Come, Follow Me
Oṣù Kéje 13–19. “Ó Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Ísráẹ́lì”: 2 Àwọn Ọba 16–25


“Oṣù Kéje 13–19. ‘Ó Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Ísráẹ́lì’: 2 Àwọn Ọba 16–25,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Kéje 13–19. ‘Ó Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Ísráẹ́lì,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026

ẹgbẹ́ júù púpọ̀ nrin ìrìnàjò kúrò lọ sí Bábílónì

Sísálọ ti àwọn Ẹlẹ́wọn, láti ọwọ́ James Jacques Joseph Tissot àti àwọn ẹlòmírán

July 13–19: “Ó Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Ísráẹ́lì”

2 Àwọn Ọba 16-25

Pẹ̀lú iṣẹ́ ìrànṣẹ́ alágbára ti Èlíṣà, àwọn ènìyàn apá Àríwá Ìjọba Ísráẹ́lì kò ronúpìwàdà. Nígbẹ̀hìn, Ìjọba Assíríà ṣẹ́gun wọ́n sì fọ́n àwọn ẹ̀yà mẹwa Ísráẹ́lì ká. Nísisìyí, apá Gúsù Ìjọba Júdàh kò ṣe dáadáa síi: ìbọ̀rìṣà bákannáà tàn káàkiri níbẹ̀.

Ní àárín gbogbo ìbàjẹ́ ti ẹ̀mí, àwọn ìwé mímọ́ dárúkọ àwọn ọba Júdàh méjì, ní ìgbàkan tí wọ́n, yíàwọn ènìyàn padà sí Olúwa. Ọ̀kan ni Hesekíàh. Nínú ìjọba rẹ̀, àwọn Àssíríà ṣẹ́gun púpọ̀ àwọn Júdàh. Ṣùgbọ́n Hesekíàh àti àwọn ènìyàn rẹ̀ fi ìgbàgbọ́ hàn nínú Olúwa, tí o´ gba Jérúsálẹ́mù là ní ọ̀nà ìyanilẹ́nu. Lẹ́hìnnáà, lẹ́hìnàkokò míràn ti ìyapa-kúrò-nínú-ìgbàgbọ́, Jòsíàh di ọba. Ní ìmísí ní apakan ní títún-ṣe-àwárí ti ìwé òfin Mósè, Jòsíàh mú àwọn àtúnṣe tí ó mú ìyípò ìgbé ayé ẹ̀sìn àwọn ènìyàn rẹ̀ padà wá.

Bíiti Ísráẹ́lì àti Júdàh, gbogbo wa nṣe àwọn àṣàyàn rere àti búburú. Nígbàtí a bà wòye pé ìgbé ayé wa nílò àtúnṣe, a lè gba ìyànjú láti inú àwọn àmì dídán méjì wọ̀nyí nínú àwọn ọdún òkùnkùn ti ìwé-ìtàn Júdàh. Bóyá àwọn àpẹrẹ ti Hesekíàh àti Jòsíàh lè mísí wa láti “gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run wa” (2 Àwọn Ọba 18:22).

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Kíkọ́ni ní Ilé àti Ìjọ

2 Àwọn Ọba 18-19

àmì sẹ́mínárì
Mo lè dúró nítòótọ́ sí Olúwa nígbàtí a bá pe ìgbàgbọ́ mi níjà.

Púpọ̀jùlọ lára wa ní ìrírí tí ó pe ìgbàgbọ́ wa níjà. Fún Hesekíàh àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ọ̀kan lára àwọn ìpènijà wọ̀nnì wá nígbàtí àwọn ọmọ ogun Àssíríà dé Jérúsálẹ́mù. Bí ẹ ti nka 2 Àwọn Ọba 18–19, ẹ ròó pé ẹ̀ ngbé ní Jérúsálẹ́mù ní àkokò yí. Báwo ni ẹ̀ ti lè nímọ̀lára sí, fún àpẹrẹ, gbígbọ́ tí àwọn Àssíríà nṣáátá nínú 2 Àwọn Ọba 18:28–37; 19:10–13? Kínni ẹ̀yin ìbá ti ṣe? Ṣe àfiwé èrèdí àwọn Àssíríà fún àwọn Ísráẹ́lì láti máṣe gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú àwọn èrèdí tí Sátánì nfúnni fún wa láti ṣiyèméjì ìgbàgbọ́ wa ní òní. Bákannáà ẹ lè fi èrèdí àwọn Àssíríà ní ìlòdì sí èrèdí yín ìdí tí ẹ ṣe ngbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

Kínni ẹ kọ́ láti inú àwọn ìṣe Hesekíàh nínú ipò yí? (wo 2 Àwọn Ọba 19:1–7, 14–19). Báwo ni Olúwa ṣe fèsì? (wo 2 Àwọn Ọba 19:35–37). Kínni ìdí tí ẹ fi ró pé Hesekíàh dúró nínú òtítọ́? (wo 2 Àwọn Ọba 18:5–7). Ẹ jíròrò bí Olúwa ti ṣe ìmúdúró yín ní àwọn àkokò pípeni-nijà. Kínni ẹ ní ìmísí láti ṣe láti mú ìgbẹ́kẹ̀lé yín nínú Rẹ̀ pọ̀ si?

Ọ̀rọ̀ Ààrẹ Jeffrey R. Holland “Máṣe Bẹ̀rù: Gbàgbọ́ Nìkan!” (Làìhónà, Oṣù Karun 2022, 34–36) ní ìmọ̀ràn ìrànwọ́ fún àwọn àkokò ẹ̀rù tàbí iyeméjì. Orin ìsìn kan bíi “Ẹ Jẹ́ Kí A Tẹ̀síwájú” (Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 243) bákannáà lè ní àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàni-níyànjú. Kínni ohun tí ẹ rí nínú àwọn ohun èlò wọ̀nyí tí ó nràn yín lọ́wọ́?

Bákannáà wo 2 Króníkà 31–32; 3 Néfì 3–4; Jörg Klebingat, “Jíjẹ́ Akọni Ọmọlẹ́hìn ní àwọn Ọjọ́ Ìkẹhìn,” Làìhónà, Oṣù Karun 2022, 107–10.

Ẹ lo àṣàrò láti ṣèrànwọ́. Ìjọ npèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èlò láti ràn yín lọ́wọ́ láti ní òye àwọn ìwé mímọ́. Fún àpẹrẹ, nínú Ibi-ìkàwé Ìhìnrere ẹ lè rí Atọ́nà sí àwọn Ìwé Mímọ́, Àwọn àkọlé àti Ìbèèrè, àti àwọn ìwé ìròhìn Ìjọ. Ní àfikún, bí ẹ ti nka Májẹ̀mú Láéláé, ẹ lè wá àkóónú tó ṣèrànwọ́ tí ó sì ní ìjìnlẹ̀ òye nínú, “Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Inú” àtẹ̀kọ nínú Wá, Tẹ̀lé Mi. Àtẹ̀kọ tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Jésù Yíò Sọ fún Gbogbo Ísráẹ́lì, ‘Ẹ Wá Sílé’” lè ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àṣàrò ti 2 Àwọn Ọba 16–25.

Ẹbí nka àwọn ìwé mímọ́ papọ̀

2 Àwọn Ọba 19:20–37

Ohun gbogbo wà ní ọwọ́ Olúwa.

Sẹnnakéríbù, ọba Àssíríà, ní èrèdí rere láti gbàgbọ́ pé àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yíò ṣẹ́gun Jérúsálẹ́mù (wo 2 Àwọn Ọba 17; 18:33–34; 19:11–13). Ṣùgbọ̀n Olúwa ní ọ̀rọ̀ kan ní ìkàsí Sẹnnakéríbù, tí a fúnni nípasẹ̀ wòlíì Ísáíàh. Tí a kọsílẹ̀ nínú 2 Àwọn Ọba 19:20–34. Kínni àwọn òtítọ́ tí ẹ rí nínú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ràn yín lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú Òun àti ètò Rẹ̀?

2 Àwọn Ọba 21-23

Àwọn ìwé mímọ́ lè yí ọkàn mi padà sí Olúwa.

Ṣé ẹ ti nímọ̀lára rí pé ẹ̀ nṣe aláìní ohun ti ẹ̀mí kan? Bóyá ẹ nímọ̀lára pé ìbáṣepọ̀ yín pẹ̀lú Ọlọ́run lè di alágbára síi. Kínni ó ràn yín lọ́wọ́ láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀? Ẹ jíròrò àwọn ìbèèrè wọ̀nyí bí ẹ ti nka 2 Àwọn Ọba 21–23, èyí tí ó ṣe àpèjúwe bí Ìjọba Júdàh ṣe ṣubú kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa lábẹ́ Ọba Mánássè (wo 2 Àwọn Ọba 21) àti bí Ọba Jòsíàh ṣe ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti yípadà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (wo 2 Àwọn Ọba 22–23). Báwo ni àti kínni ìdí tí Jòsíàh àti àwọn ènìyàn rẹ̀ fi yípadà? (wo 2 Àwọn Ọba 22:8–11; 23:1–6, 21, 24).

Ààrẹ Spencer W. Kimball pè ìtàn Ọba Jòsíàh ní “ọ̀kan lára àwọn ìtàn dídárajùlọ nínú gbogbo àwọn ìwé mímọ́” (Ìkọ́ni àwọn Ààrẹ: Spencer W. Kimball [2006], 62). Ẹ ka àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Kimball nípa Ọba Jòsíàh (àwọn ojú-ewe 62–64). Bóyá ẹ lè ronu nípa ìrírí kan nígbàtí ẹsẹ ọ̀rọ̀ ti ìwé mímọ́ “ti[ṣiṣẹ́] pẹ̀lú agbára” nínú yín. Kínni ẹ lè ṣe láti gba àwọn ìrírí bí irú èyí síi?

Bákannáà wo Álmà 31:5; “Jòsíàh àti Ìwé Òfin” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

12:25

Josiah and the Book of the Law

2 Àwọn Ọba 23:1-25

Májẹ̀mú ni ìfarajì gbogbo-ọkàn ní àárín èmi àti Olúwa.

Kínni ó wọ̀ yín lọ́kàn nípa májẹ̀mú tí Jòsíàh dá nínú 2 Àwọn Ọba 23:3? Bí ẹ ti tẹ̀síwájú ní kíka orí 23, ẹ kíyèsí ohun tí Jòsíàh ṣe láti fi ìfarajì rẹ̀ hàn sí Olúwa (bákannáà wo àwòrán náà ní òpin ìlànà yí). Báwo ni ẹ ṣe lè fi ìfarajì yín hàn sí I?

Fún púpọ̀ síi, ẹ wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .

àmì ìpín àwọn ọmọdé

Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé

2 Àwọn Ọba 18:3–6; 19:14–19

Mo lè gbẹ́kẹ̀lé Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì.

  • Nínú 2 Àwọn Ọba 18:3, 5–6, ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe àwárí ohun tí ó mú He®sekíàh jẹ́ ọba rere. Lẹ́hìnnáà ẹ ka 2 Àwọn Ọba 19:14–19, papọ̀ kí wọ́n lè ṣe àwárí bí òun ṣe gbẹ́kẹ̀lé Olúwa. Ẹ lè wo àwòrán kan nípa Jésù kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí a fi lè gbẹ́kẹ̀lé E. Báwo ni a ṣe lè fihàn pé a gbẹ́kẹ̀lé Olúwa?

2 Àwọn Ọba 22:1-7

Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì lè gbẹ́kẹ̀lé mi.

  • Nínú 2 Àwọn Ọba 22:1, ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe àwárí bí Jòsíàh àtijọ́ ṣe wà nígbàtí ó di ọba. Kínni a kọ́ nípa Jòsíàh nínú ẹsẹ 2? Ẹ yẹ iṣẹ́ ṣíṣe kan wò tí ó lè júwe títẹ̀lé Olúwa àti kí ó máṣe yí sí “ẹ̀gbẹ́ sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí sí òsì.”

  • Àwọn òṣìṣẹ́ ṣe àpèjúwe nínú 2 Àwọn Ọba 22:3–7 pé a gbẹ́kẹ̀lé wọn pẹ̀lú owó sí títún tẹ́mpìlì kọ́ “nítorí wọ́n ṣe ìṣe òtítọ́” (ẹsẹ 7). Lẹ́hìn kíka àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí a ti gbé lé yín lọ́wọ́. Báwo ni a ṣe lè di olótìítọ́ bíi ti àwọn òṣìṣẹ́ nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí?

akọ̀wé pẹ̀lú Ọba Jòsíàh

Akọ̀wé kan nmú ìwé kíkọ ti ìwé mímọ́ bọ̀ fún Ọba Jòsíàh; ìjúwe láti ọwọ́ Robert T. Barret

2 Àwọn Ọba 22:8–11; 23:2–3

Àwọn ìwé mímọ́ kọ́ mi láti tẹ̀lé Jésù Krístì.

  • Láti fi ìtàn Ọba Jòsíàh hàn nínú 2 Àwọn Ọba 22–23, ẹ lè fi ẹ̀dà kan ti ìwé mímọ́ pamọ́ níbìkan nínú yàrá. Ẹ pe àwọn ọmọ yín láti wá a. Lẹ́hìnnáà ẹ lè pín ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbàtí ọ̀kan lára àlùfáà Jòsíàh rí àwọn ìwé mímọ́ nínú tẹ́mpìlì (wo 2 Àwọn Ọba 22:8–11; bákannáà wo “Ọba Jòsíàh” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 148–49). Kínni ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí wa bí a kò bá ní àwọn ìwé mímọ́? Ẹ pín ìdí tí inú yín fi dùn pé a ní àwọn ìwé mímọ́ ní òní pẹ̀lú arayín.

    1:36

    King Josiah

  • Lẹ́hìn kíka 2 Àwọn Ọba 23:2–3, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwé mímọ́ tí o´ ti mísí yín láti “rìn tẹ̀lé Olúwa” (ẹsẹ 3). Bákannáà ẹ lè kọ orin nípa àwọn ìwé mímọ́, bí irú “Wákiri, Jíròrò, àti Gbàdúrà” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 109).

2 Àwọn Ọba 23:1-3

Èmi ó pa àwọn májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.

  • Nígbàtí Jòsíàh àti àwọn ènìyàn rẹ̀ kọ́ àwọn òfin Ọlọ́run, wọ́n dá májẹ̀mú láti gbé wọn. Ẹ kà nípa èyí pẹ̀lú àwọn ọmọ yín nínú 2 Àwọn Ọba 23:1–3, kí ẹ sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn ọ̀rọ tí ó fi bí àwọn ènìyàn ṣe nímọ̀lára nípa àwọn òfin Ọlọ́run. Bóyá àwọn ọmọ yín lè dúró kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó lè túmọ̀sí láti “[dúró] ti májẹ̀mú.” Lẹ́hìnnáà wọ́n lè rìn ní ibìkan kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó lè túmọ̀sí láti “rìn tẹ̀lé Olúwa.” Títẹ̀le, wọ́n lè gbé ọwọ́ wọn lé ọkàn wọn kí wọ́n sì dá àbá àwọn ọ̀nà tí a lè fi pa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ “pẹ̀lú gbogbo ọkàn [wa].”

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .

àwọn ènìyàn nfa ère kan sílẹ̀ pẹ̀lú okùn

Àwọn ènìyàn Jòsíàh nmú àwọn òrìṣà kúrò nínú ìlú, ìjúwe láti ọwọ́ William Hole

Ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Àwọn ìwé mímọ́ kọ́ mi láti tẹ̀lé Jésù Krístì