Làìhónà
Rìn pẹ̀lú Mi
Làìhónà Oṣù Kínní 2026


Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kínní 2026

Rìn pẹ̀lú Mi

Àkórí Ọ̀dọ́ 2026 yíò rán yín létí pénígbàtí ẹ bá dúró súnmọ́ Ọlọ́run típẹ́típẹ́, Òun yíò rìn pẹ̀lú yín—nígbàgbogbo.

Àjọ Ààrẹ Gbogbogbò Àwọn Ọ̀dọ́mọbìrin

Láti òsìn sí ọ̀tún: Tamara W. Runia, Olùdámọ̀ràn Kínní; Emily Belle Freeman, Ààrẹ; àti Andrea Muñoz Spannaus, Olùdámọ̀ràn Kejì

Ẹ kò dánìkanwà

Njẹ́ a ti ní kí ẹ ṣe ohun kan tí ẹ kò rò pé ẹ lè ṣe rí? Bóyá ẹ kò ní ìmọ̀lára okun tó tàbí jáfáfá tó, tàbí ẹ̀ ndàmú pé àwọn ẹlòmíràn yíò rẹrin sí yín ní àti pé kí wọ́n sì ṣọ̀fíntótó yín. Bí ẹ bá ti ní ìmọ̀lára ní ọ̀nà yí rí, ẹ kò dánìkanwà.

Ẹgbẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́hìn, ọkùnrin kan wà tí a npe orúkọ rẹ̀ ní Énọ́kù. Ọlọ́run ní kí Énọ́kù wàásù ìrònúpìwàdà sí àwọn ènìyàn—àwọn kan lára àwọn tí ó burú jùlọ tí ayé ti rí rí.

Énọ́kù kò ronú pé òun lè ṣe é. Ó wí fún Ọlọ́run pé òun ti kéré jù, kò sí ẹni tí ó fẹ́ràn òun, òun sì ní “ẹ̀mí ìlọ́ra ní ọ̀rọ̀ sísọ” (wo Mósè 6:31).

Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún Énọ́kù ní ìlérí kan. Ó wí fún ọkùnrin tí ó nbẹ̀rù náà, “Jáde lọ kí o sì ṣe bí èmi ti pàṣẹ fún ọ” àti pé “àwọn òkè yíò sì sá níwájú rẹ̀, àti gbogbo odò yíò yà kúrò ní ipa ọ̀nà wọn; ìwọ yíò sì gbé nínú mi, àti èmi nínú rẹ; nítorínáà rìn pẹ̀lú mi” (Mósè 6:32, 34).

“Rìn pẹ̀lú mi.” Irú ìfipé ẹlẹ́wà, ìrọ̀rùn.

Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Énọ́kù pé bí òun bá ní ìgboyà tó láti bẹ̀rẹ̀, nígbànáà Ọlọ́run yíò wà pẹ̀lú rẹ ní gbogbo ìgbésẹ̀ ọ̀nà náà. Ọlọ́run yíò mú Énọ́kù ní agbára yíò sì fun un lókun láti ṣe púpọ̀ síi ó sì ràn án lọ́wọ́ láti dà bí òun ti lè rò láé.

Ọ̀kan lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orúkọ Olùgbàlà ni Èmmánúẹ́lì, tàbí “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa” (Máttéù 1:23). Ó wà ní orúkọ Olúwa àti ìwà ẹ̀dá láti rìn pẹ̀lú wa. Yíyàn náà jẹ́ tiwa—a ó rìn pẹ̀lú Rẹ̀, pẹ̀lú?

Ní òde òní, à nwo Énọ́kù bí ọkùnrin ìgbàgbọ́ kan àti wòlíì nlá kan àti olórí. Ṣùgbọ́n ṣíwájú wòlíì, níbẹ̀ ni Énọ́kù ọ̀dọ́ kékeré wà tí ó ṣiyèméjì ararẹ̀ ṣùgbọ́n síbẹ̀ ó yàn láti rìn pẹ̀lú Ọlọ́run.

Nígbàtí ayé bá le, nígbàtí ẹ kò bá ní ìmọ̀lára bíi pé ẹ kò tó, ẹ rántí ìlérí Olúwa sí Énọ́kù, àti síi yín. Òun yíò rìn pẹ̀lú yín. Òun kò ní fi yín sílẹ̀ ní dídánìkanwà, kìí ṣe fún ìgbésẹ̀ ẹyọ kanṣoṣo.

Èmmánúẹ́lì. Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa. Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín!

Àjọ Ààrẹ Gbogbogbò Àwọn Ọ̀dọ́mọbìrin

Àjọ Ààrẹ Gbogbogbò Àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin

Láti òsì sí ọ̀tún: David J. Wunderli, Olùdámọ̀ràn Ìkínní; Timothy L. Farnes, Ààrẹ; àti Sean R. Dixon, Olùdámọ̀ràn Kejì

Pẹ̀lú Ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, Ẹ Le Ṣe Àwọn Ohun Gbogbo

Bíiti ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin, Olúwa ní kí Énọ́kù mú àwọn ojúṣe pàtàkì oyè àlùfáà ṣẹ. Iṣẹ́ rẹ̀ ni láti wàásù ìrònúpìwàdà sí àwọn ènìyàn búburú. Énọ́kù fi iyèméjì rẹ̀ hàn. “Bí [èmi] ṣe jẹ́ ọ̀dọ́,” ni ó wí. “Gbogbo ènìyàn kórìíra mi … èmi sì ní ẹ̀mí ìlọ́ra ní ọ̀rọ̀ sísọ; nítorí kíni èmi ha ṣe jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ?” (Mósè 6:31).

Olúwa fèsì pẹ̀lú agbára àti ìtúndánilójú. “Jáde lọ kí ó sì ṣe bí mo ti pàṣẹ fún ọ. … La ẹnu rẹ, a ó sì kún un … . Ẹ̀mi mi wà ní orí rẹ̀ … ; àwọn òkè yíò sì sá níwájú rẹ … ; nítorínáà rìn pẹ̀lú mi ” (Mósè 6:32, 34).

Énọ́kù kọ́ pé nígbàtí Olúwa bá fún wa ní iṣẹ́ kan, a kò ní dánìkan kojú rẹ̀. Nígbàtí a bá dá tí a sì pa májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Krístì, a ó rìn pẹ̀lú Rẹ̀ kí a sì pín nínú agbára Rẹ̀—a ó di àwọn ohun èlò nínú ọwọ́ Rẹ̀.

Bíiti Énọ́kù, ẹ ní kókó ojúṣe: ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, sísìn ní tẹ́mpìlì, ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, ṣíṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́, gbígbé òṣùwọ̀n ìhìnrere, ríronúpìwàdà, mímúrasílẹ̀ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti púpọ̀ síi. O lè dàbí ìbonimọ́lẹ̀. Ẹ lèní ìmọ̀lára àìtó. Èyí Dára. Kìí ṣe nípa dídánìkan ṣe é. Ó jẹ́ nípa yíyan òní—ọjọ́ yí àti gbogbo ọjọ́—láti rìn pẹ̀lú Ọlọ́run.

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, a le ṣe àwọn ohun gbogbo. Òun yíò fún wa lókun, dáríjì, yíò sì jẹ́kí ẹ lè ṣe kọjá agbára ìlèṣe àbínibí yín. Ó fẹ́ràn yín! Gẹ́gẹ́bí Àjọ Ààrẹ Gbogbogbò Àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin, a fẹ́ràn yín a sì nwo iwájú láti darapọ̀ mọ́ yín ní wíwá ìmísí àkórí 2026: “Rìn pẹ̀lú Mi.”

Àjọ Ààrẹ Gbogbogbò Àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin