Come, Follow Me
Oṣù Kejìlá 7–13. “Mímọ́ sí Olúwa”: Hággáì 1–2; Sekaríàhh 1–4; 7–14


“Oṣù Kejìlá 7–13. ‘Mímọ́ sí Olúwa”: Hággáì 1–2; Sekaríàh 1–4; 7–14,’ Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Kejìlá 7–13. ‘Mímọ́ sí Olúwa,’” Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026

Tẹ́mpìlì Laie Hawaii lábẹ́ àwọ̀sánmọ̀ ọ̀run kan

Tẹ́mpìlì Laie Hawaii

Oṣù Kejìlá 7–13: “Ìwà-mímọ́ sí Olúwa.

Hággáì 1–2; Sekaríàh 1–4; 7–14

Lẹ́hìn àwọn díkédì ti ìgbèkùn, ẹgbẹ́ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì kan, bóyá títí kan wòlíì Hággáì àti Sekaríàh, ni a yọ̀ọ̀da láti padà sí Jerúsálẹ́mù. Àwọn kan nínú ẹgbẹ́ yìí rántí bí tẹ́mpìlì náà ṣe rí kí wọ́n tó pa á run. Sí àwọn wọnnì tí wọ́n nní ìyàlẹ́nu bóyá yíò tún dà bí “ilé Olúwa nínú ògo rẹ̀ àkọ́kọ́” (Hággáì 2:3), Hággáì sọ ọ̀rọ̀ ìyànjú Olúwa pé: “Ẹ jẹ́ alágbára, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà, ni Olúwa wí, kí ẹ sì ṣiṣẹ́: nítorí èmi wà pẹ̀lú yín, … ẹ má bẹ̀rù.” “Èmi yíò fi ògo kún ilé yìí, … ní ibí yìí ni èmi yíò sì fi àláfíà fúnni” (Hággáì 2:4–5, 7, 9).

Ṣùgbọ́n kìí ṣe tẹ́mpìlì mímọ́ nìkan ni ó nílò àtúnṣe. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà, àwọn ènìyàn Ọlọ́run ti ní ìparun ti ẹ̀mí. Àti pé gbígbé àwọn ènìyàn mímọ́ ga tún gba ohun tí ó ju gígé òkúta àti gbígbé wọn sí ipò kíkọ́ ilé mímọ́ kan lọ. Ó túmọ̀ sí àkọlé náà “Ìwà-mímọ́ sí Olúwa” ni a gbọ́dọ̀ fín sí ára ògiri tẹ́mpìlì nìkan, tàbí sí ára “agogo àwọn ẹṣin” àti “gbogbo ìkòkò ní Jerúsálẹ́mù” (Sekaríàh 14:20–21). Wọ́n gbọ́dọ̀ fín wọn sí orí gbogbo ọkàn.

Fún àlàyé ṣókí nípa àwọn ìwé Hággáì àti Sekaríàh, wo “Hággáì” àti “Sekaríà” nínú Ìtumọ̀ Bíbélì.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Ikẹkọ ní Ilé àti ní Ìjọ

Hággáì 1; 2:1–9

àmì sẹ́mínárì
“Ẹ yẹ àwọn ọ̀nà yín wò.”

Ọ̀pọ̀ nkan pàtàkì ló wà láti ṣe láti tún Jerúsálẹ́mù kọ́. Ṣùgbọ́n lẹ́hìn nkan bí ọdún mẹ̀ẹ́dógún ti kọjá láti ìgbà ìpadàbọ̀ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì, inú Olúwa kò dùn pé wọn kò ti fi àtúnkọ́ tẹ́mpìlì náà jẹ́ ààyò wọn (wo Hággáì 1:2–5; bákannáà wo Ẹ́sìrà 4:24). Bí ẹ ṣe nka Hággáì 1; 2:1–9, ẹ yẹ àwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí wò:

  • Kíni àwọn àbájáde tí ọmọ Ísráẹ́lì dojúkọ nítorí pé wọn kò tíì parí tẹ́mpìlì náà?

  • Àwọn ìbùkún wo ni Olúwa ti ṣe ìlérí fún wọn tí wọ́n bá parí kíkọ́ ilé Rẹ̀?

  • Kíni ọ̀rọ̀ Olúwa sí i yín ní Hággáì 1:5–7? Báwo ni ẹ ṣe lè tò àwọn ohun pàtàkì yín pọ̀ pẹ̀lú ti Olúwa? Nígbàwo ni a ti bùkún yín fún fífi Ọlọ́run ṣe àkọ́kọ́ nínú ayé yín?

Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn àkọ́kọ́ dojúkọ irú ipò kannáà tí ó súnmọ ti àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ní ọjọ́ Hággáì (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 95). Kíni ẹ kọ́ látinu àwọn àpẹrẹ méjì nípa àwọn ìmọ̀lára Olúwa nípa tẹ́mpìlì?

Bákannáà wo Dale G. Renlund, “Jésù Krístì Ni Ìṣúra,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2023, 96–99; Terence M. Vinson, “Àwọ Ọmọẹ̀hìn Tòótọ́ ti Olùgbàlà,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2019, 9–11; “A Fẹ́ràn Ilé Yín, Ah Ọlọ́run,” Àwọn orin, nọ́mbà 247; “Tẹ́mpìlì Ilé-iṣẹ́ Ìlú nlá Provo ti Parí” (fídíò), ChurchofJesusChrist.org.

7:17

Provo City Center Temple Completed

Sekaríàh 1–3; 7–8; 14

Olúwa lè sọ mí di mímọ́.

Nínú èrò rẹ, ànfààní wo ni ó wà nínú fífi “Ìwà-mímọ́ sí Olúwa” tí a fín sí ára àwọn nkan ojojúmọ́ bíi ti Sekaríàh 14:20? (Bákannáà wo Ẹ́ksódù 28:36–38). Kíni iyì tí níní fínfín sí àwọn tẹ́mpìlì ní òní? Kíni gbólóhùn yí túmọ̀ sí fún yín? Báwo ni ẹ ṣe lè sọ ìwàmímọ́ di ara ìgbésí-ayé yín ojojúmọ́? Ronú lórí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí bí ẹ ṣe nka àwọn ìfipè Olúwa sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ láti di mímọ́ síi nínú Sekaríàh 1:1–6; 3:1–7; 7:8–10; 8:16–17.

Ẹ tún lè ka Sekaríàh 2:10–11; 8:1–8; 14:9–11, 20–21 láti kọ́ bí ìwàláàyè yíò ti rí ní ọjọ́ iwájú nígbàtí gbogbo wa bá ngbé pẹ̀lú Olúwa ní ipò ìwà-mímọ́. Kíni ó wọ̀ yín lọ́kàn nípa ìran Sekaríà nípa ọjọ́ iwájú Jerúsálẹ́mù? Kíni ẹ rí ní ìhín tí ẹ fẹ́ràn láti rí ní agbègbè yín? Báwo ni ẹ ṣe lè múrasílẹ̀ láti gbé nínú àwọn ipò tí Sekaríà ṣe àpèjúwe?

Jésù wọ Jerúsálẹ́mù lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́

“Kíyèsí i, Ọba rẹ nbọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ: olódodo ni òhun, ó sì ní ìgbàlà; o nírẹ̀lẹ̀, ó sì ngun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́” (Sekaríàh 9:9). Wíwọlé pẹ̀lú Ìṣẹ́gun, láti ọwọ́ Harry Anderson

Sekaríàh 9:9–11; 11:12–13; 12:10; 13:6–7; 14:1–9

Jésù Krístì ni Mèssíàh tí a ṣe ìlérí.

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé Sekaríàh tọ́ka sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Jésù Krístì lórí ilẹ̀ ayé àti sí Bíbọ̀ Rẹ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì níkẹhìn. Nísàlẹ̀ ni díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Sekaríàh, papọ̀ pẹ̀lú àwọn Ìwé Mímọ́ nípa ìmúṣẹ wọn. Bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ẹ bi ara yín léèrè: Kíni èyí kọ́ mi nípa Olùgbàlà?

  • Sekaríàh 9:9–11 (wo Máttéù 21:1–11; 1 Pétérù 3:18–19)

  • Sekaríàh 11:12–13 (wo Máttéù 26:14–16; 27:1–7)

  • Sekaríàh 12:10 (wo Jòhánnù 19:37; Ìfihàn 1:7)

  • Sekaríàh 13:6–7; 14:1–9 (wo Máttéù 26:31; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 45:47–53)

Kíni ẹ rò pé ìbá ti rí láti wà lára àwọn ènìyàn tó nkí Jésù káàbọ̀ sí Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́bí a ti ṣe àpèjúwe nínú Sekaríàh 9:9–11? Bawo ni ẹ ṣe lè ṣe ìtẹ́wọ́gbà Rẹ̀ sínú ayé yín, àwọn ilé yín, àti agbègbè yín?

Bákannáà wo Ìtọ́sọ́nà sí Ìwé Mímọ́, “Mèssíàh,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere; “Wíwọlé pẹ̀lú Ìṣẹ́gun Olúwa sí Jerúsálẹ́mù” (fídíò), Ibi Ìkàwé Ìhìnrere; Ronald A. Rasband, “Hòssánà sí Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo,” Làìhónà, Oṣù karun 2023, 108–12.

1:22

The Lord's Triumphal Entry into Jerusalem

Fún púpọ̀ sí i, wo àwọn ìtẹ̀jáde àwọn ìwé-ìròhìn oṣù yí ti Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .

ìpín àmì àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Hággáì 1:2–8

“Gbèrò àwọn ọ̀nà rẹ.”

  • Bí ẹ ti nka ara Hággáì 1:2–5 pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ìdí tí inú Olúwa kò fi dùn sí àwọn ènìyàn náà. Bóyá àwọn ọmọ yín lè mú gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan látinú ẹsẹ 6 kí ẹ sì ya àwòrán rẹ̀. Wọ́n lè fi han ara wọn kí wọ́n sì ṣe àmọ̀rò kíni gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ìyàwòrán kọ̀ọ̀kan dúró fún. Nígbàtí a bá lo àkokò lórí àwọn ohun míràn yàtọ̀ sí ohun tí Olúwa nfẹ́, báwo ni èyí ṣe dàbí jíjẹun ṣùgbọ́n tí a kò yó? Ẹ lè bá ara yín sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ ṣe lè wá àyè fún àwọn ohun tó ṣe pàtàkì fún Olúwa.

  • Ẹ tún lè ka ẹsẹ 8 fún àwọn ọmọ yín kí ẹ sì pè wọ́n láti ṣe bí ẹni pé wọn “ngòkè lọ sí orí òkè,” “mú igi wá,” kí a sì “kọ́ ilé [Olúwa].” Àwọn ọmọ yín lè ṣe àtòkọ àwọn ohun tí wọn ṣe ní ọjọ́ yí gan, pẹ̀lú àwọn ohun tí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn láti ṣe. Ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín láti “yẹ àwọn ọ̀nà [wọn] wò” nípa yíyí ohun tí Olúwa lè sọ pé ó jẹ́ àwọn ohun pàtàkì jùlọ nínú àtòkọ wọn ká.

Àárín-gbùngbùn Ìkọ́ni Ilé. Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé ilé gbọ́dọ̀ jẹ́ “oókan ti ẹ̀kọ́ ìhìnrere” (“Dídi Àpẹrẹ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2018, 113). Bí ẹbí yín ṣe nṣe àṣàrò ìmọ̀ràn Hággáì pé ká “yẹ nípa àwọn ọ̀nà wa wò,” ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe lè fi Ọlọ́run ṣáájú nínú ìgbésí-ayé ẹbí wa.

Sekaríàh 3:1–7

Ṣíṣe àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi láti dàbí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì.

  • Nínú ìran, Sekaráyà rí àlùfáà àgbà kan tí a “fi aṣọ èérí wọ̀” (Sekaríàh 3:3). Ángẹ́lì kan fún un ní aṣọ mímọ́. Ẹ lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe àwárí àwọn òtítọ́ pàtàkì nípa kíka Sekaríàh 3:1–7 papọ̀ àti sísọ̀rọ̀ nípa ohun tí aṣọ ẹlẹ́gbin àti aṣọ mímọ́ lè dúró fún. Báwo ni a ṣe lè mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa, àní lẹ́hìn tí a ṣe ìrìbọmi? Báwo ni májẹ̀mú ìrìbọmi wa ṣe nràn wá lọ́wọ́ láti “rìn ní àwọn ọ̀nà [Olúwa]”?

  • Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè wo àwòrán ìrìbọmi, bí èyí tó wà nínú ìlànà yìí. Kínìdí tí a fi nwọ aṣọ funfun nígbà ìrìbọmi wa? Ẹ tún lè kọ orin kan nípa ìrìbọmi, gẹ́gẹ́bí “Nígbàtí Mo Ṣè Ìrìbọmi” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 103); Kíni orin náà kọ́ni nípa ìdí tí Olúwa fi fẹ́ kí a ṣe ìrìbọmi?

baba tí ó nṣe ìrìbọmi fún ọmọbìnrin rẹ̀ nínú odò kan

Sekaríàh 9:9–11; 11:12; 13:6–7

Jésù Krístì ní Mèssíàh tí a ṣe ìlérí.

  • Àwọn ọmọ yín lè fọkàn ya àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ tí Sekaríàh 9:9, sọ tẹ́lẹ̀, nígbàtí Jésù dé Jerúsálẹ́mù ní ọ̀sẹ̀ tó gbẹ̀hìn ayé ikú Rẹ̀. Láti ṣe ìrànwọ́ pẹ̀lú èyí, ẹ fi àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ hàn wọ́n, bí èyí tí ó wà nínú ìlànà yi. Ẹ tún lè ṣe àbápín pẹ̀lú wọn “Olùgbàlà Lọ Sí Jerésálẹ́mù” (nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Titun, 110–12). Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé tọ́ka sí àwọn ènìyàn nínú àwọn àwòrán tí wọ́n “nyọ̀ gidigidi.” Tani Ọba nínú Sekaríàh 9:9? Kínìdí tí a fi dúpẹ́ fún Un?

    1:35

    Chapter 44: The Savior Goes to Jerusalem

  • Ẹ yẹ ríran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti fi àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Sekaríàh wéra pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Májẹ̀mú Titun tí ó nṣe àpèjúwe ìmúṣẹ wọn. Ní ìhín ni àwọn àpẹrẹ díẹ̀: Sekaríàh 9:9 àti Máttéù 21:5–9; Sekaríàh 9:11 àti 1 Pétérù 3:18–19; Sekaríàh 11:12 àti Máttéù 26:14–16; Sekaríàh 13:7 àti Máttéù 26:31. Kíni a kọ́ nípa Olùgbàlà látinú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí?

Fún púpọ̀ sí i, wo ìtẹ̀jáde ìwé ìròhìn oṣù yí ti Fríẹ́ndì .

Àwọn àmì orí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ tẹ́mpìlì nka “Ìwà-mímọ́ sí Olúwa” àti “Ilé Olúwa” ní onírurú èdè

“Ìwà-mímọ́ sí Olúwa” hàn lórí gbogbo tẹ́mpìlì.

Ojú ewé ìṣe alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Jésù Krístì lè sọ ẹ̀mí mi di mímọ́