Come, Follow Me
Oṣù Kẹfà 29 sí Oṣù Kéje 5. “Bí Olúwa Bá Jẹ́ Ọlọ́run, Ẹ Tẹ̀lé E”: 1 Àwọn Ọba 12–13; 17–22


“Oṣù Kẹfà 29 sí Oṣù Kéje 5. ‘Bí Olúwa Bá Jẹ́ Ọlọ́run, Ẹ Tẹ̀lé E’: 1 Àwọn Ọba 12–13; 17–22,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Kẹfà 29 sí Oṣù Kéje 5. ‘Bí Olúwa Bá Jẹ́ Ọlọ́run, Ẹ Tẹ̀lé E,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026

Èlíjàh ní iwájú pẹpẹ tí ó njó

Èlíjàh Nbá àwọn Àlùfáà Báálì Jà, láti ọwọ́ Jerry Harston

Oṣù Kẹfà 29 sí Oṣù Kéje 5: “Bí Olúwa Bá Jẹ́ Ọlọ́run, Ẹ Tẹ̀lé E”

1 Àwọn Ọba 12–13; 17–22

Ilé Ísráẹ́lì wà nínú ìdàmú Ìjọba náà ti pínyà, pẹ̀lú ẹ̀yà mẹwa tí wọ́n jẹ́ apá Ìjọba Àríwá ti Ísráẹ́lì àti ẹ̀yà méjì tí wọ́n jẹ́ apá Ìjọba Gúsù ti Júdàh. Ṣùgbọ́n bíburújù ìyapa wọn kúrò ní ọ̀dọ̀ ara wọn ni méjèèjì àwọn ìjọba tí wọ́n yapa kúrò nínú májẹ̀mú wọn. Àwọn ọba búburú darí àwọn ènìyàn kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn sì kúrò nínú ìgbàgbọ́ wọn.

Nínú àgbẹ́kalẹ̀ yí, Olúwa pe Èlíjàh láti jẹ́ wòlíì. Ayé rẹ̀ fihàn pé ẹnìkan lè ní ìgbàgbọ́ nla nínú Olúwa àní àwọn ipò búburú. Nígbàmíràn Olúwa nfèsì sí irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìwọnilọ́kan, iṣẹ́ ìyanu gbangba, bíiti iná tí o nsọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Ṣùgbọ́n Òun bákannáà nṣe iṣẹ́ jẹ́jẹ́, àwọn iṣẹ́ ìyanu ìkọ̀kọ̀, bìiti bíbọ́ olótítọ́ opo kan àti ọmọ rẹ̀. Àti nígbàkugbà jùlọ àwọn iṣẹ́ ìyanu Olúwa jẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gidi tí a fi mọ̀ wọ́n nìkan sí ẹnìkan—fún àpẹrẹ, nígbàtí Olúwa fi Ararẹ̀ hàn sí yín nípasẹ̀ “ohùn jẹ́jẹ́ kékeré” (1 Àwọn Ọba 19:12).

Fún púpọ̀ síi nípa Èlíjàh, wo “Èlíjàh” nínú Ìtumọ̀ Bíbélì.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Kíkọ́ni ní Ilé àti Ìjọ

1 Àwọn Ọba 12:1–20

Àwọn olùdarí bíiti Krístì nsin àwọn ènìyàn tí wọ̀n ndarí.

Báwo ni ẹ ó ti ṣe àpèjúwe àṣìṣe tí Ọba Rèhóbóámù, ọmọ Sólómọ́nì, ṣe nínú 1 Àwọn Ọba 12:1–14? Kínni àwọn ìhùwàsí bíiti Krístì tí ìbá ti ran Rèhóbóámù lọ́wọ́ láti gba ìjọba rẹ̀ là? (wo ẹsẹ 7; Máttéù 20:25–28; Mòsíàh 2:10–21). Báwo ni ẹ ṣe lè lo àwọn ìhùwàsí wọ̀nyí bí olùdarí kan—Bóyá nínú Ìpè Ìjọ tàbí bí olùdarí ti ayé ara yín?

1 Àwọn Ọba 17:8–16; 19:19–21

àmì sẹ́mínárì
Ìfipè kan láti rúbọ jẹ́ ànfààní kan láti lo ìgbàgbọ́ mi nínú Jésù Krístì.

Wòlíì Èlíjàh ní kí opó kan fún òun ní oúnjẹ àti omi ṣíwájú bíbọ́ ararẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ tí ebi npa. Kínni ìdí tí Ó níláti ṣe bẹ́ẹ̀? Ìbéèrè Èlíjàh ni a lè rí bí ìbùkún fún ẹbí kékeré yí. Wọ́n nílò àwọn ìbùkún Olúwa, àti pé ìrúbọ nmú àwọn ìbùkún wá—pẹ̀lú ìbùkún ìgbàgbọ́ alágbára síi.

Bí ẹ ti nka 1 Àwọn Ọba 17:8–16, ẹ ronú pé ẹ jẹ́ fèrèsé yí. Kínni ó wọ̀ yín lọ́kàn nípa rẹ̀? Bákannáà ẹ lè ṣe ìtòsílẹ̀ àwọn àṣàyàn tí ó bèèrè fún ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì (fún àwọn àpẹrẹ, wo Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́: Atọ́nà Kan sí Ṣíṣe Àṣàyàn [2022]). Kínni ẹ kọ́ láti inú fèrèsé yí nípa lílo ìgbàgbọ́?

Báwo ni àwọn ìṣe Èlíṣà nínú 1 Àwọn Ọba 19:19–21 ṣe jẹ́ irúkannáà sí àwọn ìṣe ti opó?

Ẹ ronú nípa àwọn ìrúbọ tí ẹ ti ṣe láti tẹ̀lé Olùgbàlà. Kínni 1 Àwọn Ọba 17:8–16; 19:19–21 kọ́ọ yín nípa ìrúbọ wọ̀nyí? Báwo ni ìmọ̀ ti Olùgbàlà ṣe nràn yín lọ́wọ́ nígbàtí Ó bá ní kí ẹ ṣe ìrúbọ? Báwo ni Ó ti bùkún yín?

Báknnáà wo Máttéù 4:18–22; 6:25–33; Lúkù 4:24–26; “Èlíjàh àti Opó Sáréfátì” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere; “Nígbàtí Ìgbàgbọ́ Bá Dúró Pẹ́ Títí,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 128.

10:13

Elijah and the Widow of Zarephath

1 Àwọn Ọba 18

“Bí Olúwa Bá Jẹ́ Ọlọ́run, Ẹ Tẹ̀lé E.”

Àwọn Ísráẹ́lì lè ti nímọ̀lára pé wọ́n ní àwọn èrèdí rere sí jíjọ́sìn Báálì, ẹnití a mọ̀ bí ọlọ́run àwọn ìjì àti òjò. Lẹ́hìn ọdún mẹ́ta ọ̀gbẹlẹ̀, wọ́n nílò òjò taratara. Àti pé jíjọ́sìn Báálì ni ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní àwùjọ tí a sì ngbéga nípasẹ̀ ọba àti ayaba. Bí ẹ ti nka 1 Àwọn Ọba 18, ẹ ronú nípa ìdí tí ẹnìkan ní ọjọ́ wa fi lè jẹ́ aláìnípinnu nípa títẹ̀lé Olúwa. Nínú orí yí, kínni ẹ rò pé Olúwa ngbìyànjú láti kọ́ nípa Ararẹ̀? Kínni àwọn ìrírí tí o´ ti ràn yín lọ́wọ́ láti farajì sí títẹ̀lé Olùgbàlà?

Bákannáà wo D. Todd Christofferson, “Àṣàyàn àti Ìfarajì” (ìsìn àkànṣe káríayé fún àwọn ọ̀dọ́ àgbà,Oṣù Kínní 12, 2020), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

Èlíjàh lórí Òkè Hórébù

Ìjúwe Èlíjàh, láti ọwọ́ Wilson Ong

1 Àwọn Ọba 19:1–18

Olúwa nsọ̀rọ̀ ní àwọn ọ̀nà kẹ́lẹ́, ìrọ̀rùn léraléra.

Ní bíbanújẹ́, iṣẹ́ ìyanu lórí Òkè Kámẹ́lì kò mú kí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Èlíjàh rọrùn rárá. Ní tòótọ́, ayé rẹ̀ wà nínú ewu, ó sì ní láti sápamọ́ sínú ihò-òkúta nínú aginjù. Níbẹ̀, ó làkàkà pẹ̀lú dídánìkanwà àti àìnìrètí, ó ní ìrírí pẹ̀lú Olúwa tí ó yàtọ̀ gan kúrò ní ìrírí orí Òkè Kámẹ́lì. Kínni ìrírí Èlíjàh nínú 1 Àwọn Ọba 19:1–18 kọ́ yín nípa bí Olúwa ṣe nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú yín ní àwọn àkokò àìní yín?

Ẹ jíròrò àwọn àkokò nígbàtí ẹ ti nímọ̀lára tí Olúwa ti sọ̀rọ̀ síi yín. Bàwo ni ẹ yíò ti ṣe àpèjúwe ọ̀nà tí ó fi nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú yín? Kínni ìdí tí àwọn ọ̀rọ̀ náà “kẹ́lẹ́” and “kékeré” fi jẹ́ àwọn ọ̀nà láti ṣe àpèjúwe ohùn Ẹ̀mí? Àwọn ọ̀rọ̀ míràn wo ni ẹ rí nínú Hẹ́lámánì 5:30; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 6:22–23; 11:12–14? Kínni ẹ nílò láti ṣe láti gba itọ́sọ́nà Olúwa léraléra síi?

Bákannáà wo Orin Dáfídì 46:10.

Lo onírúurú ọgbọ́n láti mú ìkọ́ni gbòòrò. Gbogbo wa nkọ́ nípa ayé nípasẹ̀ ọgbọ́n wa marun. Lílo ọgbọ́n wọnnì bákannáà lè mú ìkọ́ni ìhìnrere gbòòrò. Fún àpẹrẹ, ẹ ronú nípa àwọn àwòrán tàbí ìró tí ẹ lè lò láti júwe àwọn ọ̀rọ̀ náà “kẹ́lẹ́” àti “kékeré” bí ẹ ti nkọ́ nípa ohùn Olúwa nínú 1 Àwọn Ọba 19.

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jàde oṣù yí ti àwọn ìwé ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .

ìpín àmì àwọn ọmọdé

Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé

1 Àwọn Ọba 17

Olúwa nbùkún mi bí mo ti nní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀.

  • Láti ran àwọn ọmọ yín lówọ́ láti kọ́ àwọn ìtàn ìgbàgbọ́ nínú 1 Àwọn Ọba 17, ẹ lè fi àwọn àwòrán tàbí nkan hàn wọ́n láti júwe àwọn ìtàn, bí irú àwọn ẹyẹ, búrẹ́dì, tàbí ọmọdékùnrin kan. Bí ẹ ti nsọ àwọn ìtàn wọ̀nyí fún àwọn ọmọ yín, ẹ pè wọ́n láti wá àwòrán tàbí nkan tí ó lọ pẹ̀lú ìtàn kọ̀ọ̀kan. “Wòlíì Èlíjàh” (nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 121–24) lè ràn yín lọ́wọ́ láti sọ àwọn ìtàn wọ̀nyí. Kínni ìtàn kọ̀ọ̀kan kọ́ yín nípa fífi ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì hàn?

    1:58

    Elijah the Prophet

  • Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi lè fi ìgbàgbọ́ wọn nínú Jésù Krístì hàn. Kíkọ orin pẹ̀lú wọn nípa ìgbàgbọ́, bí irú “Mo Ní Ìgbàgbọ́ nínú Olúwa, Jésù Krístì” (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere), àti láti pín ohun tí ẹ kọ́ nípa ìgbàgbọ́ láti inú orin náà pẹ̀lú ara yín.

Èlíjàh, opó kan, àti ọmọ rẹ̀

Ìjúwe Èlíjàh àti ìwòsàn ọmọ opó, láti ọwọ́ Charles Edmund Brock

1 Àwọn Ọba 17:8–16

Nígbàtí Olúwa bá ní kí nṣe ìrúbọ, mo lè gbọ́ran nínú ìgbàgbọ́.

  • Bóyá àwọn ọmọ yín lè ya àwòrán kan nípa ohun tí Olúwa ní kí opó fún Èlíjàh (wo 1 Àwọn Ọba 17:12–13) àti ohun tí opó gbà ní àpadàbọ̀ (wo 1 Àwọn Ọba 17:15–16). (Bákannáà wo ojú-ewé ṣíṣe ọ̀sẹ̀ yí.) Bákannáà wọ́n lè wá àwọn àwòrán ti àwọn ènìyàn míràn tí wọ́n fi ohunkan tí wọ́n fẹ́ sílẹ̀ fún ohunkan dídárajù. Ẹ pe àwọn ọmọ yín láti wá àwọn àwòrán nínú Ìwé Ọnà Ìhìnrere tàbí Wá, Tẹ̀lé Mi. Kíní Olúwa ní kí a rúbọ? Báwo ni Òun ṣe nbùkún wa?

1 Àwọn Ọba 18:17–39

Mo lè yàn láti tẹ̀lé Jésù Krístì.

  • Bí ẹ ti nka 1 Àwọn Ọba 18:17–39 papọ̀, àwọn ọmọ yín lè mú ẹsẹ kan kí wọ́n sì ya àwòrán nípa ohun tí a ṣe àpèjúwe. Wọ́n lè lo àwọn àwòrán wọn láti sọ ìtàn náà nínú àwọn ọ̀rọ̀ ara wọn. (Bákannáà wo “Èlíjàh àti àwọn Àlùfáà Báálì,” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 125–28.)

    2:17

    Elijah and the Priests of Baal

  • Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ipò nígbàtí wọ́n lè nílò làti pinnu bóyá tàbí láti máṣe tẹ̀lé Jésù Krístì. Bóya wọ́n lè ya àwọn àwòrán ti arawọn tí wọ́n nṣe àṣàyàn tótọ́. Ẹ pín ìdí tí ẹ fi yàn láti tẹ̀lé Jésù pẹ̀lú ara yín.

1 Àwọn Ọba 19:9-12

Olúwa nsọ̀rọ̀ sí mi nípasẹ̀ ohùn kẹ́lẹ́, kékeré ti Ẹ̀mí Mímọ́.

  • Bí ẹ ti nṣe àkópọ̀ 1 Àwọn Ọba 19:9–12, ẹ pe àwọn ọmọ yín láti ṣe àwọn ìṣe láti rọ́pò ìjì líle, isẹ́lẹ̀, àti iná. Nígbànáà ẹ pè wọ́n láti joko kẹ́lẹ́ bí ẹ ti nsọ, nínú ohùn jẹ́jẹ́ papọ̀, “lẹ́hìn iná ni ohùn kẹ́lẹ́ kékeré” (ẹsẹ 12). (Bákannáà wo “Olúwa Nbá Èlíjàh Sọ̀rọ̀,” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 129–31.) Ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín àwọn àkokò nígbàtí ẹ ti ní ìrírí ohùn kẹ́lẹ́, kékeré ti Ẹmí Mímọ́.

    1:48

    The Lord Speaks to Elijah

  • Ẹ kọ orin kan jẹ́jẹ́ nípa Ẹ̀mí “Ohùn Kẹ́lẹ́ Kékeré” (Iwé-orin àwọn Ọmọdé, 106–7). Kínni ó lè dà wá lámú kúrò ní dídá Ẹ̀mí mọ̀? Kínni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbọ́ Ọ?

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde òṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .

Opó Sárépátì àti ọmọ rẹ̀

Opó Sárépátì, láti ọwọ́ Rose Datoc Dall

Ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Nígbàtí Olúwa bá ní kí nṣe ìrúbọ, mo lè gbọ́ran nínú ìgbàgbọ́.