Come, Follow Me
Àwọn Èrò láti mú Ẹ̀kọ́ Kíkọ́ Gbèrú nínú Ilé àti nínú Ìjọ


“Àwọn Èrò láti mú Ẹ̀kọ́ Kíkọ́ Gbèrú nínú Ilé àti nínú Ìjọ,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

ẹbí nṣe àṣàrò papọ̀

Àwọn Èrò láti mú Ẹ̀kọ́ Kíkọ́ Gbèrú nínú Ilé àti nínú Ìjọ

Bí ẹ ti nṣe àṣàrò ìhìnrere Olùgbàlà ní ilé àti ní ìjọ, ẹ yẹ àwọn ìbèèrè ìwọ̀nyí wò:

  • Báwo ni ẹ ṣe lè pe Ẹ̀mí sínú àṣàrò yín?

  • Báwo ni ẹ ṣe lè fojúsún sára Olùgbàlà nínú àṣàrò yín?

  • Báwo ni ẹ ṣe lè ní ànfààní àwọn àkókò ẹ̀kọ́ kíkọ́ ojojúmọ́?

  • Báwo ni ẹ ṣe lè gba ẹbí àti àwọn ọmọ kíláàsì níyànjú láti ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ ní ààyè ara wọn kí wọ́n sì pín ohun tí wọ́n nkọ́?

Ní ìhín ni àwọn ọ̀nà tó rọrùn làti mú àṣàrò yín nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbòòrò.

Gbàdúrà fún ìmísí.

Àwọn ìwé mímọ́ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nítorínáà ẹ bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ láti ní òye wọn.

Ẹ wá àwọn òtítọ́ nípa Jésù Krístì

Ohun gbogbo jẹ́ ẹ̀rí nípa Krístì (wo 2 Néfì 11:4; Mósè 6:63), nítorínáà ẹ gbèrò ṣíṣe àkíyèsí tàbí sàmì sí àwọn ẹsẹ tí ó jẹ́ ẹ̀rí nípa Olùgbàlà, ẹ mú ìfẹ́ yín fún Un jinlẹ̀, kí ẹ sì kọ́ni bí ẹ ó ti tẹ̀lé E. Nígbà míràn àwọn òtítọ́ nípa Olùgbàlà àti ìhìnrere Rẹ̀ ni a sọ tààrà, àti pé nígbà míràn wọ́n jẹ́ mímọ̀ nípasẹ̀ àpẹrẹ tàbí ìtàn. Ẹ bèèrè lọ́wọ́ ara yín, “Àwọn òtítọ́ ayérayé wo ni a kọ́ nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí? Kínni àwọn òtítọ́ wọ̀nyí kọ́ mi nípa Olùgbàlà?”

Ẹ fétísílẹ̀ sí Ẹ̀mí

Ẹ fiyèsí àwọn èrò àti àwọn ìmọ̀lára yín, pàápàá tí wọ́n bá dàbí ẹnipé kò bá ohun tí ẹ nkà mu. Àwọn ìtẹ̀mọ́ra wọ̀nyí lè jẹ́ àwọn ohun tí Baba yín Ọ̀run fẹ́ kí ẹ kọ́.

Ẹ ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìtẹ̀mọ́ra yín

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà ló wà láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìtẹ̀mọ́ra tó wá bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò. Fún àpẹrẹ, ẹ lè ri pé àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn-ọ̀rọ̀ kan pàtó nínú àwọn ìwé mímọ́ tẹ̀ mọ́ ọkàn yín; ẹ lè sàmì sí wọn kí ẹ sì ṣe àkọsílẹ̀ àwọn èrò yín bí àkọsílẹ̀-ránpẹ́ nínú àwọn ìwé mímọ́ yín. Bákannáà ẹ lè tọ́jú ìwé-àkọọ́lẹ̀ àwọn ìwòye, àwọn ìmọ̀lára, àti àwọn ìtẹ̀mọ́ra tí ẹ gbà.

ọ̀dọ́mọbìnrin nṣe àṣàrò

Ẹ pín ohun tí ẹ̀ nkọ́ pẹ̀lú àwọn míràn

Sísọ̀rọ̀ àwọn ìwòye láti inú àṣàrò araẹni yín jẹ́ ọ̀nà tí ó dára láti kọ́ àwọn míràn, àti bákannáà láti ṣèrànwọ́ láti fún òye yín lókun nípa ohun tí ẹ ti kà. Ẹ pín ohun tí ẹ̀ nkọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́bí àti ọ̀rẹ́ (ní ojúkojú tàbi ní orí ẹ̀rọ), kí ẹ sì pè wọ́n láti ṣe bákannáà.

Ẹ fi àwọn ìwé-mímọ́ ṣe àkàwé ìgbésí ayé yín

Ẹ ṣe àyẹ̀wò bí àwọn ìtàn àti ìkọ́ni tí ẹ nkà ṣe wúlò sí ìgbésí ayé yín. Fún àpẹrẹ, ẹ lè bèèrè lọ́wọ́ ara yín pé, “Àwọn ìrírí wo ni mo ti ní tí ó jẹ́ irúkannáà sí ohun tí mò nkà?”

Ẹ bèèrè àwọn ìbèèrè bí ẹ ti nṣe àṣàrò

Bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́, àwọn ìbéèrè lè wá sí ọkàn. Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí lè bá ohun tí ẹ̀ nka tàbí ìgbésí ayé yín mu ní àpapọ̀. Ẹ jíròrò àwọn ìbèèrè wọ̀nyí, kí ẹ sì wá ìdáhùn bí ẹ ti ntẹ̀síwájú nínú àṣàrò ìwé-mímọ́.

ọ̀dọ́mọkùnrin nṣe àṣàrò

Ẹ lo àwọn ìrànlọ́wọ́ àṣàrò ìwé-mímọ

Láti jèrè àlékún àwọn ìwòye sínú àwọn ẹsẹ tí ẹ kà, ẹ lo àwọn àkọsílẹ̀-ránpẹ́ ìsàlẹ̀, Àkòrí Atọ́nà, ìtumọ̀ Bíbélì, Atọ́nà sí Àwọn Ìwé-Mímọ́, àti àwọn ìrànlọ́wọ́ àṣàrò míràn.

Ẹ yẹ ọ̀rọ̀ kíkà ti inú àwọn ìwé-mímọ́ wò

Ẹ lè wá àwọn ìwòye tí ó nítumọ̀ nípa ẹsẹ ìwé-mímọ́ kan bí ẹ bá yẹ ọ̀rọ̀ kíkà rẹ̀ wo, pẹ̀lú awọn ipò tàbí ìgbékalẹ̀ tí ó ti wá. Fún àpẹrẹ, mímọ̀ ìpìlẹṣẹ̀ àti ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn náà tí Ọlọ́run bá sọ̀rọ̀ lè ṣèrànwọ́ fún yín láti ní òye ìdí àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ.

Ẹ ṣe àṣàrò àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì àti àwọn àpóstélì ọjọ́-ìkẹhìn.

Ẹ ka ohun tí àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì ọjọ-ìkẹhìn ti kọ́ni nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí ẹ rí nínú àwọn ìwé-mímọ́.

ìyá àti ọmọkùnrin nṣe àṣàrò papọ̀

Ẹ gbé nípa ohun tí ẹ kọ́

Àṣàrò ìwé mímọ kò níláti mí sí wa nìkan ṣùgbọ́n bákannáà ó nílati darí wa láti yí bí a ṣe ngbé ìgbésí-ayé wa padà. Ẹ fetísílẹ̀ sí ohun tí Ẹ̀mi nṣí yín létí láti ṣe bí ẹ ṣe nkàá, àti lẹ́hìnnáà kí ẹ ṣe ìṣe lórí àwọn ìṣílétí wọ̀nyí.

Ẹ lo orin

Àbá àwọn orin ìyìn àti orin àwọn ọmọdé ni a rí ní gbogbo Wá, Tẹ̀lé Mi. Ẹ lo orin mímọ́ láti pe Ẹ́mí kí ẹ sì mú ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí yín jinlẹ̀ nípa áwọn òtítọ́ ìhìnrere.

ẹbí nkọrin papọ̀

Kọ́ àwọn ìwé mímọ́ sórí

Ẹ yan ẹsẹ ìwé mímọ́ kan tí ó ní ìtumọ̀ sí yín, ẹbí yín, tàbí kíláàsì yín, kí ẹ sì kọ sórí nípa títunsọ lojojúmọ́ tàbí nípa ṣíṣe eré ìdárayà àkọ́sórí kan.

Ẹ pín àwọn ẹ̀kọ́ tó ní nkan èlò

Ẹ wá àwọn nkan èlò tó bá àwọn orí-ìwé àti ẹsẹ tí ẹ nkà mu. Ẹ ṣe àgbéyẹ̀wò bí ohun èlò kọ̀ọ̀kan ṣe bá àwọn ìkọ́ni mu nínú àwọn ìwé mímọ́.

Fi ọwọ́ yà, wá rí, tàbí ya àwòrán kan

Ẹ ka àwọn ẹsẹ díẹ̀, lẹ́hìnnáà kí ẹ ya ohun kan tí ó bá ohun tí ẹ kà mu. Tàbí ẹ lè wá àwòrán kan nínú Ìwé Iṣẹ́-ọnà Ìhìnrere tàbí níbòmíran ní Ibi-Ìkàwé Ìhìnrere. Bákannáà ẹ lè ya àwòrán kan tí ó júwe ohun tí ẹ kọ́.

E ṣe eré-ìtàgé ìtàn kan

Lẹ́hìn kíka ìtàn kan, ẹ pe àwọn ọmọlẹ́bí láti ṣe eré rẹ̀ jáde. Lẹ́hìnnáà, ẹ sọ̀rọ̀ nípa bí ìtàn náà ṣe bá àwọn ohun tí ẹ nní ìriri rẹ̀ mu.

Ẹ jẹ́ ẹni-rírọ̀ ní ilé

Bí ẹ bá ní àwọn ọmọlẹ́bí tí wọn kò fẹ́ láti kópa nínú àṣàrò ìwé-mímọ ẹbí, ẹ wá àwọn ọ̀nà míràn láti sopọ̀ mọ́ wọn. Fún àpẹrẹ, ṣé ẹ lè pín òtítọ́ ayérayé ní àdánidá nínú àwọn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ yín tàbí pín ìwé mímọ́ tó nítumọ̀ ní ọ̀nà kan tí kò dàbí wíwàásù tàbí àpọ̀jù? Àṣàrò ìwé mímọ kò ní láti rí bákannáà nínú gbogbo ẹbí. Àwọn ọmọ kan lè ṣe dáradára sí ṣíṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ ní ọ̀kan sí ọ̀kan. Ẹ gbàdúrà kí ẹ sì tẹ̀lé àwọn ìṣíléti ti Ẹ̀mí.

Àwọn ìpàdé ìgbìmọ̀ Olùkọ́ni fún àwọn òbí. Bí ẹ bá fẹ́ àfikún ìrànlọ́wọ́ nínú ìtiraka yín láti kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ wádìí bóyá wọ́ọ̀dù yín nṣe àwọn ìpàdé ìgbìmọ̀ olùkọ́ni fún àwọn òbí. (wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 17.5). Àwọn ìpàdé wọ̀nyí ni ànfààní fún àwọn òbí láti dámọ̀ràn àti láti kọ́ ẹ̀kọ́ papọ̀ nípa bí wọn ó ti mú ìkọ́ni wọn dárasíi. Wọ́n lè sọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ nínú Ìkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà, àwọn èrò lorí àwọn ojú-ewé wọ̀nyí fún mímú àṣàrò ìwé mímọ́ ẹbí dára síi, àti àwọn àbá kíkọ́ ẹ̀kọ́ àti kíkọ́ni tí a rí ní gbogbo Wá, Tẹ̀lé Mi.