Oṣù Kẹrin 13–19. ‘Ẹ Dúró Jẹ́ẹ́, Kí Ẹ Sì Rí Ìgbàlà Olúwa’: Ẹ́ksódù 14–18,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
Oṣù Kẹrin 13–19. “Ẹ Dúró Jẹ́ẹ́, Kí Ẹ Sì Rí Ìgbàlà Olúwa,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Oṣù Kẹrin 13-19: “Ẹ Dúró Jẹ́ẹ́, Kí Ẹ Sì Rí Ìgbàlà Olúwa”
Ẹ́ksódù 14– 18
Àwọn ọmọ Ísráẹ́lì jẹ́ dídẹ̀kùn fún. Òkun Pupa wà ní ẹ̀gbẹ́ kan, ogun Fáráò sì nbọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ míràn. Sísálọ wọn kúrò ní Égíptì, ó dàbí pé, kò ní pẹ́ títí. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ní ọ̀rọ̀ kan fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì tí Ó fẹ́ kí wọ́n rántí fún ìrandíran: “Ẹ máṣe bẹ̀rù. … Olúwa yíò jà fún yín” (Ẹ́ksódù 14:13–14).
Láti ìgbà náà lọ, nígbàtí àwọn ènìyàn Ọlọ́run bá ti nílò ìgbàgbọ́ àti ìgboyà, ni wọ́n ti máa nsọ ìtàn yí. Nígbàtí Néfì nfẹ́ láti mísí àwọn arákùnrin rẹ̀, ó wípé, “Ẹ jẹ́ kí a ní agbára bíiti Mósè; nítorí ó sọ̀rọ̀ nítòótọ́ sí omi Òkun Pupa wọ́n sì pínyà sí ìhín àti sí ọ̀hún, àwọn baba wa sì kọjá wá, jáde kúrò nínú ìgbèkùn, lórí ìyàngbẹ́ ilẹ̀” (1 Néfì 4:2). Nígbàtí Ọba Límhì nfẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a mú ní ìgbèkùn láti “gbé orí [wọn] sókè, kí wọ́n sì yọ̀,” ó rán wọn létí ìtàn kannáà (Mòsíàh 7:19). Bẹ́ẹ̀ náà ni Álmà ṣe, nígbàtí ó nfẹ́ láti jẹ́ ẹ̀rí sí ọmọ rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run (ẹ wo Álmà 36:28). Nígbàtí a bá sì ní ìmọ̀lára pé a wà ní ìdẹ̀kùn—nígbàtí a nílò ìgbàgbọ́ díẹ̀ síi láti “rí ìgbàlà Olúwa”—a lè rántí bí “Olúwa ṣe gba Isráẹ́lì là ní ọjọ́ náà” (Ẹ́ksódù 14:13, 30).
Àwọn èrò fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti Ìjọ
Ẹ́ksódù 14; Ẹ́ksódù 15:1–21
Olúwa lè ṣe “iṣẹ́ nlá” nínú ayé mi.
Bí ẹ ti nka Ẹ́ksódù 14:1–10, ro bí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ṣe lè ti ní ìmọ̀ara bí wọ́n ṣe ri tí àwọn ọmọ ogun Fáráò nsún mọ́ wọn. Bóyá ẹ ní ìmọ̀ pé ẹ nílò iṣẹ́ ìyanu kan láti yè nínú ìpènijà líle tí ẹ̀ nkojú. Kínni ẹ rí nínú Ẹ́ksódù 14:13–31 tí ó mísí yín láti wá agbára Ọlọ́run nínú ayé yín? Ẹ jíròrò bí ẹ ti rí agbára Rẹ̀ ní àtẹ̀hìnwá. Kínni ẹ ti kọ́ nípa Rẹ̀ láti inú àwọn ìrírí wọ̀nyí?
Ẹ́ksódù 15:1–19 ni orin ìyìn tí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì kọ lẹ́hìn tí Olúwa pín Òkun Pupa níyà. Àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ wo nínú orin yí ní ẹ rí tí ó nítumọ̀ nípàtàkì? Bóyá orin ìsìn kan wà tí ẹ nní ìmọ̀ara kíkọ nígbàtí Olúwa bá ṣe ohun kan tí ó níyanu fún yín, bíi irú “Olùràpadà Isráẹ́lì” (Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 6). Ẹ gbèrò kíkọ tàbí fífetísílẹ̀ sí i ní apákan ìjọsìn yín ní òní.
Bákannáà ẹ wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 8:2–3.
Ẹ́ksódù 15:22–27; 16:1–15; 17:1–7
Olúwa lè mú àwọn ohun kíkorò dùn.
Kíkà nípa ìrìnàjò Isráẹ́lì lè darí yín sí ìronú nípa àwọn ohun inú ayé yín tí ó dàbí ẹnipé ó “korò” bíiti àwọn omi Márà (wo Ẹ́ksódù 15:23–27). Báwo ni Olúwa ṣe nmú àwọn ohun ìkorò inú ayé yín dùn? Kíní iyì tí àwọn ìrírí wọ̀nyí ní nínú ayé yín?
Ẹ yíò kíyèsí àwọn àpẹrẹ púpọ̀ ti àwọn ìrírí kíkorò síi fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì nínú Ẹ́ksódù 16 àti17. Ó jẹ́ gbígba ìdánwò kí kíkùn àti ìkùnsínú wọn kọnilóminú, ṣùgbọ́n bí ẹ ti nkà á, ẹ yẹ bóyá ẹ ti ṣe ohun kannáà rí wò. Kínni ẹ kọ́ láti inú àwọn ìrírí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì tí ó lè ràn yín lọ́wọ́ láti dínkù ní ìkùnsínú àti láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run síi? Kínni àwọn ẹsẹ wọ̀nyí kọ́ yín nípa Ọlọ́run?
Bákannáà wo 1 Néfì 2:11–12.
Àwọn ọmọ Ísráẹ́lì nkó mánnà jọ. Neo-gothic fresco, Trnava (àlàyé)
Ẹ́ksódù 1–16
Olúwa fun mi ní ìṣìkẹ́ ti ẹ̀mí ní ojojúmọ́.
Nígbà tí ó jẹ́ pé gbogbo wa nílò láti jẹun, Olúwa nṣe àfiwé àwọn ohun ti ẹ̀mí sí oúnjẹ nígbàkugbà. Ẹ wá àwọn ẹ̀kọ́ ti ẹ̀mí Rẹ̀ nínú ìrírí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì pẹ̀lú mánnà nínú Ẹ́ksódù 16. Fún àpẹrẹ, Kínni ẹ rí nínú àwọn ìkọ́ni Olúwa nínú Ẹ́ksódù 16:16, 19, 22–26 tí ó wúlò sí ìṣìkẹ́ ti ẹ̀mí yín?
Láti ṣe àwárí àwọn ẹ̀kọ́ míràn tí Olúwa fẹ́ kí a kọ́ láti inú iṣẹ́ ìyanu yí, ẹ jíròrò àwọn ìbèèrè bí ìwọ̀nyí:
-
Kínni Olúwa fún mi tí ó dàbí mánnà ojojúmọ́ tí Ó fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì?
-
Kínni mo lè ṣe tí ó lè dabí kíkó mánná jọ?
Ẹ lè rí àfikún àwọn ìwòye nínú ọ̀kan tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn fídíò wọ̀nyí: “Búrẹ́dì Ojojúmọ́: Àwòṣe,” “Búrẹ́dì Ojojúmọ́: Ìrírí,” àti “Búrẹ́dì Ojojúmọ́: ìyípadà” (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere).
Daily Bread: Pattern
Daily Bread: Experience
Daily Bread: Change
Ẹ ronú nípa àwọn ohun míràn, yàtọ̀ sí jíjẹun, tí ẹ̀ nṣe ní ojojúmọ́. Kínni ìdí tí a fi níláti ṣe àwọn nkan ní ojojúmọ́ láti lè múnádóko? Kínni ohun tí ẹ ní ìmísí láti ṣe láti wá àwọn ìrírí ti ẹ̀mí ojojúmọ́?
Bákannáà wo Dieter F. Uchtdorf, “Ìmúpadàbọ̀sípò Ojojúmọ́,” Làìhónà, Nov. 2021, 77–79; “Ìmúpadàsípò Ojojúmọ́” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Daily Restoration
Ẹ́ksódù 17:1–7
Jésù Krístì ni àpáta àti omi ìyè ti ẹ̀mí mi.
Ẹ ronú nípa Olùgbàlà bí ẹ ti nka Ẹ́ksódù 17:1–7. Báwo ni Jésù Krístì ṣe dàbí àpáta kan síi yín? (wo Orin Dáfídì 62:6–7; Hẹ́lámánì 5:12). Báwo ni Ó ṣe dàbí omi? (wo Jòhánnù 4:10–14; 1 Kọ́ríntì 10:1–4; 1 Néfì 11:25).
Ẹ wá àwọn ohun ti ara láti jẹ́ ẹ̀rí nípa Krístì. Ìgbàkugbà tí àwọn ìwé mímọ́ bá júwe àwọn ohun tí ó lè jẹ́ àmì ti Jésù Krístì Ẹ́ksódù 17:1–7 ṣé, ó lè jẹ́ ànfààní fún ohun ẹ̀kọ́ kan. Wíwo tàbí fífọwọ́kan àpáta tàbí omi lè mu rọrùn láti ní òye bì àwọn ohun wọ̀nyí ṣe dàbí Jésù Krístì. Bí ẹ bá fi ọgbọ́n púpọ̀ sí inú ìkọ́ni, yíò jẹ́ onírántí àti onípa.
Ẹ́ksódù 17:8–16; 18:13–26
Àwọn ọmọẹ̀hìn nṣèrànwọ́ fún arawọn láti “gbé ẹrù” ti ṣíṣe iṣẹ́ Olúwa.
Ìgbà míràn lè wà nínú ayé yín nígbàtí ẹ le ní ìjọmọ́ Mósè—nígbàtí àwọn míràn ngbárálé yín, ṣùgbọ́n ọwọ́ “yín [dàbí] ó wúwo” (Ẹ́ksódù 17:12). Ìgbà míràn, ẹ lè dàbí Ááròni, Húrì, àti Jẹ́trò síi, tí ó ti Mósè lẹ́hìn. Ẹ fi ara yín sí ipò ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn ènìyàn wọ̀nyí bí ẹ ti nka Ẹ́ksódù 17:8–16; 18:13–26, kí ẹ sì rí ohun tí Olúwa nkọ́ yín nípa iṣẹ́ Rẹ̀.
Bákannáà wo Mòsíàh 4:27; 18:8–9.
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé-ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun Ọ̀dọ́ .
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Ẹ́ksódù 14:5–22
Olúwa lè ṣe “iṣẹ́ nlá” nínú ayé mi.
-
Nígbàtí Olúwa pínyà Òkun Pupa, Mósè àti àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ri bí Ó ti lágbára tó. Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín ràn yín lọ́wọ́ láti ronú nípa ọ̀nà láti tún ìtàn náà ṣe láti inú Ẹ́ksódù 14:5–22 (bákannáà wo “Ìrékọjá” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 70–74). Bóyá ẹ lè gbé àwọn àga tàbí ìbora kalẹ̀ kí ẹ sì “pín” wọn bíiti Òkun Pupa. Nígbànáà ẹ lè pín bí ẹ ó ti rí agbára Ọlọ́run nínú ayé yín pẹ̀lú ara yín.
2:54The Passover
-
Kínni Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 8:2–3 fikún òye yín nípa ìtàn náà nínu Ẹ́ksódù 14? Ẹ yẹ sísọ fún àwọn ọmọ yín nípa ìrírí kan nígbàtí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ ohunkan fún yín nínú ọkàn yín wò, kí ẹ sì pè wọ́n láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìrírí wọn. Bákannáà ẹ lè kọ orin nípa Ẹ̀mí Mímọ́, bí irú “Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣe Atọ́nà” (Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 143).
Ẹ́ksódù 15:22 -25
Olúwa lè mú àwọn ohun kíkorò dùn.
-
Bóyá ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè mu ohunkan dídùn àti ohunkan kíkorò nígbàtí à bá nṣe àṣàrò Ẹ́ksódù 15:22–25 papọ̀. Báwo ni Olúwa ṣe mú àwọn ìrírí “ìkorò” inú ayé yín dùn?
Ẹ́ksódù 15:23–25; 16:14–15; 17:1–6
Jésù ni Omi Ìyè mi, Búrẹ́dì Ìyè mi, àti Àpàta mi.
-
Bí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín ka Ẹ́ksódù 15:23–25; 16:14–15; 17:1–6, ẹ jẹ́ kí wọn ṣèrànwọ́ fún yín láti wá àwọn ohun láti ṣèrànwọ́ láti sọ ìtàn kọ̀ọ̀kan—bíiti ẹ̀ka kan (láti wo omi Márà sàn), ago tàbí ìkòkò kan (láti kún fún mánnà), àti àpáta (fún omi Hórébù). Kínni àwọn ìtàn wọ̀nyí rán wá létí nípa ohun tí Jésù Krístì ṣe fún wa? Bí ara ìbárasọ̀rọ̀ yín, ẹ lè ka Matteu 7:24–27; Jòhánnù 4:10–14; 6:29–35, 48–51; Hẹ́lámánì 5:12; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 20:77, 79.
Ọ̀kan Ṣíwájú Ọlọ́run, láti ọwọ́ Joseph Brickey (detail)
Ẹ́ksódù 17:8–16; 18:13–26
Mo lè ṣèrànwọ́ láti “gbé ẹrù” ti ṣíṣe iṣẹ́ Olúwa.
-
Bí ẹ ti nka Ẹ́ksódù 17:8–16, ẹ lè pe ọmọ kan láti di ọwọ́ wọn mú sí òkè ní afẹ́fẹ́. Nígbàti ó bá rẹ ọmọ, àwọn ọmọ míràn lè ṣèrànwọ́, ní ọ̀nà tí Ááróni àti Húrì ṣe ran Mósè lọ́wọ́. Kínni ìtàn yí kọ́ni nípa bí a ṣe lè ran ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyege? Bákanáà ẹ lè ka Ẹ́ksódù 18:13–26 kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ojúṣe wíwúwo ti àwọn ènìyàn tí wọ́n nsìn nínú wọ́ọ̀dù yín. Kínni a lè ṣe ní òní láti ran àwọn olùdarí wa lọ́wọ́, gẹ́gẹ́bí Áárónì àti Húrì ṣe ran wòlíì Mósè lọ́wọ́?
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹjáde oṣù yí ti ìwé-ìròhìn Fríẹ́ndì .