“Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Iyè-inú: ‘Jésù Yíò Wí Fún Gbogbo Isráẹ́lì Pé, ‘Ẹ Wá Sílé’” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Iyè-inú: ‘Jésù Yíò Wí Fún Gbogbo Isráẹ́lì Pé, ‘Ẹ Wá Sílé,”’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Iyè-inú
“Jésù Yíò Wí Fún Gbogbo Isráẹ́lì Pé, ‘Ẹ Wá Sílé’”
Nínú ijù ti Sínáì, Mósè kó àwọn ọmọ Isráẹ́lì jọ ní ẹsẹ̀ òkè kan. Níbẹ̀ Olúwa kéde pé Òun nfẹ́ láti yí ẹgbẹ́ tí a gbàsílẹ̀ nínú ẹrú yí sílẹ̀ sí àwọn ènìyàn alágbára. “Ẹ̀yin ó jẹ́ sí mi bí,” ni ó wí, “ìjọba àwọn àlùfáà, àti orílẹ̀-èdè mímọ́ kan” (Ẹ́ksódù 19:6). Ó ṣe ìlérí pé wọn yíò gbilẹ̀ àti ṣe rere, àní nígbàtí a bá yí wọn ká nípasẹ̀ àwọn ọ̀tá alágbára, títóbijù síi.
Gbogbo èyí yíò ṣẹlẹ̀ kìí ṣe nítorí pé àwọn ọmọ Ísráẹ́lì pọ̀ rẹrẹ tàbí ní agbára tàbí ní iṣẹ́. Yíò ṣẹlẹ̀, ni Olúwa ṣàlàyé, bí wọn yíò bá “gbọ́ràn sí ohùn [Rẹ̀] lódodo, tí wọ́n sì pa májẹ̀mú [Rẹ̀] mọ́” (Ẹ́ksódù 19:5). Agbára Ọlọ́run, kìí ṣe tiwọn, yíò mú wọn di títóbi.
Síbẹ̀ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì kò gbọ́ràn sí ohùn Ọlọ́run nígbàgbogbo, àti pé ní ìgbà díẹ̀ wọ́n dáwọ́dúró ní pípa májẹ̀mú Rẹ̀ mọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ njọ́sìn àwọn ọlọ́run míràn wọ́n sì nṣe àgbàtọ́ àwọn ìṣe ti àwọn àṣà ní àyíká wọn. Wọ́n kọ ohun gan tí ó mú orílẹ̀-èdè wọn jẹ́ ọ̀tọ̀ sílẹ̀—májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú Olúwa. Láìsí agbára Ọlọ́run tí ó ndá ààbò bò wọ́n, kò sí ohunkóhun tí ó dá a`wọn ọ̀tá wọn dúró.
Fífọ́nká Náà
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní àárín bí 735 àti 720 BC, àwọn Assyríà bo Ìjọba Apá Àríwá ti Isráẹ́lì mọ́lẹ̀, ibùgbé fún àwọn ẹ̀yà mẹwa, wọ́n sì kó ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ Isráẹ́lì nígbèkùn sínú àwọn apákan onírúurú Ìjọba àwọn ọmọ Assyríà. Àwọn ọmọ Ísráẹ́lì wọ̀nyí di mímọ̀ bí “àwọn ẹ̀yà tó sọnù,” ní apákan nítorí a mú wọn kúrò ní ilẹ̀-ìní wọn a sì fọ́n wọn ká àárín àwọn orílẹ̀-èdè míràn. Ṣùgbọ́n bákannáà wọ́n sọnù nínú ọgbọ́n jíjinlẹ̀: ní ìgbà díẹ̀ wọ́n sọ ọgbọ́n ìdánimọ̀ wọn nù bí àwọn ènìyàn májẹ̀mú Ọlọ́run.
Ní ìgbẹ̀hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ní Apá Ìjọba Gúsù ti Júdàh bákannáà yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa. Àwọn Àssyríà kọlù wọ́n wọ́n sì kó púpọ̀jù àwọn ìjọbà náà lọ pẹ̀lú; Jérúsálẹ́mù nìkan ni a pa mọ́ pẹ̀lú ìyanu. Lẹ́hìnnáà, ní àárín 597 àti 580 BC, àwọn Bábílónì pa Jérúsálẹ́mù run, pẹ̀lú tẹ́mpìlì náà, wọ́n sì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn nígbèkùn. Bí Àádọ́rin ọdún lẹ́hìnnáà, àwọn ìyókù ti Júdàh ni a fàyè gbà láti padà sí Jérúsálẹ́mù kí wọ́n sì tú tẹ́mpìlì náà kọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀, bàkannáà, dúró ní Bábílónì.
Ìparun Jérúsálẹ́mù nípasẹ̀ Nebuzar-adan, láti ọwọ́ William Brassey Hole, © Providence Collection/licensed láti goodsalt.com
Bí àkokò ti nlọ, àwọn ọmọ Ísráẹ́lì láti gbogbo ẹ̀yà ni a “fọ́nká … pẹ̀lú ìjì-líle ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀” (Sekaríà 7:14). Àwọn kan ni Olúwa darí kúrò lọ sí àwọn ilẹ̀ míràn. Awọn míràn kúrò ní Isráẹ́lì láti sálọ fún kíkólọ tàbí fún òṣèlú tàbí àwọn èrèdí ọrọ̀ ajé.
A pe gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yí ní fífọ́nká Isráẹ́lì. Ó sì ṣe pàtàkì láti mọ̀ nípa fífọ́nká fún onírúurú àwọn èrèdí. Fún ohun kan, ó jẹ́ kókó àkọlé ti Májẹ̀mú Láéláé—ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlíì Májẹ̀mú Láéláé ni wọ́n jẹ́ ẹlẹri ti ìṣubú ẹ̀mí tí ó darí sí fífọ́nká náà. Wọ́n ti rí i tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ti kìlọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn kan lára wọn tilẹ̀ gbé nínú rẹ̀. Èyí jẹ́ ìrànlọ́wọ́ láti rántí nígbàtí ẹ bá nka àwọn ìwé Ísáíàh, Jeremíàh, Ámósì, àti àwọn wòlíì míràn nínú apá tí ó kẹ́hìn ní Májẹ̀mú Láéláé. Pẹ̀lú àkóónú yí ní iyè-inú, nígbàtí ẹ bá nka àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Assyria àti Bábílónì, ìbọ̀rìṣà àti ìgbèkùn, ìparun àti ìmúpadàsípò nígbẹ̀hìn, ẹ ó mọ ohun tí wọ́n nsọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
Níní òye ìfọ́nká Isráẹ́lì yíò ràn yín lọ́wọ́ láti ní òye Ìwé ti Mọ́mọ́nì dáradára síi pẹ̀lú, nítorí Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni àkọsílẹ̀ ẹ̀ka ti àwọn Isráẹ́lì tí a fọ́nká. Àkọsílẹ̀ yí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹbí Léhì tí wọ́n nsá kúrò ní Jérúsálẹ́mù nì bíi ọdún 600 kí a tó bí Krístì ṣíwájú kí àwọn Bábílónì tó kọlù wọ́n. Léhì ni ọ̀kan lára àwọn wòlíì wọnnì tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa fífọ́nká Isráẹ́lì. Àwọn ẹbí rẹ̀ ṣèrànwọ́ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ, wọ́n mú ẹ̀ka Isráẹ́lì wọ́n sì gbìn ín sí ẹ̀gbẹ́ kejì ayé, ní Àwọn Amerika.
Kíkójọ Náà
Fífọ́nká Isráẹ́lì náà, bákannáà, ni ìlàji ìtàn náà nìkan. Olúwa kìí gbàgbé àwọn ènìyàn Rẹ̀, tàbí kí Ó pa wọ́n tì, àní nígbàtí wọ́n bá pa Á ti. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run yíò fọ́n Isráẹ́lì ká ni ó bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlerí wá pé Òun yíò kó wọ́n jọ ní ọjọ́ kan.
Ọjọ́ náà ni òní—ọjọ́ wa. Kíkójọ náà ti bẹ̀rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ní 1836, ẹgbẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́hìn tí Mósè kó àwọn ọmọ Isráẹ́lì jọ ní ẹsẹ̀ Òkè Sínáì, ó farahàn ní Tẹ́mpìlì Kirtland láti fún Jósẹ́fù Smith “ní àwọn kọ́kọ́rọ́ kíkójọ Ísráẹ́lì láti igun mẹ́rin ilẹ̀ ayé” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 110:11). Nísisìyí, pẹ̀lú dídarí àwọn ènìyàn tí wọ́n di àwọn kọ́kọ́rọ́ wọ̀nyí mú, àwọn ẹ̀yà Ísráẹ́lì ni à nkójọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè níbití àwọn ìránṣẹ́ Olúwa lè lọ.
Mósè, Élíásì, àti Èlíjàh Farahàn nínú Tẹ́mpìlì Kirtland, láti ọwọ́ Gary E. Smith
Ààrẹ Russell M. Nelson ti pè kíkójọ yí ní “ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ tí ó nṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní òní. Kò sí ohun míràn tí a lè fi wé títóbi rẹ̀, kò sí ohun míràn tí a lè fi wé pàtàkì rẹ̀, kò sí ohun míràn tí a lè fi wé ọlánlá rẹ̀. Bí ẹ bá sì yàn láti, bí ẹ bá fẹ́, ẹ lè jẹ́ apákan pàtàkì ti rẹ̀.”
Báwo ni a ṣe lè ṣè irànlọwọ́? Kínni ó túmọ̀ sí láti kó Isráẹ́lì jọ? Njẹ́ ó túmọ̀sí mímúpadàbọ̀sípò àwọn ẹ̀yà méjìlá sí ilẹ̀ tí wọ́n ti gbé rí? Dájúdájú, ó túmọ̀sí ohunkan títóbijù púpọ̀, ayérayé púpọ̀ jù. Bí Ààrẹ Nelson ti ṣàlàyé:
“Nígbàtí a sọ̀rọ̀ nípa kíkójọ,, à nsọ jẹ́jẹ́ nípa ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ òtítọ́: gbogbo àwọn ọmọ Bàbá wa Ọ̀run, ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìkelè, lẹtọ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì. …
“Ìgbàkugbà tí ẹ bá ṣe ohunkóhun tí ó ran ẹnìkẹ́ni lọ́wọ́—ní èyíkéyí ẹ̀gbẹ́ ìkelè— láti gbé ìgbésẹ̀ kan síwájú ní dídá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run àti gbígba àwọn ìlànà pàtàkì wọn ti ìrìbọmi ati ti àwọn ìlànà tẹ́mpìlì, ẹ nṣe ìrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ. Ó jẹ́ rírọrùn bí èyí.”
Èyí ṣẹlẹ̀, bí Ísáíàh ti wípé, “ọ̀kan sí ọ̀kan” (Ísáíàh 27:12) tàbí, bí Jeremíàh ṣe sọtẹ́lẹ̀, “ọ̀kan ti ìlú kan, àti méjì ti ẹbí kan” (Jeremíàh 3:14).
Kíkó Isráẹ́lì jọ túmọ̀sí mímú àwọn ọmọ Ọlọ́run padà wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó túmọ̀ sí mímúpadàbọ̀sípò wọn sí májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú Rẹ̀. Ó túmọ̀sí àtún-gbékalẹ̀ “orílẹ̀-èdè mímọ́” tí Ó dá àbá láti gbékalẹ̀ tipẹ́tipẹ́ sẹ́hìn (Ẹ́ksódù19:6).
Wá Sílé
Bí ọ̀kan tí ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, ẹ jẹ́ apákan ilé Isráẹ́lì. Ẹ ti kó wa jọ, ẹ sì jẹ́ olùkójọ. Ìtàn akọni a`wọn sẹ́ntúrì-pípẹ́ nípa a`wọn ènìyàn májẹ̀mú tí wọ́n nkọ́lé lọ dé ìparí rẹ̀, ẹ sì jẹ́ kókó olùṣeré. Ìsisìyí ni àkokò náà nígbàtí “Jésù yíò wí fún Gbogbo Isráẹ́lì, ‘Wá Sílé’”
Èyí ni ọ̀rọ̀ àwọn olùkójọ: Wá sílé sí májẹ̀mú náà. Wá sílé sí Síónì Wá sílé sí ọ̀dọ̀ Jésù Krístì, Ẹni Mímọ́ Isráẹ́lì, Òun ó sì mú yín wá sílé sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Baba yín.