Come, Follow Me
Oṣù Kẹfà 1–7. “Ọkàn Mi Yọ̀ nínú Olúwa”: Ruth; 1 Samuel 1–7


Oṣù Kẹfà 1–7. ‘Ọkàn Mi Yọ̀ nínú Olúwa’: Rúùtù 1; 1 Sámúẹ́lì 1–7,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

Oṣù Kẹfà 1–7. ‘Ọkàn Mi Yọ̀ nínú Olúwa,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026

Rúùtù àti Nàómì nrin ìrìnàjò papọ̀

Ibikíbi Tí Ìwọ Bá Lọ, láti ọwọ́ Sandy Freckleton Gagon

Oṣù Kẹfà 1– 7: “Ọkàn Mi Yọ̀ nínú Olúwa”

Rúùtù; 1 Sámúẹ́lì 1–7

Nígbàmíràn a nronú pé ìgbésí ayé wa níláti tẹ̀lé ipa ọ̀nà kedere láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ópin. Ọ̀nà kúkúrú jùlọ ní àárín àmì méji ni ilà tààrà, lẹ́hìn gbogbo rẹ̀. Àti síbẹ̀ ìgbé ayé nígbàkugbaà nkún fún ìdádúró àti ìyípadà ọ̀nà tí ó nmú wa lọ̀ sí àwọn ìdarí àìròtẹ́lẹ̀.

Rúùtù àti Hánnà dájúdájú ní òye èyí. Rúùtù kìí ṣe ará Isráẹ́lì, ṣùgbọ́n ó fẹ́ ọ̀kan, nígbàtí ọkọ rẹ̀ sì kú, ó ní àṣàyàn kan láti ṣe. Njẹ́ òun ó padà sọ́dọ̀ ẹbí rẹ̀ àti ìgbésí ayé, titẹ́lẹ̀ tí ó faramọ́,tàbí yíò rọ̀mọ́ ìgbàgbọ́ ará Ísráẹ́lì àti ilé titun pẹ̀lú ìyá ọkọ rẹ̀? (wo Rúùtù 1:4–18). Ètò Hánnà fún ayé rẹ̀ niláti bí àwọn ọmọ, ṣùgbọ́n kò lè bí, èyí sì fi í, sílẹ̀ “sínú ìkorò ti ẹ̀mí” (wo 1 Samuẹlì 1:1–10). Bí ẹ ti nkà nípa Rúùtù àti Hánnà, ẹ yẹ ìgbàgbọ́ tí wọ́n ti gbọ́dọ̀ ní láti rin ìrìnàjò ti ipa ọ̀nà àìròtẹ́lẹ̀. Nígbànáà ẹ ronú nípa ìrìnàjò ti ara yín. Ó yàtọ̀ sí ti Rúùtù àti Hánnà—ẹnikẹ́ni míràn. Ṣùgbọ́n nínú gbogbo àwọn àdánwò àti ìyanilẹ́nú ní àárin ìhín àti òpin , ayérayé yín “Ọkàn Mi Yọ̀ nínú Olúwa” (1Sámúẹ́lì 2:1).

Bákannáà wo Ìtumọ̀ Bíbélì fún àkópọ̀ àwọn ìwé ti Rúùtù àti 1 Sámúẹ́lì.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Kíkọ́ni ní Ilé àti Ìjọ

Rúùtù

Jésù Krístì lè yí àjálù pada sínú ìṣẹ́gun.

Ìgbésí ayé le fún opó ní eyikeyi àkokò. Ṣùgbọ́n nígbàtí ọkọ Rúùtù kú, ipò rẹ̀ le nípàtàkì. Nínú àṣà ará Ísráẹ́lì ní àkokò náà, obìnrin kàn láìsí ọkọ tàbí ọmọ kò ní ẹ̀tọ́ sí ohun-ìní ó sì ní àwọn ọ̀nà díẹ̀ láti ríṣẹ́ ṣe. Bí ẹ ti nka ìtàn Rúùtù, ẹ kíyèsi bí Olúwa ti yí àjálù padà sínú ìbùkún nlá. Kínni ẹ kíyèsí nípa Rúùtù tí ó lè ti ràn án lọ́wọ́? Báwo ni Bóásì ṣe ra Rúùtù padà kúro nínú ipò àìnírètí rẹ̀? (wo Rúùtù 4:4–10). Báwo ni méjèèjì Rúùtù àti Bóásì ṣe dàbí Jésù Krístì?

Bákannáà wo “Dúró Jẹ́ẹ́, Ọkàn Mi,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 124.

Rúùtù; 1 Sámúẹ́lì 1

Mo lè nígbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run yíò ṣe àtọ́nà yíò sì ràn mí lọ́wọ́ láìka ipò mi sí.

Bóyá ẹ ti jìyà àdánù nlá, bí Rúùtù àti Nàómì ti ṣe (wo Rúùtù 1:1–5). Tàbí bóyá, bíiti Hánnà, ẹ̀ nfẹ́ àwọn ìbùkún tí ẹ kò tíì rí gbà síbẹ̀ (wo 1 Samuẹlì 1:1–10). Báwo ni àwọn obìnrin wọ̀nyí ṣe fi ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọlọ́run hàn? Kínni ẹ kọ́ láti inú àwọn ìrírí wọn?

Bẹ́ẹ̀ni, kìí ṣe gbogbo ènìyàn tí wọ́n ngbàdúrà fún ọmọ ní wọ́n nrí gbà, kìí sì iṣe gbogbo àwọn tí lọ́kọláya wọn kú ni wọ́n ntú ìgbèyàwó ṣe. Ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó bá yípadà sí Olùgbàlà ngba ìrànlọ́wọ́ àti ìtọ́sọ́nà Rẹ̀. Ẹ yẹ bí ẹ ti “wá láti gbẹ́kẹ̀lé” Olúwa (Rúùtù 2:12) ní àwọn àkokò ìṣòro.

Bákannáà wo Amy A. Wright, “Gbé Ọjọ́ náà nínú Krístì,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2023, 9–11.

Hánnà àti ọmọ rẹ̀

Fún Ọmọ Yí Ni Mo Gbàdúrà, láti ọwọ́ Elspeth Young

1 Sámúẹ́lì 2; 4–7

Láti gba ìrànlọ́wọ́ Olúwa, mo nílò láti gbẹ́kẹ̀lé E kí nsì gbọ́ran sí àwọn òfin Rẹ̀.

Nígbàtí àwọn ọ̀tá wọn kọ̀lú wọ́n, àwọn ará Ísráẹ́lì ní híhàn kedere rò pé níní àpótí ti májẹ̀mú lásán yíò dá ààbò bò wọ́n. Bí ẹ ti nka 1 Sámúẹ́lì 4–6, ẹ ronú nípa ìdí tí ìyẹn kò fi ṣiṣẹ́. (Bákannáà ẹ kíyèsí àwọn ìṣe àìṣòdodo ti àwọn ọmọ Élì, nínú 1 Sámúẹ́lì 2:12–25.) Kínni ẹ rò pé Olúwa ngbìyàjú láti kọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀? Kínni ẹ kọ́ láti inú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Filístínì lẹ́hìn gbígba àpótí náà? (wo àwọn orí 5–6). Kínni ẹ kọ́ láti inú ìtiraka Ísráẹ́lì láti tún ààbò Olúwa gbà padà nínú 1 Sámúẹ́lì 7?

Ẹ lè ní ìmísí nípa kíka ewì Hánnà nípa ìyìn nínú 1 Sámúẹ́lì 2:1–10. Kínni ẹ rí nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó lè ran àwọn ọmọ Élì àti ìyókù ará Ísráẹ́lì lọ́wọ́?

1 Sámúẹ́lì 3

àmì sẹ́mínárì
Mo lè gbọ́ kí n sì gbọ́ran sí ohùn Olúwa.

Ní ìgbàmíràn, ẹ lè ní ìmọ̀lára bíiti Sámúẹ́lì, ẹnití ó gbọ́ ohùn Olúwa ṣùgbọ́n tí kò dá a mọ̀. Bíiti gbogbo wa, Sámúẹ́lì níláti kọ́ bí òun ó ti dá ohùn Olúwa mọ̀. Bí ẹ ti nka 1 Sámúẹ́lì 3, kínni ẹ kọ́ ní ọ̀dọ̀ ọmọdékùnrin yí nípa gbígbọ́ àti gbígbọ́ran sí ohùn Olúwa? Bákannáà ẹ lè ṣe ìwákiri àfikún àwọn ìwé mímọ́ kí ẹ sì ṣe ìtòsílẹ̀ àwọn ìtọ́sọ́nà tí ó lè ran ẹnìkan lọ́wọ́ láti dá ohùn Olúwa mọ̀: 1 Àwọn Ọba 19:11–12; Lúkù 24:15–32; 3 Néfì 11:3–7; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 6:22–23; 8:2–3; 9:7–9.

Ní ìgbàmíràn, ẹ lè ní ìmọ̀lára pé ọ̀run ti tì àti pé Ọlọ́run kò fẹ́ láti bá yín sọ̀rọ̀. Ààrẹ Russell M. Nelson wípé, “Njẹ́ Ọlọ́run fẹ́ láti bá yín sọ̀rọ̀ lódodo? Bẹ́ẹ̀ni!” (“Ìfihàn fún Ìjọ, Ìfihàn fún Ìgbé Ayé Wa,” Làìhónà, Oṣù Karun 2018, 93–96. Bí ẹ ti nṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Ààrẹ Nelson, Kínni ohun tí ẹ rí tí ó mísí yín láti gbọ́ kí ẹ sì gbọ́ran sí ohùn Olúwa? Kínni Ààrẹ Nelson pè yín láti ṣe, kí sì ni àwọn ìbùkún tí ó ṣèlérí? Bákannáà ẹ lè rí ìfipè àti ìlérí àwọn ìbùkún nípa ìfihàn nínú “Ẹ Rìn nínú Ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run” (Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́: Atọ́nà kan fún Ṣíṣe Àṣàyàn, 16–20). Ẹ yẹ yíyan ohunkan tí ẹ lè ṣe láti “mú agbára ti ẹ̀mí yín láti gba ìfihàn pọ̀si.”

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .

ìpín àmì àwọn ọmọdé

Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé

Rúùtù

Mo lè fi ìfẹ́ àti inúrere hàn sí àwọn ènìyàn ní àyíká mi.

  • Bí ẹ ti npín ìtàn Rúùtù pẹ̀lú àwọn ọmọ yín (ẹ lè lo “Rúùtù àti Nàómì” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 100–103), ẹ pè wọ́n láti gbé ọwọ́ wọn sókè ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbọ́ ìṣe inúrere kan nínú ìtàn náà. Bákannáà wọ́n lè pín bí wọ́n ṣe ní ìmọ̀lára sí nígbàtí àwọn ẹlòmíràn bá ṣerere sí wọn, tàbí nígbàtí wọ́n bá ṣerere sí àwọn ẹlòmíràn. Báwo ni Olùgbàlà ṣe ní inúrere sí wa? Báwo ni a ṣe lè tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀? (wo “Inúrere Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Mi,Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 145).

    2:0

    Ruth and Naomi

Rúùtù; 1 Sámúẹ́lì 1

Èmi lè ní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa.

  • Àwọn ìtàn Rúùtù àti Hánnà lè mísí àwọn ọmọ yín láti dúró ní òtítọ́ ní ìgbà líle. Ẹ yẹ ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti dá fífa-ìlà ìrọ̀rùn kan sílẹ̀ pẹ̀lú àkọlé Àwọn Àdánwò, Àwọn Ìṣe, Àwọn Ìbùkún. Nígbànáà Rúùtù 1:3–5, 8, 16; 2:1–3, 8–12; 4:13–17; 1 Sámúẹ́lì 1:1–18 kí ẹ sì kọ̀wé sí abẹ́ àwọn àkọlé náà ohun tí ẹ rí nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí. Báwo ni Rúùtù àti Hánnà ṣe fi ìgbàgbọ́ wọn nínú Olúwa hàn? Ẹ̀yin tàbí àwọn ọmọ yín nígbànáà lè pín àwọn àpẹrẹ nípa bí Olúwa ṣe bùkún yín ní àkokò líle.

1 Sámúẹ́lì 1:1–18

Baba Ọ̀run ngbọ́ ó sì ndáhùn àwọn àdúrà mi.

  • Láti kọ́ nípa Hánnà, àwọn ọmọ yín lè ka 1 Sámúẹ́lì 1:1–18 tàbí “Hánnà” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé (104–5) tàbí wo “Ìgbàgbọ́” (fídíò, Ibi-ìkàwé). Ó lè jẹ́ ìgbádùn láti ju bọ́ọ̀lù sí ọmọ kàn kí a sì pè wọ́n láti sọ ara ìtàn náà ṣíwájú jíju bọ́ọ̀lù náà sí ẹlọ̀míràn. Kínni ẹ kọ́ nípa àdúrà láti inú àpẹrẹ Hánnà?

    1:15

    Hannah

    3:9

    Hannah's Faith

Sámúẹ́lì àti Élì

Sámúẹ́lì Sọ Òtítọ́ Fún Élì, láti ọwọ Robert T. Barrett

1 Sámúẹ́lì 1:1–10

Mo lè gbọ́ kí nsì gbọ́ran sí ohùn Olúwa.

  • Bóyá ṣíṣe eré ìrọ̀rùn kan jáde lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ láti inú ìrírí pẹ̀lú ìfihàn ti Sámúẹ́lì. Ọmọ kan lè díbọ́n láti jẹ́ Sámúẹ́lì, kí òmíràn sì díbọ́n láti jẹ́ Élì bí ẹ ti nka 1 Sámúẹ́lì 3:1–10 (bákannáà wo “Wòlíì Sámúẹ́lì” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 106–9, tàbí fídíò “Sámúẹ́lì àti Élì,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere). Kínni a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Sámúẹ́lì nípa bí a ṣe lè gbọ́ ohùn Olúwa? Báwo ni a ṣe lè fihàn pé a ní ìfẹ́ láti gbọ́ nígbàtí Olúwa bá nṣọ̀rọ̀ sí wa?

    2:10

    Samuel the Prophet

    1:58

    Samuel and Eli

  • Ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ bí wọ́n ṣe lè ṣe àlàyé fún ẹnìkan bí Olúwa ṣe nbá wọn sọ̀rọ̀. Ẹ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá àwọn ìdáhùn nínú Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 6:22–23; 8:2–3; 9:7–9.

Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ láti dá Ẹ̀mí mọ̀. Kìí rọrùn láti wòye ní àárín àwọn ìmọ̀lára ti arawa àti Ẹ̀mí Mímọ́. Olukúlùkù ènìyàn ntiraka pẹ̀lú èyí láti akokò sí àkokò. Ẹ mú gbogbo ànfààní tí ẹ ní láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti dáamọ̀ nígbàtí wọ́n bá ní ìmọ̀lára ipa ti Ẹ̀mí. Fún àpẹrẹ, bí ẹ ti nka 1 Sámúẹ́lì 3:1–10 àti àwọn ẹsẹ tí a dá àbá nínú Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú, ẹ lè pín àwọn ìrírí nínú èyí tí Olúwa ti kọ́ yín ní inú àti ọkàn yín.

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jàde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .

Sámúẹ́lì jí dìdè nínú bùsùn

Ọmọkùnrin Sámúẹ́lì ni a Pè nípasẹ̀ Olúwa, láti ọwọ́ Harry Anderson

Ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Baba Ọ̀run yíò gbọ́ yíò sì dáhùn àwọn àdúrà mi