Come, Follow Me
Oṣù Kẹfà 15–21. “Ti Olúwa Ni Ogun Náà”: 1 Sámúẹ́lì 17–18; 24–26; 2 Sámúẹ́lì 5–7


“Oṣù Kẹfà 15–21. ‘Ti Olúwa Ni Ogun Náà’: 1 Sámúẹ́lì 17–18; 24–26; 2 Sámúẹ́lì 5–7,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Kẹfà 15–21. ‘Ti Olúwa Ni Ogun Náà,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026

Dáfídì di kànnànkànnàn mú

Dáfídì àti Goliath, láti ọwọ́ Steve Nethercott

Oṣù Kẹfà 15– 21: “Ti Olúwa Ni Ogun Náà”

1 Sámúẹ́lì 17–18; 24–26; 2 Sámúẹ́lì 5–7

Láti ìgbàkan rí ni àwọn ẹ̀yà Ísráẹ́lì ti tẹ̀dó sí ilẹ̀ ìlérí, àwọn Fílístínì ti jẹ́ ìbẹ̀rú tí ó nlọ lọ́wọ́ sí ààbò wọn. Olúwa ti gbà wọ́n sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní àtẹ̀hìnwá, ṣùgbọ́n nísisìyí àwọn alàgbà Ísráẹ́lì bèèrè “Àwà ó ni ọba … [láti] máa ṣaájú wa, kí ó si máa ja ogun wa” (1 Samuel 8:19–20). Nítorínáà Sáùlù ni a fi àmì òróró yàn bí ọba Àti síbẹ̀ nígbàtí Gòlíátì títóbi nyọlẹ́nu tí ó sì nrú ìpènijà rẹ̀ sí àwọn ọmọ ogun Ísráẹ́lì, Sáùlù—bíiti ìyókù ọmọ ogun rẹ̀—ní “ìbẹ̀rù gidi” (1 Sámúẹ́lì 17:11). Ní ọjọ́ náà, kìí ṣe Ọba Sáùlù ni ó gba Ísráẹ́lì là ṣùgbọ́n ọmọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ olùṣọ́-àgùtàn kan tí a pè ní Dáfídì, ẹnití kò wọ Ìhámọ́ra kankan ṣùgbọ́n ó wọ àṣọ pẹ̀lú àìlèwọ̀ ìgbàgbọ́ nínú Olúwa. Ogun yí fihan Ísráẹ́lì, àti ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ogun ti ẹ̀mí láti jà, pé “Olúwa kò fi ọ̀kọ̀ òun idà gbanilà” àti pé “ogun náà ti Olúwa ni” (1 Sámúẹ́lì 17:47).

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Kíkọ́ni ní Ilé àti Ìjọ

1 Samuẹlì 17

àmì sẹ́mínárì
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa, mo lè borí ìpènijà eyikeyi.

Ìtan Dáfídì àti Gòlíátì ni ọ̀kan lára àwọn ìtàn tí a mọ̀jùlọ nínú ìwé mímọ́. Bẹ́ẹ̀ni, à nsábà fojúsí Dáfídì. Ṣùgbọ́n ní àkokò yí, bí ẹ ti nṣe àṣàrò 1 Sámúẹ́lì 17, bákannáà ẹ jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ ti àwọn ènìyàn míràn nínú orí yí (ẹ wo ìtòsílẹ̀ nísàlẹ̀). Kínni ẹ kọ́ nípa wọn àti èrò-inú wọn? Kínni ẹ kọ́ nípa Dáfídì? Báwo ni ó ṣe yàtọ̀?

  • Gòlíátì: àwọn ẹsẹ 8–10, 43–44

  • Élíábù: ẹsẹ 28

  • Sáùlù: ẹsẹ 33

  • Dáfídì: àwọn ẹsẹ 26, 32, 34–37, 39, 45–47

Ìtàn yín, bíótilẹ̀jẹ́pé kìí ṣe mímọ̀ dáradára bíi ti Dáfídì, dánilójú pé yíò ní àwọn ìpènijà irú ìwọ̀n ti Gólíátì láti borí àti àwọn ànfààní láti lo ìgbàgbọ́ nínú Olúwa. Kínni àpẹrẹ Dáfídì kọ́ yín nípa kíkojú ìpọ́njú nínú ìtàn yín? Bákannáà ẹ lè ka ọ̀rọ̀ Ààrẹ Camille N. Johnson “Ẹ Pe Krístì láti ṣe Olùkọsílẹ̀ Ìtàn Yín” (Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2021, 80–82) pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn ìpènijà ní inú. Ẹ wá àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè bí ìwọ̀nyí: Báwo ni Olúwa ṣe fẹ́ kí èmi wo àwọn ìpènijà mi? Báwo ni Ó ṣe ràn mí lọ́wọ́ ní àtẹ̀hìn wá? Báwo ni mo ṣe lè fihàn pé mo gbẹ́kẹ̀lé E láti kọ ìtàn mi?

Ẹ lè mọ̀ tẹ̀lẹ̀ pé àwọn orí olóró kàn wà lẹ́hìnwá nínú ìtàn Dáfídì (fún àpẹrẹ, wo, 2 Sámúẹ́lì 11). Bí ẹ bá ní ànfààní láti fún Dáfídì ní àwọn ìmọ̀ràn kan lẹ́hìn ogun rẹ̀ pẹ̀lú Gòláítì, kínni ìwọ yíò sọ? Báwo ni ìmọ̀ràn yí ṣe lè wúlò sí ìgbésí ayé yín?

Bákannáà wo “Olúwa Yíò Gbà Mi Sílẹ̀” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

3:24

The Lord Will Deliver Me

1 Sámúẹ́lì 17:26–50

Ẹnìkan pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Krístì lè mú ìyàtọ̀ wá.

Ní àfikún sí àwọn ìpènijà araẹni, bákannáà à nkojú àwọn wàhálà, títóbi, líle, tí ó nní ipá lórí gbogbo ayé. Nígbàtí àwọn ipa ibi bá “nkórajọ papọ̀ … láti jagun” dojúkọ àwọn ipa rere (1 Sámúẹ́lì 17:1), ó lè yà wá lẹ́nu bí ìtiraka olúkúlùkù wa ṣe lè ṣeéṣe láti mú ìyàtọ̀ wá. Kínni ẹ rí nínú ìtàn Dáfídì tí ó fún yín ní ìrètí?

Bákannáà ẹ wo “Ẹ Jẹ́ Kí Gbogbo Wa Tẹ̀síwájú,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 243.

Jónátánì àti Dáfídì

Ìbádọ́rẹ́ àti Ọ̀wọ̀-Araẹni Tòótọ́, láti ọwọ́ Wilson Ong (àlàyé)

1 Samuẹlì 18

“Jónátánì fẹ́ràn [Dáfídì] bí ẹ̀mí ti ararẹ̀.”

Bí ẹ ti nka 1 Sámúẹ́lì 18, ẹ gbèrò ṣíṣe àfiwéra Sáùlù àti ọmọ rẹ̀ Jónátánì (ẹnití, bí kò bá ṣe ti Dáfídì, ìbá ti rò pé òun ó di ọba tí ó kàn). Báwo ni Sáùlù àti Jónátánì ṣe dá sí àṣeyege Dáfídì? Kínni ẹ kọ́ láti inú ìrírí yí?

Kínni ẹ rí nínú ìwà àti ìṣe Jónátánì tí ó nrán yín létí nípa Jésù Kríst?

“Fi ìwé mímọ́ wé ra” (1 Néfì 19:23). Àwọn ìwé mímọ́ pèsè ànfààní púpọ̀ láti kọ́ ẹ̀kọ́ láti inú àwọn ìwúrí àti ìṣe ti àwọn ènìyàn bíiti Dáfídì, Jònátànì, àti Sáùlù. Ẹ yíò ri pé kò sí ẹnìkankan nínú àwọn ìwé mímọ́ tí kò lábàwọ́n. Fún àpẹrẹ, bí ẹ ṣe nkà, nípa àwọn àṣàyàn òtítọ́ ti Dáfídì, ẹ ṣí ọ̀kàn yín sí ìkọ́ni bákannáà kúrò nínú àwọn àṣìṣe rẹ̀. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn àìlera tí ó lè wà nínú ara wa kí a sì “kọ́ láti ní ọgbọ́n sísi ju bí [àwọn ẹlòmíràn] ti jẹ́” (Mọ́mọ́nì 9:31).

1 Sámúẹ́lì 16:7

Ìdáríjì ni ipa ọ̀nà tí ó dájú sí àlàáfíà àti ìwòsàn.

Nínú 1 Sámúẹ́lì 24–26, ẹ wá àwọn ẹ̀kọ́ nípa ìgbéraga, ìdáríjì, àti akóra-ẹni-níjánu. Bákannáà ẹ lè yẹ ọ̀rọ̀ Alàgbà Mark A. Bragg wò “Ìdúró Bíiti Krístì” bí ara àṣàrò yín (Làìhónà, Oṣù Karun 2023, 60–63). Báwo ni Dáfídì, Ábígẹ́lì, àti àwọn ẹlòmíràn ṣe júwe—tàbí kùnà ìjúwe—ìdúró bíiti Krístì nínú àwọn orí wọ̀nyí? Kínni àwọn ànfààní tí ẹ ní láti fi ìdúró bíi ti Krístì hàn?

Ọ̀rọ̀ Arábìnrin Kristen Yee “Eérú fún Ẹ̀wà: Ipa Ọ̀nà Ìwòsàn ti Ìdáríjì” (Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2022, 36–39) lè ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àṣàrò 1 Sámúẹ́lì 25. Báwo ni Ábígẹ́lì ṣe dàbí Jésù Krístì?

2 Sámúẹ́lì 5:17–25

Olúwa lè fún mi ní ìdarí.

Àní lẹ́hìn tí Dáfídì ṣẹ́gun Gòlíátì, àwọn ìdàmú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ará Filístínì ko tíì parí. Bí ẹ ti nka 2 Sámúẹ́lì 5:17–25, ẹ yẹ bí àpẹrẹ Dáfídì ṣe lè ràn yín lọ́wọ́ nínú àwọn ìpènijà tí ẹ nkojú wò (bákannáà wo 1 Sámúẹ́lì 23:2, 10–11; 30:8; 2 Sámúẹ́lì 2:1). Báwo ni ẹ ṣe ndi alábùkúnfún nípa ṣíṣe ìṣe lórí ìfihàn tí ẹ gbà?

2 Sámúẹ́lì 7

Kínni “ilé” tí Olúwa ṣèlérí fún Dáfídì?

Nígbàtí Dáfídì gba láti kọ́ ilé kan, tí ó túmọ̀ sí tẹ́mpìlì, fún Olúwa (wo 2 Samuẹlì 7:1–3), Olúwa fèsì pé ọmọ Dáfídì ni yíò kọ́ ọ (wo àwọn ẹsẹ 12–15; bákannáà wo 1 Króníkà 17:1–15). Bákannáà Olúwa wí pé Òun náà yíò kọ́ “ilé,” kan fún Dáfídì tí ó túmọ̀sí àtẹ̀lé kan, àti pé i`tẹ́ rẹ̀ yíò wà títí láé (wo 2 Sámúẹ́lì 7:11, 16, 25–29; Orin Dáfídì 89:3–4, 35–37). Ìlérí yí ni a múṣẹ nínú Jésù Krístì, Ọba wa Ayérayé, ẹnití ó jẹ́ ìran ti Dáfídì (wo Máttéù 1:1; Lúkù 1:32–33; Jòhánnù 18:33–37).

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .

ìpín àmì àwọn ọmọdé

Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé

1 Sámúẹ́lì 17:20–54

Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì lè ràn mi lọ́wọ́ láti ní ìgboyà.

  • Ẹ lè fẹ́ láti lo “Dáfídì àti Gòlíátì” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 112–16, láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní ìfaramọ́ pẹ̀lú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú 1 Sámúẹ́lì 17:20–54. Nígbànnáà ẹ lè jẹ́ kí wọ́n tún ìtàn náà sọ ní lílo àwọn àwòrán tàbí yíya ìlà nínú ìlànà yí. Bèèrè lọ́wọ́ wọn ohun tí wọ́n rò pé Olúwa fẹ́ kí wọ́n kọ́ láti inú ìtàn yí.

    2:36

    David and Goliath

  • Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín bákannáà lè ṣe ìtòsílẹ̀ àwọn ìpènijà ṣíṣòro tí ẹ lè kojú nínú ìgbésí ayé yín. Lẹ́hìnnáà ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá àwọn ohun tí Dáfídì sọ pé ó lè ṣèrànwọ́ pẹ̀lú àwọn ìpènijà wọ̀nyí (wo 1 Sámúẹ́lì 17:26, 32, 34–37, 45–47). Ẹ pín bí Jésù Krístì ṣe ràn yín lọ́wọ́ nínú àwọn ìpènijà.

