Come, Follow Me
Lílo Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ


“Lílo Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

tọkọtaya nṣe àṣàrò papọ̀

Lílo Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ

Tani Ohun-èlò Yí Wà Fún?

Wá, Tẹ̀lé Mi wà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ láti inú àwọn ìwé mímọ́—ní olúkúlùkù, bí ẹbí, àti nínú kíláàsì Ìjọ. Bí ẹ kò bá tíì ṣe àṣàrò ìwé mímọ́ déédé ní àtẹ̀hìnwá, ohun-èlò yí lè ràn yín lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀. Bí ẹ bá ti ní ìwà rere ti àṣàrò ìwé mímọ tẹ́lẹ̀, ohun-èlò yí lè ràn yín lọ́wọ́ láti ní àwọn ìrírí tó nítumọ̀ síi.

Àwọn Olúkúlùkù àti Ẹbí ní Ilé

Ibi tó yẹ láti kọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere ni ilé. Àwọn Olùkọ́ ní ìjọ lè ṣe àtìlẹhìn fún yín, ẹ sì lè gba ìyànjú láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ wọ́ọ̀dù míràn. Ṣùgbọ́n láti yè ní ti ẹ̀mí, ẹ̀yin àti ẹbí yín nílò ìṣìkẹ́ ojojúmọ́ láti inú “ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run” (Mórónì 6:4; bákannáà wo Russell M. Nelson, “Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2018, 6–8).

Ẹ lo ohun-èlò yí ní eyikeyi ọ̀nà tí ó jẹ́ ìrànlọ́wọ́ sí yín. Àwọn ìlànà fi àwọn òtítọ́ ayérayé kan tí a rí nínú Májẹ̀mú Láéláé hàn. Bákannáà wọ́n dá àbá àwọn èrò àti iṣẹ́ ṣíṣe láti ràn yín lọ́wọ́ ṣe àṣàrò ìwé mímọ́ ní olúkúlùkù, pẹ̀lú ẹbí yín, tàbí àwọn ọ̀rẹ́, Bí ẹ ti nṣe àṣàrò, ẹ tẹ̀lé Ẹ̀mí atọ́nà láti wá àwọn òtítọ́ ayérayé tí ó jẹ́ onítumọ̀ sí yín. Ẹ wá àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, kí ẹ sì tẹ̀lé àwọn ìṣílétí tí ẹ gbà.

Àwọn olùkọ́ àti àwọn Akẹkọ ní Ilé ìjọsìn

Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ jẹ́ ohun èlò fún àwọn kíláàsì Ọjọ́ Ìsinmi nínú Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, Ilé Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi àwọn ọ̀dọ́ àti àgbà, Awọn kíláàsì Ọ̀dọ́mọbìnrin, àti àwọn ìpadé iyejú Oyè Àlùfáà Árọ́nì. Bí ẹ bá nkọ́ni nínú eyikeyi àwọn àgbékalẹ̀ wọ̀nyí, a gbà yín níyànjú láti lo àwọn ìlànà inú ohun-èlò yí fún àṣàrò ti araẹni yín àti bí ẹ ṣe nmúrasílẹ̀ láti kọ́ni. Ẹ bẹ̀rẹ̀ nípa níní àwọn ìrírí ti ara yín nínú àwọn ìwé mímọ́. Ìmúrasílẹ̀ yín tó ṣe pàtàkì jùlọ yíò ṣẹlẹ̀ bí ẹ ṣe nwákiri nínú àwọn ìwé mímọ́ tí ẹ sì nwá ìmísí Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ wá àwọn òtítọ́ ayérayé tí ó nràn yín lọ́wọ́ láti dàbí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì síi. Wá, Tẹ̀lé Mi lè ràn yín lọ́wọ́ láti dá àwọn kan mọ̀ lára àwọn òtítọ́ wọ̀nyí kí ẹ sì ní òye àkóónúti àwọn ìwé mímọ́ náà.

Ẹ níi nínú pé kíkọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere, ní dídárajùlọ rẹ̀, jẹ́ ti ààrin gbùngbùn ilé tí Ìjọ sì nṣe àtìlẹhìn. Ní ọ̀rọ̀ míràn, kókó ojúṣe yín ni láti ti àwọn ènìyàn tí ẹ̀ nkọ́ lẹ́hìn nínú ìtiraka wọn láti kọ́ ẹ̀kọ́ àti láti gbé ìgbé ayé ìhìnrere ní ilé. Ẹ máṣe dààmú nípa níní àkóónú àrà ọ̀tọ̀ láti pèsè fún wọn nínú kíláàsì. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ fún wọn ní àwọn ànfààní láti pín àwọn ìrírí wọn, èrò, àti ìbèèrè nípa àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ tí wọ́n ti kà ní ilé. Ẹ pè wọ́n láti pín àwọn òtítọ́ ayérayé tí wọ́n ti rí. Èyí ṣe pàtàkì ju píparí iye ohun-èlò kan pàtó.

Àwọn Kíláàsì Ilé Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi ti Àwọn Ọ̀dọ́ àti Àgbà

Kókó èrèdí kan tí a fi nkórajọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi ni láti ṣe àtìlẹhìn àti láti gba ara wa níyànjú bí a ti ntiraka láti tẹ̀lé Jésù Krístì. Ọ̀nà ìrọ̀rùn kan láti ṣe èyí ni láti bèèrè ìbéèrè kan bíi “Kínni Ẹmí Mímọ́ kọ́ yín ní ọ̀sẹ̀ yí bí ẹ ti nṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́?” Àwọn ìdáhùn sí ìbèèrè náà lè darí sí àwọn ìsọ̀rọ̀ tó nítumọ̀ tí yíò mú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ dàgbà.

Lẹ́hìnnáà ẹ lè pe ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀ tó dálé àwọn àbá àṣàrò nínú Wá, Tẹ̀lé Mi. Fún àpẹrẹ, èrò àṣàrò kan lè dá àbá wíwá inú Ìsàíàh 53, ní wíwá àwọ̀n ọ̀rọ̀ tó júwe iṣẹ́́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà. Ẹ lè ní kí àwọn ọmọ kíláàsì pín èyíkéyìí àwọn èrò tàbí ìmọ̀lára tí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe bíi ìmísí fún wọn. Tàbí ẹ lè lo àkokò díẹ̀ ní wíwá àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí bí kíláàsì kan.

Àwọn Kíláàsì Iyejù Oyè àlùfáà Árọ́nì àti àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin

Nígbàtí àwọn kíláàsì Iyejù Oyè àlùfáà Árọ́nì àti àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin bá npàdé ní àwọn Ọjọ́ Ìsinmi, èrèdí wọn nyàtọ̀ díẹ̀ sí kíláàsì Ilé Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi. Ní àfikún sí ríran ara wọn lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere Jésù Krístì, àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí bákannáà npàdé láti dámọ̀ràn papọ̀ nípa ṣíṣe àṣeyọrí iṣẹ́ ìgbàlà àti Ìgbéga (wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 1.2). Wọ́n nṣe èyí pẹ̀lú ìdarí àwọn àjọ ààrẹ kíláàsì àti àwọn iyejú.

Fún èrèdí yí, ìpàdé iyejú tàbí kílásì kọ̀ọ̀kan níláti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ àjọ ààrẹ iyejú tàbí kílásì tí ó ndarí ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìtiraka, fún àpẹrẹ, láti gbé ìgbé ayé íhìnrere, ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn nínú àìní, pín ìhìnrere, tàbí kópa nínú iṣẹ́ tẹ́mpìlì àti ìtàn ẹbí.

Lẹ́hìn àkokò fún dídámọ̀ràn pápọ̀ yí, olùkọ́ni kan ó darí kíláàsì tàbí iyejú nínú kíkọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere papọ̀. Àwọn olùdarí àwọn àgbà tàbí àwọn ọmọ kíláàsì tàbí iyejú ni a lè yàn láti kọ́ni. Àjọ ààrẹ kíláàsì tàbí ti iyejú, ní dídámọ̀ràn pẹ̀lú àwọn olùdarí àwọn àgbà, láti ṣe àwọn yíyànsíṣẹ́ wọ̀nyí.

Àwọn ènìyàn tí a yàn láti kọ́ni níláti múrasílẹ̀ nípa lilo àwọn àbá kíkọ́ ẹ̀kọ́ nínú ìlànà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti Wá, Tẹ̀lé Mi. Nínú ìlànà kọ̀ọ̀kan, àmì yí àmì sẹ́mínárì fi iṣẹ́ ṣíṣe kan hàn tí ó ní í ṣe nípàtàkì sí àwọn ọ̀dọ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èyíkéyìí àwọn àbá inú ìlànà náà ni a lè lò bíi iṣẹ́ ṣíṣé ẹ̀kọ́ kíkọ́ fún àwọn ọ̀dọ́.

Fún àpẹrẹ kan ti ìtòsílẹ̀ ìṣe fún iyejú àti àwọn ìpàdé kílásì, wo Àfikún D.

Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀

Ìmúrasílẹ̀ yín láti kọ́ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ nbẹ̀rẹ̀ bí ẹ ti nṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ ní ti araẹni àti pẹ̀lú ẹbí yín. Bí ẹ ti nṣeé, ẹ ṣí sílẹ̀ sí àwọn ìtẹ̀mọ́ra àti ìwòye ti ẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ nípa àwọn ọmọ inú kíláàsì Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ yín. Ẹ máà gbàdúrà, Ẹ̀mí sì lè mí síi yín pẹ̀lú àwọn èrò láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì.

Bí ẹ ti nmúrasílẹ̀ láti kọ́ni, ẹ lè jèrè àfikun ìmísí nípa wíwá inú àwọn èrò ìkọ́ni nínú Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ. Ìlànà kọ̀ọ̀kan nínú ohun-èlò yí ní ìpín kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé.” Ẹ ronú nípa àwọn èrò wọ̀nyí bí a ti dá àbá láti wú ìmísí yín jáde. Ẹ mọ àwọn ọmọ inú kíláàsì Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ yín—ẹ ó sì máa mọ̀ wọ́n àní ní dáradára síi bi ẹ ti nba wọn ṣe nínú kíláàsì. Ọlọ́run mọ̀ wọ́n pẹ̀lú, Òun yíò sì mí síi yín pẹ̀lú àwọn ọ̀nà dídára jùlọ láti kọ́ àti láti bùkún wọn.

Ó ṣeéṣe pé àwọn ọmọ kíláàsì yín yíò ti ṣe àwọn kan lára àwọn iṣẹ́ ṣíṣe nínú Wá, Tẹ̀lé Mi pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn. Èyí Dára. Àtúnsọ dára. Ẹ gbèrò pípe àwọn ọmọ láti ṣe àbápín ohun tí wọ́n kọ́ ní ilé pẹ̀lú ara wọn—bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ ẹ níláti ṣe èto àwọn ọ̀nà fún àwọn ọmọ láti kópa bákannáà àní bí wọ́n kò bá tilẹ̀ kọ́ ẹ̀kọ́ ní ilé. Àwọn ọmọ nkọ́ àwọn òtítọ́ ìhìnrere dáradára síi nígbàtí a bá kọ́ àwọn òtítọ́ wọ̀nyí léreléra nípasẹ̀ onírúurú àwọn iṣẹ́ ṣíṣe. Bí ẹ bá ríi pé iṣẹ́ ṣíṣe fún ẹ̀kọ́ kíkọ́ kan jẹ́ dáradára fún àwọn ọmọ, ẹ gbèrò àtúnṣe rẹ̀, nípàtàkì bí ẹ bá nkọ́ àwọn ọmọdé kékeré. Ẹ lè ṣe àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ ṣíṣe kan bákannáà láti inú ẹ̀kọ́ kan tó ti kọjá.

Ní àwọn oṣù tí ó ní Ọjọ́ Ìsinmi márun, àwọn olùkọ́ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ni a gba níyànjú láti rọ́pò ìlàsílẹ̀ ìlànà Wá, Tẹ̀lé Mi ní Ọjọ́ Ìsinmi karun pẹ̀lú ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn iṣẹ́ ṣíṣe fún ẹ̀kọ́ kíkọ́ nínú “Àfikún B: Fún Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀—Mímúra àwọn Ọmọ Sílẹ̀ fún Ìgbé-ayé ní Ipa-ọ̀nà ti Májẹ̀mú Ọlọ́run.”