Oṣù Kẹrin 6–12. ‘Ẹ Rántí Ọjọ́ Yí, nínú Èyítí Ẹ Jáde Wá láti Égíptì’: Exodus 7–13,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
Oṣù Kẹrin 6–12. ‘Ẹ Rántí Ọjọ́ Yí, nínú Èyítí Ẹ Jáde Wá láti Égíptì,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Ìjúwe Mósè àti Áárọ́nì nínú ọgbà Fáráò, láti ọwọ́ Robert T. Barrett
Oṣù Kẹ́rin 6-12: “Ẹ Rántí Ọjọ́ Yí, nínú Èyítí Ẹ Jáde Wá láti Égíptì”
Ẹ́ksódù 7–13
Àjàkálẹ̀ àrùn lẹ́hìn àjàkálẹ̀ àrùn pọ́n Égíptì lójú, ṣùgbọ́n Fáráò kọ̀ láti dá àwọn Ísráẹ́lì sílẹ̀. Àti síbẹ̀ Ọlọ́run tẹ̀síwájú láti fi agbára Rẹ̀ hàn ó sì fún Fáráò ní àwọn ànfààní láti gbà “pé èmi ni Olúwa” àti pé “kò sí ẹlòmíràn bí èmi ní gbogbo ayé” (Ẹ́ksódù 7:5; 9:14). Ní báyìí, Mósè àti àwọn Ísráẹ́lì gbọ́dọ̀ ti wò àwọn ìfihàn wọ̀nyí pẹ̀lú ìyanu ní ti agbára Ọlọ́run ní ìtìlẹhìn wọn. Dájúdájú àwọn àmì títẹ̀síwájú wọ̀nyí fi ẹsẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọlọ́run múlẹ̀ ó sì fún níní ìfẹ́ wọn lókun láti tẹ̀lé wòlíì Ọlọ́run. Nígbànáà, lẹ́hìn tí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn mẹsan ti kùnà láti gba àwọn Ísráẹ́lì, àjàkálẹ̀ àrùn kẹwàá—ikú àwọn àkọ́bí, pẹ̀lú àkọ́bí Fáráò— ni ó parí ìgbèkùn náà nígbẹ̀hìn. Èyí dàbí ìbámu nítorí nínú gbogbo ọ̀ràn ìgbèkùn ti ẹ̀mí, ọ̀nà àbáyọ̀ kanṣoṣo ni ó wà lódodo. Ó jẹ́ ẹbọ ọrẹ Jésù Krístì, ti Àkọ́bí—ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn aláìní-èérí—ni yíò gbà wá là.
Àwọn èrò fún Kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti nínú Ìjọ
Ẹ́ksódù 7– 11
Mo lè yàn láti mú ọkàn mi rọ̀.
Pẹ̀lú ìrètí, ìfẹ́ yín kò tako ìfẹ́ Ọlọ́run láéláé bí ti Fáráò ti ṣe. Síbẹ̀, a ní àwọn àkokò nígbàtí ọkàn wa kò rọ̀ bí ó ti yẹ kí wọ́n jẹ́. Kínni ó dúró dá yàtọ̀ sí yín nípa àwọn èsì Fáráò sí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn nínú Ẹ́ksódù 7:14–25; 8:5–32; 9:1–26; 10:12–29; 12:29–33? Ẹ kíyèsí àsọyé nínú Ìyírọ̀padà Jósẹ́fù Smith ti Ẹ́ksódù 7:3, 13; 9:12.
Kínni ìdí tí “le” fí jẹ́ ìjúwe rere ti ọkàn Fáráò? Ẹ gbèrò ohun tí ẹ kọ́ láti inú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí nípa níní ọkàn rírọ̀: 1 Néfì 2:16; Mòsíàh 3:19; Álmà 24:7–8; 62:41; Étérì 12:27. Bí ẹ ti nkà nípa àwọn àyọrísí ti ọkàn líle Fáráò, ẹ jíròrò ipò ti ọkàn yín. Kínni àwọn ìyípadà tí ẹ ní ìmọ̀lára ìmísí láti ṣe?
Eksódù 12:1–42
Jésù Krístì lè gbà mí là nítorí Ètùtù Rẹ̀.
Ọ̀nà kanṣoṣo fún àwọn Ísráẹ́lì láti jẹ́ dídásílẹ̀ kúrò nínú àjàkálẹ̀ àrùn kẹwàá, tí a ṣe àpèjúwe nínú Ẹ́ksódù 11:4–5, ni láti tẹ̀lé àwọn ìkọ́ni tí Olúwa fún Mósè nínú Ẹ́ksódù 12, ọ̀nà ẹ̀sìn kan tí a mọ̀ sí Ìrékọjá. Ìrékọjá kọ́ wa nípasẹ̀ àwọn àmì pé gẹ́gẹ́bí Olúwa ṣe gba àwọn Ísráẹ́lì sílẹ̀ láti inú ìgbèkùn ní Égíptì, Òun bákannáà lè gbà wá sílẹ̀ kúrò nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀. Láti ṣe ìwákiri àmì yí nínú Ẹ́ksódù 12:1–42, ẹ lè lo àwòrán bí èyí yíì:
|
Àmì |
Àwọn ìtumọ̀ tó ṣeéṣe |
Ọrọ̀ Ọlọ́run sí mi |
|---|---|---|
Àmì Ìbẹ̀rẹ̀ àwọn oṣù náà (ẹsẹ 2; Olúwa pàṣẹ fún àwọn Ísráẹ́lì láti lo ìṣẹ̀lẹ̀ yí láti fi àmì sí ìbẹ̀rẹ̀ kàlẹ́ndà wọn). | Àwọn ìtumọ̀ tó ṣeéṣe Èyí níláti jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ titun fún Ísráẹ́lì. Wọ́n níláti di “àtúnbí.” | |
Àmì Ọ̀dọ́-àgùtàn náà (àwọn ẹsẹ 3–5). | Àwọn ìtumọ̀ tó ṣeéṣe Wo Jòhánnù 1:29; 6:54; 1 Pétérù 1:19. | |
Àmì Ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùtàn ní ẹnu-ọ̀nà (àwọn ẹsẹ 7, 13, 23). | Àwọn ìtumọ̀ tó ṣeéṣe Wo Mòsíàh 4:2; Ìfihàn 12:11. | |
Àmì Àkàrà aláìwú (àwọn ẹsẹ 8, 15, 19–20). | Àwọn ìtumọ̀ tó ṣeéṣe Wíwú, tàbí ìwúkàrà, lè jẹ́ àmì ìdibàjẹ́ kan nítorí ó nbajẹ̀ pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Wo Máttéù 16:6–12; Jòhánnù 6:35. | |
Àmì Àgbo kíkorò (ẹsẹ 8). | Àwọn ìtumọ̀ tó ṣeéṣe Ìrántí ìkorò ẹ̀ṣẹ̀ àti ìgbèkùn Wo Ẹksódù 1:14; Mósè 6:55. | |
Àmì Yíyára jẹun, wíwọṣọ láti kúró (ẹsẹ 11). | Àwọn ìtumọ̀ tó ṣeéṣe Àmì kíákíá kan láti fi ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀. Wo Gẹ́nẹ́sísì 39:12; 2 Tímótéù 2:22. | |
Àmì Apanirun náà (àwọn ẹsẹ 13, 23). | Àwọn ìtumọ̀ tó ṣeéṣe | |
Àmì Àwọn Ísráẹ́lì ni a dásílẹ̀ (àwọn ẹsẹ 29–32). | Àwọn ìtumọ̀ tó ṣeéṣe | |
Kínni ohun míràn tí ẹ rí nínú àwọn ìkọ́ni àti àmì ti Ìrékọjá tí ó nrán yín létí nípa Jésù Krístì àti Èyùyù Rẹ̀? Kínnì àmì wọ̀nyí dá àbá sí yín nípa bí a ó ṣe gbà àwọn ìbùkún ti Ètùtù Rẹ̀?
Wá sọ́dọ̀ Krístì nípa yíyẹ àwọn àmì náà tí ó jẹ́ ẹ̀rí nípa Rẹ̀ wò. “Gbogbo ohun,” Olúwa Kéde, “ní a dá tí a sì ṣe láti jẹ́rìí nípa mi” (Mósè 6:63; bákannáà wo 2 Néfì 11:4). Nínú Ẹ́ksódù 12, àwọn àmì bí ọ̀dọ́-àgùtàn, ẹ̀jẹ̀, àkàrà àìlèwú, iṣẹ́ ìyanu, àti ìdándè gbogbo nawọ́ sí Krístì. “Nígbàtí a bá ti ní òye bí àwọn nkan wọ̀nyí ṣe bá Olùgbàlà mu, wọ́n lè kọ́ wa nípa ìhùwàsí àti Agbára Rẹ̀” (Ìkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà,7).
Ní Ìrántí Mi, láti ọwọ́ Walter Rane
Ẹ́ksódù 12:14–17, 24–27; 13:1–16
Oúnjẹ Olúwa nran mi létí bí ìdándè mi nípasẹ̀ Jésù Krístì.
Olùgbàlà pàṣẹ fún àwọn Ísráẹ́lì láti ṣe àkíyèsí Ìrékọjá ní ọdọọdún láti ran wọ́n lọ́wọ́ láti rántí pé Òun ti gbà wọ́n sílẹ̀, àní lẹ́hìn tí ìgbèkùn wọn ti di ìrántí jíjìn. Bí ẹ ti nka àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ nínú Ẹ́ksódù 12:14–17, 24–27; 13:1–16, ẹ ronú nípa ohun tí ẹ̀ nṣe láti rántí àwọn ìbùkún Ọlọ́run fún yín. Báwo ni ẹ ṣe lè pa ìrántí náà mọ́ “jákèjádò àwọn ìran yín”? (Wo Ẹ́ksódù12:14, 26–27).
Kínni àwọn ohun irúkannáà tí ẹ rí ní àárín àpèjẹ ti Ìrékọjá àti oúnjẹ Olúwa? Kínni ẹ lè ṣe láti “rántí Jésù Krístì” nígbàgbogbo? (Mórónì 4:3; 5:2).
Ẹ lè jíròrò àwọn ohun míràn tí Olúwa nfẹ́ kí ẹ ṣe láti rántí Rẹ̀ bákannáà; fún àpẹrẹ, wo, Hẹ́lámánì 5:6–12; Mórónì 10:3; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 3:3–5, 10; 18:10; 52:40.
Bákannáà wo Kevin W. Pearson, “Ṣé Ẹ Ṣì Ní Ìfẹ́?,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2022, 67–69; “Rántí Rẹ̀ Nígbàgbogbo” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere; “Ní Irántí Ẹnití a kàn-mọ́-àgbélèbú,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 190.
Always Remember Him
Fún púpọ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé
Ẹ́ksódù 7– 11
Olúwa ní agbára lórí ohun gbogbo.
-
Àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tí a ṣe àpèjúwe nínú Ẹ́ksódù 7–11 fihàn àwọn ará Égíptì àti àwọn Ísráẹ́lì pé Olúwa ní agbára nlá. Olúwa yíò ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbésí ayé wọn nígbàtí wọ́n bá ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Rẹ̀. Láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kọ́ ẹ̀kọ́ láti inú ìtàn yí, ẹ lè fún ọmọ kọ̀ọ̀kan ní bébà tí a pín sí ipín mẹwàá, kí ẹ sì pè wọ́n láti ya àwòrán àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tí a ṣe àpèjúwe nínú àwọn ẹsẹ: Ẹ́ksódù 7:17–18; 8:1–4; 8:16–17; 8:20–22; 9:1–6; 9:8–9; 9:22–23; 10:4–5; 10:21–22; 11:4–7 (bákannáà wo “Àwọn Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Égíptì” nínú Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 67–69). Ẹ ka Ẹ́ksódù 7:5 àti 9:14 papọ̀ láti ṣe àlàyé ìdí tí Olúwa fi rán àwọn àjàkálẹ̀ àrùn.
2:3The Plagues of Egypt
-
Ẹ pín pẹ̀lú àwọn ọmọ yín bí Olúwa ṣe ti fihàn yín “pé kò sí ẹlòmíràn bíi [Tirẹ̀] ní gbogbo ayé” (Ẹ́ksódù 9:14). Ẹ jẹ́ kí wọ́n pín bí wọ́n ṣe mọ̀ pé Olúwa jẹ́ alágbára.
Ẹ́ksódù 8:28–32; 9:7
Olúwa lè ràn mí lọ́wọ́ láti ní ọkàn rírọ́.
-
Láti ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti wo ohun tí ó túmọ̀sí láti ní ọkàn rírọ̀, ó lè jẹ́ ìgbádùn láti fi nkan tí ó jẹ́ líle hàn wọ́n, bíi òkúta kan, àti òmíràn tí ó rọ̀ àti tí ó lè fa omi mu, bíi kàìnkàìn. Ẹ lè da omi sórí àwọn nkan wọ̀nyí láti ṣe àpèjúwe bí ó ti rọrùn tó fún ọkàn rírọ̀ láti gba ọ̀rọ̀ Olúwa. Nígbànnáà ẹ lè ka àwọn ẹsẹ díẹ̀ papọ̀ tí ó nṣe àpèjúwe bí Fáráò ṣe fèsì sí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tí Olúwa rán (wo Ẹ́ksódù 8:28–32; 9:7). Èwo lára àwọn nkan náà ni ó rọ́pò ọkàn tàbí ìhùwàsí Fáráò jùlọ? Kínni ó túmọ̀sí láti ní ọkàn rírọ̀? (wo Mòsíàh 3:19).
-
Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè ṣe ìtòsílẹ̀ àwọn ìṣe kan tí ó lè hàn nígbàtí a bá ní ọkàn líle (fún àpẹrẹ, lílo àwọn ọ̀rọ̀ àìdára tàbí jíjẹ́ àìní-ìfẹ́ láti pín nkan). Báwo ni a ṣe lè fihan Olúwa pé a fẹ́ láti ní ọkàn rírọ̀?
Ẹ́ksódù 12:1–13
Oúnjẹ Olúwa lè ràn mí lọ́wọ́ láti rántí Jésù.
-
Ìrékọjá kọ́ àwọn Ísráẹ́lì láti wo iwájú sí Olùgbàlà àti ẹbọ ọrẹ Rẹ̀ fún wa. Bí ẹ ti nṣe ìwákiri Ẹ́ksódù 12:1–13 papọ̀, ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti rí ìsopọ̀ ní àárín àlàyé kíníkíní ti Ìrékọjá àti Ètùtù Jésù Krístì (bákannáà ẹ wo “Ìrékọjá Náà” nínu Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 70–74). Fún àpẹrẹ, báwo ni Jésù ṣe dàbí ọ̀dọ́-àgùtàn tí a ṣe àpèjúwe nínú ẹsẹ 5?
2:54The Passover
-
Ní òní, a njẹ oúnjẹ Olúwa láti rántí ẹbọ ọrẹ ti Jésù. Ẹ lè fi àwòrán oúnjẹ Olúwa han àwọn ọmọ yín kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa bí ìlànà yí ṣe nràn wá lọ́wọ́ láti rántí Jésù Krístì. Ẹ lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti rí ọ̀rọ̀ náà “rántí” nínú àdúrà oúnjẹ Olúwa (wo Mórónì 4–5). Tàbí kọ orin isìn mímọ̀ kan papọ̀ nípa oúnjẹ Olúwa, kí ẹ sì ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe àkíyèsí ìmọ̀lára àlàáfíà tí wọ́n ní nígbàtí wọ́n bá ronú nípa Olùgbàlà. Báwo ni a ṣe lè wá ìmọ̀lára náà nígbàtí a bá njẹ oúnjẹ Olúwa?
Fún púpọ̀ síi, ẹ wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .