Oṣù Kẹfà 8–14. ‘Olúwa nwo ọkàn’: 1 Sámúẹ́lì 8–10; 13; 15–16,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
Oṣù Kẹfà 8–14. ‘Olúwa nwo ọkàn,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Ní Ẹ̀gbẹ́ àwọn Omi Dídákẹ́ Rọ́rọ́, láti ọwọ́ Simon Dewey
Oṣù Kẹfà 8–14:“Olúwa nwo ọkàn”
1 Sámúẹ́lì 8–10; 13; 15–16
Sáùlù jẹ́ olùpamọ́ àwọn ràkúnmi Bíótilẹ̀jẹ́pé ó ga ó sì rẹwà, ó “kéré ní ojú ara [rẹ̀]” ó sì ní ìfura-araẹni nípa ogún ẹbí rẹ̀ (wo 1 Sámúẹ́lì 9:2–3, 21; 15:17). Ní ọjọ tí a níláti fi í han Isráẹ́lì bí ọba wọn, kò fi ara hàn; ó ngbọ̀n rìrì tó bẹ́ẹ̀ tí “ó pa ararẹ̀ mọ́” (1 Sámúẹ́lì 10:21–22). Ní wíwo Sáùlù, ẹ lè má tilẹ̀ ròó pé òun yíò darí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì sí ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wọn—tàbí pé óun yíò di agbéraga àti aṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa.
Dáfídì jẹ́ olùpamọ́ àwọn àgùtàn. Òun kò sì jẹ́ wíwuni níti ara bíiti àwọn arákùnrin rẹ̀ àgbà méje. Ní ọjọ́ tí Sámúẹ́lì wá láti yan ọba titun fún Ísráẹ́lì, kò dàbí ẹnipé ó yẹ láti fi Dáfídì kún àárín àwọn adíjè tó ṣééṣe, nítorínáà a fi í sílẹ̀ nínú pápá pẹ̀lú àwọn àgútàn. Ní wíwo Dáfídì, ẹ lè má tilẹ̀ ròó pé òun yíò ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà láti borí alágbára kan kí ó sì di ọba Isráẹ́lì tí ó yege jùlọ.
Ṣùgbọ́n Olúwa nwò kọjá àwọn àlẹ̀mọ́ wa, ìrísí ti ara wa, àìní-ààbò wa. Dípò bẹ́ẹ̀, Ó nwo, “ọkàn” (1 Sámúẹ́lì 16:7). Àní nígbà tí ọkàn wà kò bá sí ní títọ́, bí a bá nfẹ́, Òun yíò fún wa ní “ọkàn míràn” (1 Sámúẹ́lì 10:9).
Àwọn èrò fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti Ìjọ
1 Sámúẹ́lì 8
Jésù Krístì ni Ọba mi.
1 Sámúẹ́lì 8 sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tí yíò yí àyànmọ́ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì padà títí láé. Fún ààbò ní ìlòdì sí àwọn ọ̀tá, àwọn ọmọ Ísráẹ́lì nfẹ́ ohun tí àwọn aladugbo wọn ní—ọba láti ṣe àkóso ní orí wọn. Bí ẹ ti nkà nípa ìbèèrè wọn àti èsì Olúwa, ẹ ronú nípa ẹni tí ẹ̀ nwò fún ààbò àti atọ́nà. Ẹ yẹ ohun tí ó túmọ̀ sí wò láti jẹ́ kí Olúwa “jọba lórí [yín]” (1 Sámúẹ́lì 8:7).
Ní àwọn ọ̀sẹ̀ tí ó nbọ̀, ẹ yíò kà nípa oye àwọn ọba tí a pè láti darí Ísráẹ́lì. Bí ẹ ti nkọ́ nípa wọn, ẹ yẹ àwọn ìbèèrè wọ̀nyí wò:
-
Báwo ni a ṣe nmú àwọn ìkìlọ̀ Olúwa ṣẹ nínú 1 Sámúẹ́lì 8:10–18?
-
Báwo ni a ṣe pa àwọn ọmọ Isráẹ́lì lára nípa yíyan wọn láti ní ọba ti ayé?
-
Báwo ni Jésù Krístì ṣe yàtọ̀ sí àwọn ọba ayé? Ẹ gbèrò àwọn ohun ipa ti ayé tí ẹ lè nílò láti mú kúrò nínú ayé yín láti lè jẹ́ kí Krístì jẹ́ ọba yín.
Bákannáà ẹ wo “Ẹ Yọ̀, Olúwa ni Ọba!,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 66.
1 Sámúẹ́lì 9–10; 16:1–13
Ọlọ́run npe àwọn ènìyàn nípa àsọtẹ́lẹ̀ láti sìn nínú ìjọba Rẹ̀.
