“Oṣù Kẹfà 22–26. ‘Gbọ́ Àdúrà Wọn Ní Ọ̀run’: 2 Sámúẹ́lì 11–12; 1 Àwọn Ọba 3; 6–9; 11,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹfà 22–26. ‘Gbọ́ Àdúrà Wọn Ní Ọ̀run,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Sólómọ́nì Nya Tẹ́mpìlì sí Mímọ́ ní Jérúsálẹ́mù, láti ọwọ́ James Tissot àti àwọn ẹlòmíràn
Oṣù Kẹfà 22– 28: “Gbọ́ Àdúrà Wọn Ní Ọ̀run”
2 Sámúẹ́lì 11–12; 1 Àwọn Ọba 3; 6–9;11
Sáùlù, Dáfídì, àti Sólómọ́nì, àwọn ọba mẹ́ta àkọ́kọ́ ti Ísráẹ́lì, gbogbo wọ́n bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìlérí tó pọ jọjọ. Nínú ìrẹ̀lẹ̀, ìgboyà, àti ọgbọ́n, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn rí ojúrere pẹ̀lú Olúwa—aó kéréjù ní àkọ́kọ́. Pẹ̀lú ìbánujẹ́, ọba kọ̀ọ̀kan bákannáà fírasílẹ̀ fún àwọn àìlera ènìyàn àti àdánwò. Wọ́n fi ìfẹ́-inú ara wọn ṣíwájú ti Olúwa. Bí a sì ti ríi lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kansi nínú àwọn ìwé mímọ́—àti nínú ayé ti ara wa—ti darí lọ sí àjálù.
Ṣùgbọ́n ohunkan pàtàkì ṣẹlẹ̀ nínú ìjọba Sólómọ́nì tí ó pèsè ìrètí díẹ̀ fún ìmúdúró nínú ayé àwọn ènìyàn májẹ̀mú. Sólómọ́nì kọ́ tẹ́mpìlì kan Ó yẹ kó jẹ́ ilé Olúwa títílọ ju bí àgọ́ ti jẹ́ Yíò sì rọ́pò wíwà títílọ síi ti Olúwa ní àárín àwọn ènìyàn Rẹ̀. Sólómọ́nì mọ̀ pé àwọn ènìyàn yíò tẹ̀síwájú láti kojú àìlera àti àwọn àdánwò ti irú oríṣiríṣi. Ní yíya ilé mímọ́ titun náà sí mímọ́, Sólómọ́nì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa, “Bí wọ́n bá fi … gbogbo ọkàn wọn yípadà sí ọ, … nígbànáà ni ìwọ́ ó gbọ́ àdúrà wọn” (1 Àwọn Ọba 8:47–48). Èyí ni ara ohun tí àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì nṣe fún wa—wọ́n dá ìsopọ̀ kan sílẹ̀ sí Ọlọ́run. Wọ́n ṣe ìmúdúró ìlérí náà nípa ìrònúpìwàdà àti àánú fún wa, Òun lè “gbé ní àárín [wa]” kì yíò sì kọ̀ wá sílẹ̀ (1 Àwọn Ọba 6:13).
Fún àkópọ̀ ìwé Àwọn Ọba, wo “ìwé ti, Àwọn Ọba” nínú Ìtumọ̀ Bíbélì.
Àwọn èrò fún Kíkọ́ni ní Ilé àti Ìjọ
2 Sámúẹ́lì 11; 12:1–14
Olúwa lè ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àṣàyàn rere nígbàtí a bá dán mi wò láti dẹ́ṣẹ̀.
Nígbàmíràn à nwo àwọn ènìyàn tí ó dá bí ẹnipé wọ́n lágbára nínú ìgbàgbọ́ wọn, a ó sì rò pé wọ́n kò ní ìpalára nípa àdánwò. Àwọn àṣàyàn àjálù tí a ṣe àpèjúwe nínú 2 Sámúẹ́lì 11 hàn kedere pé èyí kìí ṣe ọ̀ràn náà. Ẹ yẹ àwọn ẹ̀kọ́ tí ẹ lè kọ́ láti inú àwọn ìrírí rẹ̀. Àwọn ìbèèrè bí ìwọ̀nyí lè ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àṣàrò 2 Sámúẹ́lìl 11–12:
-
Kínni àwọn àṣàyàn tí Dáfídì ṣe tí ó darí rẹ̀ lọ sí ipa ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀? Kínni àwọn àṣàyàn òdodo tí ẹ lè ṣe dípò bẹ́ẹ̀? (Bákannáà wo fídíò “Láti Wò Ó,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.)
4:15To Look Upon
Lílo àwọn fídíò. Àwọn fídíò lè ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ láti inú àwọn ìwé mímọ́ kí a sì yẹ bí wọ́n ṣe wúlò sí wa wò. Ẹ yẹ bí ẹ ṣe lè lò wọ́n láti mú ìkọ́ni àti kíkọ́ ẹ̀kọ́ gbòòrò. Fún àpẹrẹ nígbàtí ẹ bá nwo “Láti Wò Ó” (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere), ẹ yẹ dídá fídíò náà dúró ní onírúurú àmì tàbí sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbèèrè tí dá àbá nínú ṣíṣe yí.
-
Báwo ni ọ̀tá ṣe ngbìyànjú láti darí yín lọ sílẹ̀ sí ipa ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀? Kínni àwọn àṣàyàn tí ẹ lè ṣe nísisìyí láti dúró láìléwu níti ẹ̀mí?
-
Ẹ kíyèsí ìdáhùn Dáfídì sí Nátánì nínú 2 Sámúẹ́lì 12:1–6. Kínni ìdáhùn rẹ̀ dá ní àbá nípa bí Dáfídì ṣe wo ararẹ̀? Kínni Olúwa ti ṣe láti ràn yín lọ́wọ́ láti rí arayín déédé síi?
-
Báwo ni ẹ ó ti ṣe àkópọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti 2 Sámúẹ́lì 11–12 nínú ìkìlọ̀ ẹ̀là ọ̀rọ̀ kan?
Kíkà nípa àwọn àṣàyàn búburú Dáfídì lè darí yín láti kọ́ nípa àwọn ewu ti pònógíráfì àti ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀. Ohun èlò rere kan fún èyí ni Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́: Atọ́nà Kan fún Ṣíṣe àwọn Àṣàyàn, nípàtàkì àwọn ìpín tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Kínni a níláti ṣe ní àkokò náà” àti “Ara yín jẹ́ mímọ́” (àwọn ojú-ewé 21–28). Bóyá ẹ lè wo inú ohun èlò náà fún ìmọ̀ràn tí ìbá ti ran Dáfídì lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àṣàyàn dáradára. Tàbí ẹ lè ka “Jésù Krístì yíò ràn yín lọ́wọ́” (àwọn ojú-ewé 6–9), wíwá ohunkan tí ìbá ti ran Dáfídì lọ́wọ́ láti padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa.
Ẹ yẹ kíkọ orin ìsìn kan bíi “Mo Nílò Rẹ Ní Gbogbo Wákàtí” (Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 98) kí ẹ sì jíròrò bí Olùgbàlà ṣe nfún yín lókun nígbàtí ẹ bá kojú àdánwò.
Bákannáà wo 2 Néfì 28:20–24; Ulisses Soares, “Wá Krístì nínú Gbogbo Èrò,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2020, 82–85; “Gbígba Àkóso Ẹ̀rọ Ìgbàlódé,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere; “Ẹ Wo Ìgbésẹ̀ Yín” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Watch Your Step
1 Àwọn Ọba 3:1–15
Ẹ̀bùn ìwòyè nràn mí lọ́wọ́ láti mọ̀ ìyàtọ̀ ní àárín títọ́ àti àṣìṣe.
Bí Olúwa bá sọ fún yín pé, “Bèèrè ohun tí èmi o´ fún ọ” (1 Àwọn Ọba 3:5), kínni ìwọ yíò bèèrè fún? Kínni ó wọ̀ tín lọ́kàn nípa ìbèèrè Sólómọ́nì? Jíròrò ìdí “ọkàn tó ní òye” láti “mọ ìyàtọ̀ ní àárín rere àti búburú” (ẹsẹ 9) ni ẹ̀bùn oníyelórí. Kínni ẹ lè ṣe láti wá ẹ̀bùn yí?
Bákannáà wo Mórónì 7:12–19.
1 Àwọn Ọba 6–8; 9:1–9
Nípa àwọn májẹ̀mú tí a ṣe ní ilé Olúwa, Olúwa ngbé pẹ̀lú mi.
Nínú 1 Àwọn Ọba 6–7 ẹ yíò rí ìjúwe ti ilé mímọ́ tí Sólómọ́nì kọ́ fún Olúwa. Àlàyé náà lè má dàbí ó ṣe pàtàkì sí yín bí wọ́n ti ṣe sí àwọn Ísráẹlì àtijọ́. Ṣùgbọ́n kíka àwọn orí wọ̀nyí lè fún yín ní ọgbọ́n fún bí ó ti ṣe pàtàkì sí wọn láti ní ilé Olúwa. Kínni ìdí tí ó fi jẹ́ pàtàkì sí yín?
Ẹ lè jíròrò ohun tí yíyàtọ̀ ara tẹ́mpìlì Sólómọ́nì lè fihàn. Fún àpẹrẹ, ẹ yẹ ohun tí Kérúbù, igi, àti òdòdó nínú 1 Àwọn Ọba 6:35 lè rọ́pò wò. (Bákannáà wo Gẹ́nẹ́sísì 3:24.)
Orí 8 àwọn àkọsílẹ̀ àdúrà Sólómọ́nì ní píparí tẹ́mpìlì (wo àwọn ẹsẹ 22–61). Ẹ yẹ ṣíṣe ìtòsílẹ̀ kan nípa àwọn ìbùkún tí Sólómọ́nì bèèrè fún. Kínni ó wọ̀ yín lọ́kàn nípa àwọn ìbùkún wọ̀nyí? (Bákannáà ẹ kíyèsí àwọn ìlérí Olúwa nínú 2 Àwọn Ọba 6:11–13; 9:1–9.) Bí ẹbá ti dé ilé Olúwa rí, ẹ ronú nípa àwọn ìrírí yín ti jíjọ́sìn níbẹ̀. Báwo ni pípa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì mọ́ ṣe nràn yín lọ́wọ́ láti ní ààyè sí àwọn ìbùkún Olúwa?
Bákannáà wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 109; Henry B. Eyring, “Mo Fẹ́ràn láti Rí Tẹ́mpìlì,” Làìhónà, Oṣù Karun 2021, 28–31.
Tẹ́mpìlì Barranquilla Colombia
1 Àwọn Ọba 8:61; 11:1–11
“Ọkàn rẹ̀ kò pé pẹ̀lú Olúwa.”
Kínni ó túmọ̀sí láti “jẹ́ kí ọkàn rẹ … pé pẹ̀lú Olúwa”? (1 Àwọn Ọba 8:61). Ṣe èyí yàtọ̀ sí àwọn ìṣe wa ní jíjẹ́ pípé? Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ẹ ka 1 Àwọn Ọba 11:1–11, kí ẹ sì ṣe àkíyèsí ohun tí Olúwa sọ nípa Sólómọ́nì. Ẹ lè jíròrò bóyá àwọn ipa wọ̀ nínú ayé yín tí ó lè yí ọkàn yín kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa àti sí “àwọn ọlọ́run míràn.”
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé
2 Sámúẹ́lì 11
Olúwa lè ràn mí lọ́wọ́ nígbàtí mo bá jẹ́ dídánwò.
-
“Ọba Dáfídì” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 117–20, lè ràn yín lọ́wọ́ láti sọ ìtàn náà fún àwọn ọmọ yín nínú 2 Sámúẹ́lì 11. Ẹ lè bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ yín láti mọ àwọn àṣàyàn àṣìṣe tí Dáfídì ṣe àti láti dá àbá àwọn àṣàyàn rere tí ìbá ti ṣe dípò bẹ́ẹ̀. Kínni àwọn ohun kan tí a lè ṣe nígbàtí a bá jẹ́ dídánwò tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àṣàyàn tótọ́?
2:11King David
-
Kíkà nípa àjàlù ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì lè jẹ́ ànfààní rere láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ewu pọ̀nógíráfì. Fídíò “Kínni Mo Níláti Ṣe Nígbàtí Mo Bá Rí Pọ̀nógíráfì?” (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere) ní itọ́sọ́nà tó le ṣèrànwọ́. Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe ètò nípa ohun tí wọn yíò ṣe nígbàtí wọ́n bá pàdé pọ̀nógíráfì.
5:46What should I do when I see pornography?
1 Àwọn Ọba 8:22–61
Dída àwọn májẹ̀mú nínú ilé Olúwa—àti pípa wọ́n mọ́—nràn mí lọ́wọ́ láti rìn ní àwọn ọ̀nà Rẹ̀.
-
Bí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín ti nkọ́ nípa ìyàsímímọ́ tẹ́mpìlì nínú 1 Àwọn Ọba 8, ẹ lè wo àwọn àwòrán ti tẹ́mpìlì nínú ìlànà ọ̀sẹ̀ yí. Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín sọ̀rọ̀ nípa àlàyé tí wọ́n rí nínú àwọn àwòrán náà. Ẹ lè tẹnumọ́ àwọn ẹsẹ 57–58. Kínni ó túmọ̀sí láti “rìn ní gbogbo àwọn ọ̀nà [ti Olúwa]”? 1 Àwọn Ọba 19:12 Bóyá àwọn ọmọ yín lè gbé ìgbésẹ́ kan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìdáhìn tí wọ́n fúnni.
-
Ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín bí ẹ ti lè pa àwọn májẹ̀mú tí ẹ dá nínú tẹ́mpìlì nràn yín lọ́wọ́ láti rìn ní àwọn ọ̀nà Olúwa. Ẹ lè sọ fún wọn ohun tí àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí jẹ́ (wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 27.2, Ibi-ìkàwé Ìhìnrere). Bákannáà ẹ lè kọ orin papọ̀ bíiti “Mo Fẹ́ràn láti Rí Tẹ́mpìlì” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 95).
Ìjúwe tẹ́mpìlì Sólómọ́nì, láti ọwọ́ Sam Lawlor
1 Àwọn Ọba 11:1–11
Mo lè fi Olúwa ṣíwájú nínú ayé mi.
-
Kíkà nípa bí àwọn ìyàwó Sólómọ́nì ṣe ní ipá lórí rẹ̀ lè darí sí ìbárasọ̀rọ̀ nípa àwọn àpẹrẹ ti “àwọn ọlọ́run míràn”—tàbí ohun tí àwọn ènìyàn njọ́sìn tàbí fẹ́ràn dípò Olúwa. Báwo ni a ṣe nfihàn pé a fẹ́ràn Rẹ̀ ju ohunkóhùn míràn nínú ayé wa?
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .