Come, Follow Me
Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Iyè-inú: Ilé Isráẹ́lì Náà


“Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Iyè-inú: Ilé Isráẹ́lì,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Ilé Isráẹ́lì Náà,” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026

àmì àwọn èrò

Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Iyè-inú

Ilé Isráẹ́lì Náà

Níbìkan nínú aginjù ìlà òòrùn ti Kénánì, Jákọ́bù nínú àìfọkànbalẹ̀ dúró de ìbápàdé pẹ̀lú ìbejì arákùnrin rẹ̀, Ésàù. Ìgbà tó kẹ́hìn tí Jákọ́bù ti rí Ésàù, ní bíi ogún ọdún ṣíwájú, Ésàù fẹ́ láti pa á. Jákọ́bù lo gbogbo òru nínú ìjàkadì, ó nwá ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Bí àbájáde ìgbàgbọ́, ìtẹramọ́, àti ìpinnu ti Jákọ́bù, Ọlọ́run dáhùn àwọn àdúrà rẹ̀. Ní orù náà orúkọ Jákọ́bù ni a yípadà sí Ísráẹ́lì, orúkọ tí ó túmọ̀ sí, ní àárín àwọn ohun míràn pé, “ó faradà pẹ̀lú Ọlọ́run” (Gẹ́nẹ́sísì 32:28, àkọsílẹ̀ ránpẹ́ ìsàlẹ̀ b).

Odò Jábbókù

Nítòsí Odò Jábbókù, Jákọ́bù gba orúkọ náà Ísráẹ́lì.

Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí orúkọ náà Ísráẹ́lì ó farahàn nínú Bíbélì, ó sì jẹ́ orúkọ kan tí ó ní ìfaradà nínú gbogbo ìwé àti gbogbo ìwé-ìtàn. Láìpẹ́ orúkọ náà wá láti tọ́ka sí ju ọkùnrin kanṣoṣo lọ. Ísráẹ́lì ní àwọn ọmọ méjìlá, àwọn àtẹ̀lé wọn lápapọ̀ jẹ́ mímọ̀ bí “ilé Ísráẹ́lì,” àwọn “ẹ̀yà Ísráẹ́lì,” àwọn “ọmọ Ísráẹ́lì,” tàbí “àwọn ọmọ Ísráẹ́lì.”

Ní gbogbo ìwé-ìtàn, àwọn ọmọ Ísráẹ́lì fi jíjẹ́ pàtàkì nlá sí àtẹ̀lé wọn láti ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà méjìlá Ísráẹ́lì hàn. Ìran wọn ni ara pàtàkì ti májẹ̀mú ìdánimọ̀ wọn. Àpóstélì Páùlù kéde pé òun ni “ara ẹ̀yà ti Bẹ́njámínì” (Àwọn ará Rómù 11:1). Èrèdí kan tí Léhì fi rán àwọn ọmọ rẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù láti gba àwọn àwo idẹ ni àwọn àwo náà tí ó ní “ìtàn àwọn baba wa nínú” (1 Néfì 5:14). Léhì ri pé òun ni àtẹ̀lé Jósẹ́fù kan, àti pé níní òye ìran rẹ̀ nípa ìsopọ̀ wọn sí ilé Isráẹ́lì ti ṣàfihàn pàtàkì sí wọn ní àwọn ọdún tó tẹ̀le.

Nínú Ìjọ ní òní, ẹ lè gbọ́ nípa Isráẹ́lì nínú àwọn ọ̀rọ̀ sísọ bíi “Ìkójọpọ̀ Isráẹ́lì.” A nkọrin nípa “Olùràpadà Isráẹ́lì,” Ìrètí “ti Isráẹ́lì,” àti “Ẹ̀yin Alàgbà Isráẹ́lì.” Nínú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí, a kìí nsọ̀rọ̀ tàbí kọ orin nípa ìjọba àtijọ́ ti Isráẹ́lì tàbí orílẹ̀-èdè ode òní tí a pè ní Isráẹ́lì. Dípò bẹ́ẹ̀, à ntọ́ka sí àwọn ènìyàn tí a ti kójọ láti inú àwọn orílẹ̀-èdè ayé sínú Ìjọ Jésù Krístì. À ntọ́ka sí àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìfaradà pẹ̀lú Ọlọ́run, ẹni tí ó fi ìtara wá àwọn ìbùkún Rẹ̀, àti ẹnití, nípasẹ̀ ìrìbọmi, ti di àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ̀. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson, láti jẹ́ ti Isráẹ́lì túmọ̀ sí “láti jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ayé wa, … láti jẹ́ kí Ọlọ́run jẹ́ ipa alágbára jùlọ nínú ayé wa.”

Ìbùkún ti babanlá yín kéde ìsopọ̀ yín sí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà ilé Isráẹ́lì. Ìyẹn ju ẹ̀là wíwuni ti ìwé-ìtan ẹbí lọ. Bákannáà ó ní í ṣe pẹ̀lú ayé yín lọ́wọ́lọ́wọ́ àti ní ọjọ́ ọ̀la. Jíjẹ́ ara ilé Isráẹ́lì kan túmọ̀ sí pé ẹ ní ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú kan pẹ̀lú Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì. Ó túmọ̀ sí pé ẹ̀yin, bíi Ábráhámù, níláti jẹ́ “ìbùkún kan” sí àwọn ọmọ Ọlọ́run (Gẹ́nẹ́sísì 12:2; Ábráhámù 2:9–11). Ó túmọ̀ sí, ní àwọn ọ̀rọ̀ Pétérù, pé “ẹ̀yin ni ìran tí a yan, oyè àlùfáà ọlọ́lá, orílẹ̀-èdè mímọ́, ènìyàn ọ̀tọ̀; kí ẹ̀yin kí ó lè fi ìyìn ẹnití ó pè yín jáde kúrò nínú òkunkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn” (1 Pétérù 2:9). Ó túmọ̀ sí pé kí ẹ “jẹ́kí Ọlọ́run borí”—pé ẹ̀yin ni ẹni tí ó “ní ìfaradà pẹ̀lú Ọlọ́run” bí ẹ ti nbọ̀wọ̀ fún àwọn májẹ̀mú yín pẹ̀lú Rẹ̀.

igi ẹbí

Igi Ẹbí ti Jákọ́bù (Ísráẹ́lì), láti ọwọ́ Brent Evans

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Bákannáà wo Gẹ́nẹ́sísì 32:24–32. Àwọn ìtumọ̀ míràn tí ó wà fún orúkọ Isráẹ́lì, wà pẹ̀lú “àwọn òfin Ọlọ́run,” “Ọlọ́run njà tàbí ní ìfaradà,” àti láti “Jẹ́kí Ọlọ́run borí.”

  2. Wo Ìsàíàh 26:36; 3 Néfì 20:25.

  3. Àwọn Orin Ìsìn (1985), nos. 6, 259,319.

  4. Russell M. Nelson, “Jẹ́kí Ọlọ́run Borí,” Lìàhónà, Oṣú Kọkànlá 2020, 92.