Ẹ kà nípa bí Ọlọ́run ṣe yan àwọn ọba Ísráẹ́lì ní 1 Sámúẹ́lì 9–10 àti16 (nípàtàkì wo 9:15–17; 10:1–12; 16:1–13). Ẹ wá àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ tí ó nràn yín lọ́wọ́ láti ní òye ohun tí ó túmọ̀sí láti “gba ìpè láti ọwọ́ Ọlọ́run, nípa àsọtẹ́lẹ̀” nínú Ìjọ Olúwa ní òní (Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ 1:5). Ẹ lè yẹ fífi arayín sí ipò ti olùdarí tí ó nnawọ́ ìpè sí (Sámúẹ́lì), ẹni tí à npè ni (Sáùlù àti Dáfídì), àti àwọn ènìyàn tí a pè wọ́n láti sìn (àwọn ọmọ Ísráẹ́lì). Kínni ohun tí ẹ kọ́ láti inú àwọn ọ̀rọ̀ wọn àti ìṣe nínú àwọn orí wọ̀nyí?
Ìjúwe ti Sámúẹ́lì tí ó nfi àmì òróró yan Sáùlù, láti ọwọ́ P. Mann, ©Lifeway Collection/licensed láti ọ̀dọ̀ goodsalt.com
1 Sámúẹ́lì 13: 5–14;15
“Láti gbọ́ran dára ju ìrúbọ lọ.”
Ẹ ṣe àyẹ̀wò bí àìsé-èémí Sáùlù ṣe dàbí nínu 1 Sámúẹ́lì 10, ó yanilẹ́nu láti kà nípa “ìṣọ̀tẹ̀” àti “agídí” lẹ́hìn ti ó di ọba (1 Sámúẹ́lì 15:23). Kínni ìdí tí ẹ ṣe rò pé èyí ṣẹlẹ̀? Nínú 1 Sámúẹ́lì13:5–14, Kínni àwọn ìhùwàsí àti ìwà tí ẹ rí tí ó darí sí ìjákulẹ̀?
Nínu 1 Sámúẹ́lì 15, ẹ yíò kà nípa òfin láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí Sáùlù kò gbọ́ran sí nítorí ó rò pé òun ní èrèdí rere. Láti kẹkọ láti inú àwọn yíyàn búburú ti Sáùlù, wòó ní ẹsẹ 22 kí ẹ fi rọ́pò àwọn ọ̀rọ̀ “ìrúbọ” àti “ọ̀rá àgbò” pẹ̀lú àwọn ohun tí ó dàbí rere ṣùgbọ́n tí wọn kò jẹ́ pàtàkì bí gbígbọ́ àti gbígbọ́ran sí Olúwa. Ṣe a ti bùkún yín bí ẹ ti nfi ìfẹ́ Olúwa ṣíwájú nínú ayé yín?
1 Sámúẹ́lì 16:6-12
“Olúwa nwo ọkàn.”
Ṣé ẹ ti ṣe ìpìnnu kan rí tí ó dá lé “ìwò ojú” ti ohun kan tàbí ẹnìkan, kí ẹ tó ri pé ẹ̀ ṣe àṣìṣe? Bóyá ẹ jẹ ohun kan tí kò dára bí ó ti rí. Tàbí bóyá ẹ ṣe ìdájọ́ ẹnìkan ní àìdára.
Nígbàtí Sámúẹ́lì nwá ọba titun kan fún Isráẹ́lì, Olúwa kọ́ ọ ní ọ̀nà dídára kan. Ẹ kà nípa rẹ̀ ní 1 Sámúẹ́lì 16:6–7, kí ẹ sì gbèrò ṣíṣe ìtòsílẹ̀ àwọn ọ̀nà tí àwọn ènìyàn fi nṣe ìdájọ́ àwọn ẹlòmíràn “ní ìwò ojú.” Ẹ lè rí àwọn àpẹrẹ nínú ọ̀rọ̀ Alàgbà Christophe G. Giraud-Carrier “Àwa Ni Àwọn Ọmọ Rẹ̀” (Làíhónà, Oṣù Kọkànlá. 2023, 114–16). Kínni ó túmọ̀sí láti wo “ọkàn,” bí Olúwa ti ṣe? (1 Sámúẹ́lì 16:7). Ẹ lè rí àwọn àpẹrẹ ti èyí, pẹ̀lú, nínú ọ̀rọ̀ Alàgbà Giraud-Carrier. Bóyá ẹ lè ronú nípa àwọn ìgbà míràn nígbàtí Olùgbàlà bá wò kọjá ìwò ojú ti ẹnì kan. (Fún àpẹrẹ, wo, Márkù 12:41–44; Lúkù 5:1–11; 19:1–9; Jòhánnù 4:5–30; Mósè 6:31–36.) Kínni ẹ kọ́ láti inú àwọn àpẹrẹ ìwọ̀nyí.
Báwo ni ẹ ṣe lè tẹ̀lé àpẹrẹ Olùgbàlà ní ọ̀nà tí ẹ fi rí àwọn ẹlòmíràn—àti arayín? Báwo ni ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ṣe ní ìpalára sí àwọn ìbàṣe yín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn? Ẹ yẹ sísọ fún ẹnìkan wò nípa inúrere tí ẹ rí nínú ọkàn yín.
Bákannáà wo Ulisses Soares, “Ẹ̀yin Arákùnrin àti Arábìnrin nínú Krístì,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2023, 70–73.
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé ìròhìn ti Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
1 Sámúẹ́lì 8
Jésù Krístì ni Ọba mi.
-
Bí ẹ ti nka 1 Sámúẹ́lì 8 pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí àwọn èrèdí tí Sámúẹ́lì fi wí fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì pé níní ọba jẹ́ èrò búburú. Kínni ìdí tí ó fi dára láti ní Jésù Krístì bí ọba wa? Bóyá ẹ lè ṣe bẹ́bà adé papọ̀ kí ẹ sì yí ní wíwọ̀ ọ́ àti pípín ohunkan tí a lè ṣe láti fihàn pé à nfẹ́ kí Jésù jẹ́ Ọba wa. (Bákannáà wo Jeremíàh 23:5; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 45:59.)
1 Sámúẹ́lì 8:6; 9:15–17; 10:1–24; 16:1–13
Àwọn ènìyàn tí wọ́n nsìn nínú Ìjọ ni a pè láti ọwọ́ Ọlọ́run.
-
Àwọn àkọsílẹ̀ Ọlọ́run ní yíyan Sáùlù àti Dáfídì láti jẹ́ àwọn ọba ni ó lè ràn àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye bí a ti npe àwọn ènìyàn láti sìn nínú Ìjọ ní òní nípa ìfihàn. Láti kọ́ wọn ní ìtàn wọ̀nyí, ẹ lè kọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ sílẹ̀ láti inú àwọn ìtàn lórí ìlà bébà, àti pé àwọn ọmọ yín lè fi wọ́n sí èrò títọ́ bí ẹ ti nka àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ papọ̀ (bákannáà wo “David kékeré” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 110–11). Nígbànáà ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìgbà nígbàtí Ọlọ́run ti bùkún yín pẹ̀lú agbára ti ẹ̀mí láti mú àwọn ìyànni-síṣẹ́ tàbí ìpè ṣẹ (wo 1 Samuẹlì 10:9–10).
1:16Young David
-
Èyí bákannáà lè jẹ́ àkokò rere láti kọ́ àwọn ọmọ yín ní nkan ìgbàgbọ́ karun. Wí fún wọn bí ẹ ti gba ìpè yín nínú Ìjọ. Báwo ni ẹ ṣe mọ̀ pé a pè yín láti ọwọ́ Ọlọ́run?
Wòlíì Sámúẹ́lì fi Àmì Òróró Yan Dáfídì láti Jẹ́ Ọba Isráẹ́lì ní Bẹ́tlẹ́hẹ́mù, láti ọwọ́ Balage Balogh
1 Sámúẹ́lì 16:7
Olúwa nwo ọkàn.
-
Kókó ẹ̀kọ́ kan lè ràn àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ nínú 1 Sámúẹ́lì 16:7. Fún àpẹrẹ, ẹ lè fi àwọn oúnjẹ tàbí ìwé kan pẹ̀lú ìwé-wíwé tàbí ìdérí tí kò bá àwọn àkóónú òtítọ́ rẹ̀ mu. Kínni 1 Sámúẹ́lì 16:7 àti kókó ẹ̀kọ́ dá àbá nípa bí a ṣe níláti wo arawa àti àwọn ènìyàn míràn? Kọ orin kan tí ó tẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ yí, bí irú “Ẹ Fẹ́ràn Ara Yín” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé,136).
Ẹ lo àwọn kókó ẹ̀kọ́. Nígbàtí àwọn ọmọ yín bá ní ohun kan láti rí àti láti fọwọ́kan ohun tí ó bá ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere mu, ó lè mú kí wọ́n rántí rẹ̀ si. Fún àpẹrẹ, bí ẹ ti nka 1 Sámúẹ́lì 16:7 pẹ̀lú wọn, ẹ lè jẹ́ kí wọ́n ràn yín lọ́wọ́ láti wá àwọn àpẹrẹ ìtanra-ẹnijẹ ti ojú láti júwe àmì pé a níláti gbìyànjú láti rí bí Olúwa ti ṣe—nípa wíwo “ọkàn”—dípò àwọn dídájọ́ tí ó dálé “ìwò ojú.”
-
Ẹyin àti àwọn ọmọ yín lè pín àwọn ìrírí nínú èyí tí ẹ ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìdí tí ẹ fi níláti “wo ọkàn,” kìí ṣe “ìwò ojú nìkan” (ẹsẹ 7). Bákannáà ẹ lè gba àkokò ní sísọ fún ara yín nípa àwọn ìwà rere tí ẹ rí nínú ọkàn ara yín.
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé-ìròhìn Fríẹ́ndì .