“Ìyípadà-ọkàn Ni Ìlépa Wa,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
Ìyípadà-ọkàn Ni Ìlépa Wa
Ìlépa gbogbo kíkọ́ ẹ̀kọ́ àti kíkọ́ni ní ìhìnrere ni láti mú ìyípadà-ọkàn wa jìnlẹ̀ àti láti ràn wá lọ́wọ́ láti dà bíi ti Jésù Krístì síi. Fún èrèdí yí, nígbàtí a bá nṣe àṣàrò ìhìnrere, a kìí wá ìwífún titun lásán; à nfẹ́ láti di “ẹ̀dá titun kan” (2 Kọ́ríntì 5:17). Èyí túmọ̀ sí gbígbara lé Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì láti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àyípadà ọkàn wa, ìwò wa, ìṣe wa, àti àbínibí wa gan-an.
Ṣùgbọ́n irú kíkọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere tí ó nfún ìgbàgbọ́ wa lókun tí ó sì ndarí sí iṣẹ́ ìyanu ti ìyípadà-ọkàn gbogbo rẹ̀ kìí ṣẹ̀lẹ̀ lẹ́ẹ̀kannáà. Ó kọjá yàrá-ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ sí inú ọkàn àti ilé olúkúlùkù. Ó gba ìtiraka léraléra, lójoojúmọ́ láti ní òye àti láti gbé ìgbé ayé ìhìnrere náà. Ìyípadà-ọkàn tòótọ́ nbèèrè fún ipá ti Ẹ̀mí Mímọ́.
Ẹ̀mí Mímọ́ ntọ́ wa sí òtítọ́ ó sì njẹ́ ẹ̀rí sí wa nípa òtítọ́ náà (wo Jọ̀hánnù 16:13). Ó ntan ìmọ́lẹ̀ sí iyè-inú wa, ó nsọ òye wa di ààyè, ó sì nfi ọwọ́ kan ọkàn wa pẹ̀lú ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, orísun gbogbo òtítọ́. Ẹ̀mí Mímọ́ nsọ ọkàn wa di mímọ́. Ó nmí sí wa pẹ̀lú ìfẹ́-inú láti gbé nípa òtítọ́, Ó sì nsọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí inú wa àwọn ọ̀nà láti ṣe èyí. Nítòótọ́, “Ẹ̀mí Mímọ́ … yíò kọ́ [wa] ní ohun gbogbo” (Jòhánnù 14:26).
Nítorí àwọn èrèdí wọ̀nyí, nínú ìtiraka wa láti gbé, kọ́ ẹ̀kọ́, àti láti kọ́ni ní ìhìnrere, a níláti kọ́kọ́ àti ṣíwájú jùlọ wá jíjẹ́ ojúgbà ti Ẹ̀mí. Ìlépa yi níláti ṣe àkóso àwọn yíyàn wa kí ó sì ṣe atọ́nà àwọn èrò àti ìṣe wa. A níláti lépa ohunkóhùn tí ó npe ipá ti Ẹ̀mí kí a sì ṣe ìkọ̀sílẹ̀ ohunkóhun tí ó bá nlé ipá náà kúrò—nítorí a mọ̀ pé bí a bá lè jẹ́ kíkàyẹ ní wíwà níwájú Ẹmí Mímọ́, a lè jẹ́ kíkàyẹ bákannáà láti gbé níwájú Baba Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì.