“Alabápin ti Iwà-ẹ̀dá Atọ̀runwá,” Làìhónà, Oṣù Kínní 2026.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kínní 2026
Alabápin ti Iwà-ẹ̀dá Atọ̀runwá
(2 Pétérù 1:4)
Ìmọ̀ ètò ìgbàlà npèsè ìrísí iyebíye, tí ó nṣìkẹ́ àwọn ayọ̀ wa, tí ó sì nmú wa borí àwọn ìpènija àti ìpọ́njú wa.
Krístì Pè àwọn Ọmọẹ̀hìn Méjì, láti ọwọ́ Gary E. Smith
Àpóstélì Pétérù rán wa létí pé fún àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì, agbára Rẹ̀ “bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí íṣe ti ìyè àti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹnití ó pè wá nípa ògo àti ọlánlá rẹ̀:
“Nípa èyítí ó ti fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó sì ṣe iyebíye: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin kí ó lè di alábapín nínú ìwà Ọlọ́run” (2 Pétérù 1:3–4; àfikún àtẹnumọ́).
Ètò Baba Ọ̀run ṣe àpèjúwe àwọn òtítọ́ tí ó tóbi púpọ̀ àti ìyebíye àti àwọn ìlérí tí ó túmọ̀ ìdánimọ̀ àti èrèdí ayérayé wa.
Bí a ti ṣàlàyé nínú “Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àgbáyé”:
“Gbogbo ẹlẹ́ran-ara—ọkùnrin àti obìnrin—ni a dá ní àwòrán Ọlọ́run. Ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ àyànfẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin ẹ̀mí ti àwọn òbí Ọ̀run, àti pé, bí ó ti rí bẹ́ẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìwà-àbínibí àti àyànmọ́ tọ̀run. …
“Ní ìṣaájú-ayé ikú, àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin ẹ̀mí mọ Ọlọ́run, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run gẹ́gẹ́bí Baba Ayérayé wọn, wọ́n sì gba ètò Rẹ̀ nípa èyí tí àwọn ọmọ Rẹ̀ lè fi gba àgọ́ ara kí wọ́n sì jèrè ìrírí orí ilẹ̀ ayé láti tẹ̀ síwájú sí jíjẹ́-pípé àti nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín mọ́ kádàrá tọ́run gẹ́gẹ́bí ajogún ìyè ayérayé.”
Baba Ọ̀run ṣe ìlérí fún àwọn ọmọ Rẹ̀ pé bí wọ́n bá tẹ̀lé àwọn ìlànà ti ètò Rẹ̀ àti àpẹrẹ ti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, pa àwọn òfin mọ́, tí a sì forítì nínú ìgbàgbọ́ dé òpin, wọn “yíò ní ìyè ayérayé, ẹ̀bùn èyí tí ó ga jùlọ nínú àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 14:7).
Iṣẹ́ Ọlọ́run ni à nkọjúsí lórí ìlọsíwájú àti ìgbéga àwọn ọmọ Rẹ̀. Gbogbo ètò Rẹ̀ ni a yà láti bùkún àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Rẹ̀ nítorí “àwọn ọkàn ṣe iyebíye ní ojú [Rẹ̀]” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 18:10).
Ètò ti Baba Náà
Ní ìgbìmọ̀ ìṣaájú-ayé, Baba Ọ̀run gbé ètò Rẹ̀ kalẹ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀mí Rẹ̀ fún ìlọsíwájú àti ìdùnnú ayérayé wọn.
“Àwa ó ṣe ayé kan níbi-èyí tí àwọn yí lè gbé;
“A ó sì dán wọn wò ní báyí,” láti ríi bóyá wọn yíò ṣe gbogbo ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run wọn yíó paláṣẹ fún wọn;
“Àti pé àwọn tí ó bá pa ohun ìní wọn àkọ́kọ́ mọ́ yíò ní àfikún lórí wọn; àwọn tí kò bá sì pa ohun ìní wọn àkọ́kọ́ wọn mọ́ kì yíò ní ògo nínú ìjọba kannáà pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ó pa ohun ìní àkọ́kọ́ wọn mọ́; àti pé àwọn tí ó pa ohun ìní wọn kejì mọ́ yíò ní àfikún ògo lórí wọn títíláé àti láéláé
“Olúwa sì wípé: Tàni Èmi ó rán? Ọkàn sì dáhùn bíi Ọmọ Ènìyàn: Èmi nìyí, rán mi. Òmíràn sì dáhùn ó sì wípé: Èmi nìyí, rán mi. Olúwa sì wípé: Èmi yíò rán ẹni àkọ́kọ́.
“Ẹnikejì sì bínú, kò sì pa ipò àkọ́kọ́ rẹ̀ mọ́; àti, ní ọjọ́ náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì tẹ̀lé e” (Ábráhámù 3:24–28).
Ẹ kíyèsi pé ètò kanṣoṣo ni a gbékalẹ̀ nínú ìgbìmọ̀ ìṣaájú-ayé—ètò Baba náà. Baba wa Ọ̀run ko fi ìbèèrè náà, “Kíni a ó ṣe?” Òun kò wá ìfisí, wá ìyìn, tàbí bèèrè ìgbèèrò. Ṣùgbọ́n, Ó gbé àwọn kókó ohun èlò ti ètò Rẹ̀ sílẹ̀ ó sì bèèrè pé, “Tani èmi ó rán?” Àkójá ti ìbèèrè Rẹ̀ dojúkọ ẹnití a níláti rán láti ṣe àwọn ọ̀ràn àti ipò ètò Rẹ̀.
Àwọn àbájáde ti ọ̀tẹ̀ ọ̀tá bákannáà ni a ṣe àpèjúwe nínú àwọn ìwé mímọ́.
“Nísisìyí, nítorí pé Sátánì ṣe ọ̀tẹ́ sí mi, àti tí ó wá ọ̀nà láti ṣe ìparun agbara ènìyàn láti yàn, èyítí èmi … ti fi fún un, àti bákannáà, pé kí èmi kí ó lè fi agbára tèmi fún un … , mo mú kí a jù ú sí ìsàlẹ̀;
“Òun sì dì Sátánì, … èṣù, baba gbogbo àwọn èké, láti tànjẹ àti láti mú àwọn ènìyàn fójú, àti láti darí wọn sí ìgbèkùn bí ìfẹ́ inú rẹ̀, àní bí iye àwọn tí wọn kò fetísílẹ̀ sí ohùn mi” (Mósè 4:3–4; àfikún àtẹnumọ́).
Lúsíférì kò gbé ètò kan tí a dìbò fún sílẹ̀ nípasẹ̀ púpọ̀jù àwọn olùkópa nínú ìgbìmọ̀ ìṣaájú-ayé. Òun kì íṣe ẹni aláàánú tí ó sọ ìbò kan nù. Ó ṣọ̀tẹ̀! Ìgbéraga, ìyájú, àti ìmọtara-ẹni-nìkan mú ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ní ìlòdì sí ètò ti Baba.
Ètò ti Baba àti Ìhìnrere Olùgbàlà
Ètò náà ṣe àpèjúwe àwọn iṣẹ́ Baba àti Ọmọ tí ó fún gbogbo ènìyànní àwọn ìbùkún ti ìyè ayérayé ní àrọ́wọ́tó.
Ìhìnrere Jésù Krístì wà pẹ̀lú ọ̀nà nípa èyí tí a fi ngbà àwọn ìbùkún ìlérí nínú ètò Ọlọ́run, àní ẹ̀kọ́, àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́, àwọn ìlànà, àti àwọn ọkùnrin àti obìnrin májẹ̀mú gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ kí wọ́n sì tẹ̀lé. “Kò sí orúkọ míràn tí a fi fúnni lábẹ́ ọ̀run àfi ti Jésù Krístì yí … nípa èyí tí a ó fi gba ènìyàn là” (2 Néfì 25:20). Nítòótọ́, Olúwa Jésù Krístì ni “ọ̀nà, òtítọ́, ati ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le wá sí ọ̀dọ̀ Baba, bíkòṣe nípasẹ̀ [Rẹ̀]” (Jòhánnù 14:6; àfikún àtẹnumọ́).
Ààrẹ Russell M. Nelson ṣàlàyé:
“Ètò náà bèèrè fún Ìṣẹ̀dá, àti pé èyí ní àbábọ̀ bèèrè fún méjèèjì Ìṣubú àti Ètùtù. Ìwọ̀nyí ni àwọn èròjà ìpìlẹ̀ mẹ́ta nípa ètò náà. Ìṣẹ̀dá ti ayé rere wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ayé ikú àti ikú wá sínú ayé nípasẹ̀ Ìṣubú ti Ádámù [wo 2 Néfìi 2:25; Mósè 6:48]. Ayé àìkú àti ìlèṣe ìyè ayérayé ni a pèsè nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì [wo 2 Nephi 2:21–28]. …
“… A wá sí ilẹ̀ ayé fún àkokò ìgbà ránpẹ́ kan, foríti àwọn ìdánwò àti àdánwò wa, kí ẹ sì múrasílẹ̀ láti tẹ̀síwájú àti sókè sí ìpadàwálé ológo [wo Orin Dáfídì 116:15; Álmà 42:8]. Àwọn èrò àti ìṣe wa nígbàtí a wà [nínú ayé ikú] yíò jẹ́ elérò síi dájúdájú bí a bá ní òye ètò Ọlọ́run tí a sì jẹ́ ọlọ́pẹ́ fún tí a sì gbọ́ran sí àwọn òfin Rẹ̀ [wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 59:20–21].”
Àwọn àkọlé Ètò nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì
A kọ́ àwọn òtítọ́ pàtàkì nípa dídánimọ̀ àti ṣíṣe àṣàrò ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àkọlé yíyàtọ̀ fún ètò ti Baba nínú Ìwé Ti Mọ́mọ́nì: Ẹ̀rí Míràn ti Jésù Krístì. Fún àpẹrẹ, gbèrò títẹ̀lé àwọn àkọlé tí a yàn wọ̀nyí:
“Ètò àánú ti Aṣẹ̀dá Nlá” (2 Néfì 9:6).
“Ètò Ọlọ́run wa” (2 Néfì 9:13).
“Ètò ìgbàlà” (Járọ́mù 1:2; Álmà 24:14).
“Ètò ìràpadà” (Álmà 12:25, 26, 30, 32, 33; 42:11, 13).
“Ètò ìmúpadàbọ̀sípò” (Álmà 41:2).
“Ètò ìdùnnú” (Álmà 42:16).
“Ètò àánú nlá” (Álmà 42:31).
Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àkọlé wọ̀nyí nrànwálọ́wọ́ láti ní òye kedere àwọn ìlérí iyebíye síi nípa ètò ti Baba náà kí ó sì ṣìkẹ́ ìrísí wa nípa àwọn èrèdí àti níní ìtúmọ̀ ìgbé ayé ikú wa.
Ní pàtàkì, lílò àkọlé lemọ́lemọ́ jùlọ fún ètò Ọlọ́run nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì dojúkọ ìràpadà tí ó ṣeéṣe nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì.
Álmà kéde, “Bí kò bá ṣe ti ìlànà ìràpadà, èyítí a ti fi lélẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, kì bá ti sí àjĩnde òkú; ṣùgbọ́n ìlànà ìràpadà kan wà tí a fi lélẹ̀, èyítí yíò mú àjĩnde kúrò nínú ipò òkú wá sí ìmúṣẹ” (Álmà 12:25).
Bákannáà ó kìlọ̀ pé, “Ẹ bẹ̀rẹ̀sí gbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, pé yíó wá láti ra àwọn ènìyàn rẹ padà, àti pé yíò jìyà yíò sì kú láti ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn; àti pé yíò tún jínde kúrò nínú ipò òkú, èyítí yíò mú àjínde náà ṣẹ, pé gbogbo ènìyàn yíò dúró níwájú rẹ̀, láti jẹ́ dídá lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹhìn àti ti ìdájọ́, ní ìbámu sí àwọn iṣẹ́ wọn” (Álmà 33:22).
Ọ̀nà náà Ni A Múrasílẹ̀
Àwọn ẹ̀mí wa níláti wúsókè pẹ̀lú ìmoore bí a ṣe ngbèrò ètò ìgbàlà, ìràpadà, ìmúpadàbòsípò, àánú, àti ìdùnnú nlá ti Ọlọ́run. Ìmọ̀ ètò ìgbàlà Rẹ̀ npèsè ìrísí iyebíye, tí ó nṣìkẹ́ àwọn ayọ̀ wa, tí ó sì nfún wa lókun láti borí àwọn ìpènija àti ìpọ́njú wa.
Baba Ọ̀run ntara fún wa láti padà sí ilé sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó npe ó sì nṣe ìlérí àwọn ìbùkún, ṣùgbọ́n Òun kò ní mú wa nípá, yíwalọ́kànpadà, tàbí díwalọ́wọ́ láti lo àgbára ìwà tí Ó fi fún wa. A gbọ́dọ̀ ṣe ìṣe kí a sì yàn láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nípa títẹ̀lé àpẹrẹ ti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀.
Ọwọ́ Rẹ̀ Ṣì Nà Síta Síbẹ̀, láti ọwọ́ Elizabeth Thayer
“Ọ̀nà náà ni a múrasílẹ̀, bí a ó bá sì wòó a lè gbé títíláé” (Álmà 37:46; àfikún àtẹ̀numọ́).
Mo fi pẹ̀lú ayọ jẹ́ ẹ̀rí pé Baba Ọ̀run ni olùpilẹ̀ṣẹ̀ ètò àtọ̀runwá fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Jésù Krístì ni Olùràpadà Olùgbàlà wa. Àti bí ọ̀kan lára àwọn Àpóstélì ọjọ́-ìkẹhìn, mo jẹ́ ẹ̀rí pé nítòótọ́ Òun ni “ọ̀nà náà, òtítọ́, àti ìyè” (Jòhánnù 14:6; àfikún àtẹnumọ́).
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kínní 2026. Yoruba. 19932 779