  • Àwọn ọmọ yín lè yan bíi pé wọ́n jẹ́ Dáfídì tí ó nlọ láti bá Gòlíátì jà nígbàtí ó nkọ orin nípa jíjẹ́ onígboyà, bí irú “Èmi Ó Jẹ́ Akọni” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 162).

1 Sámúẹ́lì 18:1 4

Àwọn ọ̀rẹ́ rere lè jẹ́ ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

  • Báwo ni ẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ láti inú ìbádọ́rẹ́ Jónátánì àti Dáfídì? Ọ̀nà kan yíò jẹ́ fífún ọmọ kọ̀ọ̀kan ní bébà méjì ọkàn, ọ̀kan láti rọ́pò Dáfídì àti àwọn míràn láti rọ́pò Jònátànì. Nígbànnáà ẹ ka gbólóhùn ọ̀rọ̀ díẹ̀ láti inú 1 Sámúẹ́lì 18:1–4 tí ó tẹnumọ́ ìfẹ́ tí àwọn ọ̀rẹ́ méjì wọ̀nyí ní fuń ara wọn papọ̀. Àwọn ọmọ yín nígbànnáà lè kọ tàbí yàwòrán lórí ọkàn bí wọn ṣe lè fi ìfẹ́ hàn sí ọ̀rẹ́ kan.

2 Sámúẹ́lì 05:19, 23

Bí mo bá nílò ìtọ́sọ́nà, mo lè bèèrè lọ́wọ́ Baba Ọ̀run.

  • Nínú àwọn orí wọ̀nyí, Dáfídì di ọba Ísráẹ́lì. Ó lè jẹ́ ìgbádùn fún àwọn ọmọ yín láti díbọ́n láti jẹ́ ọba tàbí ayaba kan. Kínni àwọn òfin tí wọn yíò ṣe? Níbo ni wọn yíò lọ fún ìrànlọ́wọ́? Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe àwárí pé nígbàtí Dáfídì nílò ìrànlọ́wọ́, ó “bèèrè,” tàbí gbàdúrà, fún àwọn ìdáhùn. Fún àpẹrẹ, bí ẹ ti nka 2 Sámúẹ́lì 5:19, 23, ẹ pe àwọn ọmọ láti fetísílẹ̀ fún ọ̀rọ̀ náà “bèèrè” kí wọ́n sì di apá wọn nígbàtí wọ́n bá gbọ́ ọ. Kínni ìdí tí Dáfídì fi nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nínú ojúṣe titun rẹ̀?

  • Ẹ sọ fún ara yín nípa àwọn àkokò nígbàtí ẹ ti gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Baba Ọ̀run. Kínni ìyàtọ̀ tí ó mú wá láti jẹ́ kí Ó ràn yín lọ́wọ́?

ọmọbìnrin kan ngbàdúrà

2 Sámúẹ́lì 7:16–17

Jésù Krístì ni Ọba Ayérayé mi.

  • Àwọn ọba tí a kà nípa rẹ̀ nínú Májẹ̀mú Láéláé ni gbogbo wọn ní àṣìṣe, gbogbo ìjọba wọn sì parí. Ṣùgbọ́n Jésù Krístì ni Ọba pípé yíò sì jọba títíláé. Ẹ lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe àwárí èyí nípa kíka ohun tí wòlíì Nátánì sọ fún Ọba Dáfídì papọ̀ nínú 2 Sámúẹ́lì 7:16–17. Báwo ni ìjọba Dáfídì kì yíò ṣe ní òpin? Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti wá àti láti ka àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ tí o´ kọ́ni pé Jésù Krístì, ìran ti Dáfídì, ni Ọba wa, bí irú Lúkù 1:32–33; Jòhánnù 18:33–37; àti Ìfihàn 19:16. Báwo ni Jésù ṣe yàtọ̀ sí àwọn ọba ti ayé? Báwo a ṣe nbu-ọlá fún Jésù Krístì bí Ọlá Ayérayé wa?

Fún púpọ síi, wo àtẹ̀jàde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .

Dáfídì àti Goliath

Ìjúwe Dáfídì, láti ọwọ́ Dilleen Marsh

Ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì lè ràn mi lọ́wọ́ láti ní ìgboyà.