 5:1–3, 9–14. Ẹ ṣe àyẹ̀wò lílo “Èlíṣà Wo Náámánì Sàn” (nínú Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 134–37) tàbí àwòrán Náámánì nínú ìlànà ti ọ̀sẹ̀ yí. Kínni ìdí tí Náámánì kò fẹ́ láti wẹ̀ nínú Odò Jọ́dánì, àní bíótilẹ̀jẹ́pé Èlíṣà wípé èyí ni yíò wo àìsàn rẹ̀ sàn. Báwo ni Náámánì ṣe di alábùkún nígbàtí ó tẹ̀lé àwọn àṣẹ Èlíṣà? Ẹ lè pín àwọn ìrírí ìgbàtí ẹ gbọ́ràn sí Olúwa, àní nígbàtí kò dá yín lójú pé ẹ fẹ́ ṣeé pẹ̀lú arayín.
1:52Elisha Heals Naaman
-
Bákannáà ẹ lè tẹnumọ́ 2 Àwọn Ọba 5:13, níbití àwọn ìránṣẹ́ Náámánì ti ràn án lọ́wọ́ láti pinnu láti gbọ́ran sí wòlíì Èlíṣà. Àwọn ọmọ yín nígbànáà lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi lè ran àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ọmọ ẹbí wọn lọ́wọ́ láti fetísílẹ̀ sí wòlíì.
2 Àwọn Ọba 6:8-17
Èmi kò dánìkanwà.
-
Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè ròó pé a yíi yín ká nípa àwọn ọmọ ogun kan pẹ̀lú àwọn ọ̀kọ̀, ẹṣin, àti kẹ̀kẹ́ ogun. Báwo ni ẹ ó ṣe ní ìmọ̀lára sí? Kínni ẹ yíò ṣe? Àwọn ọmọ yín nígbànáà lè pa ojú wọn dé nígbàtí ẹ ó ka 2 Àwọn Ọba 6:16–17 to them. (Bákannáà wo “Èlíṣà àti Ọmọ Ogun Olúwa,” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 138–39, tàbí àwòrán ní o`pin ìlànà yí.) Nígbàtí ẹ ba dé àwọn ọ̀rọ̀ “la ojú rẹ̀” (ẹsẹ 17), ẹ ni kí àwọn ọmọ la ojú wọn. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ìránṣẹ́ náà rí. Ẹ pín àwọn ọ̀nà tí ẹ fi ní ìmọ̀lára pé Olúwa wà pẹ̀lú yín nínú àwọn ìpènijà yín, àní nígbàtí ó dàbí ẹ dánìkanwà pẹ̀lú ara yín.
1:9Elisha and the Lord’s Army
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .