Oṣù Kẹ́ta 2–8. ‘Ẹ Jẹ́kí Ọlọ́run Borí’,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
Oṣù Kẹ́ta 2–8. ‘Ẹ Jẹ́kí Ọlọ́run Borí’,” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026
Ésàù Ta Ogún-ìbí Rẹ̀, láto ọwọ́ Glen S. Hopkinson (detail)
Oṣù Kẹ́ta 2–8: “Ẹ Jẹ́kí Ọlọ́run Borí”
Gẹ́nẹ́sísì 24–33
Báwo ni ẹ ṣe nṣe ìmúdúró ìbùkún fún arayín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run? Ẹ lè sọ pé àkọsílẹ̀ Jákọ́bù, ọmọ-ọmọ Ábráhámù àti Sáràh, ni ìtàn ti ọkùnrin kan tí ó kọ́ ìdáhùn sí ìbèèrè náà. Nínú àṣà níbití àkọ́bí ọmọkùnrin ti ngba ìbùkún ogún-ìbí, Jákọ́bù ni a bí ṣìkejì, tí ó di gìgísẹ̀ arákùnrin ìbejì rẹ̀ Ésàù, mú. Orúkọ náà “Jákọ́bù” túmọ̀sí “olùjágbà”—ẹnití ó nrọ́pò ẹnìkan míràn. Jákọ́bù gbé ìgbésí orúkọ náà nípa gbígbìyànjú, ju ẹ̀ẹ̀kan lọ, láti ṣe ìjágbà Ésàù bí olùjogún ti ìbúkún ogún-ìbí nítorí Ésàù kò yẹ nípa rẹ̀ (wo Gẹnẹ́sísì 25-30. 25:30–34; 26:34–35; 27:36). Àbájáde náà ni asọ̀ nínú ẹbí, Jákọ́bù sì níláti sá kúrò fún ayé rẹ̀ sínú aginjù.
Àwọn ọdún lẹ́hìnnáà, Ọlọ́run pàṣẹ fún Jákọ́bù láti padà sílé. Ní ojú ọ̀nà, nínú ìrẹ̀lẹ̀, lẹ́ẹ̀kansi ó wá ìbùkún láti ọ̀dọ́ Ọlọ́run. Àwọn ìwé mímọ́ ṣe àpèjúwe àkokò yí bí “ìjàkadi” fún Jákọ́bù, ó sì kéde pé òun kò ní kúrò “bíkòṣepé ìwọ bá súre fún mi” (Gẹ́nẹ́sísì 32:26). Lẹ́hìnnáà ni ẹ̀kọ́ náà wá—àti ìbùkún. Ọlọ́run yí orúkọ Jákọ́bù padà sí Ísráẹ́lì—tí ó túmọ̀sí, ní àárín àwọn ohun míràn, “ẹ jẹ́ kí Ọlọ́run borí.” Ísráẹ́lì kọ́ láti gba àwọn ìbùkún oníyelórí jùlọ ti Ọlọ́run, àwọn ìbùkún májẹ̀mú Rẹ̀, kò pọndandan láti já ti ẹnìkẹ́ni míràn gbà. Àwọn ìbùkún Rẹ̀ ni a kò rà tàbí jágbà tàbí yege. Ó fún wọn ní ọ̀fẹ́ sí gbogbo ẹnití ó gbé ìgbésí ayé orúkọ Ísráẹ́lì—ẹnití ó jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ayé wọn.
Àwọn èrò fún Kíkọ́ni ní Ilé àti Ìjọ
Gẹ́nẹ́sísì 24
Ìgbéyàwó májẹ̀mú ṣe pàtàkí sí ètò ayérayé Ọlọ́run.
Nígbàtí ẹ bá nka Gẹ́nẹ́sísì 24, ẹ bèèrè lọ́wọ́ arayín ìdí tí Ábráhámù fi yẹ ìgbeyàwó ọmọ rẹ̀ wò láti jẹ́ pàtàkì gan. Kínni ìdí tí ìgbeyàwó fi jẹ́ pàtàkì sí Ọlọ́run?
Kínni àwọn ìwà tí ẹ rí nínú Rèbékà tí yíò dásí ìgbeyàwó àti ẹbí alágbára? (Nípàtàkì wo àwọn ẹsẹ 15–28, 57–61).
Wo Àwọn Àkọlé àti Àwọn Ìbèèrè, “Ìgbeyàwó,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Gẹ́nẹ́sísì 25:29–34
Mo lè mọyì àwọn ohun ayérayé lórí àwọn ohun ti ayé.
Nínú àṣà Ísáákì àti Rèbékà, ọmọ àgbà ó gba ogún-ìbí, èyí tí o´ túmọ̀sí ogún títóbijù, ní ẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ojúṣe títóbijù fún ṣíṣe ìtọ́jú fún ẹbí náà. Bí ẹ ti nka Gẹ́nẹ́sísì 25:29–34, ẹ jíròrò ìdí tí Ésàù fi lè ti ní ìfẹ́ láti fi ogún-ìbí rẹ̀ sílẹ̀ fún oúnjẹ kan. Kínni àwọn ẹ̀kọ́ tí ẹ rí fún arayin nínú àkọsílẹ̀ yí? Ó lè ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe ìtòsílẹ̀ méjì: (1) àwọn ìbùkún ayérayé tí Ọlọ́run nfẹ́ láti fún yín àti (2) àwọn ohun ti ayé tí ó lè dà yín láàmú. Nígbànáà ẹ lè ka ẹsẹ ọ̀rọ̀ náà, kí ẹ rọ́pò “ogún-ìbí” pẹ̀lú ohunkan látinú ìtòsílẹ̀ àkọ́kọ́ àti “àṣáró” pẹ̀lú ohunkan látinú ìkejì. Báwo ni ẹ ṣe lè kọjúsí Olùgbàlà àti àwọn ìbùkún ayérayé ti ìhìnrere Rẹ̀?
Bákannáà wo Máttéù 6:19–33; M. Russell Ballard, “Ẹ Rántí Ohun Tó Ṣe Dandan Jùlọ,” Làìhónà, Oṣù Karun 2023, 105–7.
Jákọ́bù ní Bẹ́tẹ́lì, láti ọwọ́ James Smetham
Gẹ́nẹ́sísì 28
Àwọn májẹ̀mú ilé Olúwa nmú agbára Ọlọ́run wá sínú ayé mi.
Nígbàtí ó nsùn lórí ìrọ̀rí ti àwọn òkúta, Jákọ́bù lá àlá ìgbésí ayé-ìyípada. Ó jẹ́ irú ìrírí mímọ́ tí Jákọ́bù sọ orúkọ ibi náà ní Bẹ́tẹ́lì, tàbí “ilé Olúwa,” ní kíkéde, “Dájúdájú Olúwa wà ní ibí yi” (Gẹ́nẹ́sísì 28:16).
Bí ẹ ti nka Gẹ́nẹ́sísì 28, ẹ lè bèèrè lọ́wọ́ arayín ohun tí ó mú èyí jẹ́ ìrírí tí ó jẹ́ mímọ́ gan sí Jákọ́bù. Kínni ó nlà kọjá ní àkokò náà? Báwo ni ó ṣe lè ti ní ìmọ̀lára sí? Ẹ lè wá àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn bákannáà nínú àwọn ẹsẹ 10–22 tí ó rán yín létí nípa ilé Olúwa. Kínni àwọn ìwọnilọ́kàn tí ẹ gbà nípa Ọlọ́run, ilé Rẹ̀, àti àwọn májẹ̀mú Rẹ̀?
Ní òpin ti ìlànà yí ni àwòrán kan tí ó fi àlá Jákọ́bù hàn; ẹ lè tọ́kasí i bí ẹ ti nkà á. Bí ẹ bá níláti dá ìfìhàn àtinúdá ti ara yín sílẹ̀ nípa àlá rẹ̀, kínni ohun tí ẹ yíò ṣe? Kínni àwọn òtítọ́ láti inú ìtàn náà tí ẹ yíò gbìyànjú láti fihàn?
Orin ìsìn “Sísúnmọ́, Ọlọ́run Mi, síi Sí Ọ” (Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 100) ni ó dá lé ìrírí Jákọ́bù. Kini àwọn ìsopọ̀ tí ẹ rí ní àárín orin yí àti Gẹ́nẹ́sísì 28:10–22? Báwo ni tẹ́mpìlì ṣe nràn yín lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ sísúnmọ́ Ọlọ́run síi? Ẹ yẹ wíwá àwọn ìdáhùn sí ìbèèrè ọrọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson yí wò “Tẹ́mpìlì àti Ìpilẹ̀sẹ̀ Ti Ẹ̀mí Yín” (Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2021, 93–96). Bákannáà ẹ lè ṣe àtúnwò àwọn májẹ̀mú àti ìbùkún ti ile Olúwa nínú Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 27.2 (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere). Báwo ni pípa àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí mọ́ ṣe nmú agbára Ọlọ́run wá sínú ayé yín?
Ẹ jẹ́ alátinúdá. Àwọn ọ̀nà púpọ̀ wà láti kọ́ ẹ̀kọ́ látinú àwọn ìwé mímọ́ yàtọ̀ sí kíkà wọ́n lásán. Àwọn ènìyàn kan ri pé wọ́n nní òye àwọn ìwé mímọ́ dáradára bí wọ́n bá ya àwọn àwòrán ti àwọn àkọsílẹ̀ náà. Àwọn ẹlòmíràn nrí ìjìnlẹ̀ òye nínú orin mímọ́ tí ó bá àwọn ìwé mímọ́ mu. Ẹ máṣe dí arayín kù sí ọ̀nà kan ti kíkọ́ ẹ̀kọ́; ẹ fàyè gba gbígbìyànjú onírúurú àwọn ọ̀nà.
Gẹ́nẹ́sísì 29:31–35; 30:1–24
Olúwa nrántí mi nínú àwọn àdánwò mi.
Bí ẹ ti nka Gẹ́nẹ́sísì 29:31–35 àti 30:1–24, ẹ wá àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe àpèjúwe àánú Ọlọ́run sí Rákẹ́lì àti Léàh. Ẹ jíròrò bí Ọlọ́run ti “wo ìpọ́njú [yín]” tí ó sì “rántí” yín (Gẹ́nẹ́sísì 29:32; 30:22).
Gẹ́nẹ́sísì 32–33
Olùgbàlà lè wo ẹbí mi sàn.
Bí Jákọ́bù ṣe padà sí Kenáánì, ó “bẹ̀rù ó sì ní ìrẹ̀wẹ̀sì gidigidi” nípa bí arákùnrin rẹ̀, Ésàù, yíò ti gbà á (Gẹ́nẹ́sísì 32:7). Bí ẹ ti nka Gẹ́nẹ́sísì 32–33, ẹ jíròrò àwọn ìbáṣepọ̀ ti ẹbí arayín—bóyá nípàtàkì wọ́n jẹ́ ọ̀kan tí ó nílò ìwòsàn. Bóyá ìtàn yí lè mísí yín láti nawọ́ jáde sí ẹnìkan. Àwọn ìbèèrè bíiti ìwọ̀nyí lè ṣe atọ́nà yín ní kíka:
-
Báwo ni Jákọ́bù ṣe múrasílẹ̀ sí pípàdé Ésàù?
-
Kínni ó jáde sí yín gbọ̀ngbọ̀n nípa àdúrà Jákọ́bù tí a rí nínú Gẹ́nẹ́sísì 32:9–12?
-
Kínni ẹ kọ́ nípa ìdáríjì látinú àpẹrẹ Ésàù?
-
Báwo ni Olùgbàlà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti wo àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí sàn?
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé ìròhìn Làòhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé
Gẹ́nẹ́sísì 24:10–21
Èmi lè ṣe rere sí àwọn ẹlòmíràn.
-
Láti fi àpẹrẹ inúrere wíwọnilọ́kàn ti Rèbékà hàn, ẹ lè fi àwòrán ìsàlẹ̀ han àwọn ọmọ yín tàbí ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe ọ̀sẹ̀ yí bí ẹ ti nṣe àkópọ̀ ìtàn náà nínú Gẹ́nẹ́sísì 24:10–21. Àwọn ọmọ yín lè gbádùn ṣíṣe eré ìtàn náà jáde. Èyí lè darí sí ìbárasọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣe inúrere tí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín ti rí.
-
Ẹ gbèrò kíkọ orin kan papọ̀ nípa inúrere, bi irú “Inúrere Bẹ̀rẹ pẹ̀lú Mi” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 145). Àwọn ọmọ lè fetísílẹ̀ fún ọ̀rọ̀ náà “inúrere” (tàbí ọ̀rọ̀ irú kannáà) kí wọ́n sì dúró nígbàtí wọ́n bá gbọ́ ọ. Báwo ni a ṣe lè jẹ́ onínúrere bíiti Rèbékà?
Àwọn Akọni Májẹ̀mú Láéláé, láti ọwọ́ Dilleen Marsh (àlàyé)
Gẹ́nẹ́sísì 25:21–34
Àwọn ohun ayérayé ṣe pàtàkì ju àwọn ohun ti ayé lọ.
-
Ẹ yẹ lílo “Jákọ́bù àti Ésàù wò” (nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 38–41) láti ràn àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye ìtàn náà nínú Gẹ́nẹ́sísì 25:21–34. Bóyá àwọn ọmọ yín lè ròó pé Ésàù bèèrè fún ìmọ̀ràn nípa bóyá kí ó ṣe títa ogún-ìbí rẹ̀ fún àṣáró. Kínni wọn ò sọ fún un?
2:5Jacob and Esau
-
Kínni àwọn ohun tí ó pọndandan níti ayérayé síi yín àti àwọn ọmọ yín? Bóyá àwọn ọmọ yín lè rí àwọn àwòrán tàbí nkan tí ó rọ́pò àwọn ohun wọ̀nyí. Báwo ni a ṣe lè fihan Olúwa pé àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ pàtàkì sí wa?
Gẹ́nẹ́sísì 28:10–22
Àwọn májẹ̀mú nràn mí lọ́wọ́ láti padà sí ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run.
-
Bí ẹ ti nka Gẹ́nẹ́sísì 28:10–22 papọ̀, ẹ lè lò àkàbà kan tàbí àtẹ̀gùn (tàbí àwòrán kan bíiti ọ̀kan ní òpin ìlànà yí) láti sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn májẹ̀mú wa ṣe dàbí àkàbà kan. Bóyá àwọn ọmọ yín lè díbọ́n láti gun àkàbà kan, àti pẹ̀lú ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan, sọ̀rọ̀ nípa àwọn àkokò nígbàtí a ṣe`lérí láti gbọ́ran sí Ọlọ́run, bí irú ìgbàtí a ṣe ìribọmi, jẹ́ oúnjẹ Olúwa, tàbí lọ sí tẹ́mpìlì. Báwo ni àwọn májẹ̀mú wa ṣe nmú wa súnmọ́ Ọlọ́run síi?
Gẹ́nẹ́sísì 32:6–11; 33:1–4
Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì lè ràn mi lọ́wọ́ láti fẹ́ràn ẹbí mi.
-
Láti fi àwọn ẹsẹ wọ̀nyí hàn, ẹ lè ṣe àlàyé pé lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ti ìmọ̀lára líle, Jákọ́bù nlọ láti pàdé Ésàù lẹ́ẹ̀kansi. Ẹ ṣe kíka papọ̀ Gẹ́nẹ́sísì 32:6–11. Báwo ni Jákọ́bù ṣe nímọ̀lára sí? Kínni ó ṣe láti gba ìrànlọ́wọ́? Ẹ ka Gẹ́nẹ́sísì 33:1–4 ṣe àwárí bí Olúwa ti dáhùn àdúrà Jákọ́bù. Bí Jákọ́bù àti Ésàù bá lè sọ̀rọ̀ sí wa ní òní, kínni ohun tí wọn yíò sọ láti ràn wá lọ́wọ́ nígbàtí ìjà bá wà nínú ẹbí wa?
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .