“Oṣù Kẹ́ta 9–15. ‘Olúwa Wà pẹ̀lú Jósẹ́fù’: Gẹ́nẹ́sísì 37–41,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹ́ta 9–15. ‘Olúwa Wà pẹ̀lú Jósẹ́fù’,” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026
Jósẹ́fù àti Àwọn Arákùnrin Rẹ̀, láti ọwọ́ Sam Lawlor
Oṣù Kẹ́ta 9–15: “Olúwa Wà pẹ̀lú Jósẹ́fù”
Gẹ́nẹ́sísì 37–41
A mọ̀ pé Ọlọ́run nbùkún àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé E tí wọ́n sì npa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n nígbàmíràn kìí dàbí pe ó rí bẹ́ẹ̀. Nígbàmíràn ẹni náà tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run ni àwọn ọmọ ẹbí nlò nílòkulò tí wọ́n sì npatì. Nígbàmíràn ẹni náà tí ó bá nígboyà tí ó kọ̀ láti rú òfin ìparaẹnimọ́ ní ó njẹ́ fífi ẹ̀sùn èké kàn lọ́nàkọnà. Nígbàtí àwọn nkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa, a lè di dídánwò láti bínú pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó lè yà wá lẹ́nu pé, “Kínní èrèdí gbígbìyànjú láti ṣe ohun tó tọ́ bí ó bá dàbíi pé yíò mú ìgbésí ayé nira síi nìkan?”
Jósẹ́fù, ọmọ Jákọ́bù, lè ti ní ìyàlẹ́nu ìyẹn. Ní ìgbàmíràn, olotitọ ènìyàn yí ó ṣerere; ní ìgbàmíràn, ó ndàbí ẹnipé bí òun bá ti jẹ́ olotitọ púpọ̀ síi, ni ìnira tí ó ndojúkọ ó ti pọ̀ si tó. Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù kò fi Olúwa sílẹ̀, Olúwa kò sì fi Jósẹ́fù sílẹ̀ rárá. Ìyẹn, kò túmọ̀ sí pé Olúwa dẹ́kun àwọn ohun búburú kúrò ní ṣíṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù, ṣùgbọ́n nínú gbogbo rẹ̀, “Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀” (Gẹ́nẹ́sísì 39:3).
Àwọn èrò fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti Ìjọ
Gẹ́nẹ́sísì 37:1–28; 39; 41:9–45
Olúwa yíò wà pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú mi.
Ní àkokò àti lẹ́ẹ̀kansi, orí rere dàbíi pé ó tì pà Jósẹ́fù tì, ṣùgbọ́n Olúwa kò ṣeé rárá. Bí ẹ ti nka ìtàn ti Jósẹ́fù, ẹ jíròrò àwọn ìbèèrè bí irú ìwọ̀nyí: Kínni Jósẹ́fù ṣe láti dúró súnmọ́ Olúwa? Báwo ni Olúwa ṣe “wà pẹ̀lú rẹ̀”? (wo Gẹnẹ́sísì 39; 40:1–19; 41:9–45). Kínni ẹ kọ́ láti inú ìtàn Jósẹ́fù tí ó lè ràn yín lọ́wọ́ láti dá wíwà lọ́dọ̀ Olúwa mọ̀ nínú ayé yín?
Bákannáà ẹ lè bèèrè irú àwọn ìbèèrè kannáà nípa ìgbesí ayé yín. Kínni ẹ̀rí tí ẹ ti rí pé Olúwa kò kọ̀ yín sílẹ̀ ní àwọn ìgbà àdánwò? E gbèrò bí ẹ ti lè pín àwọn ìrírí yín pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹbí àti àwọn ìran ọjọ́ ọ̀là (wo 1 Néfì 5:14).
Bẹ́ẹ̀ni, ẹ ó ní àwọn àdánwò míràn ní ọjọ́ ọ̀là. Kínni ẹ lè ṣe nísisìyí láti ṣèrànwọ́ láti ri dájú pé àwọn àdánwò wọ̀nyí kò fà yín kúrò lọ́dọ̀ Olúwa? Ẹ gbèrò kíkọ́ lẹ́tà kan láti gba ọjọ́ ọ̀là ti ara yín níyànjú láti dúró súnmọ́ Ọ bí ó ti wù kí ó rí. Ẹ lè fi àwọn ìwòye láti inú ìgbésí ayé Jósẹ́fù tàbí ọ̀rọ̀ Alàgbà D. Todd Christofferson si pẹ̀lú “Ìbáṣepọ̀ Wa pẹ̀lú Ọlọ́run” (Làìhónà, Oṣù Karun 2022, 78–81).
Bákannáà ẹ wo Jòhánnù 14:18; Àwọn Ará Rómù 8:28; Álmà 36:3; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 121:7–8; “Gbé pẹ̀lú Mi!,” Àwọn Orin, nọ́mbà 166.
Gẹ́nẹ́sísì 37:5–11; 40; 41:1–38
Bí mo bá jẹ́ olotitọ, Olúwa yíò tọ́sọ́nà yíò sì mí sí mi.
Jósẹ́fù ní ẹ̀bùn kan fún níní òyè àwọn ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa nípasẹ̀ àwọn àlá. Kínni ẹ lè kọ́ láti inú Gẹ́nẹ́sísì 37:5–11; 40:5–8; 41:14–25, 37–3 nípa gbígbà àti níní òye ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Olúwa? Fún àpẹrẹ, kínni ẹ lè kọ́ láti inú àpẹrẹ Jósẹ́fù nígbàtí ìfìhàn dàbí pé ó ṣòro láti ní òye? (ẹ wo Gẹnẹ́sísì 40:8; 41:16).
Ẹ jíròrò bí Olúwa ti nfi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn síi yín. Kínni ẹ̀ nṣe láti ṣe ìṣe lórí ìfihàn tí Ó ti fi fún yín? Báwo ni ẹ ṣe nwá àfikún ìtọ́nisọ́nà láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀?’
Jósẹ́fù nrọ́ àwọn àlá Agbọ́tí àti Alásè, láti ọwọ́ François Gérard
Gẹ́nẹ́sísì 39:1-20
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa, mo lè sá fún ìdánwò.
Bí Jósẹ́fù bá níláti fúnni ní ìmọ̀ràn lórí bí a ṣe lè kojú ìdánwò láti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀, kínni ẹ rò pé òun yíò wí? Ẹ ronú nípa èyí bí ẹ ti nkà nípa ìrírí rẹ̀ nínú Gẹ́nẹ́sísì 39. Fún àpẹrẹ, ẹ yẹ bí Jósẹ́fù ti lè fèsì sí àwọn àníyàn bíi ìwọ̀nyí wò:
-
Bí ẹnìkẹ́ni míràn bá mọ ohun tí èmi nṣe, kínni èrò nlá náà? (wo àwọn ẹsẹ 8–9).
-
Mo gbìyànjú láti kojú, ṣùgbọ́n kò dàbí ẹnipé ìdánwò náà fẹ́ dúró (wo ẹsẹ 10).
-
Kínni kí nṣe nígbàtí èmì bá wà nínú ipò níbití ìdánwò ti le? (wo ẹsẹ 12).
Báwo ni ẹ ó ti ṣàlàyé ìdí tí gbígbọ́ran sí òfin ìparaẹnimọ́ fi jẹ́ pàtàkì? (ẹ wo Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́: Atọ́nà kan fún Ṣíṣe àwọn Yíyàn, 23–28).
Bẹ́ẹ̀ni, àpẹrẹ Jósẹ́fù, lè wúlò sí àwọn irú ìdánwò míràn. Pẹ̀lú ìrírí Jósẹ́fù ní iyè-inú , ẹ yẹ ṣíṣe ètò kan fún yíyẹra àti kíkojú ìdánwò wò. Fún àpẹrẹ, ẹ lè ronú nípa ìdánwò kan kí ẹ sì kọ àwọn ipò láti yẹra fun sílẹ̀ àti bí ẹ ó ti “sá” nígbàtí ìdánwò bá dìde.
|
Ìdánwò | |
|
Àwọn ipò láti yẹra fún | |
|
Ṣètò láti fèsì |
Ní ìhín ni àwọn ìwé mímọ́ míràn tí ó lè sọ̀rọ̀ ètò yín. Kínni ẹ kọ́ látinú ọ̀kọ̀ọ̀kan nípa bí Olùgbàlà ti lè ràn yín lọ́wọ́ láti kojú ìdánwò? Máttéù 4:1–11; 1 Àwọn Kọ́ríntì 10:13; 1 Néfì 15:23–24; 3 Néfì 18:17–18.
Bí ẹ ti nṣe ètò yín, ó lè ràn yín lọ́wọ́ bákannáà láti ronú nípa àwọn àkokò ní àtẹ̀hìnwá nígbàtí ẹ fi yíyege yẹra tàbí kojú ìdánwò. Báwo ni Olùgbàlà ti ràn yín lọ́wọ́? (wo 2 Néfì 4:18–33).
Gẹ́nẹ́sísì 41:15–57
Olúwa yíò ràn mi lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ fún ànfààní àwọn ìnira tó ṣeéṣe.
Jósẹ́fù nípa rírọ́ àlá Fáráò darí sí àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n gidi àti ti àfojúrí fún yíyè ìyàn kan (wo Gẹnẹ́sísì 41:15–57). Ẹ yẹ irú àwọn ọ̀rọ̀ ti ẹ̀mí tí Olúwa lè ti fún yín nínú àkọsílẹ̀ yí wò. Báwo ni ẹ ṣe ní ìmọ̀lára pé Ó nfẹ́ kí ẹ múrasílẹ̀ fún àwọn ìnira ní ọjọ́ ọ̀la yín?
Bákannáà wo David A. Bednar, “A Yíò Dán Wọn Wò Ní Ìhín,” Làìhónà, Nov. 2020, 8–11.
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti Làìhónà àti àwọn ìwé-ìròhìn Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Gẹ́nẹ́sísì 37
Èmi lè ṣe rere sí ẹbí mi
-
Kíkà nípa àwọn ìmọ̀lára líle nínú ẹbí Jósẹ́fù lè mú ìbáraẹnisọ̀rọ̀ kan wáyé nípa bí a ṣe nílàti tọ́jú àwọn ọmọ ẹbí. Láti sọ ìtàn Jósẹ́fù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ láti inú Gẹ́nẹ́sísì 37, ẹ lè lo àwọn àwòrán nínú ìlànà yí tàbí nínú “Àwọn Àlá Oníìmísí ti Jósẹ́fù” (nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 47–51). Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín pín àwọn àlàyé tí wọ́n mọ̀ nípa ìtàn náà. Ẹ lè bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọdé láti rò pé wọ́n wà nínú ẹbí ti Jósẹ́fù. Kínni wọn ìbá ti sọ tàbí ṣe láti jẹ́ onílàjà kan nínú ẹbí náà? Fún àpẹrẹ, kínni ó túmọ̀ sí láti “sọ̀rọ̀ ní àlàáfíà” nínú ẹbí wa? (ẹsẹ 4). Báwo ni Jésù Krístì ti jẹ́ onílàjà nínú ẹbí Ọlọ́run?
2:17Joseph’s Inspired Dreams
Gẹ́nẹ́sísì 37:18–28; 39:20–23; 41:38
Ọlọ́run lè ràn mí lọ́wọ́ nígbàtí àwọn ohun búburú bá ṣẹlẹ̀.
-
Nígbàtí àwọn ọmọ yín bá dojúkọ àwọn àkokò ìnira, wọ́n nílò láti mọ̀ pé Olúwa yíò wà pẹ̀lú wọn, bí Òun ti wà pẹ̀lú Jósẹ́fù. Bóyá ẹ lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe ìtòsílẹ̀ kan nípa àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù (wo Gẹnẹ́sísì 37:23–28; 39:20; tàbí “Àwọn Àlá Oníìmísí ti Jósẹ́fù” àti “Jósẹ́fù ní Egypítì,” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 47–51, 52–56). Lẹ́hìn ìnira kọ̀ọ̀kan tí wọ́n rí, ẹ pe àwọn ọmọdé láti tún, “Olúwa wà pẹ̀lú Jósẹ́fù” (Gẹ́nẹ́sísì 39:2).
2:17Joseph’s Inspired Dreams
2:50Joseph in Egypt
-
Bóyá àwọn ọmọ yín lè ṣe ìwákiri Gẹ́nẹ́sísì 39:1–3, 20–23 fún gbogbo àpẹrẹ ti gbólóhùn ọ̀rọ̀ “Olúwa wà pẹ̀lú Jósẹ́fù” àti àwọn gbolóhùn ọ̀rọ irú kannáà. Ẹ jẹ́ kí wọ́n pín ohun tí wọ́n rò pé gbólóhùn ọ̀rọ̀ yí túmọ̀ sí. Ṣùgbọ́n nísisìyí, ìwọ ríi pé Olúwa wà pẹ̀lú wa? Ẹ sọ fún ara yín nípa bí ẹ ti ní ìmọ̀lára pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín ní ìgbà pípeni-níjà kan.
Jósẹ́fù ti Egypítì nínú Túbú, láti ọwọ́ Jeff Ward (àlàyé)
Gẹ́nẹ́sísì 39:7-12
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa, mo lè sá fún ìdánwò.
-
Ní ìhín ni kókó ẹ̀kọ́ tí ó lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti tẹ̀lé àpẹrẹ Jósẹ́fù ti sísá kúrò fún ìyàwó Pótífà: Ẹ lo àwọn òòfà yín láti rọ́pò Jésù Krístì àti Sátánì. Lo irin kékeré kan, bíi àpamọ́ bébà kan, láti rọ́pò wa. Nígbànáà ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín wò bí ipa òòfà kan lórí irin náà ti lágbára jù nígbàtí wọ́n bá yí nkan náà súnmọ́ ọ si. Báwo ni ìrírí Jósẹ́fù nínú Gẹ́nẹ́sísì 39:7–12 ṣe júwe òtítọ́ yí? Kínni a lè ṣe láti yí kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ kí a sì súnmọ́ Jésù? Fídíò náà “Ìdánwò Nṣá bí A ti Nwá Krístì nínú Gbogbo Èrò” (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere) àti orin kan bíiti “Mo Nílò Yín Ní Gbogbo Wákàtí” (Àwọn Orin, nọ́mbà 98) lè ṣèrànwọ́ pẹ̀lú isọ̀rọ̀ yí.
2:58Temptation Fades as We Seek Christ in Every Thought
Lo Orin “Àwọn orin àti àwọn orin ìyìn mímọ́ míràn lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ ti Ọlọ́run, ní ìmọ̀làra Ẹ̀mí, àti kíkọ́ àwọn o`títọ́ ìhìnrere. Àwọn orin aládùn, ìró, àti àwọn orin jẹ́jẹ́ lè ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti rántí àwọn òtítọ́ ìhìnrere fún àwọn ọdún tó nbọ̀. Bí ẹ ti nkọrin pẹ̀lú àwọn ọmọdé, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àwárí àti láti ní òye àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí a kọ́ni nínú àwọn orin” (Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà,32).
-
Ẹ ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ìdánwò tí wọ́n lè máa dojúkọ E jẹ́ kí wọ́n ṣe ojúṣe-eré bí wọ́n ti lè “sá” kúrò nínú àwọn ìdánwò wọ̀nyí.
Fún púpọ̀ síi, ẹ wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé-ìròhìn Fríẹ́ndì .